ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 2/1 ojú ìwé 8-11
  • Ẹ̀kọ́ Wo Lo Lè Rí Kọ́ Lára Àwọn Ọmọdé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Wo Lo Lè Rí Kọ́ Lára Àwọn Ọmọdé?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Bíi Tàwọn Ọmọdé
  • Wọ́n Rọrùn Láti Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́, Wọ́n sì Ń Fọkàn Tánni
  • “Ìkókó Ní Ti Ìwà Búburú”
  • Ẹwà Náà Padà Wá
  • Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Jésù Wá Àyè Gbọ́ ti Àwọn Ọmọdé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ogun Iyebíye Làwọn Ọmọ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 2/1 ojú ìwé 8-11

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Lè Rí Kọ́ Lára Àwọn Ọmọdé?

“Ò Ń ṣe bí ọmọdé!” Tẹ́nì kan bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí sí wa, ó ṣeé ṣe kó bí wa nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú èèyàn máa ń dùn téèyàn bá rí àwọn ọmọdé, ó ṣe kedere pé wọn ò ní irú ọgbọ́n àti ìrírí táwọn àgbà sábà máa ń ní.—Jóòbù 12:12.

Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà kan, pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà.” (Mátíù 18:3) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Àwọn ànímọ́ wo làwọn ọmọdé ní tó yẹ káwọn àgbàlagbà fara wé?

Bá A Ṣe Lè Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Bíi Tàwọn Ọmọdé

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ tó mú kí Jésù sọ gbólóhùn yẹn. Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé ìlú Kápánáúmù lẹ́yìn tí wọ́n ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Kí ni ẹ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?” Àmọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn náà kò lè fèsì, torí pé wọ́n ń bára wọn jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù láàárín wọn. Níkẹyìn, wọ́n fìgboyà béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Ní ti tòótọ́, ta ni ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run?”—Máàkù 9:33, 34; Mátíù 18:1.

Ó lè yani lẹ́nu pé lẹ́yìn táwọn ọmọlẹ́yìn yìí ti wà pẹ̀lú Jésù fún ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún mẹ́ta, wọ́n ṣì ń bára wọn jiyàn nípa ipò. Àmọ́ o, inú ẹ̀sìn àwọn Júù ni wọ́n dàgbà sí, ẹ̀sìn yìí sì ka irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ sí pàtàkì gan-an. Dájúdájú, inú ẹ̀sìn tí wọ́n ti wá yẹn, pa pọ̀ pẹ̀lú àìpé ẹ̀dá, ló nípa lórí ìrònú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà.

Jésù wá jókòó, ó pe àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́, kí ó jẹ́ ẹni ìkẹyìn nínú gbogbo yín àti òjíṣẹ́ gbogbo yín.” (Máàkù 9:35) Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn yìí yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Ohun tí Jésù sọ yìí yàtọ̀ pátápátá sí èrò àwọn Júù nípa ẹni tó tóbi jù lọ! Lẹ́yìn náà ni Jésù wá pe ọmọ kékeré kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó gbá ọmọ náà mọ́ra, ó wá tẹnu mọ́ kókó tó fẹ́ kí wọ́n lóye rẹ̀ yìí, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Láìjẹ́ pé ẹ yí padà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké, ẹ kì yóò wọ ìjọba ọ̀run lọ́nàkọnà. Nítorí náà, ẹnì yòówù tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú ìjọba ọ̀run.”—Mátíù 18:3, 4.

Ẹ̀kọ́ tó lágbára nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lèyí mà jẹ́ o! Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Àwọn géńdé ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà dúró yí ọmọ kékeré kan ká. Ojú wọn fi hàn pé wọ́n ń ro àròjinlẹ̀. Àwọn ọkùnrin yìí tẹjú mọ́ ọmọ náà. Ó dájú pé ẹ̀rù ti ní láti ba ọmọ yẹn, síbẹ̀ ó fọkàn tán wọn! Kò jowú ẹnikẹ́ni, kò sì di ẹnì kankan sínú! Ó ní ìtẹríba, kò sì rò pé òun jẹ́ nǹkan kan! Bẹ́ẹ̀ ni, ọmọ kékeré yìí fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run hàn lọ́nà tó wuni gan-an.

Ẹ̀kọ́ tí Jésù fẹ́ ká kọ́ níbí yìí ṣe kedere. Ẹ̀kọ́ náà ni pé ká tó lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo wa gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bíi tàwọn ọmọdé. Nínú ètò Jèhófà táwọn Kristẹni ti ń ṣe bí ìdílé kan ṣoṣo, kò sáyè fún gbọ́nmi-si omi-ò-to tàbí ìgbéraga tí ẹ̀mí ìbara-ẹni-díje máa ń fà. (Gálátíà 5:26) Àní, irú àwọn ìwà yìí gan-an ló sún Sátánì Èṣù láti ta ko Ọlọ́run. Abájọ tí Jèhófà fi kórìíra àwọn ìwà náà!—Òwe 8:13.

Ńṣe làwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wá bí wọ́n á ṣe lo ara wọn fún àwọn ẹlòmíràn, wọn kì í wá bí wọ́n á ṣe jẹ gàba lórí wọn. Bó ti wù kí iṣẹ́ tá a ní láti ṣe ti ṣàì fani mọ́ra tó, tàbí bó tí wù káwọn èèyàn tí à ń ṣe é fún ti rẹlẹ̀ tó, ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ló máa jẹ́ ká lè lo ara wa fún àwọn ẹlòmíràn. Irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀ ń mú ọ̀pọ̀ èrè wá. Jésù sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá gba ọ̀kan nínú irúfẹ́ àwọn ọmọ kéékèèké bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi, gbà mí; ẹnì yòówù tí ó bá sì gbà mí, kò gba èmi nìkan, ṣùgbọ́n àti ẹni tí ó rán mi jáde pẹ̀lú.” (Máàkù 9:37) Níní ẹ̀mí ọ̀làwọ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, àti irú ẹ̀mí táwọn ọmọdé máa ń ní á jẹ́ ká lè wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni tó ga jù lọ láyé àtọ̀run, àti ọmọ rẹ̀. (Jòhánù 17:20, 21 1 Pétérù 5:5) A óò tún ní ayọ̀ tí fífúnni ní nǹkan máa ń jẹ́ kéèyàn ní. (Ìṣe 20:35) Inú wa á sì tún máa dùn pé à ń jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan tó hàn kedere láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run túbọ̀ pọ̀ sí i.—Éfésù 4:1-3.

Wọ́n Rọrùn Láti Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́, Wọ́n sì Ń Fọkàn Tánni

Jésù wá sọ ẹ̀kọ́ mìíràn táwọn àgbàlagbà lè kọ́ lára àwọn ọmọdé, ó ní: “Ẹnì yòówù tí kò bá gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kì yóò wọ inú rẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Máàkù 10:15) Kì í ṣe pé àwọn ọmọdé máa ń lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ nìkan ni, ó tún máa ń rọrùn láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Ìyá kan sọ pé: “Kò sóhun tó o kọ́ wọn tí wọn ò ní mọ̀.”

Nípa bẹ́ẹ̀, ká tó lè jogún Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ Ìjọba náà ká sì fi sílò. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Bíi tàwọn ọmọdé jòjòló, a gbọ́dọ̀ “ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí [a] lè dàgbà dé ìgbàlà.” (1 Pétérù 2:2) Àmọ́ bó bá dà bíi pé ẹ̀kọ́ kan nínú Bíbélì ṣòro fún ọ láti lóye ńkọ́? Ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ ìtọ́jú ọmọdé sọ pé: “Kì í sú àwọn ọmọdé láti máa béèrè pé ‘Kí nìdí?’ títí tí wọ́n á fi rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sí ìbéèrè wọn.” Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Nítorí náà, máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó. Bá àwọn Kristẹni tí wọ́n lóye sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n. (Jákọ́bù 1:5) Kò sí àní-àní pé láìpẹ́ láìjìnnà, Ọlọ́run á dáhùn àdúrà tí ò ń gbà láìdáwọ́dúró.—Mátíù 7:7-11.

Àmọ́ àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn ò ní máa ṣi ẹni tó rọrùn láti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà?’ Èyí kò lè ṣẹlẹ̀ bó bá jẹ́ pé ibi tó ṣeé gbára lé ni wọ́n ti ń gba ìtọ́sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ìwà àwọn ọmọdé ni láti máa béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Bàbá kan sọ pé: “Àwọn òbí ń fi hàn pé àwọn ṣeé fọkàn tán nípa dídáàbò bo àwọn ọmọ wọn àti nípa pípèsè ohun táwọn ọmọ náà nílò lójoojúmọ́.” Dájúdájú, irú àwọn ìdí yìí kan náà ló yẹ kó sún àwa náà láti fọkàn tán Baba wa ọ̀run Jèhófà. (Jákọ́bù 1:17; 1 Jòhánù 4:9, 10) Jèhófà ń fún wa ní ìtọ́sọ́nà tí kì í kùnà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọọ́lẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ ń tù wá nínú ó sì tún ń tì wá lẹ́yìn. (Mátíù 24:45-47; Jòhánù 14:26) Lílo àwọn ìpèsè Jèhófà yìí kò ní jẹ́ kí àárín àwa àti Jèhófà bà jẹ́.—Sáàmù 91:1-16.

Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run gẹ́gẹ́ báwọn ọmọdé ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òbí wọn á tún jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ìmọ̀ Bíbélì sọ pé: “Nígbà tá a wà lọ́mọdé, tá a bá rìnrìn àjò, a kì í mú owó ọkọ̀ dání, bẹ́ẹ̀ la ò mọ bá a ṣe máa débi tí à ń lọ, síbẹ̀ a kì í ronú rárá pé àwọn òbí wa kò ní mú wa débi tí à ń lọ láyọ̀.” Ṣé àwa náà ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lọ́nà yìí bá a ti ń gbé ìgbésí ayé wa?—Aísáyà 41:10.

Fífi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìwà àti ìṣe tó lè ba àjọṣe àárín àwa àti Ọlọ́run jẹ́. Ó tún máa ń jẹ́ ká gbà pé òótọ́ gidi lohun tí Jésù sọ pé Baba wa ọ̀run ń rí gbogbo ohun tí à ń ṣe, àti pé níwọ̀n ìgbà tá a bá ń wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, yóò bójú tó wa. Èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìdẹwò lílé kìkì nǹkan tara, débi tá a fi máa ṣàìka àwọn nǹkan tó yẹ ká máa ṣe nípa tẹ̀mí sí.—Mátíù 6:19-34.

“Ìkókó Ní Ti Ìwà Búburú”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn ọmọdé látìgbà tí wọ́n ti bí wọn, síbẹ̀ èrò inú wọn àti ọkàn wọn mọ́, èyí sì máa ń tuni lára. Ìdí rèé tí Bíbélì fi rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ ìkókó ní ti ìwà búburú.”—1 Kọ́ríńtì 14:20.

Wo ọmọbìnrin kékeré kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Monique tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún. Ó sọ fún ìyá rẹ̀ tayọ̀tayọ̀ pé: “Bí irun mi ṣe ká yìí ni irun ọ̀rẹ́ mi tuntun tó ń jẹ́ Sarah ṣe ká!” Kò dárúkọ irú àwọ̀ ara tí Sarah ní, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ẹ̀yà tó ti wá. Ẹnì kan tó jẹ́ òbí sọ pé: “Kò séyìí tó kan àwọn ọmọdé bóyá àwọ̀ dúdú tàbí àwọ̀ funfun lẹnì kan ní. Wọn kì í ní èrò kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ní ẹ̀tanú.” Lórí kókó yìí, ẹ ò rí i pé àwọn ọmọdé gbé èrò Ọlọ́run wa yọ lọ́nà tó dára gan-an, ẹni tí kì í ṣojúsàájú tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.—Ìṣe 10:34, 35.

Àwọn ọmọdé tún máa ń tètè dárí jini. Ẹnì kan tó jẹ́ òbí sọ pé: “Nígbà tí Jack àti Levi bá bára wọn jà, a máa ń sọ fún wọn pé kí wọ́n bẹ ara wọn, kò sì ní pẹ́ tí wọ́n á tún ti jọ máa ṣeré tayọ̀tayọ̀. Wọn kì í di èèyàn sínú, wọn kì í padà sórí ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, wọn kì í sì í sọ pé béèyàn ò bá bẹ̀bẹ̀, àwọn ò ní dárí jì í. Wọ́n á kàn jọ máa bára wọn ṣeré nìṣó ni.” Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ káwọn àgbàlagbà tẹ̀ lé lèyí!—Kólósè 3:13.

Láfikún sí i, àwọn ọmọdé máa ń gbà láìjanpata pé Ọlọ́run wà. (Hébérù 11:6) Nítorí pé wọn kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, èyí sábà máa ń mú kí wọ́n wàásù fáwọn èèyàn tìgboyàtìgboyà. (2 Àwọn Ọba 5:2, 3) Àdúrà wọn tó máa ń ṣe ṣókí tó sì máa ń wá látinú ọkàn wọn lè yí ẹni tọ́kàn rẹ̀ tiẹ̀ le bí òkúta padà. Tí wọ́n bá sì wà nínú ìdẹwò, wọ́n máa ń ṣe ohun tó tọ́ tó sì jọni lójú gan-an. Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye làwọn ọmọdé jẹ́!—Sáàmù 127:3, 4.

Ẹwà Náà Padà Wá

O lè máa rò ó pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn àgbàlagbà tún lè padà ní àwọn ànímọ́ dáadáa téèyàn máa ń ní nígbà tó wà léwe?’ Ìdáhùn tó ṣe ṣókí tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ ni pé, bẹ́ẹ̀ ni! Dájúdájú, àṣẹ tí Jésù pa pé “kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọ kéékèèké,” fi hàn pé ó ṣeé ṣe.—Mátíù 18:3.

Àpèjúwe kan rèé: Àwọn kan tó ń tún àwòrán tó ti bà jẹ́ ṣe lè ṣàtúnṣe àwòrán kan tó dára gan-an tí kò ṣeé díye lé. Bí wọ́n ti ń báṣẹ́ lọ, wọ́n ha ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdọ̀tí tó ti ṣẹ́ jọ sórí àwòrán náà kúrò, wọ́n á sì ṣàtúnṣe iṣẹ́ tí ò dáa táwọn kan ti kọ́kọ́ ṣe láti dá àwòrán náà padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìsapá àti sùúrù, àwọn àwọ̀ mèremère àti ẹwà tí àwòrán náà ní yóò wá hàn síta fún gbogbo èèyàn rí. Lọ́nà kan náà, báwa náà bá ń sapá láìjáwọ́, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, àti ìtìlẹ́yìn ìjọ Kristẹni, a tún lè padà ní àwọn ànímọ́ rere tá a ní nígbà tá a wà léwe.—Éfésù 5:1.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àwọn ọmọdé máa ń ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ọmọdé kì í ní ẹ̀tanú, wọ́n máa ń tètè dárí ji ara wọn, wọ́n sì máa ń yára gbàgbé ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n bá ṣẹra wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́