Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Maccabee?
LÓJÚ ìwòye ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò àwọn Maccabee jẹ́ àkókó tí ó jẹ́ kí a mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ìgbà tí a fi parí kíkọ àwọn ìwé tó kẹ́yìn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti ìgbà tí a bí Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè ṣí ọ̀pọ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ payá lẹ́yìn tí a bá ṣàyẹ̀wò ẹ̀rọ tí ń gba ìsọfúnni sílẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú, lẹ́yìn tí ìjàǹbá ọkọ̀ náà bá ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe lè ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ṣíṣàyẹ̀wò sànmánì àwọn Maccabee fínnífínní—sànmánì kan tí ó yí orílẹ̀-èdè Júù padà.
Àwọn wo là ń pè ní Maccabee? Báwo ni wọ́n ṣe nípa lórí ẹ̀sìn àwọn Júù kí Mèsáyà tí a ti sọ tẹ́lẹ̀ tó dé?—Dáníẹ́lì 9:25, 26.
Ìsọnidi Hélénì Lọ́nà Bíbùáyà
Alexander Ńlá ṣẹ́gun gbogbo àgbègbè tí ó wà ní ilẹ̀ Gíríìsì títí dé Íńdíà (336 sí 323 ṣááju Sànmánì Tiwa). Ìjọba rẹ̀ tí ó gbòòrò jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó mú kí ọ̀làjú àwọn Hélénì—èdè àti àṣà àwọn Gíríìkì—di ohun tí ó tàn kálẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ Alexander àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ fẹ́ àwọn obìnrin àdúgbò náà, wọ́n sì da àṣà Gíríìkì pọ̀ mọ́ ti ilẹ̀ òkèèrè. Lẹ́yìn ikú Alexander, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ pín ìjọba rẹ̀ mọ́wọ́. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, Antiochus Kẹta tí ó wá láti ìdílé Seleucid ará Gíríìkì tí ń ṣàkóso Síríà fipá gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdarí ìdílé Ptolemy ará Gíríìkì tí ń ṣàkóso Íjíbítì. Báwo ni ìṣàkóso àwọn Hélénì ṣe wá nípa lórí àwọn Júù ní Ísírẹ́lì?
Òpìtàn kan kọ̀wé pé: “Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé kò sí bí àwọn Júù ti lè ṣe é tí wọn kò ní ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n tí a ti sọ di Hélénì, ká má tilẹ̀ wá sọ ti àwọn Júù ẹlẹgbẹ́ wọn tí a ti sọ di Hélénì lágbègbè náà, kíkó wọnú àṣà Gíríìkì àti ọ̀nà ìrònú Gíríìkì wá di ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. . . . Pé ẹnì kan wà láàyè ní àkókò ìsọnidi Hélénì ti tó láti mú un tẹ́wọ́ gba àṣà Gíríìkì!” Àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ orúkọ àwọn Gíríìkì. Ní onírúurú ọ̀nà, wọ́n ṣàmúlò àṣà àti ìmúra àwọn Gíríìkì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ewé wọn ti ń pẹ́ lára ọṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni ó túbọ̀ ń di ọṣẹ.
Kíkó Èèràn Ran Àwọn Àlùfáà
Láàárín àwọn Júù, àwọn tí àṣà Hélénì tètè nípa lé lórí ni àwọn àlùfáà. Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn, títẹ́wọ́gba ọ̀làjú àwọn Hélénì túmọ̀ sí jíjẹ́ kí ẹ̀sìn àwọn Júù gbèèrú bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́. Ọ̀kan lára àwọn Júù bẹ́ẹ̀ ni Jason (tí a ń pè ní Joshua lédè Hébérù), àbúrò àlùfáà àgbà, Onias Kẹta. Nígbà tí Onias lọ sí Áńtíókù, Jason fún àwọn aláṣẹ Gíríìkì ní àbẹ́tẹ́lẹ̀. Nítorí kí ni? Kí wọ́n lè yàn án sípò àlùfáà àgbà dípò Onias. Antiochus Epiphanes (175 sí 164 ṣááju Sànmánì Tiwa) tí ó wá láti ìdílé Seleucid ará Gíríìkì, tí ó jẹ́ alákòóso nígbà náà, gba àbẹ́tẹ́lẹ̀ náà. Tẹ́lẹ̀ rí, àwọn alákòóso tí ó jẹ́ Gíríìkì kì í dá sí ọ̀ràn ipò àlùfáà àgbà àwọn Júù, àmọ́ Antiochus nílò owó fún àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. Inú rẹ̀ tún dùn láti rí aṣáájú kan tí ó jẹ́ Júù, tí yóò lè fi taratara gbé ìsọnidi Hélénì lárugẹ. Nígbà tí Jason béèrè fún un, Antiochus sọ Jerúsálẹ́mù di ìlú Gíríìkì (polis). Jason sì kọ́ gbọ̀ngàn ìṣeré ìfarapitú kan síbẹ̀, níbi tí àwọn ọ̀dọ́ Júù àti àwọn ọ̀dọ́ àlùfáà wọn pàápàá ti máa ń faga gbága nínú eré ìdárayá.
Egbìnrìn ọ̀tẹ̀, bí a ti ń pàkan, nìkan ń rú. Ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, Menelaus, tí kò dájú pé ó wá láti ìdílé àlùfáà, fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pọ̀ ju ti Jason lọ aláṣẹ, ni Jason bá sá lọ. Kí ó lè rí owó san fún Antiochus, Menelaus mú owó rẹpẹtẹ lára owó tẹ́ńpìlì. Nítorí tí Onias Kẹta (tó wà ní ìgbèkùn ní Áńtíókù) tako ìgbésẹ̀ yìí, Menelaus gbìmọ̀ pé kí wọ́n pa á.
Nígbà tí òkìkí kàn pé Antiochus ti kú, Jason padà sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún ọkùnrin kí wọ́n lè gba ipò àlùfáà àgbà lọ́wọ́ Menelaus. Ṣùgbọ́n Antiochus kò kú. Gbígbọ́ tí ó sì gbọ́ nípa ìgbésẹ̀ Jason àti wàhálà tí ó dá sílẹ̀ láàárín àwọn Júù láti lè tako ìlànà ìsọnidi Hélénì tí òun ti gbé kalẹ̀, Antiochus múra láti foró yaró.
Antiochus Gbégbèésẹ̀
Nínú ìwé rẹ̀, The Maccabees, Moshe Pearlman, kọ̀wé pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkọsílẹ̀ náà kò kún tó, ó dà bí pé Antiochus ti parí èrò sí pé àṣìṣe ìṣèlú gbáà ni fífàyè gba ẹ̀sìn àwọn Júù fàlàlà. Lójú tirẹ̀, ẹ̀mí tí ó ti gbòde kan ní Jùdíà ṣáájú ìgbà tí Íjíbítì fi ń ṣàkóso ni ó fa ìṣọ̀tẹ̀ tí ń lọ lọ́wọ́ ní Jerúsálẹ́mù, kì í ṣe ọ̀ràn ẹ̀sìn nìkan, àwọn Júù sì ti fi ẹ̀mí ìṣèlú yìí hàn lọ́nà tí ó léwu nítorí pé nínú gbogbo àwọn tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, àwọn nìkan ni ó jà fún oríṣi ìjọsìn kan tí ó yàtọ̀ gedegbe, àwọn nìkan ni a sì yọ̀ǹda irú rẹ̀ fún. . . . Ó wá pinnu pé, èyí gbọ́dọ̀ dópin.”
Òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì, tí ó tún jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Abba Eban ṣákópọ̀ ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí: “Ní tẹ̀-lé-ǹ-tẹ̀-lé, ní àwọn ọdún 168 àti 167 [ṣááju Sànmánì Tiwa], a pa àwọn Júù nípakúpa, a kó àwọn ohun inú Tẹ́ńpìlì lọ, a fòfin de ẹ̀sìn àwọn Júù. Ìdádọ̀dọ́ àti pípa ọjọ́ Sábáàtì mọ́ di ẹ̀ṣẹ̀ tí a lè fìyà ikú jẹni lé lórí. Ìwọ̀sí pípabanbarì jù lọ wáyé ní December 167, nígbà tí Antiochus pàṣẹ pé kí a ṣe pẹpẹ kan fún Súúsì nínú Tẹ́ńpìlì, tí ó sì sọ pé kí àwọn Júù wá fi ẹran ẹlẹ́dẹ̀—ẹran aláìmọ̀ nínú òfin àwọn Júù—rúbọ sí ọlọ́run àwọn Gíríìkì.” Ní àkókò yìí, Menelaus àti àwọn Júù mìíràn tí a ti sọ di Hélénì ṣì di ipò wọn mú, wọ́n ń báṣẹ́ wọn lọ nínú tẹ́ńpìlì tí a ti sọ dẹ̀gbin.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù tẹ́wọ́ gba ọ̀làjú àwọn Hélénì, àwùjọ tuntun kan tí wọ́n pe ara wọn ní Hasidim—àwọn onítara ẹ̀sìn—múni lọ́kàn le láti tẹ̀ lé Òfin Mósè láìgba gbẹ̀rẹ́. Níwọ̀n bí àwọn àlùfáà tí a ti sọ di Hélénì ti wá di ẹni ìríra lójú àwọn gbáàtúù báyìí, wọ́n kúkú wá fara mọ́ àwọn Hasidim. Níwọ̀n bí a sì ti ń fipá mú àwọn Júù láti tẹ̀ lé àṣà àwọn abọ̀rìṣà àti ìrúbọ wọn, bí wọn kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n ṣe tán láti kú, àkókò ìpani nípakúpa wá bẹ̀rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ náà. Ìwé àwọn Maccabee tí ìjótìítọ́ rẹ̀ ko ṣeé fọkàn tán pátápátá ròyìn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé tí wọ́n yàn láti kù dípò tí wọn yóò fi juwọ́ sílẹ̀.
Àwọn Maccabee Fara Ya
Àṣejù Antiochus sún ọ̀pọ̀ Júù láti jà fún ẹ̀sìn wọn. Ní Modiʼin, ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jerúsálẹ́mù lẹ́bàá ìlú òde òní náà, Lod, wọ́n pe àlùfáà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mattathias sí ojúde ìlú náà. Níwọ̀n bí Mattathias ti jẹ́ ẹni tí tọmọdé tàgbà bọ̀wọ̀ fún, aṣojú ọba gbìyànjú láti yí i lérò padà kí ó lé lọ́wọ́ nínú ìrúbọ ìbọ̀rìṣà—kí ó lè gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, kí ó sì jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn aráàlú tó kù. Nígbà tí Mattathias fàáké kọ́rí, Júù mìíràn jáde síta, ó sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Inú bí Mattathias gidigidi, ó he ohun ìjà kan, ó sì pa Júù náà. Nítorí tí ìwà ipá tí ọkùnrin àgbàlagbà yìí hù bá wọn lábo, ìhùwàpadà àwọn sójà Gíríìkì kò yá kánkán. Kí wọ́n tó ṣẹ́jú pẹ́, Mattathias tún ti pa òṣìṣẹ́ ọba ará Gíríìkì gan-an alára. Kí àwọn ọmọ ogun Gíríìkì tó lè gbèjà ara wọn, ọwọ́ àwọn ọmọkùnrin Mattathias márààrún àti àwọn aráàlú náà ti ju tiwọn lọ.
Mattathias ké ní ohùn rara pé: ‘Kí gbogbo ẹni tí o bá ní ìtara fún Òfin tẹ̀ lé mi.’ Kí wọn lè bọ́ lọ́wọ́ ìforóyaró, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sá lọ sí àwọn àgbègbè tí ó wà ní orí òkè. Bí ìròyìn itú tí wọ́n pa sì ti ń tàn kálẹ̀, àwọn Júù (títí kan ọ̀pọ̀ àwọn Hasidim) dara pọ̀ mọ́ wọn.
Mattathias fi Judah, ọmọ rẹ̀, ṣolórí àwọn ọmọ ogun. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nítorí tí Judah jẹ́ a-tóó-fiṣẹ́-ogun-rán ni wọ́n fi ń pè é ní Maccabee, tí ó túmọ̀ sí “òòlù.” Hasmonaean ni orúkọ tí a ń pe Mattathias àti àwọn ọmọ rẹ̀, orúkọ kan tí ó wá láti inú orúkọ ìlú náà, Hẹ́ṣímónì, tàbí baba ńlá kan tí ń jẹ́ orúkọ náà. (Jóṣúà 15:27) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Judah Maccabee ni ẹni tí òkìkí rẹ̀ kàn jù lọ nígbà ìṣọ̀tẹ̀ náà, bí ó ti wù kí ó rí, a wá ń pe orúkọ ìdílé náà ní àwọn Maccabee.
Wọ́n Gba Tẹ́ńpìlì Padà
Ní ọdún àkọ́kọ́ ìṣọ̀tẹ̀ náà, ó ṣeé ṣe fún Mattathias àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun kékeré kan jọ. Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo kọ́ ni àwọn ọmọ ogun Gíríìkì kọ lu àwọn Hasidim ajìjàgbara lọ́jọ́ Sábáàtì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára láti gbèjà ara wọn, àmọ́ wọn kò jẹ́ ré òfin Sábáàtì kọjá. Wọ́n sì tipa báyìí dúńbú wọn lọ rẹ́kẹrẹ̀kẹ. Mattathias—tí ó ti wá di abẹnugan nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn báyìí—gbé òfin kan kalẹ̀ tí ó fàyè gba àwọn Júù láti gbèjà ara wọn lọ́jọ́ Sábáàtì. Kì í ṣe pé òfin yìí mú ìlànà tuntun wọnú ìṣọ̀tẹ̀ náà nìkan ni, ṣùgbọ́n, ó tún fi àwòkọ́ṣe kan lélẹ̀ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù, èyí tí ó yọ̀ǹda fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn láti yí òfin Júù padà bí àyíká ipò bá mú kí ó pọndandan. Ìwé Talmud fi ìtẹ̀sí yìí hàn nínú ọ̀rọ̀ tí ó sọ lẹ́yìn ìgbà náà pé: “Jẹ́ kí wọ́n sọ Sábáàtì kan di aláìmọ̀ kí wọ́n bàa lè sọ ọ̀pọ̀ Sábáàtì di mímọ́.”—Yoma 85b.
Lẹ́yìn ikú baba rẹ̀ tí ó ti dàgbà, Judah Maccabee di aṣáájú ọ̀tẹ̀ náà láìsí ẹni tí ó lè bá a dù ú. Ní mímọ̀ pé òun kò lágbára láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá òun tí ó bá di ọ̀ràn ogun gidi, ó dá ọgbọ́n tuntun, ti ó fara jọ ti àwọn agbábẹ́lẹ̀ jagun òde òní. Ó kọ lu ẹgbẹ́ ọmọ ogun Antiochus ní àgbègbè tí wọn kò ti lè lo ọ̀nà ìgbèjà tí wọ́n sábà máa ń lò láti dáàbò bo ara wọn. Nínú ọ̀pọ̀ ogun tí wọ́n jà, Judah kẹ́sẹ járí láti ṣẹ́gun àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ dáadáa.
Nítorí ẹ̀mí èmi-ni-mo-jù-ọ́-lọ tí ó wà láàárín àwọn alákòóso Ilẹ̀ Ọba Seleucid àti agbára Róòmù tó ń pọ̀ sí i, àwọn alákòóso náà kò tilẹ̀ ráyé fífọwọ́ dan-in dan-in mú rírí i pé àwọn òfin tí a fi de àwọn Júù múlẹ̀. Èyí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún Júdà láti darí ogun rẹ̀ síhà àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù gan-an. Ní December 165 ṣááju Sànmánì Tiwa (tàbí ní ọdún 164 ṣááju Sànmánì Tiwa), òun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gba tẹ́ńpìlì, wọ́n fọ àwọn ohun èlò rẹ̀ mọ́, wọ́n sì tún un yà sí mímọ́—ọdún mẹ́ta gééré lẹ́yìn tí wọ́n sọ ọ́ daláìmọ́. Ọdọọdún ni àwọn Júù ń ṣayẹyẹ yìí nígbà Hánúkà, ayẹyẹ ìyàsímímọ́.
Ìṣèlú Borí Ẹ̀mí Ẹ̀sìn
Ọwọ́ wọn ti tẹ góńgó ìṣọ̀tẹ̀ náà. Wọ́n ti mú ìkàléèwọ̀ tí a gbé kalẹ̀ lòdì sí ẹ̀sìn àwọn Júù kúrò. Wọ́n ti mú ìjọsìn àti ìrúbọ nínú tẹ́ńpìlì padà bọ̀ sípò. Nísinsìnyí tí ọwọ́ wọn ti tẹ ohun tí wọ́n ń fẹ́, àwọn Hasidim fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun Judah Maccabee sílẹ̀, wọ́n sì padà sílé wọn. Ṣùgbọ́n èrò mìíràn ń bẹ lọ́kàn Judah. Ó ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó dáńgájíá, nítorí náà, èé ṣe tí kò fi lè lò ó láti dá orílẹ̀-èdè olómìnira ti àwọn Júù sílẹ̀? A wá fi èrò ìṣèlú rọ́pò èrò ẹ̀sìn tí ó fa ìṣọ̀tẹ̀ náà. Kí alára lọ tún ara mú ni ọ̀ràn náà dà.
Láti lè rí ìtìlẹ́yìn fún ìjà tí ó ń jà nítorí ìjẹgàba Seleucid, Judah Maccabee wọnú àdéhùn pẹ̀lú Róòmù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pa á lójú ogun ní ọdún 160 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn arákùnrin rẹ̀ ń bá ìjà náà lọ. Arákùnrin Judah, Jonathan, dọ́gbọ́n sí ọ̀ràn náà tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn alákòóso Seleucid fi gbà láti yàn án gẹ́gẹ́ bí àlùfáà àgbà àti alákòóso Jùdíà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà lábẹ́ ìṣàkóso wọn. Nígbà tí wọ́n fọgbọ́n tan Jonathan, tí wọ́n mú un, tí wọ́n sì pa á gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rìgímọ̀ ará Síríà kan, arákùnrin rẹ̀ Simeon—èyí tí ó kéré jù lọ nínú àwọn Maccabee—gba ipò rẹ̀. Lábẹ́ ìṣàkóso Simeon, a mú èyí tí ó kẹ́yìn nínú ìjẹgàba Seleucid kúrò (ní ọdún 141 ṣááju Sànmánì Tiwa). Simeon tún àdéhùn tí ó wà láàárín àwọn àti Róòmù ṣe, àwọn aṣáájú Júù sì tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí alákòóso àti àlùfáà àgbà. Bí ìdílé ọba Hasmonaean ṣe di èyí tí àwọn Maccabee fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nìyẹn.
Àwọn Maccabee dá ìjọsìn padà sí tẹ́ńpìlì kí Mèsáyà tó dé. (Fi wé Jòhánù 1:41, 42; 2:13-17.) Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ àwọn àlùfáà tí a sọ di Hélénì ṣe ba ìgbọ́kànlé tí àwọn ènìyàn ní nínú ẹgbẹ́ àlùfáà jẹ́, ó tilẹ̀ tún wá túbọ̀ bà á jẹ́ lábẹ́ àwọn Hasmonaean. Ní tóótọ́, ìṣàkóso lábẹ́ àwọn àlùfáà tí ìṣèlú gbà lọ́kàn dípò ọba olóòótọ́ ti ìlà Dáfídì kò mú ìbùkún tòótọ́ wá sáàárín àwọn Júù.—2 Sámúẹ́lì 7:16; Sáàmù 89:3, 4, 35, 36.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Mattathias, baba Judah Maccabee, ké ní ohùn rara pé: ‘Kí gbogbo ẹni tí ó bá ní ìtara fún Òfin tẹ̀ lé mi’
[Credit Line]
Mattathias ń rọ àwọn Júù olùwá ibi ìsádi/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications