ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 1/15 ojú ìwé 26-29
  • Ìmọ́lẹ̀ Fòpin Sí Sànmánì Òkùnkùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ́lẹ̀ Fòpin Sí Sànmánì Òkùnkùn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Àwọn Júù ní Àkókò Àwọn Ará Persia
  • Sáà Àwọn Ará Gíríìkì
  • Ìyípadà Ìsìn
  • Ìsìn Àwọn Júù Tẹ́wọ́ Gba Onírúurú Ojú Ìwòye
  • Bí Àṣà Ilẹ̀ Gíríìsì Ṣe Nípa Lórí Àwọn Tó Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Wo Là Ń Pè Ní Maccabee?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Hasmonaean àti Ohun Tí Wọ́n Fi Sílẹ̀ Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 1/15 ojú ìwé 26-29

Ìmọ́lẹ̀ Fòpin Sí Sànmánì Òkùnkùn

AYÉ tí Jesu Kristi àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbé yàtọ̀ gédégédé sí ti àwọn àkókò tí a kọ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Àwọn olùka Bibeli, tí wọn kò lóye èyí, lè ronú nípa ipò ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà àti ìsìn tí ń bá a lọ láti ìgbà wòlíì Malaki títí dé ìgbà òǹkọ̀wé Ìhìn Rere náà, Matteu, ní wíwulẹ̀ méfò ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní 400 ọdún tí ó wà láàárín wọn.

Malaki, ìwé tí ó kẹ́yìn Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu nínú àwọn Bibeli tí ó pọ̀ jù lọ lóde òní, parí pẹ̀lú àṣẹ́kù Israeli tí wọn fìdí kalẹ̀ sí ìlú wọn, lẹ́yìn tí a dá wọn sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn ní Babiloni. (Jeremiah 23:3) A fún àwọn Júù olùfọkànsìn níṣìírí láti dúró de ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọrun láti rẹ́yìn ayé Èṣù, kí ó sì mú Sànmánì Messia wọlé. (Malaki 4:1, 2) Láàárín àkókò náà, Persia ni ó ń ṣàkóso. Àwọn ọmọ ogun Persia tí ń gbé Juda mú kí àlàáfíà jọba, wọ́n sì fi agbára ológun ṣètìlẹyìn fún àwọn òfin kábíyèsí.—Fi wé Esra 4:23.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ilẹ̀ Bibeli kò dúró sójú kan jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e. Òkùnkùn tẹ̀mí àti ìdàrúdàpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yọjú. Ìwà ipá, ìkópayàbáni, ìninilára, ìrònú àṣerégèé nípa ìsìn, ìméfò ọgbọ́n èrò orí, àti ìdàrúdàpọ̀ ọkàn nítorí àṣà ìbílẹ̀ mi àwọn Orílẹ̀-Èdè Itòsí Ìlà Oòrùn Ayé jìgìjìgì.

A kọ Matteu, ìwé àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì, nígbà sànmánì tí ó yàtọ̀. Àwọn ẹgbẹ́ ogun Romu fìdí Pax Romana tàbí Àlàáfíà Romu múlẹ̀. Àwọn tí wọ́n lẹ́mìí ìjọsìn fi tọkàntara dúró de bíbọ̀ Messia náà, láti fòpin sí ìjìyà, ìwà òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ àti òṣì, àti láti tan ìmọ́lẹ̀ sórí ìwàláàyè, aásìkí, àti ìbàlẹ̀ ọkàn. (Fi wé Luku 1:67-79; 24:21; 2 Timoteu 1:10.) Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ipá lílágbára tí ó tún àwùjọ àwọn Júù tò, ní àwọn ọ̀rúndún tí ó ṣáájú ìbí Jesu Kristi dáradára.

Ìgbésí Ayé Àwọn Júù ní Àkókò Àwọn Ará Persia

Lẹ́yìn ìpolongo Kirusi tí ó dá àwọn Júù sílẹ̀ kúrò ní ìgbèkùn àwọn ará Babiloni, ní ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn Júù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tí kì í ṣe Júù fi Babiloni sílẹ̀. Àwọn àṣẹ́kù tí wọ́n dáhùn padà nípa tẹ̀mí yìí, padà sí agbègbè ìpínlẹ̀ àwọn ìlú ńlá tí a ti pa run àti ilẹ̀ tí a ti sọ dahoro. Àwọn ará Edomu, Foniṣia, Samaria, àwọn ẹ̀yà Arabia, àti àwọn mìíràn ti gba agbègbè ìpínlẹ̀ Israeli tí ó gbòòrò tẹ́lẹ̀ rí. Ohun tí ó kù ní Juda àti Benjamini di ẹkùn ìpínlẹ̀ Juda ní agbègbè ìpínlẹ̀ gómìnà Persia, ibi tí a pè ní Abar Nahara (Níkọjá Odò).—Esra 1:1-4; 2:64, 65.

Ìwé náà, The Cambridge History of Judaism, sọ pé, lábẹ́ ìṣàkóso Persia, Juda bẹ̀rẹ̀ sí í nírìírí “sáà ìdàgbàsókè àti àwọn olùgbé tí ń pọ̀ sí i.” Ó tún sọ síwájú sí i nípa Jerusalemu pé: “Àwọn àgbẹ̀ àti arìnrìn àjò ìsìn mú ẹ̀bùn wá, Tẹ́ḿpìlì àti ìlú di ọlọ́rọ̀, ọrọ̀ wọn sì fa àwọn oníṣòwò ilẹ̀ òkèèrè àti oníṣọ̀nà mọ́ra.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Persia fàyè gba ìjọba ìbílẹ̀ àti ìsìn gidigidi, owó orí nira, irin tí ó ṣeyebíye nìkan ni a sì lè fi san án.—Fi wé Nehemiah 5:1-5, 15; 9:36, 37; 13:15, 16, 20.

Àwọn ọdún tí ó kẹ́yìn Ilẹ̀ Ọba Persia jẹ́ àwọn ìgbà oníyánpọnyánrin, tí ọ̀tẹ̀ àwọn gómìnà sàmì sí. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù lọ́wọ́ nínú rúkèrúdò kan ní Etíkun Mediterranean, a sì lé wọn lọ sí ìhà àríwá jíjìnnà réré, sí Hyrcania lórí Òkun Caspian. Ṣùgbọ́n, kò dà bíi pé ìfìyàjẹni àwọn ará Persia nípa lórí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn ará Juda.

Sáà Àwọn Ará Gíríìkì

Alexander Ńlá bẹ́ gìjà sórí Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé bí àmọ̀tẹ́kùn ní ọdún 332 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ṣùgbọ́n àwọn ọjà tí ó wù ú tí ń tòkèèrè wá sí ilẹ̀ Gíríìkì ti dé ṣáájú. (Danieli 7:6) Ní mímọ̀ pé àṣà ìbílẹ̀ Gíríìkì ní ìníyelórí ti ìṣèlú, ó mọ̀ọ́mọ̀ bẹ̀rẹ̀ sísọ ilẹ̀ ọba rẹ̀ tí ń gbòòrò di Helleni. Gíríìkì di èdè tí ó kárí gbogbo orílẹ̀-èdè. Ìṣàkóso ìgbà kúkúrú ti Alexander gbé ìfẹ́ fún ìrònú atannijẹ, ìtara fún eré ìdárayá àti ìmọrírì fún èrò orí nípa ẹwà lárugẹ. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àní òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù pàápàá fàyè gba ṣíṣàfarawé àṣà àwọn Helleni.

Lẹ́yìn ikú Alexander ní ọdún 323 ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn àtẹ̀lé rẹ̀ ní Siria àti Egipti ni wọ́n kọ́kọ́ kó ipa tí wòlíì Danieli pè ní “ọba àríwá” àti “ọba gúúsù.” (Danieli 11:1-19) Nígbà ìṣàkóso “ọba gúúsù” ti Egipti, Ptolemy Kejì Philadelphus (ọdún 285 sí 246 ṣáájú Sànmánì Tiwa), a bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sí èdè Koine, Gíríìkì tí gbogbo ayé mọ̀. A pe ìtumọ̀ yìí ní Septuagint. A ṣàyọlò ọ̀pọ̀ àwọn ẹsẹ ìwé yìí nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Èdè Gíríìkì fi ẹ̀rí ìpegedé hàn fún gbígbé ìwọ̀n ìtumọ̀ lílani lóye jáde fún ayé onídàrúdàpọ̀, tí ó ṣókùnkùn nípa tẹ̀mí.

Lẹ́yìn tí Antiochus Kẹrin Epiphanes di ọba Siria àti olùṣàkóso Palestine (ọdún 175 sí 164 ṣáájú Sànmánì Tiwa), inúnibíni tí ìjọba ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa ìsìn Júù run tán. A fipá mú àwọn Júù, lábẹ́ ìfikúhalẹ̀mọ́ni, láti sẹ́ Jehofa Ọlọrun, kí wọ́n sì rúbọ sí kìkì àwọn ọlọrun àjúbàfún ti àwọn Gíríìkì. Ní December ọdún 168 ṣáájú Sànmánì Tiwa, a kọ́ pẹpẹ kèfèrí kan sórí pẹpẹ ńlá ti Jehofa ní tẹ́ḿpìlì Jerusalemu, a sì rúbọ lórí rẹ̀ sí Zeus ti Olympia. Àwọn ọkùnrin ìgbèríko náà tí a kó ìpayà bá, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ onígboyà kóra jọ sábẹ́ ìdarí Judas Maccabaeus, wọ́n sì gbé ogun gbígbóná janjan dìde títí tí wọ́n fi gba Jerusalemu. Wọ́n tún tẹ́ḿpìlì náà yà sí mímọ́ fún Ọlọrun, ọdún mẹ́ta gééré lẹ́yìn ọjọ́ náà gan-an tí a ba ìjẹ́mímọ́ rẹ̀ jẹ́, wọ́n ṣe ìrúbọ ojoojúmọ́ lákọ̀tun.

Bí ìyókù sáà Gíríìkì ṣe ń bá a lọ, àwọn tí wọ́n wà ní àpapọ̀ àwùjọ Judea fi tìbínútìbínú fẹ́ láti mú agbègbè ìpínlẹ̀ wọn gbòòrò sí i dé ààlà rẹ̀ àtijọ́. Wọ́n lo ìgboyà àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí lọ́nà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọrun mu, láti fipá mú àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti yí padà, tí àìṣe bẹ́ẹ̀ wọn yóò sì yọrí sí ikú. Síbẹ̀, àbá èrò orí ìṣèlú Gíríìkì ń bá a nìṣó láti máa ṣàkóso àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèké.

Ní àkókò yìí, àwọn tí ń du ipò àlùfáà máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ oníwà ìbàjẹ́. Ọgbọ́n àrékérekè, ìdìtẹ̀pànìyàn, àti wàyó ìṣèlú ti ba oyè wọn jẹ́. Bí ẹ̀mí tí ń bẹ láàárín àwọn Júù ti jẹ́ aláìbá-ìfẹ́-Ọlọ́run-mu tó, bẹ́ẹ̀ ni eré ìdárayá Gíríìkì ń lókìkí sí i tó. Ẹ wo bí ó ti múni ṣe kàyéfì tó, láti rí àwọn ọ̀dọ́ àlùfáà tí wọ́n ń fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, láti baà lè lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá! Àwọn Júù eléré ìdárayá tilẹ̀ yọ̀ọ̀da ara wọn fún iṣẹ́ abẹ onírora, kí wọ́n baà lè di “aláìkọlà” láti baà lè yẹra fún ìtìjú, nígbà tí wọ́n bá ń díje níhòòhò pẹ̀lú àwọn Kèfèrí.—Fi wé 1 Korinti 7:18.

Ìyípadà Ìsìn

Ní kùtùkùtù àwọn ọdún tí ó ṣáájú òpin ìgbèkùn, àwọn Júù olùṣòtítọ́ kọ̀ láti pa àwọn ìpìlẹ̀ èrò àti ọgbọ́n èrò orí kèfèrí pọ̀ mọ́ ti ìsìn tòótọ́ tí a ṣí payá nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Ìwé Esteri, tí a kọ lẹ́yìn ohun tí ó lé ní 60 ọdún àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Persia, kò ní ẹyọ àmì ìsìn Zoroaster kan ṣoṣo. Síwájú sí i, a kò rí ipa ìdarí ìsìn Persia yìí kankan nínú ìwé Esra, Nehemiah, tàbí Malaki nínú Bibeli, a sì kọ gbogbo wọn ní kùtùkùtù sáà Persia (ọdún 537 sí 443 ṣáájú Sànmánì Tiwa).

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ gbà gbọ́ pé, nígbà apá ìparí sáà àwọn ará Persia, ọ̀pọ̀ àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàmúlò díẹ̀ nínú àwọn ojú ìwòye àwọn olùjọsìn Ahura Mazda, olórí ọlọrun àjúbàfún àwọn ará Persia. Èyí fara hàn nínú àwọn ìgbàgbọ́ nínú ohun asán lílókìkí àti ìgbàgbọ́ àwọn Essene. Àwọn ọ̀rọ̀ èdè Heberu tí gbogbo ayé mọ̀ fún ọ̀wàwà, àwọn ẹ̀dá inú aṣálẹ̀ míràn, àti àwọn ẹyẹ afòrujẹ̀ di ti ẹlẹ́mìí èṣù àti iwin inú ìtàn ìṣẹ̀m̀báyé àwọn ará Babiloni àti Persia lọ́kàn àwọn Júù.

Àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í fojú mìíràn wo èrò àwọn kèfèrí. Ìpìlẹ̀ èrò nípa ọ̀run, hẹ́ẹ̀lì, ọkàn, Ọ̀rọ̀ náà (Logos) àti ọgbọ́n, ní ìtumọ̀ míràn. Bí ó bá sì jẹ́ pé, Ọlọrun jìnnà réré tó bẹ́ẹ̀ tí kì í fi í bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti fi kọ́ wọn nígbà náà, ó nílò alárinà kan. Àwọn Gíríìkì pe àwọn ẹ̀mí tí ń ṣalárinà àti atọ́nisọ́nà wọ̀nyí ní daimones. Lẹ́yìn tí wọ́n ti tẹ́wọ́ gba èrò náà pé daimones (àwọn ẹ̀mí Èṣù) lè jẹ́ rere tàbí búburú, àwọn Júù di ẹran ìjẹ fún ìdarí àwọn ẹ̀mí Èṣù.

Ìyípadà onítẹ̀síwájú kan àwọn ìjọsìn ìbílẹ̀. Àwọn sínágọ́gù jẹ yọ bí ibi tí ìjọ àwọn Júù ládùúgbò ti ń pàdé fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àti ààtò ìsìn. A kò mọ àkókò pàtó, tí sínágọ́gù àwọn Júù jẹ yọ, ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀, àti bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀. Níwọ̀n bí wọ́n ti kúnjú àìní tí àwọn Júù tí ó wà ní ilẹ̀ òkèèrè ní fún ìjọsìn, nígbà tí wọn kò bá lè lọ sí tẹ́ḿpìlì, gbogbogbòò gbà gbọ́ pé, a dá àwọn sínágọ́gù sílẹ̀ ní àkókò ìgbèkùn tàbí ní àwọn àkókò tí ó tẹ̀ lé ìgbèkùn. Ní pàtàkì, wọ́n yọrí sí àwọn ilé àpérò tí ó pinminrin fún Jesu àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti lè ‘polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá Ọlọrun, tí ó pè wọ́n jáde kúrò ninu òkùnkùn bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.’—1 Peteru 2:9.

Ìsìn Àwọn Júù Tẹ́wọ́ Gba Onírúurú Ojú Ìwòye

Ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, onírúurú àwọn olójú ìwòye kan náà bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ yọ. Wọn kì í ṣe ètò àjọ ìsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ kéékèèké ti àwùjọ àlùfáà àwọn Júù, àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí, àti àwọn alákitiyan ìṣèlú, tí wọ́n fẹ́ láti nípa ìdarí lórí àwọn ènìyàn, kí wọ́n sì darí orílẹ̀-èdè, kí gbogbo rẹ̀ wà lábẹ́ ìṣàkóso ìsìn àwọn Júù.

Àwọn Sadusi olóṣèlú jẹ́ àwọn ọlọ́rọ̀ gan-an, tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú ìjọba àwọn ọ̀tọ̀kùlú onípò ọlá, a mọ̀ wọ́n fún ìjáfáfá wọn ní ti ọgbọ́n mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀, láti ìgbà tí àwọn Maccabee ti dìde ní àárín ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn jẹ́ àlùfáà, bí àwọn kan ti lẹ̀ jẹ́ oníṣòwò àti onílẹ̀. Nígbà tí a óò fi bí Jesu, ọ̀pọ̀ àwọn Sadusi fara mọ́ ìṣàkóso Romu ti Palestine, nítorí pé, wọ́n rò pé, ó dúró sójú kan ju tiwọn, ó sì ṣeé ṣe kí ó bójú tó bí nǹkan ṣe rí nígbà náà. (Fi wé Johannu 11:47, 48.) Àwọn kéréje (àwọn ọmọlẹ́yìn Herodu) gbà gbọ́ pé ìṣàkóso láti ọwọ́ ìdílé Herodu yóò dára jù fún èrò tí orílẹ̀-èdè náà ní. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Sadusi kò fẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà bọ́ sí ọwọ́ àwọn Júù agbawèrèmẹ́sìn tàbí kí àwọn mìíràn yàtọ̀ sí àwọn àlùfáà máa ṣàkóso tẹ́ḿpìlì. Ìgbàgbọ́ àwọn Sadusi jẹ́ ti ìlànà àtọwọ́dọ́wọ́, èyí tí a gbé karí ìtumọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ Mose ní pàtàkì, tí ó sì fi àtakò wọn sí ẹ̀ya ìsìn àwọn Farisi hàn. (Ìṣe 23:6-8) Àwọn Sadusi kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìméfò. Wọ́n rò pé, àwọn ìwé ìtàn, ewì àti òwe inú Bibeli kò ní ìmísí, kò sì ṣe pàtàkì.

Àwọn Farisi bẹ̀rẹ̀ ní sáà àwọn ará Gíríìkì, gẹ́gẹ́ bí ìhùwàpadà lílágbára sí títako sísọ àwọn Júù di Helleni. Ṣùgbọ́n, nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Jesu, wọ́n ti di aláìṣeéyípadà, atẹ̀lé òfin àtọwọ́dọ́wọ́, agbófinrù, agbéraga, àwọn aláwọ̀ṣe ajólódodo-lójú-ara-wọn àti àwọn olùkọ́ tí ó fẹ́ máa fi ìtọ́ni nínú sínágọ́gù ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà. Wọ́n wá ní pàtàkì láti inú àwọn bọ̀rọ̀kìní, wọ́n sì fojú tẹ́ḿbẹ́lú àwọn mẹ̀kúnnù. Jesu ka ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Farisi sí olùwá ire ara wọn nìkan, àwọn aláìláàánú tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ owó, tí wọ́n sì jẹ́ alágàbàgebè. (Matteu, orí 23) Wọ́n tẹ́wọ́ gba Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu látòkèdélẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àlàyé tiwọn, ṣùgbọ́n wọ́n gbà pé òfin àtẹnudẹ́nu wọn tẹ̀wọ̀n jù ú lọ tàbí kí wọn jọ jẹ́ ọgbọọgba. Wọ́n wí pé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọn jẹ “odi tí ó yí Òfin ká.” Ṣùgbọ́n, dípò jíjẹ́ odi, àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ wọn sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun di asán, ó sì sú gbogbo ènìyàn.—Matteu 23:2-4; Marku 7:1, 9-13.

Àwọn Essene jẹ́ àwọn aláwo tí ó hàn gbangba pé, wọ́n gbé ní àwọn àpapọ̀ àwùjọ tí ó jẹ́ àdádó. Wọ́n ka ara wọn sí àṣẹ́kù tòótọ́ ti Israeli, tí ń fi ìjẹ́mímọ́ dúró de Messia tí a ṣèlérí náà. Àwọn Essene gbé ìgbésí ayé afàdúràṣèsìn, olùfọkànsìn aṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́, púpọ̀ nínú àwọn ìgbàgbọ́ wọn sì fi ìpìlẹ̀ èrò àwọn ará Persia àti Gíríìkì hàn.

Onírúurú àwọn Onítara Ìsìn, ẹlẹ́mìí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, àwọn agbawèrèmẹ́sìn tí ìsìn sún ṣiṣẹ́ fi ojú burúkú wo ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèdíwọ́ fún òmìnira orílẹ̀-èdè àwọn Júù, wọ́n ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ sí ọ̀tá. Wọ́n fi wọ́n wé àwọn Maccabee, wọ́n sì kọ́kọ́ fa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin olùgbìdánwò ìdáwọ́lé, olùpètè èrò mọ́ra. Ní wíwò wọ́n bí ẹgbẹ́ adìtẹ̀pànìyàn tàbí ẹgbẹ́ ọmọ ogun alátakò, wọ́n lo àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ajaguntà, tí ó sọ àwọn ojú pópó orílẹ̀-èdè náà àti àwọn gbàgede ìkóríta di ibi eléwu, tí ó sì fi kún pákáǹleke àkókò náà.

Ní Egipti, ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì gbilẹ̀ láàárín àwọn Júù tí ń gbé Alexandria. Láti ibẹ̀, ó dé Palestine, títí dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù tí ó fọ́n káàkiri ní ẹ̀yìn ilẹ̀ Palestine. Àwọn Júù alábàá èrò orí tí wọ́n kọ Apocrypha àti Pseudepigrapha túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ Mose gẹ́gẹ́ bí òbu ìtàn olówe, tí ó rúni lójú.

Nígbà tí sànmánì Romu yóò fi dé, ìsọnidi Helleni ti yí Palestine padà ní ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ìṣèlú, àti ti ọgbọ́n èrò orí. Ìsìn àwọn Júù tí a pa pọ̀ mọ́ ìpìlẹ̀ èrò àwọn ará Babiloni, Persia àti Gíríìkì tí a lọ́ pọ̀ mọ́ ìwọ̀n òtítọ́ Ìwé Mímọ́ díẹ̀, ti dípò ìsìn àwọn Júù tí a gbé karí Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, lápapọ̀, àwọn Sadusi, Farisi àti àwọn Essene jẹ́ ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé orílẹ̀-èdè náà. Gbáàtúù àwọn Júù ‘tí a bó láwọ tí a sì fọ́n ká bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn,’ wà nínú ogunlọ́gọ̀ tí àwọn ipá tí ń forí gbárí wọ̀nyí dà lọ́kàn rú.—Matteu 9:36.

Jesu Kristi wá sínú ayè òkùnkùn náà. Ìkésíni afinilọ́kànbalẹ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú emi yoo sì tù yín lára,” pèsè ìtùnú. (Matteu 11:28) Ẹ wo bí ó ti múni lórí yá tó, láti gbọ́ tí ó ń sọ pé: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé”! (Johannu 8:12) Ní tòótọ́, ìlérí rẹ̀ amọ́kànyọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yoo rìn ninu òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣugbọn yoo ní ìmọ́lẹ̀ ìyè,” dùn mọ́ni nínú.—Johannu 8:12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Jesu fi hàn pé àwọn aṣáájú ìsìn Júù wà nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Owó ẹyọ tí ń fi bí Antiochus Kẹrin (Epiphanes) ṣe rí hàn

[Credit Line]

Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́