ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 9/15 ojú ìwé 28-31
  • Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtumọ̀ Tí Ó Ní Ìmísí Ni Bí?
  • Jáfẹ́tì Ha Gbé Inú Àwọn Àgọ́ Ṣémù Bí?
  • Àwọn Aláwọ̀ṣe àti Àwọn Olùbẹ̀rù Ọlọ́run
  • Ẹ̀dà Septuagint Tún Ọ̀nà Ṣe Sílẹ̀
  • Ẹ̀dà Septuagint Pàdánù “Ìmísí” Rẹ̀
  • Ìtumọ̀ “Septuagint”—Wúlò Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Bí Àṣà Ilẹ̀ Gíríìsì Ṣe Nípa Lórí Àwọn Tó Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣó Pọn Dandan Kó O Kọ́ Èdè Hébérù àti Gíríìkì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Nìdí Tí Oríṣiríṣi Bíbélì Fi Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 9/15 ojú ìwé 28-31

Ìtumọ̀ Bíbélì Tí Ó Yí Ayé Padà

Nígbà tí wòlíì Ọlọ́run náà, Mósè, bẹ̀rẹ̀ kíkọ Bíbélì ní ohun tí ó lé ní 3,500 ọdún sẹ́yìn, orílẹ̀-èdè kékeré kan ṣoṣo ni ó lè kà á. (Diutarónómì 7:7) Ìyẹn jẹ́ nítorí pé kìkì èdè Hébérù tí orílẹ̀-èdè yẹn ń sọ láti ilẹ̀ wá ni a fi kọ Ìwé Mímọ́. Àmọ́, bí àkókò ti ń lọ, ìyẹn yóò yí padà.

TÍTÀN tí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ń tàn kálẹ̀ àti bí ó ti ṣe ń yí àwọn ènìyàn padà láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá kò ṣẹ̀yìn ìyọrísí ẹ̀dà ìtumọ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́ náà—Septuagint. Ète wo ni wọ́n ṣe é fún? Ǹjẹ́ a sì lè sọ pé Bíbélì yìí ni ó yí ayé padà bí?

Ìtumọ̀ Tí Ó Ní Ìmísí Ni Bí?

Lẹ́yìn tí àwọn Júù kúrò ní ìgbèkùn ní Bábílónì, láàárín ọ̀rúndún keje àti ìkẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ṣì wà lẹ́yìn odi ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti Júdà ìgbàanì. Èdè Hébérù wá di èdè kejì tí àwọn Júù tí a bí sí ìgbèkùn gbọ́. Nígbà tí ó máa fi di ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn Júù kan ti wà ní Alẹkisáńdíríà, Íjíbítì—ibùdó aláṣà ìbílẹ̀ pàtàkìpàtàkì ní Ilẹ̀ Ọba Gíríìkì. Àwọn Júù wọ̀nyẹn rí àǹfààní títú Ìwé Mímọ́ sí èdè Gíríìkì, tí ó jẹ́ èdè àbínibí wọn nígbà náà.

Títí di ìgbà yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí ó ní ìmísí ti wà ní èdè Hébérù, tí a kọ díẹ̀ lára rẹ̀ ní èdè Árámáíkì tí ó fẹ́ jọ ọ́. Fífi èdè mìíràn kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ha dín ipá alágbára ti ìmísí àtọ̀runwá tí ó ní kù, bóyá kí ó tilẹ̀ yọrí sí ìtumọ̀ tí kò péye bí? Ǹjẹ́ àwọn Júù, tí a ti fi Ọ̀rọ̀ tí ó ní ìmísí náà sí ìkáwọ́ wọn, lè gbà kí iṣẹ́ títúmọ̀ mú kí àwọn gbé ìhìn iṣẹ́ ìwé náà gbòdì bí?—Sáàmù 147:19, 20; Róòmù 3:1, 2.

Àwọn ọ̀ràn ẹlẹgẹ́ yìí fa ìrònú gidigidi. Síbẹ̀, àníyàn pé àwọn Júù kò ní lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ borí gbogbo èrò mìíràn. Wọ́n pinnu láti tú Torah—àwọn ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì tí Mósè kọ—sí èdè Gíríìkì. Ìtàn àtẹnudẹ́nu kò jẹ́ kí a mọ bí ìtumọ̀ yẹn ṣe lọ gẹ́lẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Letter of Aristeas ti sọ, olùṣàkóso ilẹ̀ Íjíbítì náà, Ptolemy Kejì (ọdún 285 sí 246 ṣááju Sànmánì Tiwa), fẹ́ kí ẹ̀dà kan Pentateuch (tàbí, Torah) tí a tú sí èdè Gíríìkì wà ní ibi tí a ń kó ìwé sí ní ààfin rẹ̀. Ó gbé iṣẹ́ náà fún àwọn ọ̀mọ̀wé 72 tí wọ́n jẹ́ Júù, tí wọ́n ti Ísírẹ́lì wá sí Íjíbítì, wọ́n sì parí títú u ní ọjọ́ 72. Wọ́n wá ka ìtumọ̀ yìí sétígbọ̀ọ́ àwùjọ àwọn Júù, àwọn náà sì sọ pé ó gbámúṣé, ó sì péye. Nígbà tí ó yá, àwọn tí wọ́n fẹnu pọ́n ìtàn yìí sọ pé iyàrá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olùtumọ̀ náà sí, síbẹ̀síbẹ̀ ìtumọ̀ wọn dọ́gba, kò sì sí ọ̀rọ̀ tí ó yàtọ̀ síra. Nítorí ìgbàgbọ́ nípa àwọn olùtumọ̀ 72, a wá mọ Bíbélì tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì yìí sí Septuagint, èyí tí a gbé ka ọ̀rọ̀ èdè Látìn kan tí ó túmọ̀ sí “Àádọ́rin.”

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀mọ̀wé òde òní gbà pé ìwé tí kò ṣeé gbà gbọ́ ni Letter of Aristeas jẹ́. Wọ́n tún gbà gbọ́ pé èrò títú u kò wá láti ọ̀dọ̀ Ptolemy Kejì, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú àwùjọ àwọn Júù ní Alẹkisáńdíríà. Àmọ́, ohun tí ọlọ́gbọ́n èrò orí ará Júù ti Alẹkisáńdíríà náà, Philo àti òpìtàn ará Júù náà, Josephus, kọ àti ọ̀rọ̀ inú Talmud fi ìgbàgbọ́ àjọgbà láàárín àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní hàn pé bí Ìwé Mímọ́ àkọ́kọ́ náà ṣe ní ìmísí ni ẹ̀dà Septuagint náà ní ìmísí. Láìsí àníàní, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìyọrísí ìsapá láti mú kí àwùjọ àwọn Júù jákèjádò ayé tẹ́wọ́ gba ẹ̀dà Septuagint.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ àkọ́kọ́ náà jẹ ti kìkì ìwé márùn-ún ti Mósè, orúkọ náà, Septuagint, wá tọ́ka sí odindi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí a tú sí èdè Gíríìkì. A sì ṣètumọ̀ àwọn ìwé tí ó kù láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tí ó tẹ̀ lé e tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Dípò kí ó jẹ́ ìsapá tí a ṣe kòkárí rẹ̀, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ṣe àwọn apá tí ó para pọ̀ di odindi ẹ̀dà Septuagint. Òye àti ìmọ̀ èdè Hébérù tí àwọn tí wọ́n túmọ̀ rẹ̀ ní kò dọ́gba. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìwé rẹ̀ ni títú rẹ̀ máa ń ṣe ṣangiliti jù nígbà mìíràn, nígbà tí àwọn yòókù tí wọ́n tú kò sì rí bẹ́ẹ̀. Àwọn díẹ̀ dín ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kù sí bí ti ẹ̀dà àtijọ́ náà ṣe rí. Nígbà tí ó fi máa di òpin ọ̀rúndún kejì ṣááju Sànmánì Tiwa, gbogbo ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni a lè rí kà ní èdè Gíríìkì. Láìka àwọn èsì tí kò ṣọ̀kan délẹ̀ sí, ipa tí títú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì ní lórí àwọn ènìyàn ré kọjá ohun tí àwọn olùtumọ̀ náà ti lè retí.

Jáfẹ́tì Ha Gbé Inú Àwọn Àgọ́ Ṣémù Bí?

Níbi tí Talmud ti jíròrò nípa ẹ̀dà Septuagint, ó fa ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 9:27 yọ pé: “Kí . . . Jáfẹ́tì . . . máa gbé inú àwọn àgọ́ Ṣémù.” (Megillah 9b, Talmud ti Àwọn Ará Bábílónì) Ohun tí Talmud ń sọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ni pé nípasẹ̀ ẹwà èdè Gíríìkì tí ẹ̀dà Septuagint lò, Jáfẹ́tì (bàbá Jáfánì, tí ó jẹ́ baba ńlá àwọn Gíríìkì) gbé inú àwọn àgọ́ Ṣémù (baba ńlá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì). Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, a tún lè sọ pé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dà Septuagint ti sọ, Ṣémù gbé inú àwọn àgọ́ Jáfẹ́tì. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Lẹ́yìn tí a ṣẹ́gun Alẹkisáńdà Ńlá, ní apá ìparí ọ̀rúndún kẹrin ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tí ó lágbára láti tan èdè àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì káàkiri àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ṣẹ́gun náà. Wọ́n pe ìgbésẹ̀ yìí ní Ìsàwùjọdi Hélénì. Àwọn Júù wá ronú pé ńṣe ni wọ́n ń gbógun ti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn. Bí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ọgbọ́n èrò-orí Gíríìkì bá borí, a óò jin ìsìn àwọn Júù lẹ́sẹ̀. Kí ni yóò ṣẹ́pá ìgbóguntì yìí?

Olùtumọ̀ Bíbélì tí ó jẹ́ Júù náà, Max Margolis, sọ nípa ohun kan tí ó ṣeé ṣe kí ó mú kí àwọn Júù ṣètumọ̀ ti ẹ̀dà Septuagint pé: “Bí a bá tilẹ̀ fẹ́ ronú pé àwùjọ àwọn Júù ni wọ́n gbèrò ṣíṣètumọ̀ náà, èrò mìíràn yóò ti wá sọ́kàn, pé kí a jẹ́ kí àwọn Kèfèrí rí Òfin àwọn Júù kà, kí a sì jẹ́ kí aráyé mọ̀ pé àwọn Júù ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan tí kò bá ọgbọ́n àwọn Hélénì [Gíríìsì] mu.” Mímú kí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwùjọ ènìyàn tí ń sọ èdè Gíríìkì lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìgbèjà ara ẹni àti ìjàpadà.

Ìlànà ti Ìsàwùjọdi Hélénì tí Alẹkisáńdà ṣe ti sọ èdè Gíríìkì di èdè tí a ń sọ jákèjádò ayé. Kódà nígbà tí àwọn ará Róòmù jagun gba ilẹ̀ tí ó ń ṣàkóso, èdè Gíríìkì ti gbogbo gbòò (tàbí, Koine) ṣì ni èdè tí a ń lò nínú ìṣòwò àti ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe é tàbí ó ṣẹlẹ̀ fúnra rẹ̀ ni, kò pẹ́ tí Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ẹ̀dà Septuagint náà tẹ àwọn tí kì í ṣe Júù tí wọ́n ti mọ Ọlọ́run àti Òfin àwọn Júù tẹ́lẹ̀ rí lọ́wọ́, wọ́n sì yára tẹ́wọ́ gbà á. Àwọn àbájáde rẹ̀ ṣeni ní kàyéfì.

Àwọn Aláwọ̀ṣe àti Àwọn Olùbẹ̀rù Ọlọ́run

Nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, Philo kọ̀wé pé, “ẹwà àti iyì agbára tí a gbé lé Mósè lọ́wọ́ ti di ohun tí àwọn Júù àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ń gbé lárugẹ.” Òpìtàn Júù náà, Joseph Klausner sọ nípa àwọn Júù tí ń gbé ẹ̀yìn odi Palẹ́sìnì ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Ó ṣòro láti gbà gbọ́ pé inú Palẹ́sínì kóńkó yẹn nìkan ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Júù wọ̀nyí ti wá. Kò sí ẹni tí ó lè sẹ́ pé gbígbà tí wọ́n gba àwọn aláwọ̀ṣe lọ́kùnrin àti lóbìnrin mọ́ra pẹ̀lú wà lára ohun tó mú kí àwọn Júù náà máa pọ̀ sí i.”

Àmọ́, àwọn kókó wíwọnilọ́kàn yìí kò ṣàlàyé gbogbo ọ̀ràn náà. Òǹkọ̀wé Shaye J. D. Cohen, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìtàn àwọn Júù, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn kèfèrí, lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ni wọ́n gba ẹ̀sìn àwọn Júù ní àwọn apá ìparí àwọn ọ̀rúndún tí ó ṣááju Sànmánì Tiwa àti ní àwọn ọ̀rúndún méjì àkọ́kọ́ nínú Sànmánì Tiwa. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn kèfèrí tí wọ́n fara mọ́ àwọn apá kan nínú ẹ̀sìn àwọn Júù àmọ́ tí wọn kò gba ẹ̀sìn náà pọ̀ gan-an.” Klausner àti Cohen pe àwọn tí wọn kò gba ẹ̀sìn yìí ní olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ tí a sábà máa ń rí nínú àwọn ìwé lítíréṣọ̀ èdè Gíríìkì ní sáà yẹn.

Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín aláwọ̀ṣe kan àti olùbẹ̀rù Ọlọ́run? Àwọn aláwọ̀ṣe jẹ́ ẹni tí ó gba ẹ̀sìn láìkùsíbìkan, ní gbogbo ọ̀nà ni a sì fi kà wọ́n sí Júù nítorí pé wọ́n fara mọ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì (wọ́n sì kọ gbogbo ọlọ́run mìíràn), wọ́n dádọ̀dọ́ wọn, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ní ìdà kejì, Cohen sọ nípa àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kèfèrí wọ̀nyí ń pa ọ̀pọ̀ lára àṣà àwọn Júù mọ́, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run àwọn Júù ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, wọn kò ka ara wọn sí Júù, àwọn ẹlòmíràn kò sì kà wọ́n sí Júù.” Klausner ṣàpèjúwe wọn bí “aṣọ̀túnṣòsì-má-babìkan-jẹ́,” nítorí pé wọ́n fara mọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù, wọ́n sì “ń pa apá kan lára àwọn àṣà rẹ̀ mọ́, àmọ́ . . . wọn kò sọ ara wọn di Júù pátápátá.”

Bóyá nítorí àwọn ìjíròrò tí àwọn kan ń ní pẹ̀lú àwọn Júù tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì tàbí nípa wíwo bí ọ̀nà ìhùwàsí àti àṣà àwọn Júù ṣe yàtọ̀ ló mú kí àwọn kan wá ní ìfẹ́ ọkàn nínú ṣíṣe ti Ọlọ́run. Síbẹ̀, ẹ̀dà Septuagint ló jẹ́ lájorí ohun èlò tí ń ran àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run wọ̀nyí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run. Bí kò ti sí ọ̀nà láti mọ iye àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run pàtó tí ó wà ní ọ̀rúndún kìíní, láìsí àní-àní, ẹ̀dà Septuagint tan àwọn ìmọ̀ kan kálẹ̀ nípa Ọlọ́run jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù. A tún lo ẹ̀dà Septuagint láti fìdí àwọn ìpìlẹ̀ pàtàkì kan múlẹ̀.

Ẹ̀dà Septuagint Tún Ọ̀nà Ṣe Sílẹ̀

Ẹ̀dà Septuagint kó ipa tí ó hàn gbangba nínú títan ìhìn iṣẹ́ ìsìn Kristẹni kálẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ń sọ èdè Gíríìkì wà lára àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi fífi ìpìlẹ̀ ìjọ Kristẹni lélẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Àwọn aláwọ̀ṣe pẹ̀lú wà lára àwọn tí wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní ìbẹ̀rẹ̀ yẹn. (Ìṣe 2:5-11; 6:1-6; 8:26-38) Níwọ̀n bí a ti kọ àwọn ìwé onímìísí ti àwọn àpọ́sítélì Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn mìíràn ní àtètèkọ́ṣe pẹ̀lú ète pé kí ó dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó bá lè ṣeé ṣe tó, ńṣe ni wọ́n fi èdè Gíríìkìa kọ ọ́. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí a fà yọ láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí ó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ni ó wá láti inú ẹ̀dà Septuagint.

Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe, àwọn mìíràn múra tán láti tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kèfèrí náà, Kọ̀nílíù, jẹ́ “olùfọkànsìn àti ẹnì kan tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ̀, ó sì ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn àánú fún àwọn ènìyàn, ó sì ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nígbà gbogbo.” Ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, Kọ̀nílíù, ìdílé rẹ̀, àti àwọn mìíràn tí wọ́n péjọ sí ilé rẹ̀ ni Kèfèrí tí a kọ́kọ́ batisí bí ọmọlẹ́yìn Kristi. (Ìṣe 10:1, 2, 24, 44-48; fi wé Lúùkù 7:2-10.) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ káàkiri Éṣíà Kékeré àti Gíríìsì, ó wàásù fún ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí tí wọ́n ti bẹ̀rù Ọlọ́run ná, ó sì tún wàásù fún “àwọn Gíríìkì tí ń jọ́sìn Ọlọ́run.” (Ìṣe 13:16, 26; 17:4) Èé ṣe tí Kọ̀nílíù àti àwọn Kèfèrí mìíràn wọ̀nyẹn fi múra tán láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà? Ẹ̀dà Septuagint ti tún ọ̀nà ṣe sílẹ̀. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ẹ̀dà Septuagint “jẹ́ ìwé tí ó mú ìyípadà pàtàkì wá, tí ó jẹ́ pé bí kò bá sí i, ìsìn Kristẹni àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará ìwọ̀ oòrùn ayé ì bá má ṣeé lóye.”

Ẹ̀dà Septuagint Pàdánù “Ìmísí” Rẹ̀

Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, lílo ẹ̀dà Septuagint gan-an mú kí àwọn Júù padà lẹ́yìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìjíròrò àwọn Júù pẹ̀lú àwọn Kristẹni, wọ́n sọ pé ìtumọ̀ ẹ̀dà Septuagint kò péye. Nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, àwùjọ àwọn Júù kọ ìtumọ̀ tí wọ́n ń yìn nígbà kan pé ó ní ìmísí sílẹ̀ pátápátá. Àwọn rábì kọ ìtàn nípa àwọn olùtumọ̀ 72 náà sílẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan pé àwọn àgbààgbà márùn-ún tú Torah sí èdè Gíríìkì fún Ptolemy Ọba, a sì ka ọjọ́ yẹn sì ọjọ́ burúkú fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ọjọ́ tí wọ́n ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà, níwọ̀n bí wọn kò ti lè tú Torah náà lọ́nà pípéye.” Láti lè bá èrò àwọn rábì mu délẹ̀délẹ̀, àwọn rábì pàṣẹ pé kí a tún un tú sí èdè Gíríìkì. Ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa ni aláwọ̀ṣe Júù kan tí ń jẹ́ Aquila, ọmọ ẹ̀yìn rábì Akiba, ṣe ìtumọ̀ náà.

Àwọn Júù kò lo ẹ̀dà Septuagint mọ́, àmọ́ òun ni a fi ṣètumọ̀ “Májẹ̀mú Láéláé” ti Ìjọ Kátólíìkì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọrí bọ̀ nígbà náà títí di ìgbà tí ẹ̀dà Vulgate tí Jerome tú sí èdè Látìn gba ipò rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ èyíkéyìí kò lè gba ipò ti ìpilẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀dà Septuagint tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ kó ipa pàtàkì kan nínú títan ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù Kristi kálẹ̀. Lótìítọ́, ìtumọ̀ Bíbélì kan tí ó yí ayé padà ni ẹ̀dà Septuagint jẹ́.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó lè jẹ́ èdè Hébérù ni a kọ́kọ́ fi kọ Ìhìn Rere Mátíù, pẹ̀lú ẹ̀dà kan tí a gbé jáde lẹ́yìn náà lédè Gíríìkì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ọ̀pọ̀ àwọn tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún ni ó lóye ẹ̀dà “Septuagint”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Israel Antiquities Authority

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́