Látorí Ìjọsìn Olú Ọba Sí Ìjọsìn Tòótọ́
GẸ́GẸ́ BÍ ISAMU SUGIURA TI SỌ Ọ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ọdún 1945, ó ti hàn gbangba pé ọwọ́ ti ń tẹ ilẹ̀ Japan nínú Ogun Àgbáyé Kejì, ọkàn wa balẹ̀ pé ìjì “kamikaze” (“ẹ̀fúùfù láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run”) yóò jà, yóò sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá. Ìjì “kamikaze” ń tọ́ka sí ẹ̀fúùfù tí ó jà ní ọdún 1274 àti 1281 tí ó fọ́ ọ̀pọ̀ lára ọ̀wọ́ ọkọ̀ ogun ojú omi ti àwọn Mongol tí wọ́n dó sí etíkun Japan túútúú, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n kógun wọn lọ.
NÍTORÍ náà, ní August 15, 1945, nígbà tí Olú Ọba Hirohito, kéde pé ilẹ̀ Japan ti túúbá fún Agbo Ọmọ Ogun Apawọ́pọ̀jà, ìrètí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fara wọn jìn ín já sófo. Ọmọ kékeré tó ṣì wà nílé ẹ̀kọ́ ni mí nígbà náà, ìrètí mi pẹ̀lú já sófo. Mo kọminú pé, ‘Bí olú ọba kì í bá ṣe Ọlọ́run alààyè, ta wá ni òun í ṣe?’ ‘Ta ló yẹ kí n gbẹ́kẹ̀ lé?’
Ṣùgbọ́n, lóòótọ́, ṣíṣẹ́gun Japan nígbà Ogun Àgbáyé Kejì fún èmi àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ Japan mìíràn láǹfààní láti kọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà. Kí n tó sọ àwọn ìyípadà tó pọndandan pé kí n ṣe, jẹ́ kí n ṣàlàyé ẹ̀sìn tí a fi tọ́ mi dàgbà fún ọ.
Ipa Tí Ìsìn Ní Lórí Mi Ní Kékeré
A bí mi ní ìlú Nagora ní June 16, 1932, èmi sì ni mo kéré jù lọ nínú àwa ọmọkùnrin mẹ́rin. Iṣẹ́ wọnlẹ̀wọnlẹ̀ ni baba mi ń ṣe ní ìlú wa. Màmá mi jẹ́ olùfọkànsìn onígbàgbọ́ nínú Tenrikyo, ẹ̀ya ẹ̀sìn Ṣintó kan, ẹ̀gbọ́n mi àgbà ọkùnrin sì ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ láti di olùkọ́ ẹ̀sìn Tenrikyo. Ọmọlójú màmá mi ni mo jẹ́, ó sì máa ń mú mi lọ síbi tí a ti ń pàdé fún ìjọsìn.
Wọ́n kọ́ mi bí a ṣe ń tẹrí ba àti bí a ṣe ń gbàdúrà. Ẹ̀sìn Tenrikyo kọ́ni ní ìgbàgbọ́ nínú ẹlẹ́dàá tí a ń pè ní Tenri O no Mikoto, àti nínú àwọn ọlọ́run mẹ́wàá mìíràn tó kéré sí i. Àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ń fàdúrà ṣe ìwòsàn, wọ́n máa ń tẹnu mọ́ ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti títan ìgbàgbọ́ wọn kálẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí ọmọdékùnrin, mo máa ń tọpinpin gan-an. Mo máa ń ṣe kàyéfì nígbà tí mo bá rí òṣùpá àti àìníye ìràwọ̀ lójú ọ̀run lálẹ́, mo tún máa ń ṣe kàyéfì bí gbalasa ojúde òfuurufú ṣe jìnnà tó sí àwọsánmà. Ó máa ń fà mí mọ́ra láti kíyè sí bí ìgbá àti apálá tí mo gbìn sí ilẹ̀ kékeré kan lẹ́yìnkùlé ṣe ń dàgbà. Ṣíṣàkíyèsí ìṣẹ̀dá fún ìgbàgbọ́ mi nínú Ọlọ́run lókun.
Àwọn Ọdún Ogun
Àwọn ọdún tí mo fi lọ sílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ láti 1939 sí 1945 ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú sáà tí Ogun Àgbáyé Kejì jà. Nínú ẹ̀kọ́ wa nílé ẹ̀kọ́, a tẹnu mọ́ ìjọsìn Olú Ọba, apá pàtàkì kan nínú ẹ̀sìn Ṣintó. A fi ìlànà shushin kọ́ wa, èyí tí ó ní ẹ̀kọ́ lórí ìwà híhù tí ó ní ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ti ológun nínú. Àwọn ayẹyẹ nína àsíá sókè, kíkọrin orílẹ̀-èdè, kíkọ́ òfin tí ó jẹ mọ́ ti ilẹ̀ ọba, bíbọlá fún fọ́tò olú ọba jẹ́ apá kan ètò ẹ̀kọ́ wa.
A tún máa ń lọ sí ojúbọ Ṣintó láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun olú ọba lè ṣẹ́gun. Méjì lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ni wọ́n wà níṣẹ́ sójà. Nítorí ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tí ẹ̀sìn mi ti gbìn sí mi lọ́kàn, inú mi máa ń dùn nígbà tí mo bá gbọ́ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Japan borí.
Nagoya ni ibùdó fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ti ilẹ̀ Japan, nítorí náà, ibẹ̀ ni àwọn Ọmọ Ogun Òfuurufú ti United States dojú ìjà kọ gan-an. Lójú mọmọ, ọkọ̀ òfuurufú B-29 Afibọ́ǹbù-Ṣọṣẹ́ máa ń fò káàkiri ìlú náà, tí yóò sì wà ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárùn-ún (9,000) mítà sílẹ̀, tí yóò máa ju ọgọ́rọ̀ọ̀rún tọ́ọ̀nù bọ́ǹbù sórí àwọn àgbègbè tí ilé iṣẹ́ wà. Bó bá di ọwọ́ alẹ́, iná awá-nǹkan-rí máa ń jẹ́ kí a rí àwọn ọkọ̀ òfuurufú afibọ́ǹbù-ṣọṣẹ́ náà tí wọ́n wà ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún-lé-lẹ́gbẹ̀rún (1,300) mítà sílẹ̀. Jíju àwọn bọ́ǹbù amúnáṣẹ́yọ látòkè láìdáwọ́ dúró mú kí iná máa jó hàhàhìhì ní àwọn àgbègbè tí àwọn èèyàn ń gbé. Nígbà tí ó ku oṣù mẹ́sàn-án kí ogun náà parí, ìgbà mẹ́rìnléláàádọ́ta ní a tòkè ju bọ́ǹbù sórí Nagoya nìkan, èyí tó yọrí sí ìjìyà ńláǹlà, àwọn tó kú sì lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbàarin lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (7,700).
Nígbà tí ó fi máa di àkókò yìí, àwọn ọkọ̀ ogun ojú omi ti ń ju bọ́ǹbù sí àwọn ìlú ńláńlá mẹ́wàá tí wọ́n wà ní etíkun, àwọn ènìyàn náà sì ń sọ̀rọ̀ nípa pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ United States balẹ̀ sí Tokyo. A kọ́ àwọn obìnrin àti ọmọdékùnrin ní bí a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ tí a fi ọparun ṣe jà láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn. Ọ̀rọ̀ amóríwú wa ni “Ichioku Sougyokusai,” èyí tí ó túmọ̀ sí “Ó tẹ́ wa lọ́rùn kí ọ́gọ́rùn-ún mílíọ̀nù kù ju kí a túúbá.”
Ní August 7, 1945, àkọlé ìwé ìròyìn kan kà pé: “A Ju Oríṣi Bọ́ǹbù Tuntun sí Hiroshima.” Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, a ju òmíràn sí Nagasaki. Ìwọ̀nyí jẹ́ bọ́ǹbù àtọ́míìkì, a sì gbọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé wọ́n gbẹ̀mí tí ó tó ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Lẹ́yìn náà, ní August 15, ní òpin ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí lílo ìbọn onígi, a gbọ́ ọ̀rọ̀ olú ọba nínú èyí tí ó ti kéde pé ilẹ̀ Japan ti túúbá. A ti mú wa gbà pé a óò borí, àmọ́, nísinsìnyí a dà wá lọ́kàn rú!
Ìrètí Tuntun Ṣẹ́yọ
Bí ó ti ń di pé àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí gba àgbègbè wa, a bẹ̀rẹ̀ sí gbà pé United States ti ṣẹ́gun. Wọ́n mú ìjọba tiwa-n-tiwa wọ Japan, àti òfin tuntun tí ó mú òmìnira ìjọsìn dáni lójú. Ipò nǹkan kò fara rọ, oúnjẹ wọ́n ju ojú, nígbà tó sì di ọdún 1946, àìjẹunrekánú pa baba mi.
Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ẹ̀kọ́ tí mo ń lọ, ilé iṣẹ́ rédíò ti NHK sì bẹ̀rẹ̀ sí darí ètò kan lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ọdún márùn-ún ni mo fi ń tẹ́tí sí ètò tí ó lókìkí yìí lójoojúmọ́ tí màá sì gbé ìwé akọ́mọlédè lọ́wọ́. Èyí mú kí n máa ronú àtilọ sí United States lọ́jọ́ kan. Nítorí tí ẹ̀sìn Ṣintó àti Búdà ti já mi kulẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé bóyá a lè rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run nínú àwọn ẹ̀sìn ti Ìwọ̀ Oòrùn.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ April, 1951, mo pàdé Grace Gregory, míṣọ́nnárì Watch Tower Society. Ó dúró síwájú ibùdókọ̀ rélùwéè ti Nagoya, ó ń fi ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì àti ìwé kékeré kan lédè Japanese lọ́ni lórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí ó mú kí ó máa ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wú mi lórí. Mo tẹ́wọ́ gba ìtẹ̀jáde méjèèjì náà, mo sì gbà kí ó máa bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ṣèlérí pé màá wá sí ilé rẹ̀ fún ẹ̀kọ́ Bíbélì ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà.
Bí mo ti jókòó nínú ọkọ̀ rélùwèé tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ka Ilé Ìṣọ́ náà, ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ni ojú mi lọ sí, ọ̀rọ̀ náà ni, “Jèhófà.” N kò rí orúkọ yẹn rí. N kò retí pé kí n rí i nínú ìwé atúmọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Japanese kékeré tó wà lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n ó wà níbẹ̀! “Jèhófà . . . , Ọlọ́run Bíbélì.” Wàyí o, mo bẹ̀rẹ̀ sí wádìí nípa Ọlọ́run àwọn ẹlẹ́sìn Kristi!
Nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ tí mo ṣe sí ilé àwọn míṣọ́nnárì, mo gbọ́ pé Nathan H. Knorr, ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà náà, ń bọ̀ wá sọ àwíyé Bíbélì kan ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sí i. Òun pẹ̀lú akọ̀wé rẹ̀, Milton Henschel, fẹ́ bẹ Japan wò, wọn á sì dé Nagoya. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ Bíbélì mi kò tó nǹkan, mo gbádùn àsọyé náà gan-an, mo sì gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà níjokòó.
Ní nǹkan bí oṣù méjì lẹ́yìn náà, nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí Grace ń bá mi ṣe, mo kọ́ àwọn òtítọ́ ìpìlẹ̀ nípa Jèhófà, Jésù Kristi, ìràpadà, Sátánì Èṣù, Amágẹ́dọ́nì, àti Párádísè ilẹ̀ ayé. Ìhìn rere Ìjọba náà gan-an ni irú ìhìn iṣẹ́ ti mo ti ń wá kiri. Gbàrà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Mo gbádùn ẹ̀mí ọ̀rẹ́ tí a ń fi hàn ní àwọn ìpàdé wọ̀nyí, níbi tí àwọn míṣọ́nnárì tí máa ń fara ro àwọn ará Japan fàlàlà, tí wọ́n sì ń jókòó lórí tatami (ẹni tí a fi koríko gbígbẹ hun) pẹ̀lú wa.
Ní October 1951, a ṣe àpéjọ àyíká àkọ́kọ́ ní Japan ní Gbọ̀ngàn Gbogbogbòò ti Nakanoshima ní ìlú Osaka. Gbogbo Ẹlẹ́rìí tó wà ní Japan nígbà náà kò tó ọ̀ọ́dúnrún; síbẹ̀ nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ni ó wá sí àpéjọ náà, títí kan nǹkan bí àádọ́ta míṣọ́nnárì. Mo tilẹ̀ ní apá kékeré kan nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ohun tí mo rí àti èyí tí mo gbọ́ wú mi lórí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí mo fi pinnu lọ́kàn mi láti sin Jèhófà ní gbogbo ìgbésí ayé mi. Lọ́jọ́ kejì, mo ṣe ìrìbọmi nínú omi lílọ́wọ́ọ́wọ́ ní ilé ìwẹ̀ gbogbogbòò kan tí ó wà nítòsí.
Ayọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà
Mo fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo tún rí i pé ó pọndandan fún mi láti ran ìdílé mi lọ́wọ́. Nígbà tí mo lo ìgboyà láti sọ ọ́ níṣojú ọ̀gá mi, ẹnu yà mí láti gbọ́ tí ó sọ pé: “Inú mi yóò dùn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ bí ìyẹn yóò bá mú ọ láyọ̀.” Ọjọ́ méjì péré ni mo fi ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti ran màmá mi lọ́wọ́ ní ti ìnáwó ilé. Mo dà bí ẹyẹ tí a tú sílẹ̀ kúrò nínú àgò.
Bí ipò nǹkan ti ń sunwọ̀n sí i, mo bẹ̀rẹ̀ aṣáájú ọ̀nà ní August 1, 1954, ní àgbègbè kan tí ó wà lẹ́yìn ibùdókọ̀ rélùwéè Nagoya, ìrìn ìṣẹ́jú díẹ̀ sí ibi tí mo ti kọ́kọ́ pàdé Grace. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, mo gba iṣẹ́ àyànfúnni láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Beppu, ìlú kan ní ìwọ̀ oòrùn erékùṣù Kyushu. Wọ́n yan Tsutomu Miura gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́ mi.a Nígbà yẹn, kò sí ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gbogbo erékùṣù yẹn, ṣùgbọ́n, nísinsìnyí ọgọ́rọ̀ọ̀rún wọn wà níbẹ̀, a sì pín wọn sí àyíká méjìlélógún!
Títọ́ Ayé Tuntun Wò
Nígbà tí Arákùnrin Knorr bẹ Japan wò lẹ́ẹ̀kan sí i ní April 1956, ó ní kí n ka àwọn ìpínrọ̀ díẹ̀ jáde láti inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì. Kò sọ ìdí tó fi ní kí n ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gba lẹ́tà kan tó ní kí n wá sí kíláàsì kọkàndínlọ́gbọ̀n ti ilé ẹ̀kọ́ Gilead tó wà fún àwọn míṣọ́nnárì. Nítorí náà ní November ọdún yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò láti lọ sí United States, èyí tó mú inú mi dùn jọjọ, tó sì mú kí àlá mi ìgbà pípẹ́ ṣẹ. Gbígbé pẹ̀lú ìdílé ńlá Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn fún ọ̀pọ̀ oṣù àti ṣíṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn fún ìgbàgbọ́ mi nínú ètò àjọ Jèhófà tí a lè fojú rí lókun.
Ní February 1957, Arákùnrin Knorr wa àwa mẹ́ta tí a jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ lọ sí ọgbà Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ní Gúúsù Lansing, ní ìhà àríwá New York. Ní oṣù márùn-ún tó tẹ̀ lé e ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead, mo gba ìtọ́ni láti inú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, mo sì gbé ní àyíká ẹlẹ́wà pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi, mo tọ́ Párádísè ilẹ̀ ayé wò. A yan mẹ́wàá nínú akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún, àti èmi alára, sí Japan.
Mímọrírì Iṣẹ́ Tí A Yàn fún Mi
Nǹkan bí ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀rin (860) Ẹlẹ́rìí ni ó wà ní Japan nígbà tí mo padà dé ní October 1957. A yàn mí sí iṣẹ́ arìnrìn àjò gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ lórí iṣẹ́ yìí lọ́wọ́ Adrian Thompson ní Nagoya. Àyíká mi bẹ̀rẹ̀ láti Shimizu, nítòsí Òkè Fuji, dé Erékùṣù Shikoku, ó sì tún ní àwọn ìlú ńlá bí Kyoto, Osaka, Kobe, àti Hiroshima, nínú.
Ní ọdún 1961, a yàn mí láti di alábòójútó àgbègbè. Èyí ní nínú rírin ìrìn àjò láti erékùṣù àríwá Hokkaido oníyìnyín lọ sí erékùṣù ẹ̀gbẹ́ ẹkùn ilẹ̀ olóoru ti Okinawa títí dé àwọn erékùṣù Ishigaki nítòsí Taiwan, ìrìn àjò nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbàajì (3,000) kìlómítà.
Lẹ́yìn náà, ní 1963, a pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead olóṣù mẹ́wàá ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Nígbà ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà, Arákùnrin Knorr tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì fífi ẹ̀mí rere gba iṣẹ́ tí a bá yàn fún wa. Ó ní iṣẹ́ ọ́fíìsì kò ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ fífọ ilé ìtura. Ó wí pé, bí ilé ìtura kò bá wà ní mímọ́, èyí yóò nípa lórí gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì àti iṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn náà, apá kan iṣẹ́ mi ní Bẹ́tẹ́lì Japan ni fífọ ilé ìgbọ̀nṣẹ̀, mo sì rántí ìmọ̀ràn yẹn.
Lẹ́yìn tí mo padà sí Japan, a tún yàn mí sí iṣẹ́ arìnrìn àjò. Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní 1966, mo gbé Junko Iwasaki, aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan tí ó ti sìn ní ìlú Matsue, níyàwó. Lloyd Barry, tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka ti Japan nígbà náà, ló sọ àsọyé alárinrin lórí ìgbéyàwó náà. Ìgbà náà ni Junko dara pọ̀ mọ́ mi nínú iṣẹ́ arìnrìn àjò.
Iṣẹ́ tí a yàn fún wa yí padà ní ọdún 1968 nígbà tí a pè mí sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Tokyo láti wá ṣiṣẹ́ atúmọ̀ èdè. Nítorí iyàrá tí kò tó, mo ń fẹsẹ̀ rìn wá láti Àdúgbò Sumida, ní Tokyo, Junko sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe pẹ̀lú ìjọ àdúgbò náà. Nígbà tí yóò fi di àkókò yìí, a ti nílò ẹ̀ka tí ó tóbi sí i. Nítorí náà, ní 1970, a ra ilẹ̀ sí Numazu, tí kò jìnnà sí Òkè Fuji. A kọ́ ilé ìtẹ̀wé alájà mẹ́ta àti ilé gbígbé kan síbẹ̀. Kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà tó bẹ̀rẹ̀, a ń lo àwọn ilé kan lórí ilẹ̀ náà fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, tí ń pèsè ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn alábòójútó ìjọ. Mo láǹfààní láti kọ́ni ní ilé ẹ̀kọ́ náà, Junko sì gbọ́únjẹ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ó múni lórí yá gágá láti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Kristẹni ọkùnrin tí a fún ní àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Lọ́sàn-án ọjọ́ kan, mo gba wáyà pàjáwìrì kan. Wọ́n ti gbé Màmá lọ sí ọsibítù, kò sì sí ìrètí pé yóò yè é. Mo wọ ọkọ̀ rélùwéè ayára-bí-àṣá lọ sí Nagoya, mo sì sáré lọ sí ọsibítù náà. Kò mọ nǹkan kan mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni mo wà tí ilẹ̀ fi mọ́. Màmá kú ní òwúrọ̀ kùtùkùtù. Bí mo ti ń wọkọ̀ padà sí Numazu, n kò lè pa ẹkún mọ́ra nígbà tí mò ń rántí àwọn àkókò tí kò fara rọ tí ó ti là kọjá nínú ìgbésí ayé rẹ̀ àti ìfẹ́ tí ó ní sí mi. Bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, màá rí i lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà àjíǹde.
Kò pẹ́ tí ilé tí ó wà ní Numazu kò fi tún gbà wá mọ́. Nítorí náà, a ra hẹ́kítà ilẹ̀ méje ní Ebina City, iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka tuntun sì bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1978. Wàyí o, gbogbo àyè tí ó wà lórí ilẹ̀ yìí ni ilé ìtẹ̀wé àti ilé gbígbé, àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ tí ó lè gba ẹgbàá-lé-lẹ́gbẹ̀rin (2,800) èèyàn wà. Èyí tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fi kún un láìpẹ́ yìí, ni ilé gbígbé alájà mẹ́tàlá méjì àti ilé ìpèsè ìrànwọ́ àti ibi ìgbọ́kọ̀sí alájà márùn-ún, tí a parí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí. Ìdílé Bẹ́tẹ́lì wa ti tó nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta-lé-lọ́gbọ̀n (530) báyìí, ṣùgbọ́n ilé tí a mú gbòòrò sí i náà yóò jẹ́ kí a lè rí ilé fún èèyàn tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900).
Ìdí Púpọ̀ Wà Tí Mo Fi Ní Láti Máa Yọ̀
Ó mú inú mi dùn jọjọ láti rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń nímùúṣẹ, bẹ́ẹ̀ ni, láti rí i pé ‘ẹni kékeré kan ń di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè.’ (Aísáyà 60:22) Mo rántí pé ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin bi mí nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọdún 1951 pé, “Ó tó Ẹlẹ́rìí mélòó tó wà ní Japan?”
Mo fèsì pé: “Nǹkan bí ọ̀tà-lé-nígba.”
Ó béèrè ní fífẹnu tẹ́ńbẹ́lú wa pé: “Àṣé ẹ ò tiẹ̀ ju bẹ́ẹ̀ yẹn náà lọ?”
Mo rántí tí mò ń ronú pé, ‘Àkókò yóò jẹ́ kí a mọ iye àwọn tí Jèhófà yóò fà wá sínú ìjọsìn rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè ẹlẹ́sìn Ṣintó àti Búdà yìí.’ Jèhófà sì ti pèsè ìdáhùn náà! Lónìí, kò sí àgbègbè tí a kò yàn fúnni mọ́ fún wíwàásù ní Japan, iye àwọn olùjọsìn tòótọ́ sì ti gbèèrú dé iye tí ó lé ní ọ̀kẹ́ mọ́kànlá ó lé ẹgbàá (222,000) nínú ìjọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàajì lé ní ẹgbẹ̀rin (3,800)!
Ọdún mẹ́rìnlélógójì tó ti kọjá tí mo lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún—méjìlélọ́gbọ̀n pẹ̀lú ìyàwó mi àtàtà—ti jẹ́ aláyọ̀ gidigidi. Mo lo mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọdún yẹn ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀ Èdè ní Bẹ́tẹ́lì. Ní September 1979, wọ́n tún pè mí láti jẹ́ mẹ́ńbà ìgbìmọ̀ ẹ̀ka ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Japan.
Ó ti jẹ́ àǹfààní àti ìbùkún fún mi láti nípìn-ín díẹ̀ nínú ríran àwọn ènìyàn olóòótọ́ ọkàn àti ẹlẹ́mìí àlàáfíà lọ́wọ́ láti wá sínú ìjọsìn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ ti ṣe bí tèmi—wọ́n yí padà látorí fífọkànsin olú ọba sí jíjọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo, Jèhófà. Ó jẹ́ ìfẹ́ àtọkànwá mi láti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti wá síhà ìṣẹ́gun ti Jèhófà, kí wọ́n sì jèrè ìyè àìlópin nínú ayé tuntun alálàáfíà náà.—Ìṣípayá 22:17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Baba rẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ tí ó la bọ́ǹbù átọ́míìkì tí wọ́n jù sí Hiroshima ní ọdún 1945 já, nígbà tí ó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Japan kan. Wo Jí! October 8, 1994, ojú ìwé 11 sí 15.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ìjọsìn olú ọba kó ipa pàtàkì nínú ètò ẹ̀kọ́
[Credit Line]
The Mainichi Newspapers
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi pẹ̀lú Arákùnrin Franz ní New York
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti aya mi, Junko
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Lẹ́nu iṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtumọ̀ Èdè