Nigba Ti Ẹnikan Bá Pè, Iwọ Ha Ń Dahun Bi?
GẸGẸ BI SHINICHI TOHARA TI SỌ Ọ́
FUN apá akọkọ ninu igbesi-aye mi, emi kò pe Ọlọrun, bẹẹ ni emi kò wo ọ̀dọ̀ rẹ̀ fun itọsọna. Awọn òbí mi àgbà ti ṣí lati Japan lọ si Hawaii, ti awọn òbí mi sì jẹ́ onisin Buddha. Wọn kò jáfáfá ninu igbagbọ wọn, nipa bẹẹ èrò nipa Ọlọrun kò fi bẹẹ jẹ mi lọ́kàn bi mo ti ń dàgbà.
Lẹhin naa, mo kẹ́kọ̀ọ́ nipa efoluṣọn mo sì wá ronu bi o ti jẹ́ iwa-omugọ tó lati nigbagbọ ninu Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, bi ẹkọ-iwe mi ti ń tẹsiwaju, ikẹkọọ sayẹnsi fi oju mi mọ ìmọ̀ gbangba òfúúrufú, ìmọ̀ ijinlẹ nipa physics, ati ìmọ̀ ijinlẹ nipa ohun alaaye. Ni alẹ́ emi yoo bojuwo sanma emi yoo sì ṣe kayefi nipa bi gbogbo awọn irawọ naa ṣe dé ibẹ̀. Ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan ninu mi bẹrẹ sii beere pe: ‘Ọlọrun kan tí ń dari awọn nǹkan wọnyi ha wà bi?’ Mo wá nimọlara pe Ẹnikan nilati wà lọrun nibi ti ojú kò tó. Mo bẹrẹ sii beere ninu ọkàn mi pe, ‘Ta ni Ọlọrun yii?’
Lẹhin gbigboyejade ni ile-ẹkọ giga, mo rí i ti iṣẹ mi dè mí mọlẹ bi mo ti jẹ́ oniṣẹ makaliki ni ile-iṣẹ ti ń pọn ọtí ìrẹsì ti emi kò ni akoko kankan lati ṣaṣaro nipa awọn ibẹwo ti o dide nipa Ọlọrun. Laipẹ mo pade Masako, ẹni ti ó di iyawo mi ni 1937, ni kẹrẹkẹrẹ a fi ọmọ mẹta ta wa lọ́rẹ. Ẹ wo iru aduroṣinṣin alabaakẹgbẹpọ kan ati ìyá alaapọn ti Masako ti jẹ́!
Nisinsinyi ti mo ti ni idile, mo ronu gidigidi nipa ọjọ-ọla wa. Lẹẹkan sii mo bẹrẹ sii jade lọ sita lati bojuwo awọn irawọ. A mu mi gbagbọ pe Ọlọrun kan wà. Emi kò mọ ẹni ti Ọlọrun yẹn jẹ, ṣugbọn laika iyẹn si mo bẹrẹ sii ké pè é. Leralera ni emi bẹ̀bẹ̀ pe: ‘Bi iwọ bá wà nibikan lọhun-un yẹn, jọwọ ran idile mi lọwọ lati ri ọ̀nà lati rìn ninu ayọ.’
Ìpè Mi Ni A Dahun Nikẹhin
A ti ń gbé pẹlu awọn òbí mi lati ìgbà igbeyawo wa, ṣugbọn ni 1941 ni a bẹrẹ sii dágbé ni Hilo, Hawaii. Ni gẹ́rẹ́ ti a kó dé ile wa titun, awọn ará Japan gbejako Pearl Harbor, ni December 7, 1941. Ó jẹ́ akoko pakanleke, ti gbogbo eniyan sì daamu nipa ọjọ-ọla.
Oṣu kan lẹhin gbigbejako Pearl Harbor mo ń nu ọkọ̀ ayọkẹlẹ mi ni nigba ti ọkunrin kan wá si ọ̀dọ̀ mi ti ó sì fun mi ni iwe kan ti ó ní akọle naa Children. Ó pe orukọ araarẹ ni Ralph Garoutte, ojiṣẹ ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Emi kò loye ohun ti ó ń sọ, ṣugbọn mo lọ́kàn-ìfẹ́ ninu Ọlọrun, nitori naa, mo tẹwọgba iwe naa. Ni ọsẹ ti ó tẹle e, Ralph tun pada wá ó sì fi ikẹkọọ Bibeli inu ile lọ̀ mi. Bi o tilẹ jẹ pe mo ti gbọ́ nipa Bibeli rí, eyi ni ìgbà akọkọ ti mo tíì fi oju gán-ánní ọ̀kan. Mo tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli naa, iyawo mi ati aburo rẹ̀ obinrin sì darapọ.
Otitọ naa pe Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun dùn mọ́ mi ninu gidigidi. (2 Timoteu 3:16, 17) Pe Jehofa ni ète kan ni o tilẹ jẹ agbayanu julọ. Oun ni Ẹlẹdaa naa ti mo ti ń wa! (Isaiah 45:18) A mú wa layọ lati gbọ pe Paradise akọkọ ti a ti sọnu naa ni a o mu padabọsipo sihin-in lori ilẹ̀-ayé, ti a sì lè jẹ́ apakan rẹ̀. (Ìfihàn 21:1-4) Idahun naa si ìpè mi sí Ọlọrun niyii!
A bá ẹnikẹni ati olukuluku sọrọ nipa otitọ titun ti a ṣẹṣẹ rí. Awọn òbí mi rò pe a ń ṣiwere ni, ṣugbọn eyiini kò mu irẹwẹsi bá wa. Lẹhin ikẹkọọ Bibeli kára-kára fun oṣu mẹta, ni April 19, 1942, emi ati iyawo mi ṣeribọmi ni fifi ẹ̀rí iyasimimọ wa hàn si Ọlọrun wa, Jehofa. Aburo Masako obinrin Yoshi ati ọkọ rẹ̀, Jerry, ti wọn ti darapọ mọ ikẹkọọ Bibeli wa, ni a ṣe iribọmi fun pẹlu wa. Imọ wa kere nipa Iwe Mimọ, ṣugbọn ó tó fun wa lati fẹ́ lati ṣiṣẹsin Ọlọrun.
Pẹlu ogun agbaye keji ti ń baa lọ, mo ronu pe opin eto-igbekalẹ ti dé tan, emi ati iyawo mi sì nimọlara aini naa lati kilọ fun awọn eniyan nipa eyi. Idile Garoutte jẹ́ awokọṣe fun wa ninu ọ̀ràn yii. Ralph papọ pẹlu iyawo rẹ̀ ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna ojiṣẹ alakooko kikun ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo ṣe ifiwera ipo wa pẹlu ti Ralph. Oun ní iyawo kan ati ọmọ mẹrin. Emi ni iyawo kan pẹlu ọmọ mẹta pere. Bi oun bá le ṣe é emi gbọdọ lè ṣe é pẹlu. Nitori naa, ni oṣu ti ó tẹle iribọmi wa, a beere fun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna.
Àní ṣaaju ki a tó fọwọsi wa gẹgẹ bi aṣaaju-ọna kan, mo kó ohun gbogbo ti kò pọndandan kuro ti ó ní ninu gìtá onirin mi, fèrè saxophone, ati gìtá violin. Mo ti jẹ́ onitara ọkàn giga fun orin, ṣugbọn mo kọ ohun gbogbo silẹ ayafi dùùrù àfẹnufọn mi kekere. Ju bẹẹ lọ, iṣẹ mi ni ile-iṣẹ ti ń pọn ọtí ìrẹsì kò tun dabi eyi tí ń fanimọra mọ́. (Filippi 3:8) Mo ṣe ile àgbérìn kan mo sì duro lati rí i bi Jehofa yoo bá dahun ẹ̀bẹ̀ mi lati di ẹni ti a lò. Emi kò nilati duro pẹ́. A tẹwọgba wá gẹgẹ bi aṣaaju-ọna lati June 1, 1942. A lọ taarata sinu ṣiṣiṣẹsin Jehofa lakooko kikun a kò sì kabaamọ ṣiṣe ipinnu yẹn lae.
Ṣiṣe Aṣaaju-ọna ni Hawaii
Papọ pẹlu idile Garoutte, a kárí Hawaii, Big Island, titikan Kona, awọn agbegbe oko kọfi gbigbajumọ, ati Kau. Ni awọn ọjọ wọnni a ṣiṣẹ pẹlu ẹ̀rọ ti ń lo àwo rẹ́kọ́ọ̀dù. Ó wuwo niti gidi, ṣugbọn a ko tíì dagba ju a sì lagbara. Nitori naa, pẹlu ẹ̀rọ ti ń lo àwo rẹ́kọ́ọ̀dù ni ọwọ́ kan ati apo iwe ni ekeji, a ń tọ ipa-ọna eyikeyii ti o ba ti lè ṣamọna wa si ọdọ awọn ti yoo fetisilẹ ninu awọn pápá oko ọ̀gbìn kọfi, ati ibomiran gbogbo. Nigba naa, lẹhin kikari gbogbo erekuṣu naa, a yàn wá sí Kohala lori Big Island. Kohala jẹ́ oko ireke kekere kan, ti awọn olugbe rẹ̀ jẹ́ awọn ara Caucasus, Filipino, China, Hawaii, Japan, ati Portugal. Awujọ kọọkan ni awọn aṣa, èrò, ohun ti wọn nifẹẹ si, ati isin tiwọn.
Gbàrà ti mo ti bẹrẹ iṣẹ aṣaaju-ọna, emi kò tún ṣe iṣẹ ti ayé mọ́. Fun akoko kan a ń gbọ bukata nipasẹ owó ti mo ti fi pamọ, bi aini bá sì dide emi yoo lọ fi ìwọ̀ pẹja. Tiyanutiyanu, mo sábà maa ń pada wálé pẹlu awọn ẹja diẹ. Awa yoo já awọn ẹfọ ati ewebẹ ti ń hù lẹbaa ọ̀nà, ti awọn wọnyi sì ń rọ̀sọ̀mù abọ́ ounjẹ wa nigba ounjẹ alẹ́. Mo fi páànù ṣe ohun eelo ti a fi ń yan burẹdi, Masako sì kọ́ lati ṣe burẹdi. Ohun ni burẹdi didara julọ ti mo tii jẹ rí.
Nigba ti a lọ si Honolulu fun apejọpọ Kristian kan ni 1943, Donald Haslett ẹni ti ó jẹ́ alaboojuto ayika ni Hawaii nigba yẹn, késí wa lati wá sibẹ ki a sì maa gbé ninu ile kekere kan ti a kọ́ si òkè ibi ìgbọ́kọ̀sí Watch Tower Society. A yàn mi gẹgẹ bi olutọju awọn ohun-ìní ẹ̀ka naa mo sì gbadun ọdun marun-un iṣẹ-isin aṣaaju-ọna ti ó tẹle e ni ibẹ.
Ìpè kan Ti A Kò Reti
Ni 1943 a gbọ pe Society ti bẹrẹ ile-ẹkọ kan fun idalẹkọọ awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun fun iṣẹ-isin ni ilẹ okeere. Ó ti wù wá lati lọ tó! Bi o ti wu ki o ri, awọn idile ọlọmọ ni a kò késí, nitori naa awa kò tun ronu nipa rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn, ni 1947, Arakunrin Haslett sọ fun wa pe Society fẹ́ lati mọ bi ará Hawaii eyikeyii bá wà ti yoo fẹ́ lati ṣe iṣẹ-isin ilẹ okeere ni Japan. Oun beere ohun ti o jẹ èrò wa, mo sì sọ gẹgẹ bii ti Isaiah pe: “Rán mi.” (Isaiah 6:8) Iyawo mi nimọlara lọna kan-naa. A kò lọ́tìkọ̀ lati dahun si ìpè Jehofa.
Nipa bẹẹ, a késí wa lọ si Watchtower Bible School of Gilead lati di ẹni ti a dálẹ́kọ̀ọ́ gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun. Ikesini naa ní awọn ọmọ wa keekeeke mẹta ninu. Awọn marun-un miiran, Donald ati Mabel Haslett, Jerry ati Yoshi Toma, ati Elsie Tanigawa pẹlu ni a késí, lapapọ a mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ si New York ní ìgbà otutu ti 1948.
A wọ bọọsi sọda agbaala-ilẹ naa. Lẹhin ọjọ mẹta ninu bọọsi naa, àárẹ̀ mú gbogbo wa, Arakunrin Haslett sì dabaa pe ki a sinmi ki a sì sùn ni hotẹẹli kan mọ́jú. Nigba ti a sọkalẹ kuro ninu bọọsi, ọkunrin kan wá sọdọ wa ó sì kigbe pe: “Awọn Jap! Mo ń lọ sile lati gbé ibọn mi lati pa wọn!”
“Wọn kìí ṣe ara Japan,” ni Arakunrin Haslett wi. “Ará Hawaii ni wọn. Ṣe iwọ kò rí i pe wọn yatọ ni?” A daabobo wa nipasẹ ọ̀rọ̀ lilọgbọn-ninu ti o sọ lẹsẹkẹsẹ.
Awa ha jẹ apakan lara kilaasi Kọkanla ti Gilead nitootọ bi? Ó dabi àlá aramanda kan. Bi o tilẹ jẹ pe ijotiitọ rẹ̀ wá si gbangba laipẹ. Ninu kilaasi wa, akẹkọọ 25 ni ààrẹ Watch Tower Society nigba naa, Nathan H. Knorr ti yàn, lati di ẹni ti a dálẹ́kọ̀ọ́ fun iṣẹ-isin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Japan bi o bá ṣeeṣe. Niwọn bi mo ti jẹ ti ìlà idile awọn ara Japan ti mo sì lè sọ èdè Japan diẹ, a yàn mi lati kọ́ awọn awujọ akẹkọọ wọnyi ni èdè naa. Niwọn bi emi kò sì ti jáfáfá ninu èdè naa, eyi kò rọrun; ṣugbọn lọna kan ṣáá gbogbo wá rọ́nà gbegbà!
Ni akoko yẹn ọmọkunrin wa, Loy, jẹ́ ọmọ ọdun mẹwaa, ti awọn ọmọbinrin wa, Thelma ati Sally sì jẹ́ ọmọ ọdun mẹjọ ati mẹfa. Nigba ti a wà ni ile-ẹkọ, ki ni ó ṣẹlẹ si wọn? Wọn lọ si ile-ẹkọ pẹlu! Ọkọ bọọsi kan ń gbé wọn ni òwúrọ̀ ó sì ń gbé wọn pada wálé ni irọlẹ. Nigba ti awọn ọmọ naa bá pada sile lati ile-ẹkọ Loy yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn arakunrin ni oko Society, ti Thelma ati Sally a sì ṣiṣẹ nibi ifọṣọ ni kíká awọn aṣọ ìnujú.
Mimu Ero-inu Bá Ohun Ti A Kò Mọ̀ Mu
Nigba ti a kẹkọọyege kuro ni Gilead ni August 1, 1948, a ń yánhànhàn lati wà ni ibi àyànfúnni wa. Arakunrin Haslett lọ ṣiwaju wa lati wá ibi kan ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun yoo gbé. Nikẹhin, oun ri ile alájà meji kan ni Tokyo, idile wa sì ṣí lọ si ile wa ọjọ-ọla naa ni August 20, 1949.
Ṣaaju dide si Japan, mo sábà maa ń ronu nipa ilẹ Gabasi yii. Mo ronu nipa iduroṣinṣin awọn ará Japan ti awọn eniyan asọdoluwa ati si olu-ọba wọn. Ọpọlọpọ awọn ará Japan fi ẹmi wọn lelẹ fun awọn alakooso wọnyi. Nigba ogun agbaye keji, awọn ọmọ ogun òfúúrufú Kamikaze kú fun olú-ọba nipa mímọ̀ọ́mọ̀ dari ọkọ̀ ogun òfúúrufú wọn sí ibi ti wọn ba ti kofiri ìlà eefin ọkọ̀ oju-omi awọn ọ̀tá. Mo ranti rironu pe bi awọn ará Japan bá lè jẹ́ aduroṣinṣin sí awọn eniyan asọdoluwa, ki ni wọn yoo ṣe bi wọn bá mọ Oluwa tootọ naa, Jehofa?
Nigba ti a dé si Japan, kìkì ojihin-iṣẹ-Ọlọrun meje pere ni ó wà ati iwọnba awọn akede ni gbogbo ilẹ naa. Gbogbo wa bẹrẹ iṣẹ, mo sì lakaka lati mu ìmọ̀ mi nipa èdè naa sunwọn sii ti ó sì ṣeeṣe lati bẹrẹ awọn ikẹkọọ Bibeli pẹlu ọpọlọpọ ti ń kepe Ọlọrun lati inu ọkan-aya wọn wá. Iye pupọ ninu awọn akẹkọọ Bibeli igbaani sì ń baa lọ ninu oloootọ titi di oni yii.
Iṣẹ-isin Ojihin-iṣẹ-Ọlọrun Pẹlu Awọn Ọmọ Wa
Bawo ni a ṣe lè ṣe iṣẹ-isin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun pẹlu awọn ọmọ keekeeke mẹta lati bojuto? Ó dara, Jehofa ni agbara ti ó wà lẹhin gbogbo rẹ̀. A ń gba owó taṣẹrẹ lati ọdọ Society, Masako sì ń ṣe awọn aṣọ fun awọn ọmọ naa. Ni afikun sii a ri iranlọwọ diẹ lati ọdọ awọn obi mi.
Lẹhin kikẹkọọyege ni ile-ẹkọ giga, Loy ṣiṣẹsin ni ẹ̀ka ile-iṣẹ Watch Tower Bible and Tract Society ti Japan fun ìgbà diẹ. Bi o ti wu ki o ri, nitori iṣoro ilera, ó pinnu lati pada si Hawaii fun itọju. Oun ati iyawo rẹ̀ nisinsinyi ń ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu iṣotitọ ni California. Igbeyawo rẹ̀ yọrisi bibukun wa pẹlu awọn ọmọ-ọmọ lilẹwa mẹrin. Gbogbo wọn ti ṣe iribọmi, ti ọ̀kan pẹlu iyawo rẹ̀ sì ń ṣiṣẹsin ni Beteli ti Brooklyn, orile-iṣẹ agbaye ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Awọn ọmọbinrin mi, Thelma ati Sally, ni a ti fun ni ipo ojihin-iṣẹ-Ọlọrun nigba ti wọn dagba. Thelma nisinsinyi ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni ilu Toyama. Sally fẹ́ arakunrin ojihin-iṣẹ-Ọlọrun kan, Ron Trost, wọn sì ti ń ṣiṣẹsin ni Japan gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ninu ririnrin-ajo fun eyi ti o ju ọdun 25 lọ.
Lati Ariwa si Guusu
Lẹhin lilo ọdun meji ni Tokyo, a rán wa lọ si Osaka fun ọdun meji. Iṣẹ ayanfunni wa ti ó tẹle e mú wa lọ si ariwa si Sendai, nibi ti a ti ṣiṣẹsin fun ọdun mẹfa. Awọn ọdun wọnyẹn ní Sendai mú wa tootun fun iṣẹ ayanfunni ní ikangun ariwa ti Japan, Hokkaido. Ni Hokkaido ni ọmọbinrin wa ti gba ipo ojihin-iṣẹ-Ọlọrun. Nibẹ pẹlu ni a ti dojulumọ pẹlu ìtutù oju-ọjọ ìgbà ẹẹrun ti ó maa ń tutu bii yinyin nigba miiran. Lẹhin ilẹ olooru ti Hawaii, iyipada ńláǹlà ni ó jẹ́!
Lẹhin naa, ni ọjọ kan mo gbúròó ikesini titun, nipasẹ lẹta kan lati ọ̀dọ̀ Society. Ó sọ fun mi lati ṣí ẹ̀ka ọfiisi kan ni Okinawa, eyi ti ó ṣì wà labẹ akoso U.S. Ìṣíkúrò lati opin ariwa Japan titutu wá si ohun ti ó ti di agbegbe ti o wà ní ìkangun guusu Japan nisinsinyi yoo mu ipenija ńláǹlà lọwọ. Ki ni emi yoo ṣe? Bi o tilẹ jẹ pe mo nimọlara aikunju oṣuwọn, mo dé si Okinawa ni November 1965, pẹlu itilẹhin aya mi gẹgẹ bi o ti figba gbogbo maa ń jẹ́. Igbesi-aye ni Okinawa yoo ha jẹ́ bakan-naa bi o ti rí ni Japan bi? Ki ni nipa ti àṣà? Awọn eniyan yoo ha dahunpada si ihin-iṣẹ igbala ti Jehofa bi?
Nigba ti a dé, iye ti ó din ni 200 awọn akede ni wọn wà ni Okinawa. Nisinsinyi iye ti ó ju 2,000 lọ ni ó wà. Ni ibẹrẹ awọn ọjọ wọnni, mo jẹ́ alaboojuto ẹ̀ka alaabọ-akoko ati alaboojuto ayika alaabọ-akoko. Ririnrin-ajo jakejado awọn erekuṣu naa ṣeranwọ fun mi lati mu ipo ibatan timọtimọ dagba pẹlu awọn ará ti wọn wà nibẹ, mo sì kà á si anfaani lati ṣiṣẹsin wọn.
A Bọ́ Lọwọ Iṣoro Bi?
Iṣẹ igbesi-aye wa ti ijihin-iṣẹ-Ọlọrun kò ṣai ni awọn iṣoro tirẹ̀. Nigba ti a ń lo isinmi kuro lẹnu iṣẹ ni United States ni 1968, Masako ṣaisan ó sì nilati ṣe iṣẹ abẹ́. Wọn yọ kókó ọlọ́yún kan kuro ninu awọn ifun rẹ̀ ó sì jere ilera pada lọna ti ó jọjú. A kò ní eto adíyelófò ti ilera, a sì ṣaniyan boya a kì yoo lè pada sẹnu iṣẹ ayanfunni wa. Si iyalẹnu wa, bi o ti wu ki o ri, awọn ọ̀rẹ́ ninu igbagbọ bojuto ohun gbogbo.
Ni temi funraami, mo ń gbé nisinsinyi pẹlu awọn iṣoro ti ó wọ́pọ̀ laaarin awọn alaisan àtọ̀gbẹ. Bi o tilẹ jẹ pe oju mi kò fọ́, agbara iriran mi ti di bàìbàì gidigidi. Ṣugbọn nipasẹ inurere ailẹtọọsi Jehofa, ó ṣeeṣe fun mi lati gba awọn ounjẹ aṣaralokun tẹmi sinu deedee nipa títẹ́tí silẹ si awọn ohùn Ilé-Ìṣọ́nà ati Ji! ti a ti gbà silẹ sinu teepu. Awọn arakunrin ati arabinrin ninu igbagbọ pẹlu ṣeranwọ nipa kíka oniruuru awọn akojọpọ-ọrọ fun mi.
Bawo ni mo ṣe lè maa baa lọ lati maa funni ni ọ̀rọ̀-àsọyé fun gbogbo eniyan pẹlu oju ti o ti di bàìbàì? Lakọọkọ mo ń gba ohùn awọn ọ̀rọ̀ mi silẹ ti emi yoo sì gbé wọn safẹfẹ nipasẹ eto ohùn orin nigba ti emi yoo maa faraṣapejuwe. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu amọran ọmọbinrin mi, mo mú eyi sunwọn sii. Ni bayii mo ń gba ohùn ọ̀rọ̀ mi silẹ pẹlu ẹ̀rọ̀ igbohunsilẹ kekere ti emi yoo sì maa sọ wọn jade nipa lilo gbohungbohun akibọti lati fi gbọ ọ̀rọ̀ ti mo ti gbà silẹ tẹlẹ.
Nigbakigba ti a bá dojukọ iṣoro lilekoko, a kò kuna lati kepe Jehofa. Ni kẹrẹkẹrẹ, awọn ibukun tí ń wá lati inu yiyanju ti Jehofa ń yanju awọn iṣoro naa sábà maa ń dabi ẹni pe ó pọ ju ohun ti awọn iṣoro naa funraawọn ti lè jẹ́ lọ. Lati maa baa lọ ninu iṣẹ-isin rẹ̀ ni kìkì ọ̀nà kanṣoṣo lati fi imoore wa hàn.
Lẹhin ọdun 23 ni Okinawa, a tun yan iṣẹ fun wa si agbegbe oloju-ọjọ kan-naa nibi ti a ti ṣiṣẹsin nigba ti a kọ́kọ́ fẹsẹ ba Japan. Olu ọfiisi Society ati ibugbe titobi julọ ti awọn ojihin-iṣẹ-Ọlọrun wà ni Tokyo agbegbe ipilẹṣẹ naa nibi ti ile alájà meji, ti Arakunrin Haslett rà ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin wà.
Yatọ si Masako ati emi, 11 lara awọn ibatan wa ń ṣiṣẹsin nisinsinyi gẹgẹ bi ojihin-iṣẹ-Ọlọrun ni Japan. Gbogbo wa kà á si anfaani giga lati ri idagbasoke ti Jehofa ti mú bá ilẹ yii ti ó jẹ ti aṣa Buddha ati Shinto ni pataki. Iṣẹ ni Japan ní ibẹrẹ kekere, ṣugbọn agbara Jehofa ti mu “orilẹ-ede” ti o jú 167,000 awọn akede ihinrere jade.—Isaiah 60:22.
Nigba ti mo képe Ọlọrun, ó dá mi lohun. Nigba ti oun pè mi mo dahun lọna titọ. Emi ati iyawo mi nimọlara pe ohun ti ó yẹ ki a ṣe ni a ti ṣe. Ki ni nipa tìrẹ? Nigba ti Ẹlẹdaa rẹ bá pè, iwọ ha ń dahun bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Idile Tohara pẹlu diẹ lara awọn aṣaaju-ọna ẹlẹgbẹ́ wọn ni Hawaii, 1942
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Awọn ọmọ Tohara ni Gilead ni 1948
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Wọn layọ pe awọn ti dahun si ìpè naa, Shinichi ati Masako Tohara ti lo ọdun 43 ninu iṣẹ ojihin-iṣẹ-Ọlọrun