ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 1/1 ojú ìwé 21-25
  • Lílàkàkà Láti Jẹ́ “Aṣiṣẹ́ Tí Kò Ní Ohun Kankan Láti Tì í Lójú”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lílàkàkà Láti Jẹ́ “Aṣiṣẹ́ Tí Kò Ní Ohun Kankan Láti Tì í Lójú”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Iṣẹ́ Ológun Nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ojú Omi Germany
  • Ìmọ́lẹ̀ Tàn Níbi Ìwakùsà
  • Kíkọ́ Láti Ṣàkóso Ìbínú Mi
  • Ọwọ́ Mi Dí, Ṣùgbọ́n Ó Ṣàǹfààní
  • Àfikún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn
  • Títẹ̀síwájú Láìka Àwọn Àdánwò Sí
  • Kíka Bíbélì Lójoojúmọ́ Ti Fún Mi Lókun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Kò Sí Ohun Tí Ó Dára Bí Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 1/1 ojú ìwé 21-25

Lílàkàkà Láti Jẹ́ “Aṣiṣẹ́ Tí Kò Ní Ohun Kankan Láti Tì í Lójú”

GẸ́GẸ́ BÍ ANDRÉ SOPPA TI SỌ Ọ́

Ogun Àgbáyé Kejì jà, ó fa ìpakúpa àti ìpọ́njú tó kọjá sísọ. Oríṣiríṣi ìwà ìkà táwọn èèyàn hù séèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣojú mi kòró, torí pé èmi ni ẹ̀ṣọ́ tí ń ta Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ojú Omi Germany tó wà ní Narvik, ní Norway, lólobó. Lóru, lẹ́bàá àwọn ẹsẹ̀ odò tẹ́ẹ́rẹ́, ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀ tó mọ́ roro, máa ń mú kí n ronú jinlẹ̀-jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé. Ó dá mi lójú pé Ọlọ́run tó dá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kọ́ ló fa gbogbo ìwà ìkà táa ń rí lójú ogun.

ỌDÚN 1923 ni a bí mi ní abúlé kékeré tí a ń pè ní Lassoth (tó wà ní Poland báyìí), nítòsí ààlà Czechoslovakia, inú ìdílé tálákà tí ń gbé lóko sì ni a ti tọ́ mi dàgbà. Kátólíìkì paraku ni àwọn òbí mi, ẹ̀sìn sì kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa. Àmọ́ ṣá o, láti àárọ̀ ọjọ́ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kọminú sí ẹ̀sìn mi. Ìdílé ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì mẹ́ta ló wà lábúlé wa, àwùjọ àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kì í sì í bá wọn da nǹkan pọ̀. Èyí tojú sú mi. Katikísìmù ni wọ́n fi ń kọ́ wa níléèwé. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, mo ní kí àlùfáà ṣàlàyé Mẹ́talọ́kan, kàkà tí ì bá fi ṣàlàyé, ẹgba mẹ́wàá ni mo jẹ. Ṣùgbọ́n o, ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ló túbọ̀ jẹ́ kí n nímọ̀lára pé ìranù gbáà lọ̀ràn ṣọ́ọ̀ṣì. Láàárín oṣù kan péré, ikú pa àwọn òbí màmá mi, màmá mi kò sì rówó fi san gbèsè ètò ìsìnkú méjì nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Nítorí náà, ó béèrè lọ́wọ́ àlùfáà bóyá ó lè gbà kí òun fún un lówó náà lẹ́yìn ìgbà díẹ̀. Àlùfáà fèsì pé: “Ṣe bí àwọn òbí ẹ lẹ́rù, àbí wọn ò ní? Hẹn, lọ ta ẹrù wọn, kóo fi sanwó ètò ìsìnkú wọn kẹ̀.”

Ọdún díẹ̀ ṣáájú ìyẹn, lẹ́yìn tí Hitler gorí àlééfà ní ọdún 1933, wọ́n ni a ò gbọ́dọ̀ sọ èdè Polish mọ́ o; wọ́n ni dandan-ǹdan, èdè German ló kù tí a óò máa sọ. Àwọn tó kọ̀, tàbí àwọn tí kò lè kọ́ èdè German dàwátì ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀—ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín la gbọ́ pé àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni wọ́n kó wọn lọ. Kódà, wọ́n pa orúkọ abúlé wa dà sí ti èdè German, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní Grünfliess. Mo fi iléèwé sílẹ̀ lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlá, mo wáṣẹ́ títí, n kò rí, torí pé n kì í ṣe mẹ́ńbà ẹgbẹ́ Àwọn Èwe Hitler. Nígbà tó ṣe ṣá, wọ́n gbà mí gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ nílé arọ́. Gbàrà tógun bẹ̀rẹ̀, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà nínú ṣọ́ọ̀ṣì fún Hitler àti fún àwọn ọmọ ogun Germany. Mo ronú pé àfàìmọ̀ kó má ṣe pé àwọn ará ọ̀hún náà ń gba irú àdúrà kan náà fún ìṣẹ́gun.

Iṣẹ́ Ológun Nínú Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ojú Omi Germany

Ní December 1941, mo tọwọ́ bọ̀wé pé mo fẹ́ bá Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ojú Omi Germany ṣiṣẹ́, nígbà tó sì di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1942, wọ́n fi mí ránṣẹ́ sétíkun Norway láti lọ máa ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun tí ń ṣamí. Iṣẹ́ tiwa ni pé ká máa bá àwọn ọkọ̀ òkun tó ń lọ láti Trondheim rìn dé Oslo, àwọn ọkọ̀ òkun tó kó àwọn ọmọ ogun, ohun ìjà, tàbí ẹrù. Ìgbà táa wà lójú agbami òkun ni mo gbọ́ fínrín tí àwọn atukọ̀ méjì ń sọ̀rọ̀ nípa òpin ayé gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà wọ́n láti sọ ọ́ síta, wọ́n sọ fún mi pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòbí àwọn, ṣùgbọ́n àwọn ò kàn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn ni. Ìgbà àkọ́kọ́ mi rèé láti gbọ́ nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bógun ṣe parí, ṣe ni àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kó wa lẹ́rú, wọ́n fà wá lé àwọn ọmọ Amẹ́ríkà lọ́wọ́, pé kí wọ́n kó wa padà sí Germany. Àwa tí ilé wa ti bọ́ sábẹ́ àṣẹ ilẹ̀ Soviet báyìí ni wọ́n kó lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Liévin, àríwá ilẹ̀ Faransé, ká lọ máa ṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà. Ìyẹn jẹ́ ní August 1945. Mo rántí pé mo bi ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ wa tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé pé ẹ̀sìn wo ló ń ṣe. Ó ní: “Kátólíìkì ni.” Nígbà tó jẹ́ pé Kátólíìkì lèmi náà, mo bi í pé èwo ni gbogbo èyí táa ń ṣe yìí? Ohun tó fi dá mi lóhùn ni pé: “Má wulẹ̀ yọ ara rẹ lẹ́nu. Sáà gbà pé báa ti rí i nìyẹn.” Lójú tèmi o, kò ṣeé gbọ́ sétí, pé kí àwọn tó jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà máa bá ara wọn jà, kí wọ́n máa pa ara wọn.

Ìmọ́lẹ̀ Tàn Níbi Ìwakùsà

Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ débi ìwakùsà náà, mo bá àwọn awakùsà tí í ṣe ará ibẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀. Ọkùnrin kan báyìí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Evans Emiot bù lára búrẹ́dì rẹ̀ fún mi jẹ. Ọmọ ìpínlẹ̀ Ohio, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni, ṣùgbọ́n ó ti ṣe ọ̀pọ̀ ọdún ní ilẹ̀ Faransé. Ó bá mi sọ̀rọ̀ nípa ayé kan tí kò ti ní sí ogun. Inú rere ọkùnrin yìí jọ mí lójú gan-an ni. Kò ní ẹ̀tanú sí mi rárá, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ ọmọ Germany, tóun sì jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà. A ò ríra mọ́ títí ó fi di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1948 tó fún mi ní ìwé pẹlẹbẹ tí a ń pè ní “The Prince of Peace.” Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, inú ìwé yìí ni mo ti wá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run onínúure tó kórìíra ogun—irú Ọlọ́run tí ọkàn mi wòye nígbà tí mo ń wo ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀. Mo pinnu láti wá ẹ̀sìn tó ń fi èyí kọ́ni kàn. Ṣùgbọ́n bó ṣe jẹ́ pé òdìkejì ibi ìwakùsà náà ni Evans ti ń ṣiṣẹ́, n kò rí i bá sọ̀rọ̀. Mo bi gbogbo onírúurú ẹ̀sìn tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n káríkárí, bí wọ́n bá mọ nǹkan kan nípa ìwé pẹlẹbẹ náà, ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo akitiyan mi já sí.

Nígbà tó wá yá, ní April 1948, a tú mi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, mo sì lómìnira àtiṣiṣẹ́ tó wù mí. Ní Sunday tó tẹ̀ lé e gan-an, ó yà mí lẹ́nu nígbà tí mo gbọ́ tí wọ́n ń lu aago kékeré kan lójú pópó. Inú mi mà dùn gan-an láti rí Evans o! Ó wà lára àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó gbé pátákó kọ́rùn, níwájú àti lẹ́yìn, tí wọ́n fi ń polongo àkòrí àsọyé kan fún gbogbo ènìyàn. Ẹlẹ́rìí tó ń lu aago lọ́jọ́ yẹn ni Marceau Leroy, tó ti di mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní ilẹ̀ Faransé báyìí. Wọ́n mú mi lọ bá Joseph Kulczak, ará Poland kan tó gbọ́ èdè Germany, ẹni tó ti jìyà nínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó ní kí n wá sípàdé lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Ọ̀pọ̀ nínú ohun tí wọ́n sọ kò yé mi, ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo àwọn tó wà níjokòó nawọ́ sókè, mo bi ẹni tó jókòó tì mí pé kí ló dé tí wọ́n fi nawọ́ sókè. Ó ní: “Àwọn wọ̀nyí ló fẹ́ lọ ìlú Dunkerque lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ láti lọ wàásù.” Mo béèrè pé: “Ṣé èmi náà lè lọ?” Èsì rẹ̀ ni pé: “O lè lọ kẹ̀!” Bó ṣe di pé mo lọ wàásù láti ilé dé ilé lọ́jọ́ Sunday tó tẹ̀ lé e nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ẹni táa bá pàdé ló fara mọ́ ohun táa sọ, síbẹ̀ mo gbádùn rẹ̀, kò sì pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí wàásù déédéé.

Kíkọ́ Láti Ṣàkóso Ìbínú Mi

Láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni Àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ní àwọn bárékè tí àwọn tẹ̀wọ̀ndé ará Germany ń gbé. Èyí kò rọrùn fún mi, torí pé gbogbo wọn ló mọ̀ mí lónínú fùfù. Tí ẹnì kan bá fi iṣẹ́ ìwàásù mi ṣe yẹ̀yẹ́, màá gbójú mọ́ ọn, pé: “Bóò bá ṣọ́ra, á di wàhálà o.” Nígbà kan lẹ́nu iṣẹ́ níbi ìwakùsà, mo tilẹ̀ kan ẹnì kan tó pẹ̀gàn Jèhófà lẹ́ṣẹ̀ẹ́.

Ṣùgbọ́n o, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti yí ìwà mi padà. Lọ́jọ́ kan, báa ti ń wàásù ní bárékè wọ̀nyí, àwọn ọkùnrin kan tó ti mutí yó ń bá Àwọn Ẹlẹ́rìí kan fa wàhálà. Níwọ̀n bí àwọn ará tí a jọ wà pa pọ̀ ti mọ̀ pé mo tètè máa ń bínú, wọn ò fẹ́ kí n dá sí i rárá, ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin náà dìde gìrà sí mi, ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ́ ẹ̀wù. Mo bọ́ọ́lẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́, mo ní kó bá mi di kẹ̀kẹ́ mú, mo wá tiwọ́ bọ àpò aṣọ mi. Ó yà á lẹ́nu débi pé ó fetí sílẹ̀ sí ohun tí mo ní í sọ. Mo ní kó lọọ́lé lọ sùn, lẹ́yìn náà kó wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Ó kúkú wá, bí aago mẹ́ta ọ̀sán ṣe lù, ló yọ bí ọjọ́! Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, nǹkan bí ogún nínú àwọn tẹ̀wọ̀ndé ló tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ní September 1948 ni èmi pàápàá ṣe ìrìbọmi.

Ọwọ́ Mi Dí, Ṣùgbọ́n Ó Ṣàǹfààní

A fún mi ní ẹrù iṣẹ́ bíbójútó àwọn ìpínlẹ̀ tí a ó ti wàásù, kí n sì wá àwọn ibi tí a ti lè sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Láti lè ṣe èyí, nígbà mìíràn, mo máa ń gun alùpùpù mi kékeré lọ síbi tí ó tó àádọ́ta kìlómítà, kí n tó wá wọṣẹ́ alẹ́ níbi ìwakùsà. Bó bá wá di ìparí ọ̀sẹ̀, a ó wọkọ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ náà, a ó sì já akéde méjì tàbí mẹ́rin àti alásọyé síbẹ̀. Ní àwọn ìlú tó tóbi díẹ̀, tí a bá ríbi tó dáa, a ó to àpótí wa léra gègèrè, ìyẹn la fi ń ṣe tábìlì olùbánisọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà la máa ń lo pátákó àgbékọ́rùn níwájú àti lẹ́yìn láti fi polongo ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé tí a pe àwọn èèyàn sí.

Ọdún 1951 ni mo pàdé Jeannette Chauffour, Ẹlẹ́rìí kan láti Reims. Gbàrà táa ríra la ti nífẹ̀ẹ́ ara wa, a sì ṣègbéyàwó lọ́dún kan lẹ́yìn náà, ní May 17, 1952. A ṣí lọ sí Pecquencourt, ìlú tí wọ́n ti ń wa kùsà nítòsí Douai. Àmọ́ ṣá o, kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn. Wọ́n ní àrùn silicosis ló ń ṣe mí, àrùn kan tí ń mú kí èèyàn máa mí gúlegúle, ṣíṣiṣẹ́ níbi ìwakùsà ló sì máa ń fà á, mo wáṣẹ́ mìíràn títí, n kò rí. Fún ìdí yìí, ní ọdún 1955, nígbà tí wọ́n pè wá nígbà àpéjọ àgbáyé tí a ṣe nílùú Nuremberg, ní Germany, tí wọ́n ní ká lọ ran ìjọ kékeré tó wà ní ìlú Kehl lọ́wọ́, ìlú tó ní ọ̀pọ̀ iléeṣẹ́ ẹ̀rọ, tó wà lẹ́bàá Odò Rhine, kò sí ohun tó dí wa lọ́wọ́ láti lọ. Nígbà yẹn, akéde márùnlélógójì péré ló wà nínú ìjọ yẹn. Fún ọdún méje táa fi bá ìjọ náà ṣiṣẹ́, iye àwọn akéde lé sí i, ó di márùndínlọ́gọ́rùn-ún.

Àfikún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn

Nígbà tó ti di pé ìjọ náà ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa, a rọ Society pé kí wọ́n rán wa lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ilẹ̀ Faransé. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa pé ìlú Paris ni wọ́n rán wa lọ. Oyinmọmọ loṣù mẹ́jọ táa lò níbẹ̀. Àpapọ̀ iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí èmi àti Jeannette ní àǹfààní láti ṣe jẹ́ méjìlélógójì. Márùn-ún lára àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ṣèrìbọmi nígbà táa fi wà níbẹ̀, àwọn mọ́kànlá mìíràn sì tẹ́wọ́ gba òtítọ́ lẹ́yìn ìgbà táa fibẹ̀ sílẹ̀.

Nígbà tó jẹ́ pé Àdúgbò Látìn táwọn ọmọléèwé ń gbé làwa náà ń gbé, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń ṣalábàápàdé àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n láti yunifásítì Sorbonne. Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ọgbọ́n orí kan tó ti fẹ̀yìn tì, tó tún jẹ́ onígbàgbọ́ wòósàn, kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Lọ́jọ́ kan, mo bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú ẹnjiníà kan, tó ń ṣe wọlé wọ̀de pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni ẹlẹ́sìn Jesuit. Ó wá sílé wa láago mẹ́ta ọ̀sán, ó sì lọ láago mẹ́wàá alẹ́. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa nígbà tó tún padà dé lẹ́yìn wákàtí kan àtààbọ̀. Ó bá ẹlẹ́sìn Jesuit kan sọ̀rọ̀ tí kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Ìgbà tó di aago kan òru ló tó lọọ́lé, àfìgbà tó tún padà dé láago méje àárọ̀. Nígbà tó ṣe, òun náà di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Irú òùngbẹ bẹ́ẹ̀ fún òtítọ́ jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún èmi àti ìyàwó mi.

Lẹ́yìn sísìn nílùú Paris, wọ́n ní kí n wá sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Ayọ̀ ńláǹlà ló jẹ́ fún wa láti máa bẹ àwọn ìjọ tí ń sọ èdè Faransé àti àwọn èyí tí ń sọ èdè German wò, tí a ń fún àwọn ará lókun. Nígbà tí a ń bẹ ìjọ Rombas, tó wà ní ìlú Lorraine wò, mo ṣalábàápàdé Stanislas Ambroszczak. Ọmọ Poland ni, ó jagun nínú ọkọ̀ ogun abẹ́ omi nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Àwọn Olùgbèjà, ó jagun lágbami Norway. Ọ̀tá ni wá nígbà táa ń bára wa jagun lágbami kan náà. Wàyí o, a ti di arákùnrin alájọṣiṣẹ́pọ̀ ní sísin Jèhófà Ọlọ́run wa. Ní àkókò mìíràn, nígbà àpéjọ kan ní ìlú Paris, mo tajú kán rí ẹnì kan tí mo mọ̀. Òun ni ọ̀gá ibùdó tí mo ti ṣẹ̀wọ̀n ní àríwá ilẹ̀ Faransé. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti jọ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ nígbà àpéjọpọ̀ náà! Àbí ẹ ò rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti lágbára tó, ó sọ àwọn ọ̀tá di arákùnrin àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́!

Ó ṣeni láàánú pé, lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, mo ní láti dáwọ́ dúró nítorí àìlera. Bó ti wù kó rí, èmi àti ìyàwó mi pinnu láti máa bá sísin Jèhófà nìṣó pẹ̀lú gbogbo agbára wa. Nítorí náà, a wá ilé àti iṣẹ́ sí ìlú Mulhouse, ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé, a sì di aṣáájú ọ̀nà (ajíhìnrere alákòókò kíkún).

Ohun mìíràn tó ti fún mi láyọ̀ gan-an ní àwọn ọdún wọ̀nyí ni kíkópa tí mo kópa nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní ọdún 1985, wọ́n ní kí n ṣètò ẹgbẹ́ ìkọ́lé fún ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé. Nípa lílo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti kíkọ́ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni níṣẹ́, ó ṣeé ṣe fún wa láti ṣètò ẹgbẹ́ kan tó ti kópa nínú kíkọ́ tàbí ṣíṣàtúnṣe àwọn gbọ̀ngàn tó lé ní ọgọ́rin, tí a ń tipa báyìí sọ wọ́n di ibi yíyẹ fún ìjọsìn Jèhófà. Ẹ sì wo bí inú mi ti dùn tó, ní ọdún 1993, láti ṣiṣẹ́ níbi tí a ti kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan àti Gbọ̀ngàn Ìjọba márùn-ún ní orílẹ̀-èdè French Guiana, ní ilẹ̀ Gúúsù Amẹ́ríkà!

Títẹ̀síwájú Láìka Àwọn Àdánwò Sí

Mo lè sọ pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà pé fún àádọ́ta ọdún tí mo fi ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ṣe ni ìgbésí ayé mi kún fún ayọ̀ ńláǹlà àti àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ó dùn mí pé, ní December 1995, ìyàwó mi àtàtà, táa jọ wà pa pọ̀ fún ọdún mẹ́tàlélógójì, kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ẹ̀dùn ọkàn gbáà ni àkókò yẹn—ó ṣì ń dùn mí títí dòní—àmọ́ Jèhófà ń fún mi lókun, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi nípa tẹ̀mí ti fìfẹ́ hàn sí mi, wọ́n tì mí lẹ́yìn, èyí sì ti pẹ̀rọ̀ sí ìrora náà lọ́nà kan ṣá, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́.

Mo ṣì rántí dáadáa, ọ̀rọ̀ tí arákùnrin ẹni àmì òróró kan sọ ní àpéjọ kan ní ìlú Munich, Germany, ní ọdún 1963. Ó ní: “André, má wọ̀tún wòsì o. Àwọn ará tó lọ ságọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ rí àdánwò o. Àwa ló kù báyìí ká máa bá a lọ. A ò gbọ́dọ̀ máa rò pé ìyà ń jẹ wá. Nítorí náà, máa tẹ̀ síwájú nìṣó!” Mo ti fi ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn. Nísìnyí tí n kò lè ṣe púpọ̀ mọ́ nítorí àìlera àti ọjọ́ ogbó, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Hébérù 6:10 jẹ́ orísun ìtùnú fún mi nígbà gbogbo pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” Òdodo ọ̀rọ̀, ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni àǹfààní gíga jù lọ tí èèyàn lè ní. Fún àádọ́ta ọdún báyìí, góńgó tí mo ti lépa, tí mo sì ń lépa nìṣó, ni láti jẹ́ “aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.”—2 Tímótì 2:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Irú ọkọ̀ ojú omi tí mo ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀ ní àwọn ẹsẹ̀ odò tẹ́ẹ́rẹ́ ní Norway

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kẹ̀kẹ́ la fi ń wàásù ní àríwá ilẹ̀ Faransé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn àpótí tí a tò léra gègèrè ni tábìlì olùbánisọ̀rọ̀ nígbà àsọyé fún gbogbo ènìyàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Èmi àti Jeannette ìyàwó mi lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1952

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́