ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 1/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìdáríjì Mú Kí Ìgbàlà Ṣeé Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdáríjì Mú Kí Ìgbàlà Ṣeé Ṣe
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Àánú àti Ìdáǹdè
  • Jósẹ́fù Títóbi Jù
  • Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́
  • “Èmi Ha Wà ní Ipò Ọlọ́run Bí?”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Jèhófà Ò Gbàgbé Jósẹ́fù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Ẹ Jọ̀wọ́, Ẹ Fetí sí Àlá Tí Mo Lá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù Kórìíra Rẹ̀
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 1/1 ojú ìwé 30-31

Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Ìdáríjì Mú Kí Ìgbàlà Ṣeé Ṣe

ÀWỌN ọmọ Jékọ́bù mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n dúró níwájú Baṣọ̀run ilẹ̀ Íjíbítì mọ̀ nípa ọ̀ràn àṣírí kan tí etí mì-í-ì ò gbọ́dọ̀ gbọ́. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, wọ́n ta Jósẹ́fù, tó jẹ́ ọbàkan wọn sí oko ẹrú, wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti sọ fún baba wọn pé ẹranko búburú ló pa Jósẹ́fù jẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 37:18-35.

Wàyí o, nǹkan bí ogún ọdún ti kọjá, ìyàn ńlá kan sì jẹ́ kó di ọ̀ranyàn fún àwọn ọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá wọ̀nyí láti wá ra ọkà ní Íjíbítì. Ṣùgbọ́n nǹkan kò fara rọ fún wọn lọ́hùn-ún. Basọ̀run ilẹ̀ náà, tó tún jẹ́ alákòóso oúnjẹ, fẹ̀sùn kàn wọ́n pé amí ni wọ́n. Ó ju ọ̀kan nínú wọn sẹ́wọ̀n, ó sì pàṣẹ pé kí àwọn yòókù padà sílé, kí wọ́n lọ mú Bẹ́ńjámínì, àbúrò wọn tó kéré jù lọ, wá. Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, Baṣọ̀run náà dọ́gbọ́n kan kí ó bàa lè fàṣẹ ọba mú Bẹ́ńjámínì.—Jẹ́nẹ́sísì 42:1–44:12.

Júdà, ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jékọ́bù, bẹ̀bẹ̀. Ó wí pé, ‘Báa bá padà sílé láìmú Bẹ́ńjámínì lọ́wọ́, baba wa yóò kú.’ Lẹ́yìn èyí, ohun kan ṣẹlẹ̀ tí Júdà tàbí ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò kò retí rárá. Lẹ́yìn tí Baṣọ̀run ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn tí kì í ṣe ọmọ Jékọ́bù láti fi yàrá náà sílẹ̀, ó bú sẹ́kún gbẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn tí ara rẹ̀ balẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni Jósẹ́fù.”—Jẹ́nẹ́sísì 44:18–45:3.

Ojú Àánú àti Ìdáǹdè

Jósẹ́fù bi àwọn ọbàkan rẹ̀ pé: “Ṣé baba mi ṣì wà láàyè?” Kò sẹ́ni tó dáhùn. Láìṣe àní-àní, àwọn ọbàkan Jósẹ́fù kò mọ ohun tí wọn yóò sọ. Ṣé kí wọ́n máa dá músò ni, àbí kí wọ́n máa gbọ̀n jìnnìjìnnì? Ó ṣe tán, ogún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti ta ọkùnrin yìí sí oko ẹrú. Jósẹ́fù ní àṣẹ láti jù wọ́n sẹ́wọ̀n, ó lè dá wọn padà sílé láìta oúnjẹ fún wọn, tàbí—tó bá fẹ́ ṣe é dójú ẹ̀—ó lè ní kí a pa wọ́n! Abájọ tí àwọn ọbàkan Jósẹ́fù “kò [fi] lè dá a lóhùn rárá, nítorí pé ìyọnu bá wọn nítorí rẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 45:3.

Kíá ni Jósẹ́fù fi àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lára balẹ̀. Ó wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ sún mọ́ mi.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Èmi ni Jósẹ́fù arákùnrin yín, tí ẹ tà sí Íjíbítì. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ẹ má ṣe jẹ́ kí inú yín bàjẹ́, ẹ má sì ṣe bínú sí ara yín nítorí pé ẹ tà mí síhìn-ín; nítorí àtipa ìwàláàyè mọ́ ni Ọlọ́run fi rán mi ṣáájú yín.”—Jẹ́nẹ́sísì 45:4, 5.

Jósẹ́fù kò fi ojú àánú hàn sí wọn láìnídìí. Ó ti ṣàkíyèsí pé wọ́n ti ronú pìwà dà. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jósẹ́fù fẹ̀sùn kan àwọn ọbàkan rẹ̀ pé amí ni wọ́n, ó fetí kọ́ ọ, tí wọ́n ń sọ láàárín ara wọn pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, a jẹ̀bi nípa arákùnrin wa . . . Ìdí nìyẹn tí wàhálà yìí fi dé bá wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 42:21) Pẹ̀lúpẹ̀lú, kí wọ́n bàa lè dá Bẹ́ńjámínì padà sọ́dọ̀ baba wọn, Júdà sọ pé òun yóò kúkú di ẹrú dípò tí àwọn yóò fi fi í sílẹ̀ sẹ́yìn.—Jẹ́nẹ́sísì 44:33, 34.

Nítorí náà, ó tọ́ kí Jósẹ́fù nawọ́ àánú sí wọn. Ní tòótọ́, ó mọ̀ pé ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè yọrí sí ìgbàlà gbogbo ìdílé rẹ̀. Nítorí náà, Jósẹ́fù sọ fún àwọn ọbàkan rẹ̀ pé, kí wọ́n lọ bá Jékọ́bù, baba wọn, kí wọ́n sì wí fún un pé: “Èyí ni ohun tí Jósẹ́fù ọmọkùnrin rẹ wí: ‘Ọlọ́run ti yàn mí ṣe olúwa fún gbogbo Íjíbítì. Sọ̀ kalẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi. Má ṣe jáfara. Kí ìwọ sì máa gbé ilẹ̀ Góṣénì, kí o sì máa bá a lọ nítòsí mi, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ àti àwọn agbo ẹran rẹ àti ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti ohun gbogbo tí o ní. Èmi yóò sì pèsè oúnjẹ fún ọ níbẹ̀.’”—Jẹ́nẹ́sísì 45:9-11.

Jósẹ́fù Títóbi Jù

A lè pe Jésù Kristi ní Jósẹ́fù Títóbi Jù, nítorí pé ìjọra gbígbàfiyèsí wà láàárín àwọn ọkùnrin méjèèjì. Bí Jósẹ́fù, àwọn arákùnrin Jésù tí wọ́n jọ jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, hùwà ìkà sí i. (Fi wé Ìṣe 2:14, 29, 37.) Síbẹ̀, àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí ní àtúbọ̀tán tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, Jósẹ́fù tó jẹ́ ẹrú padà wá di Baṣọ̀run, igbákejì Fáráò. Lọ́nà jíjọra, Jèhófà gbé Jésù dìde kúrò nínú òkú, ó sì gbé e sí ipò gíga “sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”—Ìṣe 2:33; Fílípì 2:9-11.

Gẹ́gẹ́ bí Baṣọ̀run ilẹ̀ náà, ó ṣeé ṣe fún Jósẹ́fù láti ta oúnjẹ fún gbogbo àwọn tó wá sí ilẹ̀ Íjíbítì láti wá ra ọkà. Lónìí, Jósẹ́fù Títóbi Jù ní ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye lórí ilẹ̀ ayé, tí ó ń tipasẹ̀ wọn pèsè oúnjẹ tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45-47; Lúùkù 12:42-44) Ní tòótọ́, àwọn tí wọ́n bá tọ Jésù wá, “òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n mọ́ . . . nítorí Ọ̀dọ́ Àgùntàn, tí ó wà ní àárín ìtẹ́ náà, yóò máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn, yóò sì máa ṣamọ̀nà wọn lọ sí àwọn ìsun omi ìyè.”—Ìṣípayá 7:16, 17.

Ẹ̀kọ́ Táa Rí Kọ́

Jósẹ́fù fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ ní ti àánú. Ká ní ó fẹ́ tẹ̀ lé ìdájọ́ tí a kò gbé ka ìfòyebánilò ni, ṣe ni ì bá fìyà jẹ àwọn tó tà á sí oko ẹrú. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìmọ̀lára ì bá ti mú kí ó wulẹ̀ gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ wọn dá. Àmọ́, kò sí èyí tí Jósẹ́fù ṣe nínú méjèèjì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dán àwọn ọbàkan rẹ̀ wò bóyá wọ́n ti ronú pìwà dà. Lẹ́yìn náà, nígbà tó rí i pé ọkàn wọn bà jẹ́ ní tòótọ́, ó dárí jì wọ́n.

Àwa pẹ̀lú lè fara wé Jósẹ́fù. Nígbà tí ẹnì kan tó ṣẹ̀ wá bá fi ojúlówó ìyíkànpadà hàn, ó yẹ kí a dárí jì í. Àmọ́ ṣá o, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìmọ̀lára mú kí a gbójú fo ìwà àìtọ́ bíburú jáì. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, a kò ní jẹ́ kí ìbínú mú kí a má ka ojúlówó ìrònúpìwàdà sí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ‘a máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní kejì, kí a sì máa dárí ji ara wa fàlàlà lẹ́nì kìíní kejì.’ (Kólósè 3:13) Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa fara wé Jèhófà, Ọlọ́run wa, ẹni tó “ṣe tán láti dárí jini.”—Sáàmù 86:5; Míkà 7:18, 19.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́