“Ìyálóde Aginjù Síríà Abirun-dúdú Mìnìjọ̀”
APỌ́NBÉPORẸ́ ni, eyín rẹ̀ funfun kinniwin, ẹyinjú rẹ̀ dúdú, ó sì mọ́lẹ̀ roro. Ọ̀mọ̀wé gidi ni, ó sì tún jẹ́ ògbógi nínú ìmọ̀ èdè. A tilẹ̀ gbọ́ pé ìmọ̀ tí jagunjagun ọbabìnrin yìí ní, ju ti Cleopatra lọ, ẹwà àwọn méjèèjì sì fẹ́rẹ̀ẹ́ dọ́gba. Nítorí pé ó gbójú gbóyà láti dojú ìjà kọ agbára ayé tí ń ṣàkóso ní àkókò tirẹ̀, ó mú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí a sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ṣẹ. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí ó ti kú pàápàá, àwọn òǹkọ̀wé ṣì ń kan sáárá sí i, àwọn oníṣẹ́ ọnà sì ń gbé àwòrán rẹ̀ jáde lọ́nà tó túbọ̀ ń mú káwọn èèyàn gba tiẹ̀. Akéwì kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìyálóde aginjù Síríà abirun-dúdú mìnìjọ̀.” Obìnrin tí gbogbo ayé ń kan sáárá sí yìí ni Senobíà—ọbabìnrin ìlú Pálímírà ti ilẹ̀ Síríà.
Kí ló mú kí òkìkí Senobíà kàn tó bẹ́ẹ̀? Báwo ni ipò òṣèlú ti rí nígbà náà, tí agbára fi tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́? Kí la lè sọ nípa ìwà rẹ̀? Àsọtẹ́lẹ̀ wo sì ni ọbabìnrin yìí mú ṣẹ? Kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò àgbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Ìlú Ńlá Tí Ó Wà Létí Aṣálẹ̀
Pálímírà, ìlú Senobíà, wà ní nǹkan bí ẹẹ́wàálénígba kìlómítà sí ìlà oòrùn àríwá Damásíkù, ní etí àríwá Aṣálẹ̀ Síríà, níbi tí àwọn òkè Anti-Lẹ́bánónì ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọnú ilẹ̀ títẹ́jú. Òkun Mẹditaréníà wà ní ìwọ̀ oòrùn, Odò Yúfírétì wà ní ìlà oòrùn, ìlú náà wá wà ní ibi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ agbedeméjì. Ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì Ọba ti mọ̀ ọ́n sí Tádímórì, ibì kan tó jẹ́ ibi pàtàkì fún ire ìjọba rẹ̀ nítorí ìdí méjì: ó jẹ́ ibùdó àwọn ológun fún dídáàbò bo ìhà àríwá, ó sì tún jẹ́ ìkóríta ọ̀nà àwọn arìnrìn-àjò. Nítorí náà, Sólómọ́nì “tún Tádímórì ní aginjù kọ́.”—2 Kíróníkà 8:4.
Ìtàn ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìṣàkóso Sólómọ́nì Ọba kò sọ ohunkóhun nípa Tádímórì. Bó bá jẹ́ pé òun náà là ń pè ní Pálímírà, a jẹ́ pé ọdún 64 ṣááju Sànmánì Tiwa ni òkìkí rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kàn, lẹ́yìn tí Síríà di àgbègbè ẹ̀yin ibùdó fún Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Richard Stoneman nínú ìwé rẹ̀, Palmyra and Its Empire—Zenobia’s Revolt Against Rome, sọ pé: “Ọ̀nà méjì ni Pálímírà gbà ṣe pàtàkì fún Róòmù, ti ọrọ̀ ajé àti ti ológun.” Níwọ̀n bí ìlú tí igi ọ̀pẹ pọ̀ sí yìí ti jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí àwọn oníṣòwò ń gbà, tí ó so Róòmù mọ́ Mesopotámíà àti Ìlà Oòrùn, ibẹ̀ ni wọ́n ń kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ayé ìgbàanì gbà—àwọn èròjà amóúnjẹ ta sánsán láti Ìlà Oòrùn Indies, aṣọ ṣẹ́dà láti China, àti àwọn ọjà mìíràn láti Páṣíà, Ìsàlẹ̀ Mesopotámíà, àti àwọn ilẹ̀ Mẹditaréníà. Ọjà wọ̀nyí tí ń wọlé sí Róòmù láti ilẹ̀ òkèèrè ló mẹ́sẹ̀ rẹ̀ dúró.
Ní ti ológun, ẹkùn Síríà ni àgbègbè tó pààlà sáàárín agbára ayé Róòmù àti ti Páṣíà, tí ń bá ara wọn ṣorogún. Ní àádọ́talénígba ọdún àkọ́kọ́ nínú Sànmánì Tiwa yìí ni odò Yúfírétì pín Róòmù níyà kúrò lára àwọn ìlú tó wà nítòsí rẹ̀ ní apá ìlà oòrùn. Gẹ́rẹ́ níkọjá aṣálẹ̀ ni Pálímírà wà, ní ìwọ̀ oòrùn ìlú Dura-Europos lẹ́bàá Yúfírétì. Nítorí tí àwọn ọba Róòmù bí Hadrian àti Valerian mọ̀ pé ipò pàtàkì ni Pálímírà dì mú, wọ́n wá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Hadrian fi kún àwọn ilé kíkọyọyọ tí ń bẹ nínú ìlú náà, ó sì fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ta á lọ́rẹ. Valerian san èrè fún ọ̀tọ̀kùlú Pálímírà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odaenathus—ọkọ Senobíà—nípa gbígbé e sí ipò aṣojú ọba Róòmù ní ọdún 258 Sànmánì Tiwa, ìdí ni pé, ọkùnrin yìí ti ṣàṣeyọrí nínú rírẹ́yìn Páṣíà àti mímú kí ààlà Ilẹ̀ Ọba Róòmù dé Mesopotámíà. Senobíà kó ipa pàtàkì nípa bí agbára ṣe bọ́ sí ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́. Òpìtàn náà, Edward Gibbon, kọ̀wé pé: “Òye àti ìfàyàrán rẹ̀ [Senobíà] tí kò láfiwé wà lára ìdí pàtàkì tó jẹ́ kí Odaenathus ṣàṣeyọrí.”
Láàárín àkókò kan náà, Sapor Ọba Páṣíà pinnu láti dojú ìjà kọ ìjọba Róòmù, kí ó sì di aláṣẹ lórí gbogbo ẹkùn Páṣíà àtijọ́. Pẹ̀lú àkòtagìrì ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀, ó kọrí sí ìwọ̀ oòrùn, ó ṣẹ́gun ibùdó àwọn ológun tó jẹ́ ti Róòmù, tó wà ní Nisibis àti Carrhae (Háránì), ó sì tẹ̀ síwájú láti fọ́ àríwá Síríà àti Sìlíṣíà túútúú. Ọba Valerian fúnra rẹ̀ ló ṣáájú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ láti bá àwọn ọ̀tá jà, ṣùgbọ́n àwọn ará Páṣíà ṣẹ́gun rẹ̀, wọ́n sì mú un lóǹdè.
Odaenathus gbà pé ó tó àkókò wàyí láti wá fi àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye ránṣẹ́ sí ọba Páṣíà, kí òun sì mú un dá a lójú pé tirẹ̀ lòún ń ṣe. Sapor Ọba kò tilẹ̀ ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí rárá, ṣe ló pàṣẹ pé kí wọ́n lọ kó àwọn ẹ̀bùn náà dà sínú odò Yúfírétì, ó tún ní kí Odaenathus fara hàn níwájú òun kíá, pé ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn òǹdè. Ìhùwàpadà àwọn ará Pálímírà ni pé, wọ́n kó àwọn tí ń ṣí kiri nínú aṣálẹ̀ àti àṣẹ́kù ọmọ ogun Róòmù jọ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fogun lé àwọn ará Páṣíà tó ti di dandan fún láti sá. Ọgbọ́n màjàmàsá tí àwọn jagunjagun inú aṣálẹ̀ lò da ẹgbẹ́ ọmọ ogun Sapor ríborìbo—ìgbéjàkoni léraléra ti mú kí àárẹ̀ mú wọn, ẹrù tí wọ́n gbé ti wọ̀ wọ́n lọ́rùn—ni wọ́n bá fẹsẹ̀ fẹ.
Inú Gallienus, ọmọ Valerian tó rọ́pò rẹ̀, dùn gan-an fún ṣíṣẹ́gun tí Odaenathus ṣẹ́gun Sapor, fún ìdí yìí, ó fi oyè corrector totius Orientis (gómìnà gbogbo Ìlà Oòrùn) dá Odaenathus lọ́lá. Nígbà tó yá, Odaenathus fi oyè “ọba àwọn ọba” dá ara rẹ̀ lọ́lá.
Senobíà Fẹ́ Dá Ilẹ̀ Ọba Sílẹ̀
Ní ọdún 267 Sànmánì Tiwa, nígbà tí òkìkí rẹ̀ ń kàn gan an, wọ́n pa Odaenathus àti àrẹ̀mọ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ arákùnrin rẹ̀ kan tó fẹ́ gbẹ̀san ló pa wọ́n. Nítorí pé ọmọ Senobíà ṣì kéré, ló bá kúkú bọ́ sí ipò ọkọ rẹ̀. Nítorí pé obìnrin yìí lẹ́wà bí egbin, ó fẹ́ ipò ọlá, ó dáńgájíá ni ti ká ṣètò ìlú, ó máa ń bá ọkọ rẹ̀ lọ sójú ogun, ọ̀pọ̀ èdè sì yọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ṣàṣeyọrí ní rírí i pé àwọn tí òun ń ṣàkóso bọ̀wọ̀ fún òun, wọ́n sì kọ́wọ́ tì í lẹ́yìn—ó ṣe bẹbẹ láàárín àwọn Bedouin. Senobíà kì í fi ìmọ̀ ṣeré rárá, ó ní àwọn ọ̀mọ̀wé tó yí i ká. Ọ̀kan lára àwọn tí ń bá a dámọ̀ràn ni ọlọ́gbọ́n èrò orí àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́, Cassius Longinus—ẹni táa gbọ́ pé “igi ìwé àti àká ìmọ̀” lòun alára. Òǹkọ̀wé náà, Stoneman, sọ pé: “Ní ọdún márùn-ún lẹ́yìn ikú Odaenathus . . . Senobíà jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ̀ pé òun ni ìyálóde Ìlà Oòrùn.”
Páṣíà tí Senobíà àti ọkọ rẹ̀ ti sọ dilẹ̀, wà ní ìhà kan ilẹ̀ àkóso rẹ̀, Róòmù tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ẹdun arinlẹ̀ ló wà ní òdì kejì. Nígbà tí òpìtàn náà, J. M. Roberts ń sọ nípa ipò Ilẹ̀ Ọba Róòmù nígbà yẹn, ó ní: “Ọ̀rúndún kẹta . . . gbóná janjan mọ́ Róòmù ní ààlà tí ó wà ní ìlà oòrùn àti ti ìwọ̀ oòrùn, nínú ìlú gan-an, ogun abẹ́lé ń lọ lọ́wọ́, ìjà àwọn tí ń du oyè sì ti bẹ̀rẹ̀. Ọba méjìlélógún (láìka àwọn tí ń du oyè) ló gorí oyè.” Ní òdìkejì pátápátá, ìyálóde ilẹ̀ Síríà di ọbabìnrin tí ìjọba rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní àgbègbè tirẹ̀. Stoneman ṣàlàyé pé: “Nígbà tó ti jẹ́ pé òun ló ń jẹ́ kí ilẹ̀ ọba méjèèjì [ti Páṣíà àti Róòmù] fẹsẹ̀ múlẹ̀, ó lè dá ilẹ̀ ọba kẹta tí yóò gborí lọ́wọ́ méjèèjì sílẹ̀.”
Senobíà láǹfààní láti sọ agbára rẹ̀ di ńlá ní ọdún 269 Sànmánì Tiwa, nígbà tí ẹnì kan dìde ní Íjíbítì tó ń du ipò ọba Róòmù. Láìsọsẹ̀, àwọn ọmọ ogun Senobíà ti gbéra, ó di Íjíbítì, wọ́n run àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, wọ́n sì gba orílẹ̀-èdè náà mọ́ wọn lọ́wọ́. Bó ṣe ń kéde pé òun ní ọbabìnrin Íjíbítì, ló rọ owó ẹyọ tí a kọ orúkọ rẹ̀ sí. Báyìí ni ìjọba rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ láti odò Náílì tó fi dé odò Yúfírétì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìjọba rẹ̀ ìgbà náà ló ń ṣàkóso àgbègbè gúúsù ìlú Dáníẹ́lì, ní sáà yìí nínú ìgbésí ayé rẹ̀, òun ló di ipò “ọba gúúsù” mú, èyí tí àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì inú Bíbélì sọ. (Dáníẹ́lì 11:25, 26) Ó tún ṣẹ́gun apá tó pọ̀ jù lọ ní Éṣíà Kékeré.
Senobíà sọ Pálímírà, olú ìlú ìjọba rẹ̀ di alágbára àti ibi àpéwò, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí òkìkí ìlú náà fi kàn káàkiri bí ti àwọn ìlú ńláńlá mìíràn nílẹ̀ Róòmù. Iye ènìyàn tí a fojú bù pé ó ń gbé níbẹ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún tó ọ̀kẹ́ méje ààbọ̀ [150,000]. Ìlú náà kún fún àwọn ilé ìjọba tó fakíki, tẹ́ńpìlì àwòyanu, ọgbà ìtura ẹlẹ́wà, àwọn òpó tó dúró sán-ún, àti àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó jojú ní gbèsè, wọ́n sì fi odi tí fífẹ̀ rẹ̀ tó kìlómítà mọ́kànlélógún níbùú yí i ká. Àwọn ìloro tí wọ́n ga ní mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí wọ́n wà lẹ́sẹẹsẹ bí ti Kọ́ríńtì—nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500]—ló wà ní àwọn òpópónà tó gbajúmọ̀. Àwọn ère bọrọgidi àti ti orí àwọn akọni pẹ̀lú ère àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n ti fowó wọn ṣàánú, kún inú ìlú yìí. Nígbà tó wá di ọdún 271 Sànmánì Tiwa, Senobíà ṣe ère méjì, ìkan tirẹ̀, èkejì ti ọkọ rẹ̀ tó dolóògbé. Etí aṣálẹ̀ ni Pálímírà kúkú wà, tó ti ń dán gbinrin bí ẹ̀ha idẹ.
Tẹ́ńpìlì Oòrùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tó dára jù lọ ní Pálímírà, òun sì ló borí gbogbo ẹ̀sìn tó wà nílùú náà. Ó jọ pé Senobíà pẹ̀lú jọ́sìn irúnmọlẹ̀ kan tí wọ́n kà sí ọlọ́run oòrùn. Ká sọ̀rọ̀ síbi ọ̀rọ̀ wà, ilẹ̀ ẹlẹ́sìn rẹpẹtẹ ni Síríà ti ọ̀rúndún kẹta. Ní ilẹ̀ àkóso Senobíà, bí a ṣe rí àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni, bẹ́ẹ̀ la rí àwọn Júù, àwọn awòràwọ̀, àti àwọn tí ń bọ oòrùn àti òṣùpá. Ojú wo ló fi wo onírúurú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ní ilẹ̀ rẹ̀? Òǹṣèwé náà, Stoneman, ṣàlàyé pé: “Kò sí alákòóso onílàákàyè tí yóò fọwọ́ rọ́ àṣà tó rí i pé ó bá àwọn ènìyàn rẹ̀ mu tì . . . Ìgbàgbọ́ . . . àwọn ènìyàn ni pé àwọn ọlọ́run wà lẹ́yìn Pálímírà.” Ó hàn gbangba pé, Senobíà kò ní kí ẹlẹ́sìn èyíkéyìí má ṣe tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn ọlọ́run “wà lẹ́yìn Pálímírà”? Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Pálímírà àti “alákòóso onílàákàyè” rẹ̀?
Ọba Kan ‘Ru Ọkàn-Àyà Rẹ̀ Dìde’ Sí Senobíà
Ní ọdún 270 Sànmánì Tiwa, Aurelian di ọba Róòmù. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá rẹ̀ lé àwọn kògbédè tó wà ní ìhà àríwá tèfètèfè, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n. Ní ọdún 271 Sànmánì Tiwa, Aurelian—tó dúró fún “ọba àríwá” ti inú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì báyìí—“ru agbára àti ọkàn-àyà rẹ̀ dìde sí ọba gúúsù,” tí Senobíà dúró fún. (Dáníẹ́lì 11:25a) Aurelian rán àwọn kan lára ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí Íjíbítì tààrà, òun alára sì kó apá tó lágbára jù lọ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí ìlà oòrùn nípa gbígba ọ̀nà Éṣíà Kékeré.
Ọba gúúsù—orílẹ̀-èdè tí Senobíà ń ṣàkóso—“ru ara rẹ̀ sókè” nípa lílo “ẹgbẹ́ ológun kan tí ó pọ̀ lọ́nà tí ó peléke tí ó sì lágbára ńlá” lábẹ́ àwọn ọ̀gágun àgbà méjì, Zabdas àti Zabbai, láti bá Aurelian jà. (Dáníẹ́lì 11:25b) Ṣùgbọ́n, Aurelian ṣẹ́gun Íjíbítì, òun pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì kọjú ìjà sí Éṣíà Kékeré àti Síríà. Emesa (tí a ń pè ní Homs báyìí) ni wọ́n ti ṣẹ́gun Senobíà, kíá ló sá padà sí Pálímírà.
Nígbà tí Aurelian tún kógun rẹ̀ dé Pálímírà, ni Senobíà, tó rò pé òun yóò rí olùgbèjà, bá sá gba ọ̀nà Páṣíà lọ tòun ti ọmọ rẹ̀, Odò Yúfírétì ló dé tí ọwọ́ ṣìnkún àwọn ará Róòmù fi tẹ̀ ẹ́. Èyí ló mú kí àwọn ará Pálímírà yọ̀ọ̀da ìlú wọn ní ọdún 272 Sànmánì Tiwa. Aurelian mà fojú àwọn olùgbé ibẹ̀ rí nǹkan o, ó kẹ́rú, ó kẹ́rù, àní ó gbé ère kan nínú Tẹ́ńpìlì Oòrùn, ló bá padà sí Róòmù. Àmọ́ ṣá o, Ọba Róòmù yìí kò pa Senobíà, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ṣe ẹni àpéwò àrà ọ̀tọ̀ nígbà ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun tó ṣe la Róòmù já ní ọdún 274 Sànmánì Tiwa. Senobíà lo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí màmá Róòmù.
Wọ́n Run Ìlú Aṣálẹ̀ Náà
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Aurelian ti ṣẹ́gun Pálímírà, àwọn ará Pálímírà pa àwọn ọmọ ogun Róòmù tó fi sílẹ̀ nípakúpa. Nígbà tí ìròyìn ìṣọ̀tẹ̀ yìí dé etígbọ̀ọ́ Aurelian, kíá ló pàṣẹ pé kí àwọn jagunjagun rẹ̀ wá wọn lọ, lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ṣe àwọn ará ìlú ọ̀hún bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣojú. Wọ́n kó àwọn tí ikú oró náà fò dá lẹ́rú. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ ẹrù ìlú agbéraga yìí lọ, wọ́n wá run ìlú náà débi pé kò látùn-únṣe mọ́. Báyìí ni ìlú ńlá, tí èrò ti ń wọ́ tìrítìrí ṣe padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀—“Tádímórì ní aginjù.”
Nígbà tí Senobíà dojú ìjà kọ Róòmù, òun àti Aurelian Ọba kó ipa wọn gẹ́gẹ́ bí “ọba gúúsù” àti “ọba àríwá,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mọ̀, wọ́n tipa báyìí mú apá kan àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, èyí tí wòlíì Jèhófà kọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún ṣáájú. (Dáníẹ́lì, orí 11) Ìwà tó fani mọ́ra púpọ̀ tí Senobíà ní ló fi di ẹni tí ọ̀pọ̀ ń kan sáárá sí. Àmọ́ ṣá o, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni ti ipa tó kó ní ti dídúró tí ó dúró fún orílẹ̀-èdè tí a ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì. Ọdún márùn-ún péré ló fi ṣàkóso. Lónìí, abúlé lásán ni Pálímírà, olú ìlú ìjọba Senobíà. Àní Ilẹ̀ Ọba Róòmù alágbára ńlá pàápàá ti dìgbàgbé tipẹ́tipẹ́, ó ti bọ́ sábẹ́ àwọn ìjọba òde òní. Báwo ní ọjọ́ ọ̀la àwọn agbára ayé wọ̀nyí yóò ti rí? Ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí kì í kùnà ni yóò darí ohun tí yóò gbẹ̀yìn wọn.—Dáníẹ́lì 2:44.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ohun tí Senobíà Fi Sílẹ̀ Lọ
Gbàrà tí Aurelian Ọba padà dé sí Róòmù lẹ́yìn tí ó ti ṣẹ́gun Senobíà, ọbabìnrin Pálímírà, ó kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún oòrùn. Ó gbé ère ọlọ́run oòrùn tí ó gbé wá láti ìlú ọbabìnrin náà sínú rẹ̀. Ìwé ìròyìn History Today, nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan mìíràn tó ṣẹlẹ̀, sọ pé: “Ìgbésẹ̀ tó jẹ́ mánigbàgbé jù lọ nínú àwọn ìgbésẹ̀ Aurelian fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ yíyàn tí ó yan December 25, ọjọ́ kan láàárín ìgbà òtútù, ní ọdún 274 Sànmánì Tiwa, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọn yóò máa bọ oòrùn. Nígbà tí ilẹ̀ ọba yìí gba ẹ̀sìn Kristẹni, ni wọ́n wá gbé ọjọ́ ìbí Kristi wá sí ọjọ́ yìí, kí àwọn tí wọ́n ti kúndùn pọ̀pọ̀ṣìnṣìn ayẹyẹ ti tẹ́lẹ̀ lè gba ẹ̀sìn tuntun yìí. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà lèyí, pé, nítorí Ọbabìnrin Senobíà . . . ni [àwọn èèyàn] ṣe ń ṣe Kérésìmesì.”
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28, 29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ
SÍRÍÀ
Áńtíókù
Emesa (Homs)
PÁLÍMÍRÀ
Damásíkù
MESOPOTÁMÍÀ
Yúfírétì
Carrhae (Háránì)
Nisibis
Dura-Europos
[Àwọn Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
Àwọn Ìloro: Michael Nicholson/Corbis
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Owó ẹyọ Róòmù tó jọ pé àwòrán Aurelian ló wà lára rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Tẹ́ńpìlì oòrùn ní Pálímírà
[Credit Line]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ọbabìnrin Senobíà ń bá àwọn jagunjagun rẹ̀ sọ̀rọ̀
[Credit Line]
Giovanni Battista Tiepolo, Queen Zenobia Addressing Her Soldiers, Samuel H. Kress Collection, Photograph © Board of Trustees, National Gallery of Art, Washington
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Kúlẹ̀kúlẹ̀: Giovanni Battista Tiepolo, Queen Zenobia Addressing Her Soldiers, Samuel H. Kress Collection, Photograph © Board of Trustees, National Gallery of Art, Washington