ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 2/1 ojú ìwé 30-31
  • Ṣé “Jèhófà” Ni, Àbí “Yahweh”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé “Jèhófà” Ni, Àbí “Yahweh”?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó Fa Àríyànjiyàn
  • Kí Ni Ìjẹ́pàtàkì Orúkọ?
  • Kí Nìdí Tá A Fi Ń Lo Orúkọ Ọlọ́run Nígbà Tá Ò Mọ Bí Wọ́n Ṣe Ń Pè É?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Orukọ Ọlọrun—Itumọ ati Pípè Rẹ̀
    Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae
  • Ta Ni Jèhófà?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Dídá Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo náà Mọ̀
    Jí!—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 2/1 ojú ìwé 30-31

Ṣé “Jèhófà” Ni, Àbí “Yahweh”?

“ÀDÀMỌ̀DÌ ọ̀rọ̀,” “ọ̀rọ̀ àyálò,” “ọ̀rọ̀ àràmàǹdà.” Kí ló lè mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa èdè Hébérù táa fi kọ Bíbélì máa lo irú àwọn ọ̀rọ̀ líle-líle bẹ́ẹ̀? Ohun tí wọ́n ń jà lé lórí ni bóyá “Jèhófà” ni ọ̀nà tó yẹ ká máa gbà pe orúkọ Ọlọ́run. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí àríyànjiyàn náà ti wà nílẹ̀. Lónìí, ó jọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yàn láti máa lo “Yahweh” tó jẹ́ sílébù méjì. Ṣùgbọ́n, ṣé lóòótọ́ ni pé pípè náà, “Jèhófà” jẹ́ “ọ̀rọ̀ àràmàǹdà”?

Ohun Tó Fa Àríyànjiyàn

Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ló sọ orúkọ rẹ̀ fáráyé. (Ẹ́kísódù 3:15) Ẹ̀rí láti inú Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ìgbàanì lo orúkọ yẹn ní fàlàlà. (Jẹ́nẹ́sísì 12:8; Rúùtù 2:4) Àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ orúkọ Ọlọ́run pẹ̀lú. (Jóṣúà 2:9) Ní pàtàkì ni èyí rí bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn Júù tó ti ìgbèkùn Bábílónì dé ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè. (Sáàmù 96:2-10; Aísáyà 12:4; Málákì 1:11) Ìwé náà, The Interpreter’s Dictionary of the Bible sọ pé: “Ẹ̀rí púpọ̀ wà tó fi hàn pé lẹ́yìn táwọn Júù tìgbèkùn dé, ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ló bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn sí ẹ̀sìn àwọn Júù.” Àmọ́ o, nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ìgbàgbọ́ òdì kan dìde nípa orúkọ Ọlọ́run. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn Júù ṣíwọ́ lílo orúkọ Ọlọ́run ní gbangba, àfi bí ẹni pé ìyẹn kò tó, àwọn kan tilẹ̀ tún kà á léèwọ̀ pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ pe orúkọ yẹn rárá. Bó ṣe di pé kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n pè mọ́ nìyẹn—àbí a ṣì ráwọn tó mọ̀ ọ́n pè?

Kí Ni Ìjẹ́pàtàkì Orúkọ?

Nínú èdè Hébérù, báa ṣe ń kọ orúkọ Ọlọ́run nìyí יהוה. Lẹ́tà mẹ́rin yìí, tí a máa ń kà láti ọwọ́ ọ̀tún sí òsì, la sábà máa ń pè ní Tetragrammaton [lẹ́tà Hébérù mẹ́rin tí ó dúró fún orúkọ Ọlọ́run]. Ọ̀pọ̀ orúkọ àwọn èèyàn àti àwọn ibi táa mẹ́nu kàn nínú Bíbélì ló ní ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run nínú. Orúkọ wọ̀nyí ha lè pèsè ojútùú sí bí a ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run bí?

Bẹ́ẹ̀ ni o, ni ìdáhùn George Buchanan, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n-dọjọ́ọkú ní Wesley Theological Seminary, Washington, D.C., U.S.A. Ọ̀jọ̀gbọ́n Buchanan ṣàlàyé pé: “Láyé àtijọ́, orúkọ ọlọ́run tí àwọn òbí ń sìn ni wọ́n sábà máa ń sọ àwọn ọmọ wọn. Ìyẹn túmọ̀ sí pé bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ àwọn ọlọ́run yẹn gẹ́lẹ́ ni wọn yóò máa pe ọmọ wọn. Tetragrammaton wà nínú orúkọ àwọn èèyàn kan, wọ́n sì sábà máa ń lo fáwẹ̀lì àárín.”

Gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn orúkọ táa rí nínú Bíbélì tó ní ìkékúrú orúkọ Ọlọ́run nínú. Jónátánì, tó jẹ́ Yoh·na·thanʹ tàbí Yehoh·na·thanʹ nínú Bíbélì èdè Hébérù, túmọ̀ sí “Yaho tàbí Yahowah ló fún mi,” ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Buchanan sọ. Orúkọ wòlíì Èlíjà lédè Hébérù ni ʼE·li·yahʹ tàbí ʼE·li·yaʹhu. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Buchanan ti wí, orúkọ yìí túmọ̀ sí: “Yahoo tàbí Yahoo-wah ni Ọlọ́run mi.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, orúkọ tí a ń pe Jèhóṣáfátì lédè Hébérù ni Yehoh-sha·phatʹ, ó sì túmọ̀ sí “Yaho ti ṣèdájọ́.”

Bó bá ṣe pé “Yahweh” tó jẹ́ sílébù méjì ni bí a ṣe ń pe Tetragrammaton, kò ní ṣeé ṣe láti lo fáwẹ̀lì oníròó o gẹ́gẹ́ bí apá kan orúkọ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ inú Bíbélì tó ní orúkọ Ọlọ́run nínú, ìró fáwẹ̀lì àárín yìí fara hàn nínú pípè ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti èyí táa ké kúrú, bí àpẹẹrẹ, Jèhónátánì àti Jónátánì. Fún ìdí yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Buchanan sọ nípa orúkọ Ọlọ́run pé: “Kò sígbà kankan táwọn èèyàn pa fáwẹ̀lì náà oo tàbí oh jẹ rí. Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń ké e kúrú sí ‘Ya,’ ṣùgbọ́n kì í ṣe sí ‘Ya-weh.’ . . . Nígbà tí wọ́n bá lo sílébù kan fún Tetragrammaton, ‘Yah’ tàbí ‘Yo’ ni wọ́n máa ń lò. Nígbà tí wọ́n bá lo sílébù mẹ́ta fún un ‘Yahowah’ tàbí ‘Yahoowah’ ni yóò jẹ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ rárá pé wọ́n ké e kúrú sí sílébù méjì, ‘Yaho’ ni yóò jẹ́.”—Biblical Archaelogy Review.

Àlàyé wọ̀nyí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye gbólóhùn tó jáde lẹ́nu Gesenius, tó gbé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí í ṣe ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Hébérù, nínú ìwé rẹ̀, Hebrew and Chaldee Lexicon to the Old Testament Scriptures, pé: “Àwọn tó bá sọ pé יְהוָֹה [Ye-ho-wah] ni ọ̀nà tó tọ́ láti gbà pe [orúkọ Ọlọ́run] kò ṣàìní ẹ̀rí tó ti èrò wọn lẹ́yìn. Àfi báa bá gbà pé ọ̀nà yìí la gbà ń pe orúkọ Ọlọ́run, ìgbà yẹn nìkan làwọn sílébù táa ké kúrú náà, יְהוֹ [Ye-ho] àti יוֹ [Yo], tó lè ṣeé ṣàlàyé lọ́nà tó tẹ́ni lọ́rùn.”

Síbẹ̀síbẹ̀, Everett Fox ṣàlàyé nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú ìwé rẹ̀, tó ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí, The Five Books of Moses, pé: “Ìsapá àtẹ̀yìnwá àti ti lọ́wọ́lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó ‘tọ́’ láti gbà pe orúkọ [Ọlọ́run] lédè Hébérù kò tíì kẹ́sẹ járí; ì báà ṣe ‘Jèhófà’ táa sábà máa ń gbọ́ ni o, tàbí ‘Yahweh’ táwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fọwọ́ sí ni o, kò sí ìkankan nínú méjèèjì tí a lè fẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.”

Ó dájú pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ á ṣì máa jiyàn nìṣó. Àwọn Júù ṣíwọ́ pípe orúkọ Ọlọ́run tòótọ́ kó tó di pé àwọn Másórétì bẹ̀rẹ̀ fífàmì síbi tí fáwẹ̀lì wà. Nípa báyìí, kò sí báa ṣe lè sọ àwọn fáwẹ̀lì tí wọ́n ń lò pẹ̀lú àwọn kóńsónáǹtì náà, YHWH (יהוה), pẹ̀lú ìdánilójú. Síbẹ̀, orúkọ àwọn èèyàn táa rí nínú Bíbélì—tó jẹ́ pé a ṣì mọ báa ṣe ń pe orúkọ wọn lọ́nà tó tọ́—fún wa ní ojútùú tó ṣe gúnmọ́ nípa bí àwọn èèyàn ìgbàanì ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run. Fún ìdí yìí, ó kéré tán, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbà pé orúkọ náà, “Jèhófà,” kò kúkú fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ọ̀rọ̀ àràmàǹdà.”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

“Jèhófà” ni ọ̀nà tó gbajúmọ̀ jù lọ tí a gbà ń pe orúkọ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́