Sílà—Orísun Ìṣírí
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀PẸ̀PẸ̀ ìtàn ẹ̀sìn Kristẹni, ìgbòkègbodò àwọn olóòótọ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ṣe pàtàkì fún fífún ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run níṣìírí àti fún títan ìhìn rere náà dé àwọn apá ibi jíjìnnà réré jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Sílà, tó jẹ́ wòlíì, tó sì tún jẹ́ òléwájú nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn alábòójútó tí a kọ́kọ́ yàn nígbà náà lọ́hùn-ún. Ó ṣe gudugudu méje nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó tan mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wàásù ní àgbègbè Yúróòpù. Kí ló mú kí Sílà ní pàtàkì tóótun dáadáa láti ṣe gbogbo èyí? Kí sì ni ànímọ́ rẹ̀ tó yẹ ká fara wé?
Ọ̀ràn Ìdádọ̀dọ́
Ní ọdún 49 Sànmánì Tiwa, nígbà tí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ tó fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ wáyé, ó pọndandan fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso tó wà ní Jerúsálẹ́mù láti fi ìsọfúnni tó ṣe kedere tó àwọn Kristẹni létí, kí ọ̀ràn náà bàa lè ní ìyanjú. Nínú ọ̀ràn yìí, orúkọ Sílà, tí a tún ń pè ní Sílífánù, fara hàn nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí Sílà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí “àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin” yàn gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọn láti fi ìpinnu wọn tó “àwọn ará . . . ní Áńtíókù àti Síríà àti Sìlíṣíà” létí. Ní Áńtíókù, Sílà àti Júdásì (Básábà), pẹ̀lú Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, fi ohun tí wọ́n fi rán wọn jíṣẹ́, ó ṣe kedere pé, wọ́n ṣàlàyé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù, ìparí èrò tí wọ́n dé, àti ohun tó wà nínú lẹ́tà ọwọ́ wọn. Wọ́n tún “fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.” Àbájáde tó múni láyọ̀ ni pé àwọn Kristẹni ní Áńtíókù “yọ̀.”—Ìṣe 15:1-32.
Nípa báyìí, Sílà kó ipa pàtàkì nínú yíyanjú ọ̀ràn tó lè dá yánpọnyánrin sílẹ̀ yìí. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ tí a gbé lé e lọ́wọ́ yìí kò rọrùn. Kò sí ọ̀nà àtimọ irú ẹ̀mí tí ìjọ Áńtíókù yóò fi gba ìpinnu wọn. Nípa báyìí, gẹ́gẹ́ bí alálàyé kan ti sọ, “wọ́n nílò ẹnì kan tí ó jẹ́ onílàákàyè, tí ó sì ní òye tó fi lè ṣàlàyé ohun tí àwọn àpọ́sítélì kọ sínú lẹ́tà wọn.” Yíyàn tí wọ́n yan Sílà fún irú iṣẹ́ tó gbẹgẹ́ báyìí jẹ́ kí a mọ irú ẹni tó jẹ́. Ó jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé pé yóò ṣe iṣẹ́ tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso rán an dé ojú àmì. Bákan náà ó ní láti jẹ́ alábòójútó tó ní làákàyè, tó mọ bí a ṣe lè fọgbọ́n pẹ̀tù sí ọkàn ìjọ nígbà tí awuyewuye bá fẹ́ da nǹkan rú.
Ó Rìnrìn Àjò Pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù
Kò dájú bóyá Sílà padà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ yẹn. Bó ti wù kó rí, lẹ́yìn aáwọ̀ tó wà láàárín Bánábà àti Pọ́ọ̀lù nípa Jòhánù Máàkù, Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ẹni tó wà ní Áńtíókù nígbà yẹn, fún ìrìn àjò tuntun tí a kọ́kọ́ pète láti fi lọ padà ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìlú tí Pọ́ọ̀lù ti wàásù tẹ́lẹ̀ nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ àkọ́kọ́.—Ìṣe 15:36-41.
Ohun tó ṣeé ṣe kó mú kí Pọ́ọ̀lù yan Sílà ni ẹ̀mí rere tí Sílà ní sí iṣẹ́ tí wọ́n ti kọ́kọ́ rán wọn sáwọn Kèfèrí, àti ọlá àṣẹ tí ó ní gẹ́gẹ́ bí wòlíì àti agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ olùṣàkóso, láti fi sọ ìpinnu wọn fún àwọn onígbàgbọ́ ní Síríà àti Sìlíṣíà. Ìyọrísí rẹ̀ mà kọyọyọ o. Ìwé Ìṣe sọ pé: “Wàyí o, bí wọ́n ti ń rin ìrìn àjò la àwọn ìlú ńlá náà já, wọn a fi àwọn àṣẹ àgbékalẹ̀ tí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí ń bẹ ní Jerúsálẹ́mù ti ṣe ìpinnu lé lórí jíṣẹ́ fún àwọn tí ń bẹ níbẹ̀, kí wọ́n lè máa pa wọ́n mọ́. Nítorí náà, ní tòótọ́, àwọn ìjọ ń bá a lọ ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ àti ní pípọ̀ sí i ní iye láti ọjọ́ dé ọjọ́.”—Iṣe 16:4, 5.
Bí àwọn míṣọ́nnárì náà ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, ìgbà méjì ni ẹ̀mí mímọ́ darí wọn gba ibòmíràn. (Ìṣe 16:6, 7) Lísírà ni wọ́n dé lẹ́nu ìrìn àjò wọn nígbà tí wọ́n fi Tímótì kún ikọ̀ náà, lẹ́yìn “ìsọtẹ́lẹ̀” nípa rẹ̀, tí a kò sọ irú èyí tí ó jẹ́. (1 Tímótì 1:18; 4:14) Nípasẹ̀ ìran kan tí a fi han Pọ́ọ̀lù, ẹni tó jẹ́ pé òun pẹ̀lú ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, a darí àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò láti wọkọ̀ òkun gba Makedóníà lọ, ní Yúróòpù.—Ìṣe 16:9, 10.
Wọ́n Lù Ú, Wọ́n Tún Fi Í Sẹ́wọ̀n
Sílà kò lè gbàgbé ohun tójú rẹ̀ rí ní Fílípì, “olú ìlú ńlá ní àgbègbè [náà].” Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù lé ẹ̀mí ìwoṣẹ́ jáde kúrò lára ẹrúbìnrin kan, tí àwọn olówó ẹrú náà sì wá rí i pé a ti dí ìjẹ mọ́ àwọn lẹ́nu, wọ́n wọ́ Sílà àti Pọ́ọ̀lù lọ sọ́dọ̀ àwọn agbófinró ìlú náà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, wọ́n dójú tì wọ́n nípa fífi àwọn méjèèjì hàn níta gbangba gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn, àní wọ́n gbọn ẹ̀wù ya mọ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì fi ọ̀pá nà wọ́n láàárín ọjà.—Ìṣe 16:12, 16-22.
Kì í ṣe kìkì pé irú nínà bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìjìyà fífoniláyà, tó lè tanni ní sùúrù, ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù òun Sílà, irú ìjìyà bẹ́ẹ̀ kò bófin mu rárá. Èé ṣe? Òfin Róòmù sọ pé a kò gbọ́dọ̀ lu ọmọ ìlú Róòmù kankan. Pọ́ọ̀lù jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù lábẹ́ òfin, ó sì ṣeé ṣe kí Sílà jẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn “tí wọ́n ti lù wọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀,” wọ́n fi Pọ́ọ̀lù àti Sílà sí ẹ̀wọ̀n níbi tí wọ́n ti de ẹsẹ̀ wọn pinpin nínú àbà. Gustav Stählin ṣàlàyé pé àwọn àbà wọ̀nyí jẹ́ “ohun èlò búburú tí a lè fi mú kí ẹlẹ́wọ̀n yàkàtà tó bí a bá ti fẹ́, lọ́nà tí kò fi ní lè rí oorun sùn.” Síbẹ̀, ní ọ̀gànjọ́ òru, tó dájú pé gbogbo ẹ̀yìn wọn ti kún fún ọgbẹ́ yánnayànna tó ń kan wọ́n gógó, “Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.”—Ìṣe 16:23-25.
Èyí jẹ́ kí a mọ ohun mìíràn nípa irú èèyàn tí Sílà jẹ́. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé wọ́n jìyà nítorí orúkọ Kristi. (Mátíù 5:11, 12; 24:9) Ó hàn gbangba pé ẹ̀mí kan náà yìí ló mú kí Sílà àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ gbéṣẹ́ nígbà tí a fi kọ́kọ́ rán wọn níṣẹ́ sí Áńtíókù níjelòó, láti fún ìjọ níṣìírí, kí wọ́n sì fún wọn lókun, èyí ló sì mú kí wọn lè sún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn láti kún fún ayọ̀. Ó dájú pé ayọ̀ Pọ́ọ̀lù òun Sílà yóò pọ̀ sí i nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ mú kí a tú wọn sílẹ̀ kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́nà ìyanu, tí ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti ṣèrànwọ́ fún onítúbú náà tó ti kọ́kọ́ fẹ́ pa ara rẹ̀, tó fi jẹ́ pé tòun tìdílé rẹ̀ wá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run.—Ìṣe 16:26-34.
Nínà lọ́pàá àti ìfinisẹ́wọ̀n kò ṣẹ̀rù ba Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Nígbà tí wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n kọ̀, wọ́n láwọn ò ní fìtìjú yọ́ jáde kúrò ní Fílípì, gẹ́gẹ́ bí àwọn agbófinró ti retí. Wọn ò gbà o, wọ́n sì wá jẹ́ kí ojú ti àwọn agbéraga agbèfọ́ba tí wọn kì í dúró gbẹ́jọ́ náà. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi, àwa ọkùnrin tí a jẹ́ ará Róòmù, wọ́n sì sọ wá sẹ́wọ̀n; ṣé wọ́n ń tì wá jáde nísinsìnyí ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” Nítorí ìbẹ̀rù ohun tó lè gbẹ̀yìn ọ̀ràn náà, àwọn agbófinró náà wá rí i pé ó pọndandan fún wọn láti pàrọwà fún àwọn méjèèjì kí wọ́n dákun fi ìlú náà sílẹ̀.—Ìṣe 16:35-39.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ́ kí àwọn aláṣẹ mọ ẹ̀tọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ará Róòmù, Pọ́ọ̀lù àti Sílà fara mọ́ àrọwà àwọn agbófinró náà—àmọ́ wọ́n kọ́kọ́ lọ dágbére fáwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n sábà máa ń ṣe nísinsìnyí nínú gbogbo ìrìn àjò ìwàásù náà, lẹ́ẹ̀kan sí i, Sílà àti alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ‘fún àwọn ará ní ìṣírí,’ kí wọ́n tó máa lọ.—Ìṣe 16:40.
Láti Makedóníà, Ó Lọ sí Bábílónì
Nítorí tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà kò jẹ́ kí ohun tí kò bára dé tó ṣẹlẹ̀ sí wọn mú wọn rẹ̀wẹ̀sì, àwọn àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ré kọjá sí pápá míṣọ́nnárì tuntun. Nígbà tí wọ́n dé Tẹsalóníkà, wọ́n tún dojú kọ àwọn ìṣòro mìíràn. Nítorí àṣeyọrí Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ fún Sábáàtì mẹ́ta gbáko, àwọn ọ̀tá tí ń jowú kó àwọn onírúgúdù jọ, tí wọ́n sì jẹ́ kó pọndandan fún àwọn míṣọ́nnárì náà láti fi ìlú náà sílẹ̀ lóru. Ni wọ́n bá gba Bèróà lọ. Nígbà tí àwọn alátakò wọ̀nyí tún gbọ́ nípa àṣeyọrí Pọ́ọ̀lù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ní ìlú náà, wọ́n tún ti iyàn-níyàn Tẹsalóníkà wá. Pọ́ọ̀lù nìkan ló wá ń bá ìrìn àjò náà lọ, Sílà àti Tímótì dúró sí Bèróà láti bójú tó àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 17:1-15) Sílà àti Tímótì padà wá bá Pọ́ọ̀lù ní Kọ́ríńtì, wọ́n mú ìròyìn ayọ̀ wá, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n mú ẹ̀bùn wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà ní Makedóníà. Èyí ti ní láti ṣèrànwọ́ fún àpọ́sítélì tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ yìí láti lè pa ṣíṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tì, èyí tó ti ń ṣe fún ìgbà díẹ̀, kí ó sì wá padà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún pẹ̀lú okun. (Ìṣe 18:1-5; 2 Kọ́ríńtì 11:9) Ní Kọ́ríńtì, a tún pe Sílà àti Tímótì ní ajíhìnrere àti alábàákẹ́gbẹ́ Pọ́ọ̀lù. Nítorí náà, ó ṣe kedere pé, ìgbòkègbodò wọn pẹ̀lú kò falẹ̀ nínú ìlú náà.—2 Kọ́ríńtì 1:19.
Ìlò ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “àwa” jálẹ̀ àwọn lẹ́tà táa kọ sí àwọn ará Tẹsalóníkà—lẹ́tà méjèèjì tó jẹ́ pé Kọ́ríńtì la ti kọ wọ́n ní sáà yìí—ni a ti gbà pé ó túmọ̀ sí pé Sílà àti Tímótì kópa nínú kíkọ ọ́. Àmọ́ ṣá o, èrò náà pé Sílà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ akọ̀wé ní pàtàkì ni a gbé ka ohun tí Pétérù sọ nípa ọ̀kan lára lẹ́tà rẹ̀ fúnra rẹ̀. Pétérù sọ pé òun kọ ìwé òun àkọ́kọ́ láti Bábílónì “nípasẹ̀ Sílífánù, arákùnrin olùṣòtítọ́.” (1 Pétérù 5:12, 13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè túmọ̀ sí pé Sílífánù la fi rán, ìyàtọ̀ tó wà nínú ìṣọwọ́kọ àwọn lẹ́tà méjì tí Pétérù kọ lè fi hàn pé ó lo Sílà gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé láti kọ lẹ́tà ti àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n kò lò ó láti kọ lẹ́tà rẹ̀ èkejì. Nípa báyìí, òmíràn nínú onírúurú ẹ̀bùn tí Sílà ní àti ọ̀kan lára àwọn àǹfààní iṣẹ́ Ìjọba náà tí ó ní ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ akọ̀wé.
Àpẹẹrẹ Láti Fara Wé
Táa bá fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ohun táa mọ̀ tí Sílà ṣe, ìtàn rẹ̀ wúni lórí púpọ̀. Àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ fún àwọn míṣọ́nnárì òde òní àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò. Nítorí tí kò lẹ́mìí ìmọtara-ẹni-nìkan ó fi owó àpò ara rẹ̀ rìnrìn àjò gígùn, kì í ṣe fún àǹfààní nǹkan ti ara tàbí torí ipò, ṣùgbọ́n láti lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Góńgó rẹ̀ ni láti fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ràn tó yẹ, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwíyé tó tani jí, tí a sì múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, àti ìtara rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún wọn níṣìírí. Ipò yòówù tí o lè wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà tí a ṣètò, bóo bá ń làkàkà láti lẹ́mìí rere bíi tirẹ̀—kódà nígbà tí ìdààmú bá dé—ìwọ pẹ̀lú yóò jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìrìn Àjò Míṣọ́nnárì Pọ́ọ̀lù Ẹlẹ́ẹ̀kejì
Òkun Ńlá
Áńtíókù
Déébè
Lísírà
Íkóníónì
Tíróásì
Fílípì
Ámífípólì
Tẹsalóníkà
Bèróà
Áténì
Kọ́ríńtì
Éfésù
Jerúsálẹ́mù
Kesaréà
[Credit Line]
Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.