ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 99 ojú ìwé 230-ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4
  • Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Sọdá Wá sí Makedóníà”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Sílà—Orísun Ìṣírí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Fífi Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Wàásù Ìhìn Rere Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 99 ojú ìwé 230-ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4
Ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Fílípì rí i pé gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ṣì wà nínú ẹ̀wọ̀n bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀kùn ẹ̀wọ̀n náà wà ní ṣíṣí

Ẹ̀KỌ́ 99

Ẹ̀ṣọ́ Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Kan Gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọmọbìnrin kan wà nílùú Fílípì tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú. Ńṣe ni ẹ̀mí èṣù náà máa ń jẹ́ kí ọmọbìnrin náà máa sọ àsọtẹ́lẹ̀, èyí sì máa ń pa owó wọlé fáwọn ọ̀gá ẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà dé Fílípì, ńṣe ni ọmọbìnrin yìí ń tẹ̀ lé wọn kiri fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ẹ̀mí èṣù yẹn mú kí ọmọbìnrin náà máa pariwo pé: “Ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni àwọn ọkùnrin yìí.” Nígbà tó yá, ó sú Pọ́ọ̀lù, ó sì pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà pé: ‘Lórúkọ Jésù Kristi, jáde kúrò nínú ẹ̀!’ Ni ẹ̀mí èṣù yẹn bá jáde kúrò nínú ọmọbìnrin yẹn.

Nígbà táwọn ọ̀gá ọmọbìnrin náà rí i pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò ní jẹ́ kó máa pawó fáwọn mọ́, inú bí wọn gan-an. Wọ́n wá mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sílé ẹjọ́, wọ́n sì sọ fún adájọ́ pé: ‘Àwọn ọkùnrin yìí ń rú òfin, wọ́n sì ń da ìlú wa rú!’ Ni adájọ́ bá pàṣẹ pé kí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà lẹ́gba, kí wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n wá sọ Pọ́ọ̀lù àti Sílà sínú ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún tó ṣókùnkùn gan-an, wọ́n tún fi pákó de ọwọ́ àtẹsẹ̀ wọn.

Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù àti Sílà bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin sí Jèhófà, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù sì ń gbọ́. Nígbà tó di òru, gbogbo ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í mì tìtì. Ṣàdédé làwọn ilẹ̀kùn ṣí sílẹ̀, gbogbo ohun tí wọ́n fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sì já. Nígbà tí ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn rí i pé ilẹ̀kùn ti ṣí, ẹ̀rù bà á, ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà ti sá lọ, ló bá fa idà yọ láti para ẹ̀.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí i pé ọkùnrin náà fẹ́ para ẹ̀, ó pariwo pé: ‘Má para ẹ o! Gbogbo wa wà níbí!’ Ọkùnrin náà sáré wá sọ́dọ̀ Pọ́ọ̀lù àti Sílà, ó dojú bolẹ̀, ó sì sọ pé: “Kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà?” Wọ́n sọ fún un pé: ‘Ìwọ àti ìdílé ẹ gbọ́dọ̀ gba Jésù gbọ́.’ Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù àti Sílà kọ́ ọkùnrin náà àti ìdílé ẹ̀ ní ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo wọn sì ṣèrìbọmi.

“Àwọn èèyàn máa gbé ọwọ́ wọn lé yín, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí yín, wọ́n á fà yín lé àwọn sínágọ́gù lọ́wọ́, wọ́n á sì fi yín sẹ́wọ̀n. Wọ́n máa mú yín lọ síwájú àwọn ọba àti àwọn gómìnà nítorí orúkọ mi. Èyí máa jẹ́ kí ẹ lè jẹ́rìí.”​—Lúùkù 21:12, 13

Ìbéèrè: Kí nìdí tí wọ́n fi ju Pọ́ọ̀lù àti Sílà sẹ́wọ̀n? Báwo ni ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ṣe kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà?

Ìṣe 16:16-34

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́