Àwọn Ìṣòro Àrà Ọ̀tọ̀ Tó Dojú Kọ Ìdílé Onígbeyàwó Àtúnṣe
ÌDÍLÉ ONÍGBEYÀWÓ ÀTÚNṢE LÈ JẸ́ ALÁYỌ̀! BÁWO?
Ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ti di agboolé tó wọ́pọ̀ kárí ayé. Síbẹ̀, ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ní àwọn ìṣòro aláìlẹ́gbẹ́. Èyí tó le jù nínú gbogbo ìṣòro ọ̀hún ni ti ọmọ títọ́. Àmọ́ ṣá o, bí àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé e yóò ti gbìyànjú láti fi hàn, ó ṣeé ṣe láti tọ́mọ ní àtọ́yanjú nínú agboolé onígbeyàwó àtúnṣe.
GẸ́GẸ́ BÍ A TI MÁA Ń GBỌ́, ÀWỌN ÈÈYÀN KÌ Í SÁBÀ SỌ̀RỌ̀ RERE NÍPA ỌKÙNRIN MÌÍRÀN TÍ ÌYÁ wọn lọ fẹ́ tàbí obìnrin mìíràn tí baba wọn fẹ́. Nígbà táa wà lọ́mọdé, ọ̀pọ̀ lára wa gbọ́ nípa ìtàn Ọmọ Orogún, tí orogún ìyá rẹ̀ fi ìyà pá lórí. Àwọn ọmọdé ní Yúróòpù, pẹ̀lú, gbọ́ nípa ìtàn àgbọ́sọ náà, Snow White and the Seven Dwarfs. Orogún ìyá Snow White jẹ́ àjẹ́ burúkú!
Irú àwọn ìtàn àgbọ́sọ bẹ́ẹ̀ ha fúnni lójú ìwòye tó gún régé nípa ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe bí? Ṣé gbogbo òbí onígbeyàwó àtúnṣe ló burú tó yẹn? Rárá o. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ pé kó lè dáa fún àwọn ọmọ tí ọkọ tàbí aya wọn kó wá nígbà ìgbéyàwó ni wọ́n ń wá. Ṣùgbọ́n wọ́n máa ń dojú kọ àwọn ìṣòro ńláǹlà tó sábà máa ń wáyé nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe.
Ìṣòro Ọmọ Títọ́
Àìdàgbàdénú tọkọtaya ló sábà máa ń fa ìforíṣánpọ́n ìgbéyàwó àkọ́kọ́. Nínú ìgbéyàwó kejì, ọwọ́ táa fi ń mú àwọn ọmọ lè ba àjọṣe tọkọtaya jẹ́. Àwọn àkọsílẹ̀ kan fi hàn pé mẹ́rin nínú mẹ́wàá lára àwọn ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ló máa ń kọ ara wọn sílẹ̀ láàárín ọdún márùn-ún àkọ́kọ́.
Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó lè má mọ pákáǹleke, àti ojú ìwòye tó takora nípa ẹni tó yẹ ká fara mọ́, àti owú jíjẹ àti ìbínú tó lè ru nínú àwọn ọmọ tí ń bẹ nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe nítorí òbí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé dé. Àwọn ọmọ wọ̀nyí lè rò pé, òbí tó bí àwọn lọ́mọ nífẹ̀ẹ́ ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ tuntun yìí ju àwọn lọ. Síwájú sí i, ó lè nira fún òbí tó lọmọ gan-an, tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ já jù sílẹ̀, láti lóye ìdí tí ọkàn àwọn ọmọ ṣì fi fà mọ́ ọkọ tàbí ìyàwó òun àtijọ́. Ọmọkùnrin kan gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí àjọṣe àárín òun àti baba tó bí òun lọ́mọ ṣì fi ń lọ geere, ó ní, “Mọ́mì, mo mọ̀ pé nǹkan tí Dádì ṣe sí yín kò dáa, ṣùgbọ́n Dádì ń tọ́jú mi dáadáa!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ ni irú ọ̀rọ̀ yìí, ó lè mú kí ìyá máa bínú sí baba ọmọ náà.
Baba kan nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe jẹ́wọ́ pé: “Kí n sòótọ́, mi ò múra tán láti kojú gbogbo ìṣòro tó jẹ mọ́ títọ́ àwọn ọmọ tí ìyàwó mi bí fún ọkọ rẹ̀ àtijọ́. Ojú tí mo kọ́kọ́ fi wo ọ̀ràn náà ni pé níwọ̀n ìgbà tí mo ti fẹ́ ìyá wọn, mo ti di baba wọn nìyẹn. Kò jù bẹ́ẹ̀ lọ! Mi ò mọ̀dí tí ọkàn àwọn ọmọ náà fi fà mọ́ baba tó bí wọn lọ́mọ, mo sì ṣe àṣìṣe tó pọ̀ gan-an.”
Wàhálà lè bẹ́, pàápàá jù lọ lórí ọ̀ràn ìbáwí. Àwọn ọmọdé nílò ìbáwí onífẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n sábà máa ń kọ̀ ọ́, kódà nígbà tó bá jẹ́ pé òbí tó bí wọn lọ́mọ ló ń bá wọn wí. Ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ìbáwí tó wá látọ̀dọ̀ òbí tí kì í ṣe baba tàbí ìyá wọn gan-an! Lọ́pọ̀ ìgbà, tí irú òbí bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ bá wọn wí, ọ̀rọ̀ tó lè tẹnu ọmọ náà jáde ni, “Ìwọ kọ́ ni baba tó bí mi lọ́mọ!” Nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yóò mà ba òbí elérò rere náà lọ́kàn jẹ́ o!
A ha lè tọ́ àwọn ọmọ ní àtọ́yanjú nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe bí? Àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe ha lè kó ipa tó ṣe gúnmọ́ nínú gbígbé ìdílé aláṣeyọrí ró bí? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn sí ìbéèrè méjèèjì, bí gbogbo àwọn tọ́ràn kàn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì, tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a mí sí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
“Ìwọ kọ́ ni baba tó bí mi lọ́mọ!”