Ìdílé Onígbeyàwó Àtúnṣe Lè Ṣàṣeyọrí
ÌDÍLÉ ONÍGBEYÀWÓ ÀTÚNṢE HA LÈ ṢÀṢEYỌRÍ BÍ? BẸ́Ẹ̀ NI, PÀÁPÀÁ JÙ LỌ BÍ GBOGBO ÀWỌN TỌ́RÀN KÀN bá rántí pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, [tí] ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Nígbà tí olúkúlùkù bá fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àṣeyọrí dájú.
Ànímọ́ Pàtàkì
Bíbélì kò ṣòfin lọ rẹpẹtẹ láti ṣàkóso àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn. Lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, ṣe ló máa ń fúnni níṣìírí láti mú àwọn ànímọ́ àti ìṣesí rere dàgbà, èyí tí ń mú ká hùwà ọgbọ́n. Irú ìṣesí àti ànímọ́ rere bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì fún ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀.
Ó lè jọ pé kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní sísọ, ṣùgbọ́n ó ṣì yẹ ká sọ ọ́, pé ànímọ́ pàtàkì tí ìdílé èyíkéyìí nílò kó tó lè ṣàṣeyọrí ni ìfẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè. . . . Nínú ìfẹ́ ará, ẹ ní ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 12:9, 10) Àwọn èèyàn ti ṣi ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́” lò gan-an, ṣùgbọ́n ànímọ́ tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí níhìn-ín, àrà ọ̀tọ̀ ni. Ó jẹ́ ìfẹ́ lọ́nà ti Ọlọ́run, kì í sì í “kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:8) Bíbélì sọ pé kì í ṣe anìkànjọpọ́n, ó sì ṣe tán láti sin àwọn ẹlòmíràn. Ó ń ṣiṣẹ́ kárakára fún ire àwọn ẹlòmíràn. Ó ní ìpamọ́ra àti inú rere, kì í jowú rárá, kì í fọ́nnu, tàbí kó máa gbéra ga. Kì í wá ire tara rẹ̀. Ìgbà gbogbo ló máa ń ṣe tán láti dárí jì, láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé, láti nírètí, láti fara da ohun yòówù tó bá dé.—1 Kọ́ríńtì 13:4-7.
Ojúlówó ìfẹ́ máa ń ṣèrànwọ́ nínú yíyanjú aáwọ̀, ó sì máa ń so onírúurú èèyàn pọ̀, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni báa ṣe tọ́ wọn dàgbà, tí ìwà wọn sì yàtọ̀ síra pátápátá. Ó sì máa ń ṣèrànwọ́ láti gbógun ti àwọn ìyọrísí bíbaninínújẹ́ tí ń jẹ yọ láti inú ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ikú òbí tó bíni lọ́mọ. Ọkùnrin kan tó di baba nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe ṣàlàyé àwọn ohun tó jẹ́ ìṣòro gan-an fún un, ó ní: “Ìmọ̀lára tèmi ló sábà máa ń jẹ mí lógún jù, èyí kì í sì í jẹ́ kí n kọbi ara sí èrò ìmọ̀lára àwọn ọmọ ìyàwó mi, tàbí èrò ìmọ̀lára ìyàwó mi pàápàá. Mo ní láti kọ́ bí a ṣe ń bomi sùúrù mu. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ, mo ní láti kọ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀.” Ìfẹ́ ràn án lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó pọndandan.
Òbí Tó Lọmọ
Ìfẹ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà àtigbà bójú tó àjọṣepọ̀ àwọn ọmọ tí òbí wọn kò sí nítòsí mọ́. Baba kan nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe sọ tinú rẹ̀ jáde, ó ní: “Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ tí ìyàwó mi bí fún ọkọ rẹ̀ àtijọ́ fẹ́ràn mi ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ. Nígbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ baba tó bí wọn lọ́mọ, ó máa ń nira fún mi láti dákẹ́ láìṣe àríwísí baba wọn. Nígbà tí wọ́n bá padà dé látọ̀dọ̀ rẹ̀, tí wọ́n ń sọ bí gbogbo rẹ̀ ti dùn yùngbà tó, inú mi a sì bàjẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá dé, tí wọn sọ pé àwọn kò gbádùn rẹ̀ rárá, inú mi á dùn gan-an. Kí n sòótọ́, mi ò fẹ́ kí wọ́n kẹ̀yìn sí mi. Ọ̀kan lára ohun tó nira jù lọ ni láti gbà pé ipa tí baba wọn kó nínú ìgbésí ayé wọn kò kéré.”
Ojúlówó ìfẹ́ ran baba yìí lọ́wọ́ láti dojú kọ òtítọ́ náà pé, kò lè ṣeé ṣe láti retí kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun “lójú-ẹsẹ̀,” àní àlá tí kò lè ṣẹ ni. Kò yẹ kí ó nímọ̀lára pé ṣe làwọn ọmọ náà pa òun tì nígbà tí wọn kò tètè tẹ́wọ́ gbà á. Nígbà tó yá, ó wá rí i pé, kò sí bí òun ṣe lè rọ́pò baba tó bí wọn lọ́mọ pátápátá nínú ọkàn-àyà àwọn ọmọ náà. Àwọn ọmọ náà ti mọ baba wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ìgbésí ayé wọn, nígbà tó jẹ́ pé òbí yìí nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe jẹ́ ẹni tuntun tí yóò ní láti sapá láti jèrè ìfẹ́ àwọn ọmọ náà. Olùwádìí náà, Elizabeth Einstein, sọ ìrírí ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tó wí pé: “Kò ṣeé ṣe láti rọ́pò òbí tó bíni lọ́mọ—láéláé. Òbí tó ti kú pàápàá, tàbí èyí tó pa ọmọ náà tì, ṣì wà ní ipò pàtàkì nínú ìgbésí ayé ọmọ náà.”
Ọ̀ràn Ìbáwí—Ẹlẹgẹ́ Ni
Bíbélì fi hàn pé ìbáwí onífẹ̀ẹ́ ṣe kókó fún àwọn ọ̀dọ́, títí kan àwọn ọmọ inú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe. (Òwe 8:33) Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló ti bẹ̀rẹ̀ sí fara mọ́ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ceres Alves de Araújo sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá wa, kò sẹ́ni tó fẹ́ ká fòfin há òun mọ́, ṣùgbọ́n ó pọndandan. ‘O kò gbọ́dọ̀’ jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń dáàbò boni.”
Àmọ́ ṣá o, nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, ojú táa fi ń wo ìbáwí lè fa wàhálà ńlá. Àgbàlagbà tí kò sí nítòsí mọ́ ló tọ́ àwọn ọmọ táa kó wá sínú ìgbéyàwó tuntun yìí dàgbà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa hu àwọn ìwà kan tàbí kí wọ́n máa dá àwọn àṣà kan tó lè máa bí àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe nínú. Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ náà má mọ̀dí tí àwọn ọ̀ràn kan fi ń ká òbí onígbeyàwó àtúnṣe lára tó bẹ́ẹ̀. Báwo la ṣe lè yanjú ìṣòro yìí? Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Máa lépa . . . ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.” (1 Tímótì 6:11) Ìfẹ́ Kristẹni ń ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe láti jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ àti onísùúrù bí wọ́n ti ń kọ́ láti lóye ara wọn. Bí òbí nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe kò bá ní sùúrù, ‘ìbínú, ìrunú, àti ọ̀rọ̀ èébú’ lè tètè ba àjọṣepọ̀ tí wọ́n ti ní jẹ́.—Éfésù 4:31.
Wòlíì náà, Míkà, pèsè ìjìnlẹ̀ òye tó lè ṣèrànwọ́ nínú ọ̀ràn yìí. Ó sọ pé: “Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” (Míkà 6:8) Ìdájọ́ òdodo ṣe pàtàkì nígbà táa bá ń fúnni ní ìbáwí. Ṣùgbọ́n inú rere ńkọ́? Kristẹni alàgbà kan ṣàlàyé pé ó sábà máa ń ṣòro láti jí àwọn ọmọ ìyàwó òun lójú oorun láàárọ̀ Sunday, kí wọ́n lè nípìn-ín nínú jíjọ́sìn nínú ìjọ. Dípò kí ó máa jágbe mọ́ wọn, ó gbìyànjú láti fi inú rere bá wọn lò. Á tètè jí ní ìdájí, a ṣètò oúnjẹ àárọ̀, á sì pèsè ohun mímu lílọ́ wọ́ọ́rọ́ fún olúkúlùkù wọn. Torí èyí, wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu tó bá ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n dìde.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Ana Luisa Vieira de Mattos sọ ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí yìí: “Kì í ṣe irú ìdílé táa ní ló ṣe pàtàkì, bí kò ṣe báa ṣe ń bá ara wa lò. Nínú àwọn ìwádìí mi, mo ti ṣàkíyèsí pé àwọn ọ̀dọ́ tí kò mọ̀wàáhù sábà máa ń wá láti inú àwọn ìdílé tí àwọn òbí kò ti ráyè tàwọn ọmọ, tí kò sì sí òfin àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀.” Obìnrin náà tún sọ pé: “Ó yẹ ká tẹnu mọ́ ọn gidigidi pé títọ́mọ túmọ̀ sí sísọ pé rárá nígbà mìíràn.” Ní àfikún sí i, àwọn dókítà náà, Emily àti John Visher, sọ pé: “Ní pàtàkì, ìbáwí máa ń gbéṣẹ́ kìkì bí ẹni táa ń bá wí bá bìkítà nípa ìhùwàpadà àti ìbátan tó wà láàárín òun àti ẹni tí ń bá òun wí.”
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kò ṣàìmẹ́nuba ẹni tó yẹ kó fúnni ní ìbáwí nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe. Ta ló yẹ kó sọ pé rárá? Lẹ́yìn táwọn òbí bá ti jọ sọ ọ́, tí wọ́n ti forí ẹ̀ tì síbì kan, àwọn òbí kan ti pinnu pé, ní ìbẹ̀rẹ̀, òbí tó lọmọ gan-an ló yẹ kó máa pèsè ìbáwí pàtàkì, kí ó lè fún òbí tí kì í ṣe baba tàbí ìyá àwọn ọmọ náà ní àkókò láti ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ náà. Jẹ́ kí àwọn ọmọ náà ní ìfọkànbalẹ̀ pé baba tàbí ìyá yìí tí kì í ṣe òbí wọn gan-an nífẹ̀ẹ́ wọn, kí ó tó wá di pé òbí náà bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn wí.
Bó bá ṣe pé baba ni kì í ṣe òbí wọn gan-an ńkọ́? Bíbélì kò ha sọ pé baba ni olórí ìdílé bí? Bẹ́ẹ̀ ni. (Éfésù 5:22, 23; 6:1, 2) Àmọ́ ṣá o, ì bá dára bí baba tí kì í ṣe òbí àwọn ọmọ náà gan-an bá fi ọ̀ràn ìbáwí lé ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́ fún sáà kan, pàápàá jù lọ, bí ìbáwí náà bá mú ìjẹniníyà lọ́wọ́. Baba yìí lè jẹ́ kí àwọn ọmọ náà ṣègbọràn sí ‘òfin ìyá wọn,’ bí òun fúnra rẹ̀ ti ń fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún wọn láti ‘fetí sí ìbáwí baba wọn’ tuntun. (Òwe 1:8; 6:20; 31:1) Ẹ̀rí fi hàn pé, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, èyí kò tako ìlànà ipò orí. Ní àfikún, baba onígbeyàwó àtúnṣe kan sọ pé: “Mo rántí pé ìbáwí ní ìṣílétí, ìfàṣìṣehanni, àti ìtọ́sọ́nà nínú. Nígbà táa bá pèsè rẹ̀ lọ́nà tó tọ́, tó fìfẹ́ hàn, tó sì jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, táa sì tún fi àpẹẹrẹ òbí tì í lẹ́yìn, ó máa ń gbéṣẹ́.”
Ó Yẹ Kí Àwọn Òbí Máa Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀ Pọ̀
Òwe 15:22 sọ pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú.” Nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, táa sọ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, tó sì sọjú abẹ níkòó, láàárín àwọn òbí méjèèjì ṣe kókó. Òǹkọ̀wé kan tí ń kọ̀wé fún ìwé ìròyìn O Estado de S. Paulo sọ pé: “Àwọn ọmọdé máa ń fẹ́ wò ó bóyá àwọn lè ré òfin òbí kọjá, kí àwọn sì mú un jẹ.” Òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí wá túbọ̀ ṣe kedere nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe. Fún ìdí yìí, ó yẹ kí àwọn òbí fohùn ṣọ̀kan nínú oríṣiríṣi ọ̀ràn, kí àwọn ọmọ lè rí i pé wọ́n wà ní ìṣọ̀kan. Ṣùgbọ́n, bí òbí tí kì í ṣe baba tàbí ìyá ọmọ gan-an bá gbégbèésẹ̀ lọ́nà tí òbí tó lọmọ nímọ̀lára pé kò tọ̀nà ńkọ́? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ kí àwọn méjèèjì yanjú ọ̀ràn náà ní bòókẹ́lẹ́, kì í ṣe níwájú àwọn ọmọ náà.
Ìyá kan tó fẹ́ ọkọ mìíràn ròyìn pé: “Ohun tó nira jù fún ìyá ni láti rí i kí ọkọ òun máa bá àwọn ọmọ tí òun bí fún ọkọ àtijọ́ wí, pàápàá jù lọ bí ìyá náà bá nímọ̀lára pé ọkọ òun kò baralẹ̀ gbọ́ wọn yé, tàbí pé kò tilẹ̀ ṣẹ̀tọ́. Ọkàn rẹ̀ á gbọgbẹ́, á sì fẹ́ gbèjà àwọn ọmọ rẹ̀. Ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, á wá ṣòro láti wà ní ìtẹríba fún ọkọ rẹ̀ àti láti tì í lẹ́yìn.
“Nígbà kan, àwọn ọmọkùnrin mi méjèèjì tí mo bí fún ọkọ mi àtijọ́, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá àti mẹ́rìnlá, tọrọ àyè lọ́wọ́ ọkọ mi tó jẹ́ bí baba fún wọn, pé àwọn fẹ́ ṣe nǹkan kan. Lójú-ẹsẹ̀ ló kọ̀ jálẹ̀, tó sì jáde kúrò nínú yàrá, láìtilẹ̀ fún àwọn ọmọ náà láǹfààní láti ṣàlàyé ìdí tí ohun tí wọ́n ń béèrè fi jẹ àwọn lógún. Àwọn ọmọ náà fẹ́ bú sẹ́kún, mi ò sì lè sọ̀rọ̀. Èyí ẹ̀gbọ́n wò mí lójú, ó ní: ‘Mọ́mì, ṣé ẹ rí nǹkan tó ṣe?’ Mo fèsì pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo rí i. Ṣùgbọ́n òun ṣì ni olórí ìdílé, Bíbélì sáà sọ pé ká bọ̀wọ̀ fún ipò orí.’ Ọmọ dáadáa ni wọ́n, wọ́n gbà sí mi lẹ́nu, ara wọn sì balẹ̀ díẹ̀. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, mo bá ọkọ mi sọ̀rọ̀, òun náà sì wá rí i pé òun ti mú un le jù. Ó lọ tààrà sí yàrá àwọn ọmọ náà, ó sì tọrọ àforíjì.
“A rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Ọkọ mi kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí òun máa fetí sílẹ̀ kí òun tó ṣe ìpinnu. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí n máa gbé ìlànà ipò orí lárugẹ, kódà nígbà tí kò bá bá mi lára mu. Àwọn ọmọ náà kẹ́kọ̀ọ́ pé ó ṣe pàtàkì láti wà ní ìtẹríba. (Kólósè 3:18, 19) Bí ọkọ mi ṣe tọrọ àforíjì tún kọ́ gbogbo wa pé ó ṣe pàtàkì láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. (Òwe 29:23) Lónìí, Kristẹni alàgbà ni àwọn ọmọkùnrin méjèèjì.”
A ó ṣàṣìṣe. Àwọn ọmọ yóò sọ àwọn ọ̀rọ̀ tàbí kí wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí yóò dùn wá. Pákáǹleke àìròtẹ́lẹ̀ yóò mú kí àwọn òbí onígbeyàwó àtúnṣe hùwà tí kò mọ́gbọ́n dání. Bó ti wù kó rí, àwọn ọ̀rọ̀ rírọrùn náà, “Máà bínú, dákun dárí jì mí,” lè pẹ̀tù sí aáwọ̀ náà.
Fífún Ìṣọ̀kan Ìdílé Lókun
Láti mú kí àjọṣepọ̀ alárinrin wà nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe máa ń gba àkókò. Bí o bá jẹ́ òbí nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe, o ní láti ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Máa fòye báni lò, wá àkókò láti fi jókòó ti àwọn ọmọ náà. Máa bá àwọn tó kéré lára wọn ṣeré. Ṣètò láti bá àwọn tó ti dàgbà sọ̀rọ̀. Wá àyè láti jùmọ̀ wà pa pọ̀—fún àpẹẹrẹ, ké sí àwọn ọmọ náà láti bá ẹ ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, bíi gbígbọ́ oúnjẹ tàbí fífọ mọ́tò. Mú wọn dání lọ sọ́jà, kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní àfikún, àwọn ìṣe onífẹ̀ẹ́ lè fi hàn pé o fẹ́ràn wọn ní tòótọ́. (Àmọ́ ṣá o, àwọn baba nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, kí wọ́n má kọjá àyè wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọbìnrin tí aya wọn ti bí fún ọkọ mìíràn tẹ́lẹ̀, kí wọ́n má sì ṣe ohun tí ara àwọn ọmọbìnrin náà yóò kọ̀. Àwọn ìyá nínú ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe pẹ̀lú gbọ́dọ̀ rántí pé wọ́n ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àyè wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn.)
Ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe lè ṣàṣeyọrí. Ọ̀pọ̀ ló ti ṣàṣeyọrí. Àwọn tó ti kẹ́sẹ járí làwọn ìdílé tó jẹ́ pé, gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn, pàápàá jù lọ àwọn òbí, ní ìṣarasíhùwà tó tọ́ àti ìfojúsọ́nà tó bójú mu. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.” (1 Jòhánù 4:7) Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ àtọkànwá ni ojúlówó àṣírí ìdílé onígbeyàwó àtúnṣe tó láyọ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
ÀWỌN ÌDÍLÉ ONÍGBEYÀWÓ ÀTÚNṢE TÓ LÁYỌ̀
máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀ . . .
máa ń lo àkókò pa pọ̀ . . .
máa ń jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ . . .
máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ . . .