ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 3/15 ojú ìwé 24-25
  • Wọ́n Kọ́lé Sórí Ìpìlẹ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Kọ́lé Sórí Ìpìlẹ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run” àti Àwọn Òrìṣà ní Ilẹ̀ Gíríìsì Ha Fohùn Ṣọ̀kan Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Keresimesi—Ó Ha Jẹ́ Ọna Lati Kí Jesu Kaabọ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 3/15 ojú ìwé 24-25

Wọ́n Kọ́lé Sórí Ìpìlẹ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà

TẸ́ŃPÌLÌ ÀWỌN ỌLỌ́RUN wà lára ọ̀pọ̀ ohun ìránnilétí tó jojú ní gbèsè tí àwọn èèyàn ń lọ wò ní ìlú Róòmù, lórílẹ̀-èdè Ítálì. Àgbàyanu ilé àwọn ará Róòmù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé díẹ̀ níbẹ̀ tó ṣì wà bí wọ́n ṣe rí láyé ìgbàanì. Ágírípà ló bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 27 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Hadrian sì tún un kọ́ ní nǹkan bí ọdún 120 Sànmánì Tiwa. Ohun kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ lára ilé yìí ni òrùlé rìbìtì rẹ̀ tó fẹ̀ tó mítà mẹ́tàlélógójì, arabaríbí lèyí, nítorí pé lóde òní nìkan ni a tó rí àwọn òrùlé rìbìtì tó fẹ̀ jù ú lọ. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pàá, ilé ìrúbọ àwọn abọ̀rìṣà ni Tẹ́ńpìlì Àwọn Ọlọ́run, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà ni “ilé gbogbo àwọn ọlọ́run.” A ṣì kà á sí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì títí dòní. Báwo ni irú ìyípadà tí ń ṣeni ní háà bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀?

Lọ́dún 609 Sànmánì Tiwa, Póòpù Boniface Kẹrin tún ojúbọ tí wọ́n ti pa tì tipẹ́tipẹ́ yìí yà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bíi ṣọ́ọ̀ṣì “Kristẹni.” Ìgbà yẹn ni wọ́n fún un lórúkọ náà, Ṣọ́ọ̀ṣì Santa Maria Rotunda. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ kan tó jáde lọ́dún 1900 nínú ìwé ìròyìn àwọn onísìn Jesuit ti Ítálì náà, La Civiltà Cattolica, ti wí, ohun tí Boniface ní lọ́kàn pé kí wọ́n lò ó fún ni “lílò ó láti fògo fún gbogbo àwọn ajẹ́rìíkú tí ń bẹ lágbo àwọn Kristẹni, tàbí lédè mìíràn, gbogbo àwọn ẹni mímọ́, ṣùgbọ́n àkọ́kọ́ nínú wọn ni Wúńdíá Ìyá Ọlọ́run.” Àwọn orúkọ tí Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì sọ Tẹ́ńpìlì Àwọn Ọlọ́run lónìí ni—Santa Maria ad Martyres tàbí, lédè mìíràn, Santa Maria Rotunda—èyí sì fi èrò tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu hàn.—Fi wé Ìṣe 14:8-15.

Àpilẹ̀kọ kan náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: Láti yí ohun tí wọ́n ń lo Tẹ́ńpìlì Àwọn Ọlọ́run fún padà “kò ṣòro rárá. Boniface lo ìlànà tó rọrùn, ìlànà irú-wá-ògìrì-wá, tí aṣáájú rẹ̀, St. Gregory Ńlá [Póòpù Gregory Kìíní], là sílẹ̀, ọ̀gá àti àwòkọ́ṣe sì ni Gregory nídìí sísọ àwọn ilé ìrúbọ tí àwọn abọ̀rìṣà ń lò di èyí tí a ń lò fún ìjọsìn Kristẹni.” Kí ni ìlànà náà?

Nínú lẹ́tà kan tí Gregory kọ lọ́dún 601 Sànmánì Tiwa, sí míṣọ́nnárì kan tó forí lé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí í ṣe ilẹ̀ abọ̀rìṣà, Gregory lànà pé: “Kò yẹ kí a wó àwọn ojúbọ òrìṣà tó wà ní ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n òrìṣà tó wà nínú wọn nìkan ló yẹ ní píparun . . . Bí àwọn ilé ìrúbọ náà bá dúró sán-ún, ṣe ni ká fòpin sí lílò ó fún ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù, ká wá sọ ọ́ di ibi ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.” Èròǹgbà Gregory ni pé bí àwọn abọ̀rìṣà bá rí i pé wọn kò ba ilé ìrúbọ táwọn ń lò tẹ́lẹ̀ jẹ́, ó jọ pé wọn kò ní ṣíwọ́ lílọ síbẹ̀. Póòpù náà kọ̀wé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn abọ̀rìṣà máa “ń pa ọ̀pọ̀ màlúù láti fi rúbọ sáwọn ẹ̀mí èṣù,” a retí nísinsìnyí pé “wọn kò ní fi àwọn ẹran rúbọ sí ẹ̀mí èṣù mọ́, bí kò ṣe kí wọ́n máa pa wọ́n fún ìgbádùn ara wọn fún ìyìn Ọlọ́run.”

Ẹ̀sìn Roman Kátólíìkì tún “dọ́gba pẹ̀lú ti” ìbọ̀rìṣà nípa kíkọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n yà sí mímọ́ fún àwọn baba ìsàlẹ̀ “Kristẹni,” àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tí kò yàtọ̀ rárá sí ilé ìrúbọ àtijọ́ wọnnì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ọdún àbáláyé, wọ́n láwọn ti sọ ọ́ di ti ẹ̀sìn “Kristẹni.” Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí ìwé ìròyìn náà, La Civiltà Cattolica sọ, ó ní: “Gbogbo ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ òde òní ló mọ̀ pé àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan àti àwọn ayẹyẹ ẹ̀sìn àwọn Kristẹni ìjímìjí wá láti inú àwọn àṣà àti ọ̀nà abọ̀rìṣà. Wọ́n jẹ́ àwọn àṣà tí àwọn èèyàn náà fẹ́ràn gan-an, àwọn àṣà ìbílẹ̀ tó ti fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tó sì ti wé mọ́ ọ̀nà ìgbé-ayé àwọn èèyàn ìgbàanì nínú ilé àti nínú àwùjọ. Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì tí wọ́n ń pè ní ìyá àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gbà pé ó jẹ́ ìwà inú rere àti ìwà ọgbọ́n, pé kí òun má fòpin sí irú àṣà ìbílẹ̀ bẹ́ẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, nípa fífi orúkọ Kristẹni pè wọ́n àti nípa sísọ wọ́n di ohun tó gbayì tó gbẹ̀yẹ, òun ti fi ọwọ́ agbára, tó tún jẹ́ ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ borí wọn, kí òun lè jèrè ọkàn àwọn gbáàtúù àti ti àwọn ọ̀mọ̀wé láìsí ìrọ́kẹ̀kẹ̀.”

Àpẹẹrẹ kan táa mọ̀ dáadáa nípa títẹ́wọ́ gba ọdún àwọn abọ̀rìṣà ni ọdún Kérésìmesì. December 25 gan-an ni ọjọ́ táwọn ará Róòmù ìgbàanì máa ń ṣọdún dies natalis Solis Invicti, èyíinì ni, “ọjọ́ ìbí oòrùn tí kò ṣeé ṣẹ́gun.”

Nítorí pé ṣọ́ọ̀ṣì náà fẹ́ láti jèrè ọkàn àwọn abọ̀rìṣà, ó kẹ̀yìn sí òtítọ́. Ó fọwọ́ sí àmúlùmálà ìgbàgbọ́, èyíinì ni títẹ́wọ́ gba àwọn ìgbàgbọ́ abọgibọ̀pẹ̀ àti àwọn àṣà “tí àwọn èèyàn náà fẹ́ràn gan-an.” Ohun tó yọrí sí ni àdàmọ̀dì ṣọ́ọ̀ṣì apẹ̀yìndà, tó jìnnà pátápátá sí àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́. Lójú ìwòye ohun táa ti ń sọ bọ̀ yìí, kò kúkú fi bẹ́ẹ̀ yani lẹ́nu pé ilé ìrúbọ àwọn ará Róòmù láyé àtijọ́, tí wọ́n kọ́ fún “gbogbo àwọn ọlọ́run”—Tẹ́ńpìlì Àwọn Ọlọ́run—ló wá di ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì, tí wọ́n yà sí mímọ́ fún Màríà àti fún gbogbo “ẹni mímọ́.”

Ṣùgbọ́n o, ṣèbí ohun tó yẹ kéèyàn mọ̀ ni, pé yíyí orúkọ ẹni táa fi sọ ilé ìrúbọ padà, tàbí yíyí orúkọ ayẹyẹ kan padà, kò tó láti yí ‘ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù padà sí iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run tòótọ́.’ Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Ìfohùnṣọ̀kan wo . . . ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’ ‘Èmi yóò sì jẹ́ baba yín, ẹ ó sì jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mi,’ ni Jèhófà Olódùmarè wí.”—2 Kọ́ríńtì 6:16-18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́