Gbogbo Èèyàn Yóò Lómìnira
“Mo ṣírò rẹ̀ pé àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa. Nítorí ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run. Nítorí àwa mọ̀ pé gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí.”—RÓÒMÙ 8:18-22.
NÍNÚ lẹ́tà àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yìí tó kọ sí àwọn Kristẹni ní Róòmù, ó ṣàlàyé tó fakíki nípa ìdí tí kò fi sí òmìnira tòótọ́ láyé àti ìdí tí ayé fi sábà ń kún fún ìmúlẹ̀mófo àti ẹ̀dùn ọkàn. Ó tún ṣàlàyé báa ṣe lè ní òmìnira tòótọ́.
“Àwọn Ìjìyà Àsìkò Ìsinsìnyí”
Kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù fojú bíńtín wo “àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí” nígbà tó sọ pé wọn “kò jámọ́ ohunkóhun ní ìfiwéra pẹ̀lú ògo tí a óò ṣí payá nínú wa.” Nígbà ayé Pọ́ọ̀lù àti lẹ́yìn ìgbà náà pàápàá, àwọn Kristẹni jẹ baba ńlá ìyà lábẹ́ ìṣàkóso bóofẹ́bóokọ̀ tí àwọn aláṣẹ Róòmù gbé kalẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé wọn ò ka ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sí rárá. Nígbà kan, Róòmù tilẹ̀ gbà pé ọ̀tá Orílẹ̀-Èdè náà làwọn Kristẹni jẹ́, ó sì fìyà pá wọn lórí. Òpìtàn J. M. Roberts sọ pé: “Ọ̀pọ̀ Kristẹni tó wà ní olú ìlú [Róòmù] ni wọ́n pa nípakúpa ní pápá ìṣeré, wọ́n sì jó àwọn mìíràn láàyè.” (Shorter History of the World) Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó fara gbá inúnibíni Nérò yìí, ìròyìn mìíràn sọ pé: “Wọ́n kan àwọn kan mọ́gi, wọ́n rán awọ ẹranko mọ́ àwọn kan lára, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ajá lé wọn kiri, wọ́n fi ọ̀dà rẹ́ àwọn kan lára látòkèdélẹ̀, wọ́n wá ṣáná sí wọn lára, kí wọ́n lè máa fi wọ́n ríran gẹ́gẹ́ bíi fìtílà nígbà tí òkùnkùn bá ṣú.”—New Testament History, láti ọwọ́ F. F. Bruce.
Ó dájú pé àwọn Kristẹni ìjímìjí wọ̀nyẹn fẹ́ gba òmìnira kúrò lábẹ́ irú ìninilára bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò gbà láti ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀kọ́ Jésù Kristi kí wọ́n tó lè rí i gbà. Wọn ò dá sí tọ̀tún tòsì rárá, fún àpẹẹrẹ, jẹ́jẹ́ wọn ni wọ́n ń lọ nígbà táwọn aláṣẹ Róòmù àti àwọn ajàjàgbara Júù, àwọn bí Àwọn Onítara Ẹ̀sìn, ń figa gbága. (Jòhánù 17:16; 18:36) Lójú Àwọn Onítara Ẹ̀sìn, “sísọ pé ká dúró di àkókò tó tọ́ lójú Ọlọ́run kọ́ ni ohun tí rògbòdìyàn tí ń lọ́ lọ́wọ́ nígbà náà ń béèrè.” Wọ́n ní “bíbá àwọn ọ̀tá fà á kó yi tíkẹ́tíkẹ́,” ìyẹn làwọn ará Róòmù, ni ohun tí ọ̀ràn náà ń béèrè. (New Testament History) Èrò àwọn Kristẹni ìjímìjí yàtọ̀. Lójú tiwọn, “dídúró di àkókò tó tọ́ lójú Ọlọ́run” ni èrò tó dára jù lọ. Wọ́n mọ̀ dájú pé, kò sí ohun mìíràn tó lè fòpin sí “àwọn ìjìyà àkókò ìsinsìnyí” pátápátá, kó sì mú òmìnira tòótọ́, tí yóò wà pẹ́ títí wá, ju pé kí Ọlọ́run dá sọ́ràn náà. (Míkà 7:7; Hábákúkù 2:3) Ṣùgbọ́n, ká tó ṣàgbéyẹ̀wò bí ìyẹn yóò ṣe ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó fà á gan-an tí “a [fi] tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.”
‘A Tẹ̀ Ẹ́ Lórí Ba fún Ìmúlẹ̀mófo’
Níhìn-ín ọ̀rọ̀ náà, “ìṣẹ̀dá” gẹ́gẹ́ bí Benjamin Wilson ti sọ nínú ìwé náà, The Emphatic Diaglott, kò túmọ̀ sí “àwọn ẹranko àti ẹ̀dá tí kò lẹ́mìí” gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti sọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí “gbogbo aráyé.” (Fi wé Kólósè 1:23.) Ó ń tọ́ka sí gbogbo ìdílé ènìyàn—gbogbo àwa tí a ń yán hànhàn fómìnira. A ‘tẹ̀ wá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo’ nítorí ìgbésẹ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Kì í ṣe “nípasẹ̀ ìfẹ́ [wa]” tàbí nítorí pé ó wù wá bẹ́ẹ̀ lèyí ṣe ṣẹlẹ̀. A jogún ipò tí a bá ara wa ni. Táa bá fojú Ìwé Mímọ́ wò ó, ohun tí Rousseau sọ pé “a bí ènìyàn lómìnira” kò tọ̀nà rárá. Olúkúlùkù wa la bí sínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé, kí a sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, a bí wa sóko ẹrú ètò kan tó kún fún hílàhílo àti ìmúlẹ̀mófo.—Róòmù 3:23.
Èé ṣe tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé, àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, fẹ́ dà “bí Ọlọ́run,” láti má wojú ẹnikẹ́ni fún ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n lè fúnra wọn pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 3:5) Wọn kò ka kókó pàtàkì kan nípa òmìnira sí. Ẹlẹ́dàá nìkan ṣoṣo ló lè ní òmìnira tí kò láàlà. Òun ni Ọba Aláṣẹ Àgbáyé. (Aísáyà 33:22; Ìṣípayá 4:11) Òmìnira ẹ̀dá ènìyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ òmìnira tó ní ààlà. Ìdí nìyẹn tí ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù fi fún àwọn Kristẹni ní ìṣírí ní ọjọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí “òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira” máa darí wọn.—Jákọ́bù 1:25.
Lílé tí Jèhófà lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò nínú ìdílé àgbáyé rẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ó tọ́, àbárèbábọ̀ rẹ̀ sì ni pé wọ́n kú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ṣùgbọ́n àwọn àtọmọdọ́mọ wọn ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìpé, ẹ̀ṣẹ̀, àti ikú nìkan làwọn òbí wọn lè tàtaré rẹ̀ sí wọn báyìí, Jèhófà ṣàánú wọn nípa yíyọ̀ǹda pé kí wọ́n bímọ. Nítorí náà, ‘ikú tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn.’ (Róòmù 5:12) Lọ́nà yẹn, Ọlọ́run “tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo.”
“Ìṣípayá Àwọn Ọmọ Ọlọ́run”
Jèhófà tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo “nítorí ìrètí” pé lọ́jọ́ kan, ìdílé ènìyàn yóò gba òmìnira nípasẹ̀ akitiyan “àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Àwọn wo ni “àwọn ọmọ Ọlọ́run” wọ̀nyí? Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, àwọn tó jẹ́ pé bíi ti ìyókù “ìṣẹ̀dá [tó jẹ́ ènìyàn],” a bí wọn sínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé. Tó bá jẹ́ ti báa ṣe bí wọn ni, wọn kò ní àyè kankan nínú ìdílé àgbáyé ti Ọlọ́run, ìdílé pípé, ìdílé mímọ́. Ṣùgbọ́n Jèhófà ṣe ohun ribiribi fún wọn. Nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi, Jèhófà gbà wọ́n kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti jogún, ó sì polongo wọn ní “olódodo,” tàbí ẹni mímọ́ nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́ríńtì 6:11) Lẹ́yìn náà ó gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí “àwọn ọmọ Ọlọ́run,” ó mú wọn padà wá sínú ìdílé àgbáyé rẹ̀.—Róòmù 8:14-17.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí Jèhófà gbà ṣọmọ, wọn yóò ní àǹfààní ológo. Wọn yóò jẹ́ “àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí,” wọn yóò bá Jésù Kristi ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí apá kan Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run. (Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1-4) Èyí jẹ́ ìjọba kan táa fìdí rẹ̀ sọlẹ̀ gbọn-in lórí ìpìlẹ̀ òmìnira àti ìdájọ́ òdodo—kì í ṣe èyí táa fi ń nini lára, táa fi ń gboni mọ́lẹ̀. (Aísáyà 9:6, 7; 61:1-4) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ọmọ Ọlọ́run wọ̀nyí jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ Jésù, ẹni táa ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ pé òun ni yóò jẹ́ ‘irú-ọmọ Ábúráhámù.’ (Gálátíà 3:16, 26, 29) Nítorí èyí, wọ́n kó ipa pàtàkì nínú ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe fún Ábúráhámù, ọ̀rẹ́ rẹ̀. Apá kan ìlérí náà ni pé, nípasẹ̀ irú-ọmọ Ábúráhámù (tàbí, àtọmọdọ́mọ rẹ̀), “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:18.
Ìbùkún wo ni wọ́n mú wá fáráyé? Àwọn ọmọ Ọlọ́run wọ̀nyí ń nípìn-ín nínú gbígba gbogbo ìdílé ènìyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ti kó aráyé sí, wọ́n tún ń nípìn-ín nínú dídá aráyé padà sí pípé. Àwọn ènìyàn ‘láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn’ lè bù kún ara wọn nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi àti nípa jíjọ̀wọ́ ara wọn fún ìṣàkóso Ìjọba rere rẹ̀. (Ìṣípayá 7:9, 14-17; 21:1-4; 22:1, 2; Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Lọ́nà yìí, lẹ́ẹ̀kan sí i, “gbogbo ìṣẹ̀dá” yóò gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Èyí kò ní jẹ́ òmìnira ìṣèlú tó ní ààlà, tó kàn máa wà fún ìgbà kúkúrú, kàkà bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ òmìnira kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohunkóhun tó ti fa ẹ̀dùn ọkàn àti másùnmáwo fún ìdílé ènìyàn láti ìgbà tí Ádámù àti Éfà ti kọ ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run sílẹ̀. Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ pé “àwọn ìjìyà àsìkò ìsinsìnyí kò jámọ́ ohunkóhun” ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn ológo tí àwọn olóòótọ́ yóò ṣe nígbà náà!
Ìgbà wo ni “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run” yóò bẹ̀rẹ̀? Láìpẹ́ yìí ni, nígbà tí Jèhófà bá jẹ́ kí gbogbo gbòò mọ àwọn tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run ní àmọ̀dájú. Èyí yóò jẹ́ nígbà tí a bá jí “àwọn ọmọ” wọ̀nyí dìde sí ilẹ̀ ọba ẹ̀mí, tí wọ́n bá ń bá Jésù Kristi lọ́wọ́ nínú fífọ ilẹ̀ ayé mọ́ kúrò nínú ìwà ibi àti ìnira nígbà ogun Ọlọ́run ní Hamágẹ́dọ́nì. (Dáníẹ́lì 2:44; 7:13, 14, 27; Ìṣípayá 2:26, 27; 16:16; 17:14; 19:11-21) Láyìíká wa, a rí ẹ̀rí pelemọ tó fi hàn pé a ti wọnú “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” jìnnàjìnnà, nígbà tí ìfaradà tí Ọlọ́run ní fún ìṣọ̀tẹ̀ àti àbájáde ìwà ibi yóò dópin.—2 Tímótì 3:1-5; Mátíù 24:3-31.
Bẹ́ẹ̀ ni, àní òótọ́ ni ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí”—àmọ́ díẹ̀ kékeré báyìí ló kù o. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó wà láàyè nísinsìnyí yóò rí “ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo èyí tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ mímọ́ ti ìgbà láéláé,” títí kan mímú àlàáfíà, òmìnira, àti ìdájọ́ òdodo padà bọ̀ sípò fún gbogbo ìdílé ènìyàn.—Ìṣe 3:21.
Òmìnira Tòótọ́ Nígbẹ̀yìngbẹ́yín
Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe láti lè gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” yìí? Jésù Kristi wí pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Ìyẹn ni àṣírí báa ṣe lè lómìnira—kíkọ́ àwọn àṣẹ àti ìtọ́ni Kristi àti ṣíṣègbọràn sí i. Èyí ń mú òmìnira wá dé àyè kan nísinsìnyí pàápàá. Lọ́jọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ yìí, lábẹ́ ìṣàkóso Kristi Jésù, yóò mú òmìnira pátápátá wá. Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu tó yẹ ká tọ̀ ni pé kí a mọ “ọ̀rọ̀” Jésù dunjú nípasẹ̀ kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Jòhánù 17:3) Bíi ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, máa kẹ́gbẹ́ pọ̀ déédéé pẹ̀lú ìjọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tòótọ́. Bóo bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè jàǹfààní láti inú òtítọ́ tí ń sọni dòmìnira, èyí tí Jèhófà ń mú kó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ lónìí.—Hébérù 10:24, 25.
Bóo ti “ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run,” o lè mú irú ìgbọ́kànlé tí Pọ́ọ̀lù ní nínú ààbò onítọ̀ọ́jú tí Kristi ń fúnni àti ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fúnni dàgbà, ìgbọ́kànlé tí kì í yẹ̀ àní nígbà tí ìjìyà àti àìfẹ̀tọ́bánilò bá dà bí ohun tí kò ṣeé fara dà. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti jíròrò ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run, ó béèrè pé: “Ta ni yóò yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ṣé ìpọ́njú ni tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ebi tàbí ìhòòhò tàbí ewu tàbí idà?” (Róòmù 8:35) Àmọ́ ṣá o, báa bá ní ká lo àwọn ọ̀rọ̀ Rousseau, àwọn Kristẹni ní ọjọ́ Pọ́ọ̀lù ṣì wà “nígbèkùn” onírúurú àwọn agbára tí ń fara nini. Wọ́n “ń fi ikú pa [wọ́n] láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀” bí “àgùntàn fún pípa.” (Róòmù 8:36) Ǹjẹ́ wọ́n gbà kíyẹn mú ọkàn wọn pòrúurùu bí?
Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ń di ajagunmólú pátápátá nípasẹ̀ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa.” (Róòmù 8:37) Ṣe pé àwọn Kristẹni jagun mólú láìfi gbogbo ohun tí wọ́n fara dà pè? Ọ̀nà wo ni wọ́n gbé e gbà? Nínú ìdáhùn rẹ̀, ó wí pé: “Nítorí mo gbà gbọ́ dájú pé kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ tàbí àwọn agbára tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà nínú Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 8:38, 39) Ìwọ pẹ̀lú lè ‘jagun mólú’ láti inú “ìpọ́njú . . . tàbí wàhálà tàbí inúnibíni” èyíkéyìí tí o ní láti fara dà ní àkókò tí a ṣì wà yìí. Ìfẹ́ Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé, láìpẹ́ yìí sẹ́—àní láìpẹ́ sígbà táa wà yìí—a ‘óò dá wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìsọdẹrú, a óò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.’
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
“Gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀ títí di ìsinsìnyí”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
‘A óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run’