Ǹjẹ́ O Máa Ń lo Àkókò Pẹ̀lú Ìdílé Rẹ?
“WỌ́N Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Baba Ní Japan—Bí Ọwọ́ Wọ́n Tilẹ̀ Dí Lẹ́nu Iṣẹ́, Tí Wọn Kò sì Ráyè Bá Àwọn Ọmọ Wọn Ṣeré.” Àkọlé yìí fara hàn lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn nínú ìwé ìròyìn Mainichi Shimbun. Àpilẹ̀kọ náà ròyìn pé nǹkan bí ìpín méjìdínláàádọ́rùn-ún [88] nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ní Japan, tí wọ́n kópa nínú ìwádìí kan tí ìjọba ṣe, sọ pé àwọn yóò fẹ́ láti tọ́jú baba àwọn lọ́jọ́ alẹ́ wọn. Àmọ́, nígbà tí ẹ̀dà ìwé ìròyìn kan náà lédè Gẹ̀ẹ́sì máa gbé àbájáde ìwádìí náà jáde, àkọlé ọ̀tọ̀ ló fún un. Àkọlé tirẹ̀ kà pé “Àwọn Baba Àtọmọ Ti Pa Ara Wọn Tì.” Láìdàbí ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà lédè Japanese, apá mìíràn ìwádìí kan náà ni àpilẹ̀kọ náà gbé jáde: Ní gbogbo ọjọ́ iṣẹ́, kìkì ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlógójì ni àwọn baba ní Japan máa ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Ní ìfiwéra, àwọn baba ní West Germany máa ń lo ìṣẹ́jú mẹ́rìnlélógójì pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn láàárín ọ̀sẹ̀, àti ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni àwọn baba ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Àwọn baba nìkan kọ́ ni kì í ráyè jókòó ti àwọn ọmọ wọn. Àwọn ìyá tó ń jáde lọ wáṣẹ́ ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i ṣáá. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìyá tó ń dá nìkan tọ́ ọmọ ló ń ṣiṣẹ́ bóojí-o-jí-mi láti fi gbọ́ bùkátà ìdílé. Fún ìdí yìí, iye àkókò tí àwọn òbí—ìyẹn, bàbá àti màmá—ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ti dín kù gan-an.
Ìwádìí kan tó wáyé lọ́dún 1997 láàárín àwọn ọ̀dọ́langba ọmọ Amẹ́ríkà tí iye wọn ju ẹgbàafà [12,000] fi hàn pé àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn kì í sábà ní másùnmáwo, wọn kì í sábà gbèrò àtipa ara wọn, wọn kì í sábà hùwà ipá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sábà lo àwọn oògùn olóró. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tó kópa nínú ìwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn òbí kò lè ní ìbátan gúnmọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn àyàfi bí wọ́n bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn ọmọ.” Lílo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ àti bíbá wọn sọ̀rọ̀ ṣe kókó.
Àìsí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀
Ohun pàtàkì tó sábà máa ń fa àìsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ nínú ìdílé ni bí òbí kan bá lọ ń gbé nílùú mìíràn nítorí iṣẹ́. Ṣùgbọ́n ìṣòro ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ kò mọ sí àwọn ìdílé tí òbí kan ti ń gbé ní ọ̀nà jíjìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé làwọn òbí kan máa ń wá sùn, síbẹ̀ wọ́n máa ń lọ síbi iṣẹ́ kí àwọn ọmọ tó jí, àwọn ọmọ á sì ti sùn lálẹ́ kí wọ́n tó tibi iṣẹ́ dé. Láti lè dí àlàfo yìí, àwọn òbí kan máa ń lo àkókò pẹ̀lú ìdílé wọn ní ìparí ọ̀sẹ̀ àti nígbà ìsinmi ráńpẹ́ lẹ́nu iṣẹ́. Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa lílo àkókò “tó gbámúṣé” pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.
Àmọ́ o, bí àkókò ráńpẹ́ tí wọ́n ń lo pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn bá gbámúṣé, èyí ha ti yanjú ìṣòro náà bí? Olùwádìí náà Laurence Steinberg fèsì pé: “Lápapọ̀, àwọn ọmọ tó bá ń lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí wọn máa ń ṣe dáadáa ju àwọn ọmọ tí kì í lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú òbí wọn. Ó jọ pé ó ṣòro gan-an láti rí oògùn àtúnṣe sí ìṣòro àìráyè lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ. Ìtẹnumọ́ ti pọ̀ jù lórí ọ̀ràn àkókò díẹ̀ tó gbámúṣé.” Báyìí gan-an lọ̀ràn náà rí lọ́kàn obìnrin ará Burma kan. Ọkọ rẹ̀—tó jẹ́ ará Japan, tí ìṣe rẹ̀ kò sì yàtọ̀ sí ti àwọn ọkùnrin Japan—máa ń tibi iṣẹ́ dé láago kan tàbí aago méjì òru. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń lo àkókò pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ níparí ọ̀sẹ̀, ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Wíwà nílé lọ́jọ́ Sátidé àti Sunday kò lè dí àlàfo àìsí pẹ̀lú ìdílé ní gbogbo ìyókù ọ̀sẹ̀. . . . Ṣé o lè ṣàìjẹun láàárín ọ̀sẹ̀, kí o sì wá jẹ gbogbo oúnjẹ tí o kò jẹ láàárín ọ̀sẹ̀ ní ọjọ́ Sátidé àti Sunday?”
Ó Gba Ìsapá Àtọkànwá
Ṣíṣètò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ déédéé nínú ìdílé dùn-ún sọ, ṣùgbọ́n ó ṣòroó ṣe. Sísáré àtijẹ-àtimu àti gbígbọ́ bùkátà ìdílé kò jẹ́ kó rọrùn fún baba tàbí ìyá tí ń ṣiṣẹ́ láti lo àkókò pẹ̀lú ìdílé wọn. Ọ̀pọ̀ tí ipò àwọn nǹkan ti sọ ọ́ di kàráǹgídá fún wọn láti wà ní ọ̀nà jíjìn sílé máa ń kàn sílé déédéé nípa bíbá àwọn aráalé sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ tẹlifóònù tàbí nípa kíkọ lẹ́tà sí wọn. Ṣùgbọ́n, yálà ìdílé wà pa pọ̀ nílé àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó gba ìsapá àtọkànwá láti rí sí i pé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ déédéé ń wáyé nínú ìdílé.
Àwọn òbí tó bá ń dágunlá sí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdílé wọn yóò jẹ̀rán ẹ̀. Baba kan tí kò ráyè fún ìdílé ẹ̀, tí kì í tilẹ̀ bá wọn jẹun, dojú kọ ìṣòro ńlá. Ọmọkùnrin rẹ̀ ya ewèlè, ọwọ́ sì tẹ ọmọbìnrin rẹ̀ níbi tó ti ń ṣàfọwọ́rá. Lọ́jọ́ kan, láàárọ̀ Sunday, bí baba náà ti ń múra àtilọ síbi tó ti fẹ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù kan táa ń pè ní gọ́ọ̀fù, ọmọkùnrin rẹ̀ figbe ta, ó ní: “Ṣé màmá nìkan ni òbí tó wà nínú ilé yìí ni?” Ọmọkùnrin náà wá dárò pé: “Màmá ló ń dá gbogbo ìpinnu ṣe nínú ìdílé yìí. Dádì, kò tiẹ̀ sígbà kankan tí ẹ . . .”
Ọ̀rọ̀ yẹn ró kìì lọ́kàn baba yẹn. Ní àbárèbábọ̀, ó wá pinnu pé òun yóò tibi bíbá ìdílé òun jẹ oúnjẹ àárọ̀ bẹ̀rẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, òun àtìyàwó ẹ̀ nìkan ni wọ́n jọ ń jẹ oúnjẹ àárọ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn jẹun, ìgbà oúnjẹ àárọ̀ sì wá di àkókò ìjùmọ̀sọ̀rọ̀. Eléyìí wá yọrí sí jíjẹ tí ìdílé ń jẹ oúnjẹ alẹ́ pa pọ̀. Nípa báyìí, ọkùnrin yìí ń sapá láti gba ìdílé rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ fífọ́yángá.
Ìrànlọ́wọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Bíbélì rọ àwọn òbí pé kí wọ́n wá àkókò láti máa fi bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀. A fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni nípasẹ̀ wòlíì náà, Mósè, pé: “Fetí sílẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì: Jèhófà Ọlọ́run wa, Jèhófà kan ṣoṣo ni. Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo okunra rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.” (Diutarónómì 6:4-7) Bẹ́ẹ̀ ni, àwa táa jẹ́ òbí gbọ́dọ̀ ṣètò láti máa lo àkókò pẹ̀lú ìdílé wa bí a óò bá gbin ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú èrò inú àti ọkàn-àyà àwọn ọmọ wa.
Ẹ óò fẹ́ láti mọ̀ pé, ìwádìí táa mẹ́nu kàn ṣáájú, táa ṣe lọ́dún 1997, láàárín àwọn ọ̀dọ́langba àwọn ọmọ Amẹ́ríkà tó ju ẹgbàafà, fi hàn pé “lára nǹkan bí ìpín méjìdínláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún . . . tó sọ pé àwọn ń ṣe ẹ̀sìn kan, ojú pàtàkì tí wọ́n fi ń wo ẹ̀sìn àti àdúrà ń dáàbò bò wọ́n.” Àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ pé fífi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tòótọ́ kọ́ àwọn ọmọ nínú ilé máa ń dáàbò bo àwọn èwe lọ́wọ́ àwọn nǹkan bí ìjoògùnyó, másùnmáwo, ìpara ẹni, ìwà ipá, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àwọn òbí kan gbà pé ó ṣòro láti rí àyè fún ìdílé wọn. Ti àwọn ìyá tí ń dá nìkan tọ́mọ ló tilẹ̀ nira jù, nítorí pé bí wọ́n ti ń fi tayọ̀tayọ̀ lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọ́n tún ní láti máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Pẹ̀lú àkókò wọn tó há gádígádí, báwo ni wọ́n ṣe lè ráyè jókòó ti ìdílé wọn? Bíbélì rọ̀ wá pé, “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.” (Òwe 3:21) Àwọn òbí lè lo “agbára láti ronú” kí wọ́n bàa lè rí àyè fún ìdílé wọn. Lọ́nà wo?
Bóo bá jẹ́ ìyá tí ń ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tó sì máa ń rẹ̀ ẹ́ lẹ́yìn tóo bá ṣíwọ́ iṣẹ́, oò ṣe sọ pé kí ìwọ àtàwọn ọmọ jọ gbọ́ oúnjẹ? Irú àkókò bẹ́ẹ̀ tẹ́ẹ jọ lò pa pọ̀ yóò pèsè àǹfààní fún yín láti túbọ̀ sún mọ́ra. Nígbà tẹ́ẹ bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, lílọ́wọ́ tí àwọn ọmọ rẹ ń lọ́wọ́ sí i lè jẹ́ kí ó pẹ́ díẹ̀ kí oúnjẹ tó délẹ̀. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́, yóò máa dùn mọ́ ẹ, yóò sì wá yá ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
O lè jẹ́ baba tí àwọn nǹkan tóo fẹ́ ṣe níparí ọ̀sẹ̀ pọ̀ lọ jàra. Kí ló dé tí ìwọ àtàwọn ọmọ ò kúkú jọ ṣe àwọn iṣẹ́ náà? O lè máa bá wọn sọ̀rọ̀ bí ẹ ti jọ ń ṣiṣẹ́ lọ, lẹ́sẹ̀ kan náà kí o sì máa fún wọn ní ìtọ́ni tó wúlò gan-an. Ìmọ̀ràn Bíbélì pé kí o gbin ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ rẹ, rọ̀ ẹ́ pé kí o máa bá wọn sọ̀rọ̀ “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà”—àní sẹ́, ní gbogbo ìgbà. “Ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́” lò ń fi hàn nígbà tí o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ bí ẹ ti jọ ń ṣiṣẹ́.
Àjẹpẹ́ làǹfààní tí ń bẹ nínú lílo àkókò pẹ̀lú ìdílé rẹ. Òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn tí ń fikùn lukùn.” (Òwe 13:10) Nípa wíwá àyè láti bá ìdílé rẹ jùmọ̀ sọ̀rọ̀, yóò ṣeé ṣe fún ẹ láti tọ́ wọn sọ́nà ọgbọ́n nínú ìgbòkègbodò ìgbésí ayé. Irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ tóo bá fún wọn báyìí kò ní jẹ́ kí ọrùn wọ̀ ẹ́ lọ́jọ́ iwájú, á sì gbà ẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn lẹ́yìnwá ọ̀la. Ìyẹn nìkan kọ́, ó lè fi kún ayọ̀ tìẹ àti tàwọn náà. Láti lè pèsè irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀, o ní láti lọ bù nínú alagbalúgbú ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lò ó láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ rẹ, kí o sì máa fi tọ́ ìṣísẹ̀ ìdílé rẹ.—Sáàmù 119:105.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn ọ̀dọ́ tó ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn kì í sábà ní másùnmáwo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ déédéé máa ń so èso rere nínú ìgbésí ayé ìdílé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Bóo ti ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọmọ rẹ, o lè máa bá a sọ̀rọ̀, kí o sì máa kọ́ ọ ní ojúlówó ẹ̀kọ́