Inú Wa Dùn Pé Jèhófà Ń fọ̀nà Rẹ̀ Hàn wá
“Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́.”—2 SÁMÚẸ́LÌ 22:31.
1, 2. (a) Kí ló jẹ́ kòṣeémánìí fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn? (b) Àpẹẹrẹ ta ló yẹ ká fara wé?
KÒṢEÉMÁNÌÍ ni ìtọ́sọ́nà jẹ́ fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn. Àní, a ò lè rin ìrìn àjò ìgbésí ayé já láìsí ìtọ́sọ́nà. Òótọ́ ni pé Jèhófà ti fi làákàyè àti ẹ̀rí-ọkàn jíǹkí wa, kí a bàa lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó tọ́ àtohun tí kò tọ́. Ṣùgbọ́n, ẹ̀rí-ọkàn wa nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́ bí yóò bá jẹ́ atọ́nà tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. (Hébérù 5:14) Èrò inú wa ń fẹ́ ìsọfúnni tó péye—àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa bí yóò ṣe gbé ìsọfúnni ọ̀hún lé ìwọ̀n—bí a óò bá ṣe àwọn ìpinnu tó dáa. (Òwe 2:1-5) Pẹ̀lú ìyẹn pàápàá, àwọn ìpinnu wa ṣì lè forí ṣánpọ́n, torí pé láyé táa wà yìí, nígbà mí-ìn, ibi táa fojú sí, ọ̀nà lè má gbabẹ̀. (Oníwàásù 9:11) Bí a bá fi dá tiwa, ẹ̀dá tó mọ̀la ò sí.
2 Fún ìdí wọ̀nyí, àti ọ̀pọ̀ ìdí mìíràn, ni wòlíì Jeremáyà fi kọ̀wé pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Jésù Kristi, ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí, tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà. Ó sọ pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe. Nítorí ohun yòówù tí Ẹni yẹn ń ṣe, nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ ń ṣe pẹ̀lú lọ́nà kan náà.” (Jòhánù 5:19) Àbí ẹ ò rí bó ṣe lọ́gbọ́n nínú tó láti fara wé Jésù, kí a sì máa wo ojú Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nínú dídarí ìṣísẹ̀ wa! Ọba Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ní ti Ọlọ́run tòótọ́, pípé ni ọ̀nà rẹ̀; àsọjáde Jèhófà jẹ́ èyí tí a yọ́ mọ́. Apata ni ó jẹ́ fún gbogbo àwọn tí ń sá di í.” (2 Sámúẹ́lì 22:31) Báa bá ń sapá láti máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà dípò lílo ọgbọ́n ara wa, a óò ní ìtọ́sọ́nà pípé. Pípa ọ̀nà Ọlọ́run tì máa ń yọrí sí àjálù.
Jèhófà Ń Fọ̀nà Hanni
3. Báwo ni Jèhófà ṣe tọ́ Ádámù àti Éfà sọ́nà, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà fún kí ni?
3 Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn Ádámù àti Éfà yẹ̀ wò. Bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ ẹ̀dá aláìlẹ́ṣẹ̀, wọ́n nílò ìtọ́sọ́nà. Jèhófà kò fi Ádámù sílẹ̀ láti wéwèé gbogbo nǹkan fún ara rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ẹlẹ́wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fún un níṣẹ́ ṣe. Àkọ́kọ́, Ádámù gbọ́dọ̀ sọ àwọn ẹranko lórúkọ. Lẹ́yìn náà, Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ní àwọn góńgó tí yóò gba àkókò kí wọ́n tó lè lé wọn bá. Ó ní kí wọ́n ṣèkáwọ́ ilẹ̀ ayé, kí wọ́n bímọ kún un, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko tó wà ní ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Iṣẹ́ bàǹtàbanta nìyí, ṣùgbọ́n ìyọrísí rẹ̀ yóò jẹ́ párádísè kárí ayé, tó kún fún ìran ènìyàn pípé tí ń gbé ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀dá ẹranko. Àgbàyanu ìrètí mà nìyí o! Kò tán síbẹ̀ o, bí Ádámù àti Éfà ti ń fi ìṣòtítọ́ rìn ní ọ̀nà Jèhófà, wọn yóò máa bá a sọ̀rọ̀. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 3:8.) Àǹfààní yìí mà ga o—láti ní ìbátan tímọ́tímọ́, tí kò lópin pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá!
4. Báwo ni Ádámù àti Éfà ṣe fi hàn pé àwọn kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìdúróṣinṣin, pẹ̀lú ìyọrísí búburú wo?
4 Jèhófà ka jíjẹ nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú tó wà nínú Édẹ́nì léèwọ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́, èyí sì fún wọn láǹfààní lójú ẹsẹ̀ láti fi hàn pé àwọn jẹ́ onígbọràn—pé àwọn fẹ́ máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Àmọ́ ṣá o, láìpẹ́ la ó mọ̀ bóyá elétí ọmọ ni wọn. Nígbà tí Sátánì wá tú irọ́ tà fún Ádámù àti Éfà, ṣe ló yẹ kí wọ́n dúró ṣinṣin ti Jèhófà, kí wọ́n sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Rẹ̀, bí wọn yóò bá jẹ́ onígbọràn. Ó bani nínú jẹ́ pé, wọn kò lẹ́mìí ìdúróṣinṣin, wọn kò sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé. Nígbà tí Sátánì fi ẹ̀mí ìṣetinú-ẹni lọ Éfà, tó sì fẹ̀sùn èké kan Jèhófà pé Jèhófà ń purọ́, a tan Éfà jẹ, ó sì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ádámù bá Éfà wọnú ẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 1 Tímótì 2:14) Ohun tí wọ́n pàdánù gadabú. Rírìn ní ọ̀nà Jèhófà ì bá ti fún wọn ní ìdùnnú kíkọyọyọ bí wọ́n ti ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Ṣùgbọ́n, ó tán o, ìjákulẹ̀ àti ìrora ló wá kún inú ayé wọn, títí ikú fi wá lé wọn bá.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16-19; 5:1-5.
5. Kí ni ète ọlọ́jọ́ pípẹ́ tí Jèhófà gbé kalẹ̀, báwo sì ni ó ṣe ń ran àwọn ẹ̀dá ènìyàn olóòótọ́ lọ́wọ́ láti rí ìmúṣẹ rẹ̀?
5 Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà kò yí ète rẹ̀ padà pé, lọ́jọ́ kan, ilẹ̀ ayé yóò di ilé párádísè fún ẹ̀dá ènìyàn pípé aláìlẹ́ṣẹ̀. (Sáàmù 37:11, 29) Kò sì kùnà rí, nínú pípèsè ìtọ́sọ́nà pípé fún àwọn tó bá ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí wọ́n sì ń retí àtirí ìmúṣẹ ìlérí yẹn. Fún àwa táa jẹ́ elétí ọmọ, ohùn Jèhófà ń dún lẹ́yìn wa, pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísáyà 30:21.
Àwọn Kan Rìn ní Ọ̀nà Jèhófà
6. Àwọn ọkùnrin méjì wo láyé àtijọ́ ló rìn ní ọ̀nà Jèhófà, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
6 Gẹ́gẹ́ bí àkọọ́lẹ̀ Bíbélì ti wí, ìwọ̀nba kéréje lára àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà ló rìn ní ọ̀nà Jèhófà. Ébẹ́lì lẹni àkọ́kọ́ lára àwọn wọ̀nyí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kú ikú àìtọ́jọ́, inú ojú rere Jèhófà ló kú sí, nípa báyìí ó dájú pé yóò nípìn-ín nínú “àjíǹde àwọn olódodo” nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run. (Ìṣe 24:15) Yóò rí ìmúṣẹ ìlérí ńlá Jèhófà fún ilẹ̀ ayé àti aráyé nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Hébérù 11:4) Ẹlòmíràn tó tún rìn ní ọ̀nà Jèhófà ni Énọ́kù, ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa òpin pátápátá ètò àwọn nǹkan yìí wà nínú ìwé Júúdà. (Júúdà 14, 15) Ọjọ́ ayé Énọ́kù pẹ̀lú kò kún. (Jẹ́nẹ́sísì 5:21-24) Síbẹ̀, “ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.” (Hébérù 11:5) Nígbà tó kú, ó dájú pé òun náà, gẹ́gẹ́ bí Ébẹ́lì, yóò ní àjíǹde, yóò sì wà lára àwọn tí yóò rí ìmúṣẹ àwọn ète Jèhófà.
7. Báwo ni Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe fi hàn pé àwọn dúró ṣinṣin ti Jèhófà àti pé àwọn gbẹ́kẹ̀ lé e?
7 Bí ayé tó wà ṣáájú Ìkún Omi ti túbọ̀ ń jingíri sínú ìwà ibi, ṣe ni ọ̀ràn ìgbọràn sí Jèhófà wá túbọ̀ ń di èyí tí a fi ń dán ìdúróṣinṣin ẹni wò. Nígbà tí ayé yẹn wà ní ọ̀gẹ́gẹ́rẹ́ rẹ̀, àwùjọ kékeré kan ṣoṣo ló wà tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà. Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbọ́ràn sí Ọlọ́run lẹ́nu, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé ohun tó sọ. Wọ́n fi tọkàntọkàn ṣe àwọn iṣẹ́ táa gbé ka iwájú wọn ní àṣeparí, wọn ò sì jẹ́ káwọn kan fà wọ́n wọnú àwọn ìwàkiwà tó gbòde kan láyé ìgbà yẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5-7, 13-16; Hébérù 11:7; 2 Pétérù 2:5) A dúpẹ́ fún ìgbọràn wọn tó fi ìwà ìdúróṣinṣin àti ìgbẹ́kẹ̀lé hàn. Nítorí èyí, wọ́n la Ìkún Omi já, wọ́n sì di orírun wa.—Jẹ́nẹ́sísì 6:22; 1 Pétérù 3:20.
8. Rírìn ní ọ̀nà Ọlọ́run ń béèrè pé kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe kí ni?
8 Bí ọjọ́ ti ń lọ, Jèhófà dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú àwọn àtọmọdọ́mọ Jékọ́bù olùṣòtítọ́, wọ́n sì di orílẹ̀-èdè rẹ̀ lákànṣe. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Jèhófà pèsè ìtọ́sọ́nà fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó bá dá májẹ̀mú, nípasẹ̀ Òfin tí a kọ sílẹ̀, àti ẹgbẹ́ àlùfáà, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń bá a lọ ní fífọ̀nà hàn wọ́n. Ṣùgbọ́n ó kù sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́, láti tọ ọ̀nà tí a fi hàn wọ́n. Jèhófà ní kí wòlíì òun sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Wò ó, èmi ń fi ìbùkún àti ìfiré sí iwájú yín lónìí: ìbùkún, kìkì bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí èmi ń pa láṣẹ fún yín lónìí; àti ìfiré, bí ẹ̀yin kò bá ní ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yà ní ti gidi kúrò lójú ọ̀nà tí mo ń pa láṣẹ fún yín lónìí, láti rìn tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, tí ẹ̀yin kò mọ̀.”—Diutarónómì 11:26-28.
Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Pa Ọ̀nà Jèhófà Tì
9, 10. Ipò wo ló jẹ́ kó di dandan fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì í?
9 Gẹ́gẹ́ bí ó ti pọndandan pé kí Ádámù àti Éfà gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì í, bẹ́ẹ̀ náà ló pọndandan kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe bákan náà bí wọn yóò bá jẹ́ onígbọràn. Ísírẹ́lì jẹ́ orílẹ̀-èdè kékeré tí àwọn orílẹ̀-èdè arógunyọ̀ yí ká. Bí wọ́n bá yíjú sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn, Íjíbítì àti Etiópíà ló wà níbẹ̀. Bí wọ́n bá wo àríwá ìlà oòrùn, Síríà àti Ásíríà ní ń bẹ níbẹ̀. Ní ti sàkáání wọn gan-gan ń kọ́ o, Filísíà, Ámónì, Móábù, àti Édómù ló rọ̀gbà yí wọn ká. Kò sígbà táwọn ọ̀tá wọ̀nyí fi Ísírẹ́lì lọ́rùn sílẹ̀. Ìyẹn nìkan kọ́ o, gbogbo wọn ló ń ṣe ẹ̀sìn èké, tó kún fún ìjọsìn àwọn òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, ìwòràwọ̀, àti nígbà mìíràn, àwọn ààtò ìbálòpọ̀ tó burú jáì, àti ìwà òǹrorò ti fífi àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ rúbọ. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àyíká Ísírẹ́lì máa ń tẹ́wọ́ àdúrà sáwọn ọlọ́run wọn pé kí wọ́n fún wọn ní àwọn ìdílé ńláńlá, ìkórè wọ̀ǹtìwọnti, àti ìjagunmólú.
10 Ísírẹ́lì nìkan ló ń sin Ọlọ́run kan ṣoṣo, èyíinì ni Jèhófà. Ó ṣèlérí pé òun yóò fi àwọn ìdílé ńláńlá, ìkórè jìngbìnnì, àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá bù kún wọn, bí wọ́n bá ṣègbọràn sáwọn òfin òun. (Diutarónómì 28:1-14) Ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kò ṣègbọràn sáwọn òfin rẹ̀. Lára àwọn tó rìn ní ọ̀nà Jèhófà ńkọ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló jìyà nítorí ìdúróṣinṣin wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ wọ́n tilẹ̀ dá àwọn kan lóró, wọ́n fi àwọn kan ṣẹ̀sín, wọ́n na àwọn kan lọ́rẹ́, wọ́n sọ àwọn kan sẹ́wọ̀n, wọ́n sọ àwọn kan lókùúta, wọ́n tilẹ̀ pa àwọn mìíràn. (Ìṣe 7:51, 52; Hébérù 11:35-38) Ìdánwò yẹn mà pọ̀ fún àwọn olùṣòtítọ́ o! Ṣùgbọ́n, kí ló fà á tí àwọn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ṣáko lọ kúrò ní ọ̀nà Jèhófà? Àpẹẹrẹ méjì láti inú ìtàn Ísírẹ́lì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìrònú òdì wọn.
Àpẹẹrẹ Búburú Áhásì
11, 12. (a) Nígbà tí Síríà ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ Áhásì, kí ni Áhásì kọ̀ láti ṣe? (b) Ibi méjì wo ni Áhásì yíjú sí fún ààbò?
11 Áhásì jọba ní ìjọba gúúsù ti Júdà ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Kò sí àlàáfíà nígbà ìjọba rẹ̀. Nígbà kan, Síríà àti ìjọba àríwá ti Ísírẹ́lì para pọ̀ láti bá a jagun, ṣe ni “ọkàn-àyà rẹ̀ àti ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.” (Aísáyà 7:1, 2) Ṣùgbọ́n, nígbà tí Jèhófà nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí Áhásì, tí Jèhófà ní kí ó fìjà fóun jà, ṣe ni Áhásì yarí kanlẹ̀! (Aísáyà 7:10-12) Fún ìdí yìí, Júdà ò rọ́wọ́ mú nínú ogun náà, wọ́n sì pa wọ́n lọ súà.—2 Kíróníkà 28:1-8.
12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Áhásì ṣe gbọ́ńkúgbọ́ńkú sí Jèhófà, tó kọ̀ láti fìjà fún un jà, ó yani lẹ́nu pé ó lọ ń pá kúbẹ́kúbẹ́ lọ́dọ̀ ọba Ásíríà, tó ń bẹ̀ ẹ́ pé kó wá ran òun lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ọwọ́ ìyà kò tán lára Júdà, ṣe ni àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká rẹ̀ ń wẹ ọwọ́ ìyà sí i lára. Nígbà tí Ásíríà alára wá yíjú sí Áhásì, tó sì “kó wàhálà bá a,” ọba wá “bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí àwọn ọlọ́run Damásíkù tí ń kọlù ú, ó sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: ‘Nítorí pé àwọn ọlọ́run àwọn ọba Síríà ń ràn wọ́n lọ́wọ́, àwọn ni èmi yóò rúbọ sí kí wọ́n lè ràn mí lọ́wọ́.’”—2 Kíróníkà 28:20, 23.
13. Kí ni Áhásì fi hàn nípa yíyíjú sáwọn ọlọ́run Síríà?
13 Lẹ́yìn ìgbà náà, Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:17, 18) Nípa yíyíjú sáwọn ọlọ́run Síríà, Áhásì fi hàn bí ọ̀nà òun ti jìn tó sí ‘títọ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó máa rìn.’ Ìrònú àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣì í lọ́nà pátápátá, nítorí pé àwọn nǹkan tí kò lè gba ara wọn pàápàá là ló gbára lé, kàkà tí ìbá fi gbára lé Jèhófà.
14. Èé ṣe tí Áhásì kò fi ní àwíjàre nígbà tó yíjú sáwọn èké ọlọ́run?
14 Tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti fi hàn pé “ọlọ́run tí kò ní láárí” làwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè, títí kan àwọn ọlọ́run Síríà. (Aísáyà 2:8) Níjọ́un àná, nígbà tí Ọba Dáfídì wà lórí oyè, kedere-kèdèrè ni Jèhófà fi àjùlọ han àwọn ọlọ́run Síríà, nígbà táwọn ará Síríà di ìránṣẹ́ Dáfídì. (1 Kíróníkà 18:5, 6) Kìkì Jèhófà, “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn olúwa, Ọlọ́run títóbi, alágbára ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù,” ló lè fúnni ní ààbò tòótọ́. (Diutarónómì 10:17) Ṣùgbọ́n, Áhásì kẹ̀yìn sí Jèhófà, ó wá yíjú sí ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè fún ààbò. Nǹkan burúkú ló yọrí sí fún Júdà.—2 Kíróníkà 28:24, 25.
Àwọn Júù Tó Wà Pẹ̀lú Jeremáyà ní Íjíbítì
15. Lọ́nà wo làwọn Júù tó wà ní Íjíbítì lọ́jọ́ Jeremáyà fi ṣẹ̀?
15 Jèhófà jẹ́ kí àwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tó légbá kan táwọn èèyàn rẹ̀ hù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè náà ló lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Àmọ́ ṣá o, a fi àwọn kan sílẹ̀, lára wọn ni wòlíì Jeremáyà. Nígbà tí wọ́n dìtẹ̀ pa Gómìnà Gẹdaláyà, àwọn èèyàn yìí sá lọ sí Íjíbítì, wọ́n sì mú Jeremáyà dání pẹ̀lú wọn. (2 Ọba 25:22-26; Jeremáyà 43:5-7) Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sáwọn ọlọ́run èké. Jeremáyà fi taratara rọ àwọn Júù aláìṣòótọ́ yìí, ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí ikún sí i. Wọ́n kọ̀ jálẹ̀ pé àwọn ò ní padà sọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ranrí pé àwọn ò ní yéé rú èéfín ẹbọ sí “ọbabìnrin ọ̀run.” Èé ṣe? Nítorí pé èyí ni ohun tí àwọn àti àwọn baba ńlá wọn ti ṣe ‘ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n máa ń jẹ oúnjẹ ní àjẹtẹ́rùn, tí nǹkan sì dára fún wọn, tí wọn kò sì rí ìyọnu àjálù kankan rárá.’ (Jeremáyà 44:16, 17) Àwọn Júù náà tún jiyàn pé: “Láti ìgbà tí a sì ti ṣíwọ́ rírú èéfín ẹbọ sí ‘ọbabìnrin ọ̀run’ àti dída ọrẹ ẹbọ ohun mímu jáde sí i ni a ti ṣaláìní ohun gbogbo, àti nípasẹ̀ idà àti nípasẹ̀ ìyàn sì ni a ti wá sí òpin wa.”—Jeremáyà 44:18.
16. Èé ṣe tí ìrònú àwọn Júù tó wà ní Íjíbítì fi lòdì pátápátá?
16 Ó mà kúkú ṣe o, pé ohun táa bá fẹ́ rántí la máa ń rántí! Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an? Lóòótọ́ làwọn Júù rúbọ sáwọn èké ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ tí Jèhófà fi fún wọn. Nígbà mí-ìn, wọ́n jìyà nítorí ìpẹ̀yìndà yẹn, gẹ́gẹ́ bó ti rí lọ́jọ́ Áhásì. Ṣùgbọ́n o, Jèhófà “ń lọ́ra láti bínú” sí àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀. (Ẹ́kísódù 34:6; Sáàmù 86:15) Ó rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí wọn, pé kí wọ́n rọ̀ wọ́n láti ronú pìwà dà. Nígbà mí-ìn, tí ọba olóòótọ́ bá jẹ, Jèhófà yóò bù kún rẹ̀, àwọn ènìyàn náà á sì jàǹfààní láti inú ìbùkún náà, bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòótọ́. (2 Kíróníkà 20:29-33; 27:1-6) Àwọn Júù wọnnì tó wà ní Íjíbítì, tó sọ pé ọwọ́ àwọn èké ọlọ́run ni gbogbo aásìkí táwọn gbádùn ní ilẹ̀ ìbílẹ̀ àwọn ti wá, mà kúkú ṣìnà o!
17. Èé ṣe tí Júdà fi pàdánù ilẹ̀ àti tẹ́ńpìlì rẹ̀?
17 Kí ó tó di ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ni Jèhófà ti ń rọ àwọn èèyàn Júdà pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, èmi yóò sì di Ọlọ́run yín, ẹ̀yin alára yóò sì di ènìyàn mi; kí ẹ sì máa rìn ní gbogbo ọ̀nà tí èmi yóò pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.” (Jeremáyà 7:23) Ìdí náà gan-an táwọn Júù fi pàdánù tẹ́ńpìlì wọn àti ilẹ̀ wọn ni pé wọ́n kọ̀ láti máa rìn ‘ní gbogbo ọ̀nà tí Jèhófà pa láṣẹ fún wọn.’ Ẹ yáa jẹ́ ká yàgò fún irú àṣìṣe burúkú bẹ́ẹ̀ o.
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tí Ń Rìn Lọ́nà Rẹ̀
18. Kí ni àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣe?
18 Lónìí, gẹ́gẹ́ bí tàtijọ́, rírìn ní ọ̀nà Jèhófà ń béèrè ìdúróṣinṣin—ìpinnu láti máa sin òun nìkan ṣoṣo. Ó ń béèrè ìgbẹ́kẹ̀lé—ìgbàgbọ́ àtọkànwá pé àwọn ìlérí Jèhófà ṣeé gbára lé àti pé wọn yóò ní ìmúṣẹ. Rírìn pẹ̀lú Jèhófà ń béèrè ìgbọràn—pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ láìyà bàrá àti títẹ̀lé àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga rẹ̀. “Olódodo ni Jèhófà; ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ìṣe òdodo.”—Sáàmù 11:7.
19. Àwọn ọlọ́run wo lọ̀pọ̀ èèyàn ń sìn lónìí, kí ló sì ti yọrí sí?
19 Àwọn ọlọ́run Síríà ni Áhásì yíjú sí fún ààbò. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà ní Íjíbítì ń retí pé “ọbabìnrin ọ̀run,” abo ọlọ́run tí wọ́n ń jọ́sìn jákèjádò Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ìgbàanì, yóò mú kí wọ́n di ọlọ́rọ̀ nípa tara. Ọ̀pọ̀ ọlọ́run tó wà lónìí ni kì í kàn-án ṣe òrìṣà bọrọgidi. Jésù kìlọ̀ nípa sísin “Ọrọ̀” dípò Jèhófà. (Mátíù 6:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa “ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kólósè 3:5) Ó tún sọ pé ní ti àwọn kan, ‘ikùn wọn ni ọlọ́run wọn.’ (Fílípì 3:19) Àní, owó àti dúkìá wà lára àwọn ọlọ́run pàtàkì táwọn èèyàn ń sìn lónìí. Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ—títí kan àwọn kan tó ń pe ara wọn ní olùfọkànsìn—‘gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú.’ (1 Tímótì 6:17) Ọ̀pọ̀ ló ń ṣe iṣẹ́ àṣe-fẹ́ẹ̀ẹ́-kú nídìí sísin àwọn ọlọ́run wọ̀nyí, àwọn kan sì ń rí jẹ nídìí ẹ̀—wọ́n ń gbé ilé mèremère, wọ́n ń gbádùn àwọn nǹkan olówó ńlá, wọ́n sì ń jẹ àwọn oúnjẹ dídọ́ṣọ̀. Àmọ́, kì í ṣe gbogbo wọn náà ló ń jayé bẹ́ẹ̀yẹn. Àwọn tó sì ń jayé ọ̀hún wá ńkọ́, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ṣe ni wọ́n máa ń sọ pé nǹkan wọ̀nyí kò fún àwọn ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Àwọn nǹkan wọ̀nyí kò ṣeé gbára lé, wọn kì í pẹ́ lọ́wọ́ ẹni, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í tẹ́ àwọn àìní tẹ̀mí lọ́rùn.—Mátíù 5:3.
20. Ó yẹ ká wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa kí ni?
20 Òdodo ọ̀rọ̀, ó yẹ ká máa fọgbọ́n lo ìgbésí ayé wa báa ti ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí. Ó yẹ ká máa gbégbèésẹ̀ tó tọ́ láti pèsè nípa tara fún ìdílé wa. Ṣùgbọ́n, báa bá wá ka gbígbé ìgbésí ayé ọlọ́là sóhun bàbàrà, táa ń lépa owó, tàbí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, tí nǹkan wọ̀nyí sì wá gbawájú lọ́wọ́ sísin Ọlọ́run, a jẹ́ pé àwa náà ti jìn sínú ọ̀fìn irú ìbọ̀rìṣà kan, a jẹ́ pé àwa náà kò rìn ní ọ̀nà Jèhófà mọ́. (1 Tímótì 6:9, 10) Àmọ́, ká sọ pé a dojú kọ ìṣòro ìlera, tàbí ti ìnáwó, tàbí àwọn ìṣòro mí-ìn ńkọ́? Ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bí àwọn Júù wọnnì tó wà ní Íjíbítì, àwọn tó sọ pé ìjọsìn Ọlọ́run ló fa ìṣòro àwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fa ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́, èyí tí Áhásì kọ̀ láti ṣe. Fi ìdúróṣinṣin yíjú sí Jèhófà Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà. Fi ìgbẹ́kẹ̀lé tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀, kí o sì máa gbàdúrà fún okun àti ọgbọ́n láti fi kojú ipòkípò tó bá dìde. Lẹ́yìn náà, wá fara balẹ̀ dúró de ìbùkún Jèhófà.
21. Àwọn ìbùkún wo ló ń wọlé dé fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà?
21 Jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn Ísírẹ́lì la rí i pé Jèhófà rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Ọba Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Jèhófà, ṣamọ̀nà mi nínú òdodo rẹ nítorí àwọn ọ̀tá mi.” (Sáàmù 5:8) Jèhófà jẹ́ kí ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká, àwọn tó wá ń fojú Áhásì gbolẹ̀ lẹ́yìn náà. Lábẹ́ Sólómọ́nì, a fi àlàáfíà àti aásìkí bù kún Ísírẹ́lì, irú àwọn ìbùkún táwọn Júù wọnnì tó wà ní Íjíbítì wá ń yán hànhàn fún lẹ́yìn náà. Jèhófà tilẹ̀ jẹ́ kí Hesekáyà, ọmọ Áhásì, ṣẹ́gun Ásíríà abìjàwàrà. (Aísáyà 59:1) Rárá o, ọwọ́ Jèhófà kò kúrú láti gba àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀, àwọn tí kò rìn “ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé dídùn inú wọn wà nínú òfin Ọlọ́run. (Sáàmù 1:1, 2) Lónìí pẹ̀lú, ọwọ́ Jèhófà kò kúrú. Àmọ́ o, báwo wá ni àwa lónìí ṣe lè rí i dájú pé à ń rìn ní ọ̀nà Jèhófà? A óò jíròrò èyí nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Àwọn ànímọ́ wo ló ṣe kókó bí a óò bá máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà?
◻ Èé ṣe tí ìrònú Áhásì fi lòdì?
◻ Kí ló lòdì nínú ìrònú àwọn Júù tó wà ní Íjíbítì?
◻ Báwo la ṣe lè fún ìpinnu wa lókun láti máa rìn nìṣó ní ọ̀nà Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Áhásì yíjú sáwọn ọlọ́run Síríà kàkà tí ì bá fi yíjú sí Jèhófà