ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 6/1 ojú ìwé 20-23
  • Mímú Ìlérí Mi Láti Sin Ọlọ́run Ṣẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mímú Ìlérí Mi Láti Sin Ọlọ́run Ṣẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Tọ́ Mi Dàgbà Ní Lithuania
  • Mímú Ìlérí Mi Ṣẹ
  • Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Ní Ìbẹ̀rẹ̀
  • Ìfòfindè àti Pípadà Fàṣẹ Ọba Múni
  • Dídi Ìgbàgbọ́ Mú Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n
  • Mo Padà Sẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún
  • Bíbójútó Àwọn Ìṣòro
  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́
    Jí!—1998
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • A Jà Fitafita Ká Lè Dúró Gbọin-gbọin Nínú Ìgbàgbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ọlọ́run ni Ibi Ìsádi àti Okun Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 6/1 ojú ìwé 20-23

Mímú Ìlérí Mi Láti Sin Ọlọ́run Ṣẹ

GẸ́GẸ́ BÍ FRANZ GUDLIKIES ṢE SỌ Ọ́

Mẹ́rin péré nínú àwọn sójà ẹlẹgbẹ́ mi táa lé ní ọgọ́rùn-ún ló kù tí kò tí ì kú. Nígbà tí mo ríkú báyìí, mo kúnlẹ̀, mo sì ṣèlérí fún Ọlọ́run pé, ‘Bí mo bá fi lè la ogun yìí já, ìwọ ni màá sìn títí ayé.’

MO ṢE ìlérí yẹn ní ọdún mẹ́rìnléláàádọ́ta sẹ́yìn, ní April 1945, nígbà tí mo jẹ́ sójà nínú ọmọ ogun ilẹ̀ Germany. Ó kù díẹ̀ kí Ogun Àgbáyé Kejì parí nígbà yẹn, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Soviet sì ń gbógun wọn bọ̀ ní Berlin láìfọ̀tápè. Àwọn ọmọ ogun tiwa wà nítòsí ìlú Seelow lójú Odò Oder, ibi tí kò ju kìlómítà márùnlélọ́gọ́ta sí Berlin. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń fi àwọn àgbá ọta ràgàjìràgàjì rọ̀jò ọta lé wa lórí tọ̀sántòru, wọ́n sì ti pa àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ bí rẹ́rẹ.

Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi, mo bú sẹ́kún lọ́jọ́ náà, mo sì gbàdúrà sí Ọlọ́run. Mo rántí ẹsẹ Bíbélì kan tí màmá mi tó bẹ̀rù Ọlọ́run sábà máa ń fà yọ, ẹsẹ náà kà pé: “Pè mí ní ọjọ́ wàhálà. Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀, ìwọ yóò sì máa yìn mí lógo.” (Sáàmù 50:15) Nínú kòtò tí mo wà, tí mo sì ń bẹ̀rù pé ikú ti dé, mo ṣèlérí tó wà lókè yìí fún Ọlọ́run. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún mi láti pa ìlérí náà mọ́? Báwo ni mo sì ṣe di ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Germany?

A Tọ́ Mi Dàgbà Ní Lithuania

Lọ́dún 1918, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, Lithuania polongo pé òun ti gbòmìnira, ó sì dá ètò ìjọba tiwa-n-tiwa sílẹ̀. Ọdún 1925 la bí mi, lágbègbè Memel (Klaipėda), lẹ́bàá Òkun Baltic. Ó ku ọdún kan kí wọ́n bí mi ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àgbègbè náà di ara Lithuania.

Èmi àti àwọn arábìnrin mi márààrún gbádùn ìgbà ọmọdé wa. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni baba mi jẹ́ fún wa, ó sábà máa ń jẹ́ ká jùmọ̀ ṣe nǹkan pọ̀. Àwọn òbí wa jẹ́ mẹ́ńbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ajíhìnrere, àmọ́ wọn kì í lọ ṣèsìn níbẹ̀ o, nítorí àgàbàgebè àlùfáà ibẹ̀ bí Màmá nínú. Síbẹ̀, ó fẹ́ràn Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, tí ó kúndùn àtimáa kà.

Lọ́dún 1939, Germany gba apá Lithuania tí à ń gbé. Nígbà tó yá, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1943, wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ ológun nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Germany. Nínú ọ̀kan lára ogun táa lọ jà, mo fara gbọgbẹ́, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ọgbẹ́ mi san, mo padà sí Ojú Ogun ti Ìlà Oòrùn. Nígbà tí yóò fi di àkókò yìí, ọwọ́ ogun náà ti yí padà, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Germany sì ti ń kógun wọn kúrò níwájú àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Soviet. Ìgbà yẹn ni Ọlọ́run yọ mí, tí ò jẹ́ kí wọ́n pa mí sọnú, gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn mi.

Mímú Ìlérí Mi Ṣẹ

Nígbà ogun, àwọn òbí mi ṣí lọ sí Oschatz, ní Germany, ní gúúsù ìlà oòrùn Leipzig. Ìgbà tí ogun wá rọlẹ̀, àtirí wọn tún wá di ìṣòro. Ayọ̀ ọjọ́ náà mà kọyọyọ o, nígbà táa tún padà wà papọ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín! Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn náà, ní April 1947, mo bá màmá mi lọ síbi àsọyé kan tí Max Schubert, ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ. Màmá gbà pé òun ti rí ẹ̀sìn tòótọ́, lẹ́yìn tó sì ti lọ sípàdé díẹ̀, èmi náà tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Màmá ṣubú lórí àkàsọ̀, ó fara pa, èyí ló sì pa á lẹ́yìn oṣù díẹ̀. Nígbà tó ṣì wà ní ọsibítù kó tó kú, ó fi ìfẹ́ fún mi níṣìírí pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbàdúrà pé ó kéré tán kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ mi rí ọ̀nà Ọlọ́run. Ó dá mi lójú pé àdúrà mi ti gbà, mo sì lè fọwọ́ rọrí kú báyìí.” Mo mà ń fojú sọ́nà fún àkókò náà o, nígbà tí Màmá yóò jí láti inú ipò òkú, tí yóò sì wá mọ̀ pé àdúrà òun gbà!—Jòhánù 5:28.

Ní August 8, 1947, oṣù mẹ́rin péré lẹ́yìn tí mo gbọ́ àsọyé Arákùnrin Schubert, mo ṣèrìbọmi ní àpéjọ kan ní Leipzig láti fi ẹ̀rí hàn pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín mo ń gbégbèésẹ̀ síhà mímú ìlérí tí mo ṣe fún Ọlọ́run ṣẹ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà mo di aṣáájú ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń pe àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Nígbà yẹn, nǹkan bí irínwó [400] aṣáájú ọ̀nà ló ń gbé ní ibi tó wá di Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Ilẹ̀ Germany, tàbí Ìlà Oòrùn Germany lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Ìdánwò Ìgbàgbọ́ Ní Ìbẹ̀rẹ̀

Aládùúgbò mi kan ní Oschatz gbìyànjú láti mú mi wọnú ẹgbẹ́ Àwọn Ọmọlẹ́yìn Marx, ó fi yé mi pé Ìjọba yóò rán mi lọ sí yunifásítì bí mo bá lè di ọmọ ẹgbẹ́ Elétò Àjọni ti Ilẹ̀ Germany (SED). Mo lémi ò fẹ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe lóun ò fẹ́ ohun tí Sátánì fi lọ̀ ọ́.—Mátíù 4:8-10.

Lọ́jọ́ kan ní April 1949, ọlọ́pàá méjì wá síbi iṣẹ́ mi, wọ́n ní kí n tẹ̀ láwọn. Ni wọ́n bá mú mi lọ sí ọ́fíìsì àdúgbò náà tó jẹ́ ti àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ti ilẹ̀ Soviet, níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń ṣiṣẹ́ fún ìjọba olówò bòńbàtà ní Ìwọ̀ Oòrùn. Wọ́n ní kìkì ohun tí mo fi lè fi hàn pé n kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀ ni pé kí n máa bá iṣẹ́ ilé dé ilé tí mò ń ṣe lọ, ṣùgbọ́n kí n wá máa sọ fáwọn nípa ẹnikẹ́ni tó bá sọ̀rọ̀ òdì nípa ilẹ̀ Soviet Union tàbí ẹgbẹ́ SED tàbí kí n jẹ káwọn mọ ẹnikẹ́ni tó bá wá ṣèbẹ̀wò sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí n kò bá wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀, ni wọ́n bá tì mí mọ́lé. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé mi lọ sí kóòtù kan tó jọ tàwọn ológun. Ẹjọ́ tí wọ́n dá mi rèé: Lọ fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún roko ọba ní Siberia, pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára!

N kò gbin, ìyẹn sì wú àwọn ọ̀gá náà lórí. Lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ fún mi pé màá ṣì lọ ṣẹ̀wọ̀n mi, ṣùgbọ́n kí n ṣì máa wá lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ ná títí màá fi ṣe tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn. Níbi tí mo ti ń wá ìmọ̀ràn Àwọn Ẹlẹ́rìí tó dàgbà dénú, mo gbéra, ó di Magdeburg, níbi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society wà. Ìrìn àjò ọ̀hún kò rọrùn o, nítorí àwọn ọlọ́pàá ń ṣọ́ mi lọ́wọ́lẹ́sẹ̀. Ernst Wauer tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin ní Magdeburg, sọ fún mi pé: “Má gba gbẹ̀rẹ́ o, wàá borí wọn. Tóo bá sì juwọ́ sílẹ̀, wọ́n a ṣẹ́gun rẹ. Ohun táa kọ́ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nìyẹn.”a Ìmọ̀ràn yẹn ràn mí lọ́wọ́ láti mú ìlérí mi láti sin Ọlọ́run ṣẹ.

Ìfòfindè àti Pípadà Fàṣẹ Ọba Múni

Ní July 1950, a fọwọ́ sí i pé kí n máa ṣe alábòójútó arìnrìn-àjò. Ṣùgbọ́n, ní August 30, àwọn ọlọ́pàá wá tú ilé wa wò ní Magdeburg, wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa. Nítorí náà a yí iṣẹ́ àyànfúnni mi padà. Èmi àti Paul Hirschberger ní láti ṣiṣẹ́ ní nǹkan bí àádọ́ta ìjọ, a ń lo ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta pẹ̀lú ìjọ kọ̀ọ̀kan, à ń ran àwọn ará lọ́wọ́ láti ṣètò bí wọn yóò ṣe máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lábẹ́ ìfòfindè. Ní àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, ìgbà mẹ́fà ló jẹ́ pé ó kù díẹ̀ kọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ mí!

Ẹnì kan ti yọ́ wọnú ìjọ kan tó sì ti lọ táṣìírí wa fún Stasi, Àjọ Aláàbò Orílẹ̀-Èdè. Nítorí èyí, ní July 1951, àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n gbé ìbọn lọ́wọ́ mú èmi àti Paul lójú pópó. Nígbà táa ronú padà sẹ́yìn, a wá rí i pé a kò gbára lé ètò àjọ Jèhófà tó bó ti yẹ. Àwọn ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin ti sọ fún wa pé ká má máa rìnrìn àjò papọ̀. Dídá ara wa lójú jù ti jẹ́ ká sọ òmìnira wa nù! Ní àfikún sí i, a kò jíròrò rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pé ohun báyìí la óò sọ bí wọ́n bá mú wa.

Èmi nìkan ni mo wà nínú àhámọ́ tí wọ́n fi mí sí, pẹ̀lú omijé lójú, mo bẹ Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ kí n má baà da àwọn arákùnrin mi tàbí kí n fi ìgbàgbọ́ mi báni dọ́rẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn tí oorun gbé mi lọ, ohùn Paul ọ̀rẹ́ mi ló jí mi lójijì. Òkè àhámọ́ tí wọ́n fi mí sí ni yàrá tí àwọn Stasi ti ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò wà. Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ooru mú díẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n ṣí ilẹ̀kùn ọ̀ọ̀dẹ̀ sílẹ̀, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ ló ń ta sí mi létí. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fọ̀rọ̀ wá èmi náà lẹ́nu wò, ohun kan náà tí ọ̀rẹ́ mi sọ lèmi náà sọ, èyí sì ya àwọn ọ̀gá náà lẹ́nu gan-an. Ẹsẹ Bíbélì tí Màmá fẹ́ràn jù lọ ló wá sí mi lọ́kàn, ó sì fún mi níṣìírí gidigidi, “Pè mí ní ọjọ́ wàhálà. Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀.”—Sáàmù 50:15.

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò, èmi àti Paul lo oṣù márùn-ún ní àhámọ́ kí wọ́n tó gbẹ́jọ́ wa, ọgbà ẹ̀wọ̀n Stasi tó wà ní Halle la wà, ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n tó gbé wa lọ sí Magdeburg. Nígbà tí mo wà ní Magdeburg, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan mo máa ń rí ọ́fíìsì wa tí wọ́n ti tì pa lókèèrè. Ṣe ló dà bí ẹni pé kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni mo ti ń ṣiṣẹ́ dípò ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà! Ní February 1952, wọ́n kéde ìdájọ́ wa: “Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá àti fífi ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀ dù wá fún ogún ọdún.”

Dídi Ìgbàgbọ́ Mú Lọ́gbà Ẹ̀wọ̀n

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti rán lẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá ó kéré tán ní àmì kan tí wọ́n máa ń wọ̀ ní àwọn àkókò kan tí wọ́n fi wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n. Wọ́n rán aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ pupa mọ́ ẹsẹ̀ kan ṣòkòtò wọn àti apá kan ẹ̀wù wọn. Bákan náà, wọ́n tún lẹ páálí pélébé pupa kan mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ àtìmọ́lé wa, èyí tó ń kìlọ̀ fáwọn ẹ̀ṣọ́ pé ọ̀daràn paraku ni wá.

Àwọn aláṣẹ gbà pé àwa ni ọ̀daràn tó burú jù lọ. Wọn ò gbà pé ká ní Bíbélì lọ́wọ́ nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣọ́ kan ti ṣàlàyé: “Bí ọ̀daràn tó níbọn lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ní Bíbélì lọ́wọ́.” Láti lè ṣàkójọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀díẹ̀ nínú Bíbélì, a máa ń ka àwọn ìwé òǹkọ̀wé ará Rọ́ṣíà náà, Leo Tolstoy, ẹni tó sábà máa ń fa àwọn ẹsẹ Bíbélì yọ nínú ìwé rẹ̀. A ha àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí sórí.

Kó tó di pé wọ́n fàṣẹ ọba mú mi ní 1951, mo ti ń fẹ́ Elsa Riemer sọ́nà. Ó máa ń bẹ̀ mí wò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n bó bá ti ṣeé ṣe fún un tó, ó sì máa ń fi oúnjẹ ránṣẹ́ sí mi lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ó tún máa ń fi oúnjẹ tẹ̀mí pamọ́ sínú oúnjẹ tó bá fi ránṣẹ́. Nígbà kan, ó di àwọn àpilẹ̀kọ láti inú Ilé Ìṣọ́ kan sínú oúnjẹ tó fi ránṣẹ́. Ó jẹ́ àṣà àwọn ẹ̀ṣọ́ láti tú oúnjẹ wò, kí wọ́n wò ó bóyá nǹkan kan wà táa fi pamọ́ sínú ẹ̀, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣíwọ́ iṣẹ́ ọjọ́ náà kí oúnjẹ yìí tó dé, wọn ò sì yẹ̀ ẹ́ wò.

Nígbà yẹn, èmi àti Karl Heinz Kleber ń gbé nínú àhámọ́ kótópó kan pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta mìíràn tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Báwo la ṣe wá fẹ́ ka Ilé Ìṣọ́ tí wọn ò fi ní rí wa? Ó dáa, a máa ń díbọ́n pé ọ̀tọ̀ nìwé tí à ń kà, ṣùgbọ́n tí a óò fi àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ náà hánú rẹ̀. A tún fi oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣeyebíye yìí ránṣẹ́ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.

Báa ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n a tún lo àǹfààní náà láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Inú mi dùn púpọ̀ láti rí ọ̀kan lára àwọn ta jọ wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí òun náà tipasẹ̀ èyí di onígbàgbọ́.—Mátíù 24:14.

Mo Padà Sẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún

Ní April 1, 1957, lẹ́yìn tí mo ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́fà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n tú mi sílẹ̀. Kò tó ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà, èmi àti Elsa ṣègbéyàwó. Nígbà tí àwọn Stasi gbọ́ pé wọ́n ti tú mi sílẹ̀, wọ́n wá àwíjàre láti lè dá mi padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Kí ìyẹn má bàa ṣeé ṣe, èmi àti Elsa kọjá sí òdìkejì ẹnubodè, a lọ gbé ní Ìwọ̀ Oòrùn Berlin.

Nígbà táa dé Ìwọ̀ Oòrùn Berlin, Society fẹ̀ mọ ohun tí a ń wéwèé láti ṣe. A ṣàlàyé pé ọ̀kan lára wa yóò ṣe aṣáájú ọ̀nà, nígbà tí ẹnì kejì yóò wáṣẹ́ tí yóò máa mówó wọlé.

Wọ́n bi wá léèrè pé: “Bí ẹ̀yin méjèèjì bá di aṣáájú ọ̀nà ńkọ́?”

A dáhùn pé: “Bó bá ṣeé ṣe bẹ́ẹ̀, ojú ẹsẹ̀ la ó bẹ̀rẹ̀.”

Nípa báyìí wọ́n ń fún wa ní iye owó táṣẹ́rẹ́ kan pàtó lóṣooṣù kí a lè fi gbọ́ bùkátà ara wa, a sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe lọ́dún 1958. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti rí àwọn táa ti bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n wá yí ìgbésí ayé wọn padà láti di ìránṣẹ́ Jèhófà! Ọdún mẹ́wàá táa lò tẹ̀ lé e nínú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kọ́ wa láti ṣiṣẹ́ papọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Elsa kì i fi mí sílẹ̀ o, kódà bí mo bá ń tún ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi ṣe, ẹ̀gbẹ́ mi ni yóò dúró sí. A máa ń kàwé papọ̀, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ papọ̀, a sì ń gbàdúrà pọ̀.

Lọ́dún 1969 wọ́n yàn wá sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò, a óò máa bẹ ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lè bójú tó àìní àwọn mẹ́ńbà rẹ̀. Ìmọ̀ràn tí Josef Barth, ọkùnrin kan tó ti nírìírí nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò fún mi nìyí: “Bóo bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ àyànfúnni rẹ, ṣáà ti mú àwọn ará gẹ́gẹ́ bí ẹbí rẹ.” Mo gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn yìí sílò. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, a ní àjọṣe ọlọ́yàyà àti onírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ wa, èyí tó mú kó rọrùn láti gbà wọ́n nímọ̀ràn tí wọ́n nílò.

Lọ́dún 1972, àyẹ̀wò ara fi hàn pé Elsa ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì ń béèrè pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ́ fún un. Kò tún pẹ́ lẹ́yìn náà, ó tún ní àrùn làkúrègbé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrora náà pọ̀, ó ṣì máa ń bá mi lọ láti bẹ àwọn ìjọ wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ó sì máa ń bá àwọn arábìnrin ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ dé ìwọ̀n tí agbára rẹ̀ bá mọ.

Bíbójútó Àwọn Ìṣòro

Lọ́dún 1984, àwọn àna mi nílò ìtọ́jú lójú méjèèjì, nítorí náà a fi iṣẹ́ arìnrìn àjò sílẹ̀ láti lọ bójú tó wọn títí tí wọn fi dolóògbé ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà náà. (1 Tímótì 5:8) Lẹ́yìn ìyẹn, lọ́dún 1989, òjòjò dá Elsa wó gan-an. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé ara rẹ̀ ti yá díẹ̀, ṣùgbọ́n ó di dandan pé èmi ni n óò máa ṣe gbogbo iṣẹ́ ilé. Mo ṣì ń kọ́ bí mo ṣe lè máa hùwà sí ẹnì kan tí ara máa ń ro nígbà gbogbo tí ara kò fi ní ni ín. Síbẹ̀, láìka másùnmáwo àti wàhálà náà sí, ìfẹ́ tí a ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí kò yingin.

Lónìí, a dúpẹ́ pé àwa méjèèjì ṣì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ṣùgbọ́n, a ti wá mọ̀ pé, kì í ṣe ipò táa wà tàbí báa ti lè ṣe tó ló ṣe pàtàkì jù, bí kò ṣe kí a jẹ́ olóòótọ́. A fẹ́ máa sin Ọlọ́run wa, Jèhófà, títí ayérayé, kì í ṣe pé ká sìn ín fún ọdún díẹ̀. Ìrírí wa ti jẹ́ ẹ̀kọ́ àgbàyanu tí yóò wúlò ní ọjọ́ iwájú. Àní nínú àwọn ipò tí ń dánni wò jù lọ pàápàá Jèhófà ti fún wa lókun láti yìn ín lógo.—Fílípì 4:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìtàn ìgbésí ayé Ernst Wauer wà nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 1991, ojú ìwé 25 sí 29.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Inú ọgbà ẹ̀wọ̀n Magdeburg níhìn-ín la fi mí sí

[Credit Line]

Gedenkstätte Moritzplatz Magdeburg für die Opfer politischer Gewalt; Foto: Fredi Fröschki, Magdeburg

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà táa ṣègbéyàwó lọ́dún 1957

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi pẹ̀lú Elsa lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́