ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 5/1 ojú ìwé 24-29
  • Ọlọ́run ni Ibi Ìsádi àti Okun Mi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run ni Ibi Ìsádi àti Okun Mi
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A fún Mi Lókun fún Ọjọ́ Iwájú
  • Ìdáhùn Àwọn Ọ̀tá—Ìfinisẹ́wọ̀n
  • Ní Lichtenburg
  • Ní Ravensbrück
  • Àwọn Ọdún Nínira ti Ẹ̀yìn Ogun
  • A Wà Lábẹ́ Ìfòfindè àti ní Àhámọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I
  • Okun àti Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà
  • Jèhófà Ń Bá A Lọ Láti Jẹ́ Ibi Ìsádi àti Okun Mi
  • Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Àwọn Ìjọba Bóofẹ́bóokọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Iru Ayọ Wo ni Ó Jẹ́ Lati Jokoo Nidii Tabili Jehofa!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Mo Gbọ́kàn Lé Jèhófà Pé Á Bójú Tó Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 5/1 ojú ìwé 24-29

Ọlọ́run ni Ibi Ìsádi àti Okun Mi

GẸ́GẸ́ BÍ CHARLOTTE MÜLLER ṢE SỌ Ọ́

Adájọ́ Kọ́múníìsì náà sọ pé: “Dájúdájú, ọdún mẹ́sàn-án tí o lò lábẹ́ Hitler buyì kún ọ. O lòdì sí ogun ní tòótọ́, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, o lòdì sí ìgbésẹ̀ àlàáfíà tí a ń gbé!”

Ó Ń TỌ́KA sí títì tí àwọn Nazi tì mí mẹ́wọ̀n níṣàájú, àti sí ìjọba àjùmọ̀ní ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Ìjọba Tiwantiwa ti Germany. N kò lè sọ̀rọ̀ lákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó yá, mo fèsì pé: “Kristẹni kì í jà fún àlàáfíà tòótọ́ bí àwọn mìíràn ti ń jà fún un. Mo wulẹ̀ ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò mi ni. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ràn mi lọ́wọ́ láti pa àlàáfíà mọ́ nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe.”

Ní ọjọ́ yẹn, September 4, 1951, àwọn Kọ́múníìsì rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́jọ—ó fi ọdún kan dín sí èyí tí ìjọba Nazi rán mi lọ.

Nígbà tí àwọn Oníjọba Àjùmọ̀ní àti àwọn Kọ́múníìsì ń ṣe inúnibíni sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo rí ìtùnú nínú Orin Dáfídì 46:1 (NW), tí ó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà.” Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ó fún mi ní okun láti fara dà á, bí mo sì ti ń gba Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sínú tó, bẹ́ẹ̀ ni mo ń lágbára sí i.

A fún Mi Lókun fún Ọjọ́ Iwájú

A bí mi ní 1912, ní Gotha-Siebleben, ní Thuringia, Germany. Bí àwọn òbí mi tilẹ̀ jẹ́ Pùròtẹ́sítáǹtì, bàbá mi ń wá òtítọ́ Bíbélì àti ìjọba òdodo kiri. Nígbà tí àwọn òbí mi wo “Photo-Drama of Creation” (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá), inu wọ́n dùn gan-an.a Bàbá ti rí ohun tí ó ń wá kiri—Ìjọba Ọlọ́run.

Bàbá àti Màmá, àti àwa ọmọ mẹ́fà, kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ ní March 2, 1923. A ń gbé ní Chemnitz ní Saxony, a sì dara pọ̀ mọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. (Mẹ́ta lára àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.)

Nínú ìpàdé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a tẹ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti òtítọ́ ṣíṣeyebíye mọ́ mi lọ́kàn, ìwọ̀nyí sì mú ọkàn àyà mi yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, bí mo tilẹ̀ jẹ́ ọmọdé. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ń fún àwa èwe Kristẹni, tí a lé ní 50, ní ìtọ́ni, ní ọjọ́ Sunday, tí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi, Käthe, sì gbà á fún àkókò kan. Konrad Franke ọ̀dọ́, tí ó máa ń ṣètò pé kí a rin ọ̀nà jíjìn, tí ó sì máa ń kọ́ wa lórin, wà nínú àwùjọ wa. Lẹ́yìn náà, láti 1955 sí 1969, Arákùnrin Franke ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ẹ̀ka Watch Tower, ní Germany.

Àwọn ọdún 1920 jẹ́ àkókò onídààmú, àní láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run pàápàá, nígbà míràn. Àwọn kan, tí wọ́n kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba Ilé Ìṣọ́ gẹ́gẹ́ bí ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu,’ lòdì sí ìgbòkègbodò ìwàásù ilé dé ilé. (Mátíù 24:45) Èyí yọrí sí ìpẹ̀yìndà. Ṣùgbọ́n, “oúnjẹ” yìí gan-an ni ó fún wa ní okun ti a nílò gan-an ní àkókò yẹn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn àpilẹ̀kọ kan wà nínú Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) wa, tí ó sọ pé, “Alábùkúnfún Ni Àwọn Aláìṣojo” (1919) àti “Ta Ni Yóò Bọlá fún Jèhófà?” (1926) Mo fẹ́ láti bọlá fún Jèhófà nípasẹ̀ ìgbòkègbodò onígboyà, nítorí náà, mo pín púpọ̀ lára ìwé àti ìwé pélébé tí Arákùnrin Rutherford ṣe kiri.

Ní March 1933, mo ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọdún kan náà yẹn, a fòfin de iṣẹ́ ajíhìnrere wa ní Germany. Nígbà ìrìbọmi mi, a pèsè Ìṣípayá 2:10 fún wa, gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn fún ọjọ́ iwájú, pé: “Má ṣe fòyà àwọn ohun tí ìwọ máa tó jìyà rẹ̀. Wò ó! Èṣù yóò máa bá a nìṣó ní sísọ àwọn kan nínú yín sí ẹ̀wọ̀n kí a lè dán yín wò ní kíkún, kí ẹ̀yin sì lè ní ìpọ́njú fún ọjọ́ mẹ́wàá. Jẹ́ olùṣòtítọ́ àní títí dé ikú, dájúdájú èmi yóò sì fún ọ ní adé ìyè.” Mo ronú jinlẹ̀ dáradára lórí ẹsẹ yìí, ní mímọ̀ dájúdájú pé, àwọn àdánwò lílekoko ń dúró dè mí. Èyí já sí òtítọ́.

Nítorí pé, a kò dásí tọ̀tún tòsì, ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò wa ń fura sí wa. Lẹ́yìn ìdìbò kan, àwọn aṣojú ọmọ ogun Nazi, tí wọ́n wọṣọ ogun, kígbe níwájú ilé wa pé: “Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń gbé níhìn-ín!” Àpilẹ̀kọ náà, “Ẹ Má Ṣe Bẹ̀rù Wọn,” tí ó fara hàn nínú Ilé Ìṣọ́ December 1933, ti ẹ̀dà German, jẹ́ ìṣírí àkànṣe fún mi. Mo fẹ́ láti máa bá a nìṣó gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà olùṣòtítọ́, àní lábẹ́ ipò tí ó burú jù lọ pàápàá.

Ìdáhùn Àwọn Ọ̀tá—Ìfinisẹ́wọ̀n

Ó ṣeé ṣe láti tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lábẹ́lẹ̀ ní Chemnitz títí di ìgbà ìwọ́wé 1935. Lẹ́yìn náà, a ni láti gbé ẹ̀rọ ẹ̀dà ìwé tí a ń lò lọ sí Beierfeld ní àwọn Òkè Ore, níbi tí a ti lò ó láti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde títí di August 1936. Èmi àti Käthe pín àwọn ẹ̀dà kiri fún àwọn arákùnrin tí Bàbá fún wa ní àdírẹ́sì wọn. Gbogbo nǹkan lọ dáradára fún àkókò kan. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó ṣe, àwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ mi tọwọ́ tẹsẹ̀, ní August 1936, wọ́n mú mi ní ilé mi, wọ́n sì fi mí sí àhámọ́, níbi tí mo ti ń dúró de ìgbẹ́jọ́.

Ní February 1937, àwọn arákùnrin 25 àti arábìnrin 2—tí èmi náà wà lára wọn—fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ àkànṣe kan ní Saxony. Wọ́n sọ pé, ètò àjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dojú ìjọba dé. A rán àwọn arákùnrin tí wọ́n tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún. A rán mi lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì.

Dípò kí wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́yìn tí mo parí ọdún méjì mi, àwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú mi. Wọ́n fẹ́ kí n fọwọ́ sí ìwé kan tí ó sọ pé, n kò ní fi taratara jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́. Mo kọ̀ jálẹ̀jálẹ̀, èyí tí ó mú kí inú bí ọlọ́pàá náà gidigidi, ó fò dìde, ó sì kọ ìwé àṣẹ kan pé kí wọ́n fi mi sí àhámọ́. Ìwé àṣẹ náà fara hàn nínú àwòrán. Láìjẹ́ kí n rí àwọn òbí mi, wọ́n mú mi ní kíákíá lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kékeré kan fún àwọn obìnrin, ní Lichtenburg, lórí odò Elbe. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, mo ṣalábàápàdé Käthe. Ó ti wà nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Moringen láti December 1936, ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n ti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn pa, wọ́n kó òun àti ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin mìíràn wá sí Lichtenburg. Wọ́n fi bàbá mi pẹ̀lú sí àhámọ́, n kò sì rí i sójú títí di 1945.

Ní Lichtenburg

Wọn kò yọ̀ǹda fún mi láti dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí obìnrin yòó kù lẹ́sẹ̀ kẹsẹ̀, nítorí tí wọ́n ń fìyà jẹ wọ́n fún ìdí kan. Ní ọ̀kan nínú àwọn gbọ̀ngàn náà, mo kíyè sí àwùjọ ẹlẹ́wọ̀n méjì—àwọn obìnrin tí wọ́n sábà máa ń jókòó sórí tábìlì àti Àwọn Ẹlẹ́rìí, tí wọ́n ní láti jókòó láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ lórí àpótí, tí a kò sì fún wọn ní nǹkan kan jẹ.b

Mo yára tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ èyíkéyìí tí a gbé fún mi, ní ìrètí pé, mo lè ṣalábàápàdé Käthe. Ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Ó ń lọ sí ibi iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì míràn nígbà tí a pà dé ara wa. Nítorí tí inú mi dùn rékọjá, mo gbá a mọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Ṣùgbọ́n, ẹ̀ṣọ́bìnrin tí wọ́n fi ṣọ́ wa fẹjọ́ wa sùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè wá wa lẹ́nu wò, láti ìgbà yẹn lọ, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ pín wa níyà. Ìyẹn ṣòro gidigidi.

N kò lè gbàgbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì míràn tí ó ṣẹlẹ̀ ní Lichtenburg láé. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ kan, gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní láti pé jọ sí àgbàlá láti tẹ́tí sí ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ ìṣèlú Hitler lórí rédíò. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀, níwọ̀n bí ó ti ní ètò ìfọkànsìn orílẹ̀-èdè ẹni nínú. Nítorí náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ dojú rọ́bà omi ìpaná kọ wá, wọ́n ń tú omi láti inú ẹ̀rọ omi dá sí wa lára yàà, wọ́n sì fi ń lé àwa obìnrin tí a kò lè gbèjà ara wa kiri láti àjà kẹrin dé ìsàlẹ̀ nínú àgbàlá. A ní láti dúró níbẹ̀ pẹ̀lú omi tí ń ro lára wa.

Ní ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ míràn, a pàṣẹ fún èmi, Gertrud Oehme, àti Gertel Bürlen láti fi iná mànàmáná ṣe orílé-iṣẹ́ ọ̀gá àgbà lọ́ṣọ̀ọ́, bí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Hitler ti ń sún mọ́lé. A kọ̀, ní jíjá ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ Sátánì láti gbìyànjú láti tàn wa sínú bíba ìwà títọ́ wa jẹ́ nípa jíjuwọ́sílẹ̀ nínú àwọn nǹkan kéékèèké. Láti jẹ wá níyà, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwa arábìnrin ọ̀dọ́ náà ní láti lo ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n kékeré ṣíṣókùnkùn biribiri. Ṣùgbọ́n, Jèhófà dúró tì wá, ó sì fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ibi ìsádi, àní ní irú ibi ìfòyà bẹ́ẹ̀ pàápàá.

Ní Ravensbrück

Ní May 1939, a kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ó wà ní Lichtenburg lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Ravensbrück. Níbẹ̀, a yàn mí láti ṣiṣẹ́ nílé ìfọṣọ, pẹ̀lú àwọn arábìnrin Ẹlẹ́rìí bíi mélòó kan. Kò pẹ́ lẹ́yìn tí ogun bẹ́ sílẹ̀, wọ́n retí pé kí a lọ gba àsíá swastika wá, a sì kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí èyí, wọ́n fi méjì lára wa, èmi àti Mielchen Ernst, sínú ilé tí a ti ń jẹni níyà. Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan lára ìjìyà tí ó burú jù lọ, ó sì túmọ̀ sí pé, a ní láti ṣiṣẹ́ bí ẹní máa kú lójoojúmọ́, àní ní ọjọ́ Sunday pàápàá, láìka bí ojú ọjọ́ ṣe rí sí. Bí ó ṣe máa ń rí, wọn kì í lò ju oṣù mẹ́ta lọ níbẹ̀, ṣùgbọ́n, wọ́n fi wá síbẹ̀ fún ọdún kan gbáko. Láìjẹ́ pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ ni, n kò bá tí là á já.

Ní 1942, ipò àwa ẹlẹ́wọ̀n gbé pẹ́ẹ́lí díẹ̀ sí i lọ́nà kan ṣáá, wọ́n sì yàn mí láti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú ilé fún ìdílé SS kan, tí kò jìnnà sí àgọ́ náà. Ìdílé náà fún mi ní òmìnira dé ìwọ̀n àyè kan. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan tí mo ń kó àwọn ọmọ rìn, mo ṣalábàápàdé Josef Rehwald àti Gottfried Mehlhorn, àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì tí wọ́n ní àmì onígun mẹ́ta elésè àlùkò láyà, tí ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe pàṣípààrọ̀ ìṣírí pẹ̀lú wọn.c

Àwọn Ọdún Nínira ti Ẹ̀yìn Ogun

Nígbà tí àwọn ọmọ ogun onígbèjà sún mọ́ tòsí, ní 1945, ìdílé tí mo ń bá ṣiṣẹ́ sá lọ, mo sì ní láti tẹ̀ lé wọn. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìdílé SS mìíràn, wọ́n jùmọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ arìnrìn-àjò tí ń lọ síhà ìwọ̀ oòrùn.

Àwọn ọjọ́ díẹ̀ tí ó kẹ́yìn nínú ogun náà burú púpọ̀, wọ́n sì kún fún ewu. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a pàdé àwọn jagunjagun ará America, tí wọ́n yọ̀ǹda fún mi láti forúkọ sílẹ̀ ní ìlú kejì, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ti dá sílẹ̀ lómìnira. Àwọn wo ni mo pàdé níbẹ̀? Josef Rehwald àti Gottfried Mehlhorn. Wọ́n ti gbọ́ pé, gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n wá láti àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Sachsenhausen, ti dé Schwerin, lẹ́yìn ìyan-bí-ológun tí ó lè ṣekú pani. Nítorí náà, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta forí lé ìlú yẹn, tí ó jìnnà tó kìlómítà 75. Ẹ wo irú ayọ̀ ńlá tí ó jẹ́ ní Schwerin láti rí gbogbo àwọn arákùnrin olùṣòtítọ́, tí wọ́n la àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ já, títí kan Konrad Franke.

Nígbà tí ó fi máa di December 1945, ipò nǹkan ní orílẹ̀-èdè náà ti sunwọ̀n sí i débi tí ó fi ṣeé ṣe fún mi láti rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ ojú irin. Nítorí náà, mo kọrí sílé! Ṣùgbọ́n, ìrìn àjò náà ní àkókò tí mo fi dùbúlẹ̀ sórí òrùlé ọkọ̀ ojú irin tí mo sì fi dúró nínú ọkọ̀, nínú. Ní Chemnitz, mo mú ọ̀nà mi pọ̀n láti èbúté ọkọ̀ ojú irin dé ibi tí a gbé gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan. Ṣùgbọ́n, kò ku ilé kan ṣoṣo ní ojú pópó tí àwọn ológun Nazi dúró sí ní ìgbà yẹn, tí wọ́n kígbe pé, “Àwọn ọ̀dàlẹ̀ ń gbé níhìn-ín!” Gbogbo àdúgbò náà pátá ni wọ́n ti fi bọ́ǹbù fọ́ túútúú. Ṣùgbọ́n, sí ìdùnnú mí, mo rí Màmá, Bàbá, Käthe, àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi láàyè.

Ipò ọrọ̀ ajé lẹ́yìn ogun ní Germany burú jáì. Síbẹ̀síbẹ̀, ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrú jákèjádò Germany. Watch Tower Society ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti mú wa gbára dì fún ìgbòkègbodò ìwàásù. A bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ pa dà ní Bẹ́tẹ́lì, ní Magdeburg, tí àwọn Nazi ti tì pa tẹ́lẹ̀. Ní ìgbà ìrúwé 1946, a ké sí mi láti wá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, a sì yàn mí sí ilé ìdáná.

A Wà Lábẹ́ Ìfòfindè àti ní Àhámọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Magdeburg wá jẹ́ apá kan àgbègbè yẹn ní Germany, tí ó wá sábẹ́ àkóso àwọn Kọ́múníìsì. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa ní August 31, 1950, wọ́n sì ti Bẹ́tẹ́lì tí ó wà ní Magdeburg pa. Bí iṣẹ́ ìsìn mi ní Bẹ́tẹ́lì, tí ó ti jẹ́ àkókò fún ẹ̀kọ́ oníyebíye, ṣe wá sí òpin nìyẹn. Mo pa dà sí Chemnitz, pẹ̀lú ìpinnu láti di òtítọ́ mú ṣinṣin, kí n sì máa bá a nìṣó láti polongo Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé onídààmú, kódà lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì.

Ní April 1951, mo rìnrìn àjò pẹ̀lú arákùnrin kan lọ sí Berlin, láti lọ gba àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí a pa dà dé, ó yà wá lẹ́nu gan-an láti rí àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tí ó yí ibùdó ọkọ̀ ojú irin ni Chemnitz ká. Ó ṣe kedere pé wọ́n ti ń retí wa, wọ́n sì fàṣẹ ọba mú wa lójú ẹsẹ̀.

Nígbà tí a dé sí ọgbà àhámọ́, níbi tí a ti ń dúró de ìgbẹ́jọ́, ìwé tí ó fi hàn pé, àwọn Nazi ti jù mí sẹ́wọ̀n ọdún mélòó kan, wà lára mi. Lójú ìwòye èyí, àwọn ẹ̀ṣọ́ bọ̀wọ̀ fún mi. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀gábìnrin ẹ̀ṣọ́ sọ pé: “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe ọ̀daràn; ẹ̀wọ̀n kò yẹ yín.”

Ní ọjọ́ kan, ó wá sí inú yàrá ẹ̀wọ̀n mi, tí mo ń gbé pẹ̀lú àwọn arábìnrin méjì míràn, ó sì rọra fi ohun kan pa mọ́ sábẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ibùsùn náà. Kí ni ohun náà? Bíbélì tirẹ̀ fúnra rẹ̀, tí ó yọ̀ǹda fún wa láti lò. Ní ìgbà míràn, ó kàn sí àwọn òbí mi nílé, níwọ̀n bí ilé wọn kò ti jìnnà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó gba àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti oúnjẹ díẹ̀, ó fi wọ́n pa mọ́ sára rẹ̀, ó sì rọra kó gbogbo rẹ̀ wá sínú yàrá ẹ̀wọ̀n mi.

Ohun mìíràn tún wà tí n óò fẹ́ láti pè wá sí ìrántí. Nígbà míràn, ní òwúrọ̀ Sunday, a máa ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run sókè fatafata, tí ó fi jẹ́ pé, àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòó kù fìdùnnú pàtẹ́wọ́ lẹ́yìn orin kọ̀ọ̀kan.

Okun àti Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Jèhófà

Nígbà ìgbẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ ní September 4, 1951, ni adájọ́ sọ ọ̀rọ̀ tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Mo lo àkókò ẹ̀wọ̀n mi ní Waldheim, lẹ́yìn náà ní Halle, àti nígbẹ̀yìngbẹ́yín ní Hoheneck. Ìṣẹ̀lẹ̀ ráńpẹ́ kan tàbí méjì yóò fi bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà hàn, àti bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe fokun fún wa.

Nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Waldheim, gbogbo arábìnrin Ẹlẹ́rìí máa ń pé jọ déédéé sínú gbọ̀ngàn kan, kí a baà lè ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni. Wọn kì í yọ̀ǹda fún wa láti mú ìwé àti kálàmù lọ́wọ́, ṣùgbọ́n, àwọn arábìnrin kan gán àwọn àgékù aṣọ pọ̀, wọ́n sì dọ́gbọ́n kọ àkọlé tí ó ní ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 1953 sára rẹ̀, ìyẹn ni: “Jọ́sìn Jèhófà nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́.”—Orin Dáfídì 29:2, American Standard Version.

Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́bìnrin yọ sí wa láìròtẹ́lẹ̀, ó sì fẹjọ́ wa sùn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Olórí ọgbà ẹ̀wọ̀n wá, ó sì sọ fún àwa arábìnrin méjì láti gbé àkọlé náà sókè. Ó béèrè pé: “Ta ní ṣe èyí? Kí ni èyí túmọ̀ sí?”

Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà fẹ́ jẹ́wọ́, kí ó sì ru ẹ̀bi náà fún wa, ṣùgbọ́n, a sáré sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí ara wa, a sì gbà pé, gbogbo wa pátá ni ó yẹ kí ó ru ẹ̀bi náà. Nítorí náà, a dáhùn pé: “A ṣe é láti fún ìgbàgbọ́ wa lókun.” Wọ́n gba àkọlé náà lọ́wọ́ wa, wọ́n sì jẹ wá níyà nípa fífi ebi pa wá. Ṣùgbọ́n, ní gbogbo ìgbà tí ìjíròrò náà ń lọ lọ́wọ́, àwọn arábìnrin náà gbé e sókè, kí a baà lè tẹ ìṣírí inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà mọ́ ọkàn wa.

Nígbà tí a ti ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn obìnrin ní Waldheim pa, a kó àwọn arábìnrin lọ sí Halle. Níhìn-ín, wọ́n jẹ́ kí a gba àwọn ẹrù tí a fi ránṣẹ́ sí wa, kí sì ni a rán mọ́ bàtà ìwẹ̀ tí bàbá mi fi ránṣẹ́ sí mi? Àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́! Mo ṣì lè rántí àwọn kan tí àkòrí wọ́n sọ pé, “Ifẹ Totọ Wulo Pupọ̀” àti “Eke-Ṣiṣe Ni Muni Padanu Iye.” Àwọn wọ̀nyí àti àwọn àpilẹ̀kọ mìíràn gbádùn mọ́ni ní tòótọ́, nígbà tí a sì fi wọ́n ṣọwọ́ láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹnì kejì, ní ìkọ̀kọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ṣàkọsílẹ̀ fún ara rẹ̀.

Nígbà ìtúlétúnà kan, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ rí àkọsílẹ̀ tí mo ṣe, tí mo fi pa mọ́ sábẹ́ ibùsùn mi. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, ó pè mí wọlé, láti fi ìbéèrè wá mi lẹ́nu wò, ó sì sọ pé, òun dájúdájú fẹ́ mọ ìtumọ̀ àpilẹ̀kọ náà, “Ìfojúsọ́nà Àwọn Olùbẹ̀rù Jèhófà ní 1955.” Òun, tí ó jẹ́ Kọ́múníìsì, ti ṣàníyàn gidigidi nípa ikú aṣáájú wọn, Stalin, ní 1953, ọjọ́ ọ̀la sí ṣókùnkùn biribiri. Fún àwa, ọjọ́ ọ̀la yóò mú kí ipò wa nínú ẹ̀wọ̀n sunwọ̀n sí i, ṣùgbọ́n, èmi kò tí ì mọ̀ nípa ìyẹn. Mo fi ìgbọ́kànlé ṣàlàyé pé, ìfojúsọ́nà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ó dára jù lọ. Èé ṣe? Mo ṣàyọlò láti inú ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ inú àpilẹ̀kọ náà, Orin Dáfídì 112:7 pé: “Òun kì yóò bẹ̀rù ìhìn búburú: ọkàn àyà rẹ̀ ti dè, ó gbẹ́kẹ̀ lè Jèhófà.”—AS.

Jèhófà Ń Bá A Lọ Láti Jẹ́ Ibi Ìsádi àti Okun Mi

Lẹ́yìn àìsàn burúkú kan, a dá mi sílẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọdún méjì kí ọjọ́ mi tó pé, ní March 1957. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Ìlà Oòrùn Germany tún mú nǹkan le fún mi, nítorí àwọn ìgbòkègbodò mi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nítorí náà, ní May 6, 1957, mo lo àǹfààní náà láti sá lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Berlin, mo sì ṣí lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn Germany láti ibẹ̀.

Ọdún bíi mélòó kan kọjá kí n tó jèrè ìlera mi pa dà. Ṣùgbọ́n, títí di ìsinsìnyí, mo ṣì máa ń yán hànhàn lọ́nà jíjọjú fún oúnjẹ tẹ̀mí, ti mo sì máa ń wọ̀nà fún ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tuntun kọ̀ọ̀kan. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ṣàyẹ̀wò ara mi fínnífínní. Ohun tẹ̀mí ha ṣì ń jẹ mí lọ́kàn bí? Mo ha ti mú àwọn ànímọ́ dídára dàgbà bí? Ìjójúlówó ìgbàgbọ́ mi tí a ti dán wò ha ń mú ìyìn àti ọlá wá fún Jèhófà bí? Góńgó mi ni láti ṣe gbogbo ohun tí ó wu Ọlọ́run, kí ó baà lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ ibi ìsádi àti okun mi láéláé.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a “Photo-Drama” (Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò) ní àwòrán tí ń dúró gbagidi àti èyí tí ń mira nínú, àwọn aṣojú Watch Tower Bible and Tract Society ni ó sì máa ń fi hàn káàkiri, bẹ̀rẹ̀ láti 1914.

b Ìwé ìròyìn náà, Trost (Consolation), tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde ní Bern, Switzerland, ní May 1, 1940, ojú ìwé 10, ròyìn pé, ní ìgbà kan, a kò fún àwọn obìnrin Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní Lichtenburg, ní oúnjẹ ọ̀sán fún ọjọ́ 14, nítorí tí wọ́n kọ̀ láti ṣàyẹ́sí tí ń bọlá fúnni, nígbà tí a bá ń kọrin Nazi. Àwọn 300 Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ń bẹ níbẹ̀.

c Ìròyìn nípa Josef Rehwald fara hàn nínú Jí! February 8, 1993, ojú ìwé 20 sí 23.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ọ́fíìsì SS ní Ravensbrück

[Credit Line]

Lókè: Stiftung Brandenburgische Gedenkstätten

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìwé ìrìnnà mi láti ṣiṣẹ́ lẹ́yìn àgọ́ náà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́