Ìtàn Ìgbésí Ayé
Mo Gbọ́kàn Lé Jèhófà Pé Á Bójú Tó Mi
GẸ́GẸ́ BÍ ANNA DENZ TURPIN ṢE SỌ Ọ́
Tẹ̀ríntẹ̀rín ni màmá mi fi sọ fún mi pé: “O ti lè béèrè ‘ÌBÉÈRÈ’ jù!” Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ńṣe ni mo máa ń da ìbéèrè bo àwọn òbí mi ṣáá. Àmọ́ màmá mi àti bàbá mi ò tìtorí pé mo jẹ́ ọmọdé tí mo sì fẹ́ mọ gbogbo nǹkan yìí jágbe mọ́ mi rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n kọ́ mi pé kí n máa ronú dáadáa kí n sì máa fúnra mi ṣe àwọn ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn mi tí wọ́n ti fi Bíbélì kọ́ mu. Àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí wúlò fún mi gan-an ni! Lọ́jọ́ kan, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá, ìjọba Násì kó àwọn òbí mi ọ̀wọ́n kúrò lọ́dọ̀ mi, mi ò sì padà rí wọn mọ́.
ÌLÚ Lörrach ní orílẹ̀-èdè Jámánì nítòsí ẹnubodè orílẹ̀-èdè Switzerland ni bàbá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oskar Denz, àti màmá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Anna Maria gbé. Akíkanjú ni wọ́n nínú ọ̀ràn ìṣèlú nígbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́, àwọn ará ìlú mọ̀ wọ́n dáadáa, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún wọn. Àmọ́ lọ́dún 1922, kété lẹ́yìn táwọn òbí mi ṣègbéyàwó ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú tí wọ́n sì gbájú mọ́ nǹkan míì. Màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tá a máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó gbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run yóò mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé. Kò pẹ́ tí bàbá mi náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ bíi ti màmá mi, àwọn méjèèjì wá ń lọ sí ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, ìwé kan tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn ìwé Duru Ọlọrun ni ẹ̀bùn tí bàbá mi fún màmá mi nígbà Kérésìmesì ọdún yẹn. Wọ́n bí mi ní March 25, 1923, èmi sì lọmọ kan ṣoṣo tí wọ́n bí.
Àwọn nǹkan tí mo máa ń rántí nípa ìdílé wa máa ń wú mi lórí gan-an, irú bá a ṣe jọ máa ń rìn lọ ságbègbè igbó olókè níhà gúúsù ìwọ̀ oòrùn Jámánì nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, àti bí màmá mi ṣe máa ń kọ́ mi láwọn iṣẹ́ ilé! Mo ṣì rántí dáadáa bó ṣe máa ń dúró sí yàrá ìdáná tá a máa kọ́ mi lóúnjẹ sísè. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn òbí mi kọ́ mi bí mo ṣe máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tí màá sì gbẹ́kẹ̀ lé e.
Nǹkan bí ogójì ògbóṣáṣá akéde Ìjọba ló wà nínú ìjọ wa. Tó bá di pé ká wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, kò jẹ́ ìṣòro kankan fáwọn òbí mi. Nítorí pé olóṣèlú ni wọ́n tẹ́lẹ̀, èyí mú kó rọrùn fún wọn láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, àwọn èèyàn náà sì máa ń gbà wọn tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún méje, èmi náà fẹ́ máa wàásù láti ilé dé ilé. Lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ jáde òde ẹ̀rí, ẹni tí mo bá ṣiṣẹ́ kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bíi mélòó kan lé mi lọ́wọ́, ó nawọ́ sí ilé kan, ó sì sọ fún mi pé, “Lọ fún wọn wò, bóyá wọ́n á gbà á.” Ní ọdún 1931, a lọ sí àpéjọ kan táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nílùú Basel, lórílẹ̀-èdè Switzerland. Ibẹ̀ làwọn òbí mi ti ṣèrìbọmi.
A Tinú Pákáǹleke Bọ́ Sọ́wọ́ Àwọn Ìkà
Inú pákáǹleke gidi ni Jámánì wà láyé ìgbà yẹn, ńṣe làwọn olóṣèlú tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ń bára wọn jà kiri ìgboro. Ní òru ọjọ́ kan, igbe táwọn èèyàn ń ké nílé kan tó wà ládùúgbò wa ló jí mi. Àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọn ò tíì pé ọmọ ogún ọdún ló fi àmúga gún ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin pa nítorí pé èrò tí wọ́n ní nípa òṣèlú yàtọ̀ sí tirẹ̀. Ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sáwọn Júù túbọ̀ ń le sí i. Ńṣe ni ọmọbìnrin kan máa ń dá jókòó síbì kan nílé ìwé wa nítorí pé Júù ni. Àánú rẹ̀ máa ń ṣe mi gan-an, láìmọ̀ pé wọn ò ní pẹ́ pa èmi náà tì.
Nígbà tó di January 30, 1933, Adolf Hitler di olórí ìjọba Jámánì. Ibì kan tí kò jìnnà sí gbọ̀ngàn ìlú náà la wà tá a ti ń wo báwọn tó fara mọ́ ìjọba Násì ṣe ń fò sókè sódò tí wọ́n sì ta àsíá Násì sórí gbọ̀ngàn ìlú náà. Inú àwọn olùkọ́ wa nílé ìwé dùn, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wa pé ká máa pariwo “Heil Hitler [Ti Hitler Ni Ìgbàlà]!” Mo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún bàbá mi lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Inú ẹ̀ ò dùn rárá. Ó ní: “Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò dáa. Ọ̀rọ̀ náà ‘Heil’ túmọ̀ sí ìgbàlà. Tá a bá wá ń sọ pé ‘ti Hitler ni ìgbàlà,’ ohun tá à ń sọ ni pé Hitler ló ni ìgbàlà pé kì í ṣe Jèhófà. Mi ò rò pé ìyẹn tọ̀nà o, àmọ́ ìwọ ló máa pinnu ohun tó o máa ṣe.”
Àwọn ọmọ kíláàsì mi bẹ̀rẹ̀ sí í pa mí tì nítorí pé mi ò bá wọn kókìkí Hitler. Àwọn ọmọkùnrin kan tiẹ̀ lù mí nígbà táwọn olùkọ́ wa ń wo ibòmíì. Nígbà tó yá, wọn ò yọ mi lẹ́nu mọ́, àwọn ọ̀rẹ́ mi pàápàá sọ fún mi pé àwọn bàbá àwọn sọ pé àwọn ò gbọ́dọ̀ bá mi ṣeré mọ́, pé èèyàn burúkú ni mí.
Oṣù méjì lẹ́yìn tí ìjọba Násì bẹ̀rẹ̀ ní Jámánì ni wọ́n fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n ní ọ̀tá orílẹ̀-èdè náà ni wá. Ẹgbẹ́ ogun Násì lọ ti Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Magdeburg pa, wọ́n ní a ò gbọ́dọ̀ ṣe ìpàdé kankan. Àmọ́ nítorí pé tòsí ẹnubodè là ń gbé, bàbá mi gbàwé àṣẹ tá a ó fi sọdá lọ sí ìlú Basel, níbi tá a ti wá ń ṣe àwọn ìpàdé ọjọ́ Sunday. Gbogbo ìgbà ló sì máa ń sọ pé ó wu òun káwọn arákùnrin wa tó wà ní Jámánì rí irú oúnjẹ tẹ̀mí bẹ́ẹ̀ gbà kó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìgboyà kojú ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Àwọn Ìrìn Tó Léwu
Lẹ́yìn tí wọ́n ti ẹ̀ka ilé ìṣẹ́ wa tó wà ní Magdeburg pa, ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julius Riffel wá sí Lörrach, ìlú rẹ̀, láti wá ṣètò iṣẹ́ ìwàásù abẹ́lẹ̀ níbẹ̀. Kíá ni bàbá mi sọ pé òun á ràn án lọ́wọ́. Ó pe èmi àti màmá mi jókòó, ó sì sọ fún wa pé òun ti gbà láti máa bá àwọn ará kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá sí Jámánì láti orílẹ̀-èdè Switzerland. Ó ní iṣẹ́ náà lè fẹ̀mí èèyàn sínú ewu o, ìgbàkígbà láwọn ọlọ́pàá sì lè mú òun. Kò fẹ́ ká dara wa láàmú láti bá wọn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà nítorí ó mọ̀ pé ó lè fi ẹ̀mí àwa náà sínú ewu. Àmọ́, ojú ẹsẹ̀ ni màmá mi sọ pé, “Màá bá ẹ lọ.” Àwọn méjèèjì wò mí lójú, èmi náà ní “Màá bá yín lọ o!”
Màmá mi wá rán àpò kékeré kan tí kò tóbi ju Ilé Ìṣọ́ lọ. Á rọra ki ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ bọnú àpò náà láti apá ibi kan tó ṣí sílẹ̀ lára rẹ̀, yóò sì tún rán àpò náà pa. Ó rán àwọn àpò kéékèèké sínú àwọn aṣọ bàbá mi, ó sì ran àpò ìgbànú méjì tí èmi àtòun lè máa kó àwọn ìwé kéékèèké tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí. Gbogbo ìgbà tá a bá ti lọ kó àwọn ìṣúra wọ̀nyí tá a sì padà délé lálàáfíà la máa ń mí kanlẹ̀ tá a sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. A kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà pa mọ́ sí òkè àjà ilé wa.
Lákọ̀ọ́kọ́, ìjọba Násì ò fura sí wa rárá. Wọn ò béèrè nǹkankan lọ́wọ́ wa, wọn ò sì wá yẹ ilé wa wò. Síbẹ̀, a mú nọ́ńbà kan tá a ó máa fi ta àwọn arákùnrin wa lólobó bí wàhálà bá fẹ́ ṣẹlẹ̀, nọ́ńbà náà ni 4711, ó jẹ́ orúkọ ìpara kan tí gbogbo èèyàn mọ̀. Tá a bá ti mọ̀ pé wọ́n lè ko ìṣòro lọ́nà ilé wa, a ó lo nọ́ńbà yẹn láti sọ fún wọn lọ́nà kan ṣáá. Bàbá mi tún sọ fún wọn pé kí wọ́n máa wo àwọn fèrèsé pálọ̀ wa kí wọ́n tó wọlé. Tí fèrèsé apá òsì bá wà ní ṣíṣí sílẹ̀, á jẹ́ pé wàhálà ti ṣẹlẹ̀ nìyẹn, kí wọ́n yáa sá padà.
Lọ́dún 1936 àti 1937, àwọn ọlọ́pàá Gestapo mú ọ̀pọ̀ èèyàn wọ́n sì kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, níbi tí wọ́n ti fojú winá ìwà ìkà tó burú jù lọ láyé yìí. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà nílùú Bern, lórílẹ̀-èdè Switzerland bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ jọ, títí kan èyí tí wọ́n yọ́ mu jáde láwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n wá kó gbogbo wọn pọ̀ wọ́n sì fi ṣe ìwé kan tó tú àṣírí ìwà ìkà ìjọba Násì, èyí tí wọ́n pè ní Kreuzzug gegen das Christentum (Ogun Tí Wọ́n Bá Ẹ̀sìn Kristẹni Jà). Àwa la fẹ̀mí ara wa wewu tá a kó àwọn ìròyìn àṣírí yìí gba ẹnubodè kọjá lọ sí ìlú Basel. Ká ní ìjọba Násì ṣèèṣì ká àwọn ìwé ìròyìn tí òfin ò gbà láyè yẹn mọ́ wa lọ́wọ́ ni, ojú ẹsẹ̀ ni wọn ì bá jù wá sẹ́wọ̀n. Mo sunkún nígbà tí mo kà nípa oró tí wọ́n ń dá àwọn arákùnrin wa. Síbẹ̀, ẹ̀rù ò bà mí. Ọkàn mi balẹ̀ pé Jèhófà àtàwọn òbí mi, tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́ jù lọ, á bójú tó mi.
Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mi nígbà tí mo jáde ilé ìwé tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ akọ̀wé ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta àwọn ohun èlò inú ilé àti ẹ̀yà ara ẹ̀rọ. Ọ̀sán Sátidé tàbí Sunday la lọ máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, nígbà tí bàbá mi ò bá lọ síbi iṣẹ́. Tá a bá fojú bù ú, ọ̀sẹ̀ méjì méjì la máa ń lọ. A máa ń múra bí ẹni tó kàn ń gbafẹ́ jáde, nǹkan bí ọdún mẹ́rin la fi ń lọ tá à ń bọ̀, àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹnubodè náà ò sì dá wa dúró rí bẹ́ẹ̀ ni wọn ò gbìyànjú láti yẹ ara wa wo. Bọ́rọ́ ṣe rí nìyẹn títí di ọjọ́ kan ní February 1938.
Àṣírí Tú!
Mi ò lè gbàgbé bí bàbá mi ṣe bojú jẹ́ nígbà tá a dé ibi tá a ti máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nítòsí ìlú Basel tá a sì rí i pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ló ń dúró dè wá. Nítorí pé àwọn ọlọ́pàá ti mú ìdílé tá a jọ máa ń kó àwọn ìwé náà, ìwé wá pọ̀ rẹpẹtẹ fún wa láti kó. Nígbà tá a dé ẹnubodè, aṣọ́bodè kan fura sí wa, ó ní kí wọ́n yẹ̀ ara wa wò. Bó ṣe rí àwọn ìwé wọ̀nyẹn báyìí ló gbé ìbọn rẹ̀ tì wá lẹ́yìn, ó ní ká nìṣó nídìí àwọn ọkọ̀ ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀. Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń wà wá lọ nínú ọkọ̀ náà, bàbá mi di ọwọ́ mi mú, ó sọ pé: “Má ṣe da àwọn ará ò. Má dárúkọ ẹnikẹ́ni fún wọn o!” Mo sọ fún un pé: “Mi ò ní dárúkọ ẹnikẹ́ni.” Nígbà tá a dé ìlú Lörrach, wọ́n mú bàbá mi ọ̀wọ́n lọ. Ìgbà tí wọ́n fẹ́ ti ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n jù bàbá mi sí ni mo rí i gbẹ̀yìn.
Odindi wákàtí mẹ́rin làwọn ọlọ́pàá Gestapo fi ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi, wọ́n ní kí n sọ orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí àti àdírẹ́sì wọn fáwọn. Nígbà tí mi ò sọ ọ́, inú bí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà, ó wá ń halẹ̀ mọ́ mi, ó sọ pé, “Ọ̀nà mìíràn wa tá a má fi mú ẹ sọ̀rọ̀!” Mi ò dárúkọ ẹnì kankan fún wọn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n mú èmi àti màmá mi wá sílé wa, ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n yẹ ilé wa wò sì nìyẹn. Wọ́n mú màmá mi lọ sí àhámọ́, wọ́n wá mú mi lọ́ sílé ẹ̀gbọ́n ìyá mi obìnrin, wọ́n sì ní kí n máa gbé lọ́dọ̀ rẹ̀, wọn ò mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí lòun náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fún mi láǹfààní àtilọ síbi iṣẹ́, síbẹ̀ mẹ́rin lára àwọn ọlọ́pàá Gestapo máa ń jókòó sínú ọkọ̀ tí wọ́n gbé síwájú ilé náà, wọ́n sì ń ṣọ́ gbogbo bí mo ṣe ń rìn, ọlọ́pàá kan tún máa ń rìn lọ rìn bọ̀ ní ojú ọ̀nà tí mo máa ń gbà.
Ọjọ́ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, lákòókò tá à ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán ni mo jáde síta, bí mo ṣe rí arábìnrin kan tó ń gun kẹ̀kẹ́ bọ̀ lọ́dọ̀ mi nìyẹn. Bó ṣe ń sun mọ́ mi, mo rí i pé ó fẹ́ ju bébà kan sí mi. Bí mo ṣe hán bébà náà ni mo bojú wo ibi táwọn ọlọ́pàá Gestapo náà wà kí n lè mọ̀ bóyá wọ́n rí mi. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìgbà yẹn gan-an ni gbogbo wọn ń rẹ́rìn-ín àríntàkìtì lọ́wọ́!
Ohun tó wà nínú bébà tí arábìnrin náà fún mi ni pé kí n lọ sílé àwọn òbí rẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Àmọ́ pẹ̀lú báwọn ọlọ́pàá Gestapo ṣe ń ṣọ́ mi tọwọ́tẹsẹ̀ yẹn, ọgbọ́n wo ni mo fẹ́ dá tí mi ò fi ní kó bá àwọn òbí rẹ̀? Mo wo àwọn ọlọ́pàá Gestapo mẹ́rin tó wà nínú ọkọ̀, mo tún wo ọlọ́pàá tó ń rìn sókè sódò lójú pópó. Mi ò mọ ohun tí mo máa ṣe, mo wá gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́. Lójijì ni ọlọ́pàá tó wà lójú pópó wá bá àwọn ọlọ́pàá Gestapo tó wà nínú ọkọ̀, ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún wọ́n. Bó ṣe wọnú ọkọ̀ wọn nìyẹn tí gbogbo wọn sì lọ!
Àkókò yẹn ni ẹ̀gbọ́n màmá mi dé tó sì rìn sún mọ́ ibi tí mo wà. Agogo méjìlá ti kọjá lákòókò náà. Ó ka ohun tó wà nínú bébà náà, ó sì sọ pé ká lọ sílé náà lójú ẹsẹ̀, lérò pé ó ṣeé ṣe káwọn ará ti ṣètò láti mú mi lọ sí orílẹ̀-èdè Switzerland. Nígbà tá a débẹ̀, ìdílé náà fi mi han ọkùnrin kan tí mi ò mọ̀ rí, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Heinrich Reiff. Ó sọ fún mi pé inú òun dùn pé mo bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá yẹn àti pé òun wá láti wá ràn mí lọ́wọ́ kí n lè sá lọ sí Switzerland. Ó fún mi ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú kí n wá bá òun nínú igbó kan báyìí.
Bí Nǹkan Ṣe Rí Níbi Tí Wọ́n Mú Mi Lọ
Nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ Arákùnrin Reiff, ńṣe ni omijé ń ṣàn lójú mi, ọkàn mi gbọgbẹ́ nítorí ìrònú àwọn òbí mi tí mo fẹ́ fi sílẹ̀. Gbogbo nǹkan kàn ń ṣẹlẹ̀ léraléra. Lẹ́yìn tá a dúró fúngbà díẹ̀ láìmọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀, a wá dàpọ̀ mọ́ àwọn tó ń rìnrìn àjò, a sì wọ orílẹ̀-èdè Switzerland láìséwu.
Ìgbà tí mo dé ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó wà nílùú Bern ni mo wá rí i pé àwọn ará tó wà níbẹ̀ ló ṣètò bí mo ṣe sá àsálà. Wọ́n fún mi ní ibi tí mo máa gbé. Mo wá ń ṣiṣẹ́ nílé ìdáná, mo sì gbádùn iṣẹ́ náà gan-an. Àmọ́ kò rọrùn láti wà nílẹ̀ òkèèrè o, mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí mi, àwọn méjèèjì ni wọ́n sì ti fi sẹ́wọ̀n ọdún méjì! Ìbànújẹ́ a dorí mi kodò nígbà mìíràn débi pé máa ti ara mi mọ́ balùwẹ̀, máa sì sunkún níbẹ̀. Àmọ́ èmi àtàwọn òbí mi máa ń kọ̀wé síra wa déédéé, wọ́n sì ń fún mi níṣìírí pé kí n má fi Jèhófà sílẹ̀ o.
Nítorí àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àwọn òbí mi tí mo rí, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà mo sì ṣèrìbọmi ní July 25, 1938. Lẹ́yìn tí mo lo ọdún kan ní Bẹ́tẹ́lì, mo wá lọ ń ṣiṣẹ́ ní Chanélaz, ìyẹn ilẹ̀ oko kan tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ Switzerland rà láti máa pèsè oúnjẹ fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì tún máa ń fún àwọn ará tí inúnibíni lé kúrò nílùú wọn nílé níbẹ̀.
Nígbà tí àkókò tí wọ́n dá fáwọn òbí mi láti lò lẹ́wọ̀n pé lọ́dún 1940, ìjọba Násì gbà láti dá wọn sílẹ̀ bí wọ́n bá lè sọ pé àwọn ò sin Jèhófà mọ́. Àmọ́ wọ́n ò ṣe bẹ́ẹ̀, bí wọ́n tún ṣe kó wọn lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nìyẹn, wọ́n mú bàbá mi lọ sí àgọ́ ti Dachau, wọ́n sì mú màmá mi lọ sí ti Ravensbrück. Nígbà òtútù ọdún 1941, màmá mi àtàwọn arábìnrin tí wọ́n jọ wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà kọ̀ láti ṣiṣẹ́ fáwọn ológun. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ wọ́n nìyẹn, wọ́n ní kí wọ́n dúró síta nínú òtútù ní odindi ọjọ́ mẹ́ta àti òru mẹ́ta, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá tì wọ́n mọ́ yàrá kan tó ṣókùnkùn nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, wọn ò sì jẹun kánú fún odindi ogójì ọjọ́. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n tún nà wọ́n. Màmá mi kú ní January 31, 1942, ìyẹn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lẹ́yìn tí wọ́n nà án bí ẹní máa kú.
Wọ́n mú bàbá mi kúrò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Dachau wọ́n sì mú un lọ sí àgọ́ ti Mauthausen ní orílẹ̀-èdè Austria. Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ni ìjọba Násì máa ń pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà nínú àgọ́ yìí, wọ́n á febi pa wọ́n, wọ́n á sì ní kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ bí akúra. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí màmá mi kú, ìjọba Násì lo ọ̀nà mìíràn láti pa bàbá mi. Àwọn dókítà ọgbà ẹ̀wọ̀n náà mọ̀ọ́mọ̀ fi àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ sínú abẹ́rẹ́, wọ́n sì gún àwọn ẹlẹ́wọ̀n lábẹ́rẹ́ ọ̀hún. Nígbà tó yá, wọ́n wá gún ọkàn àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lábẹ́rẹ́ tó ń pa èèyàn díẹ̀díẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sọ pé ‘ọkàn bàbá mi tí kò ṣiṣẹ́ mọ́’ ló fa ikú rẹ̀. Ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì ni nígbà tó kú. Ọ̀pọ̀ oṣù ti kọjá kí n tó gbọ́ nípa ikú oró yìí. Kò sígbà tí mò rántí àwọn òbí mi ọ̀wọ́n tómi kì í bọ́ lójú mi. Àmọ́, mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Jèhófà ò gbàgbé màmá mi àti bàbá mi tí wọ́n ní ìrètí ìyè ti ọ̀run ló tù mi nínú nígbà yẹn lọ́hùn-ún àti nísinsìnyí pẹ̀lú.
Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, mo láǹfààní láti lọ sí kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní New York. Inú mi dùn gan-an láti gba ẹ̀kọ́ tó jinlẹ̀ látinú Ìwé Mímọ́ fún odindi oṣù márùn-ún! Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ́dún 1948, wọ́n ni kí n lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Switzerland. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni mo bá arákùnrin James L. Turpin pàdé, òun náà kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kárùn-ún ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Nígbà tí wọ́n dá ẹ̀ka iléeṣẹ́ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Turkey, òun ni wọ́n fi ṣe alábòójútó ẹ̀ka. A ṣe ìgbéyàwó ní March 1951, kété lẹ́yìn ìgbéyàwó wa loyún dé! Bá a ṣe lọ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà nìyẹn, ibẹ̀ la ti bí Marlene, ọmọ wa obìnrin ní oṣù December ọdún yẹn.
Iṣẹ́ ìsìn Ìjọba tí èmi àti Jim ọkọ mi ti ń ṣe láti ọ̀pọ̀ ọdún ń fún wa láyọ̀ gan-an. Inú mi máa ń dùn tí mo bá ti rántí ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà kan tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Penny lórúkọ rẹ̀, ó máa ń fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣáá ni. Ó ṣèrìbọmi, nígbà tó sì yá, ó fẹ́ Guy Pierce, tó ti wà nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Irú àwọn ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kí ìbànújẹ́ tí ikú àwọn òbí mi fà dín kù.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2004, àwọn arákùnrin tó wà ní Lörrach, ìlú àwọn òbí mi, kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan sí àdúgbò kan tí wọ́n ń pè ní Stich Street. Ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú náà ṣe ohun kan láti fi hàn pé àwọn mọyì ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yìí, wọ́n yí orúkọ àdúgbò náà padà sí Denzstraße (Òpópónà Denz) láti yẹ́ àwọn òbí mi sí. Ìwé ìròyìn Badische Zeitung tó jẹ́ ti ìlú yẹn gbé àkọlé kan jáde tó pè ní, “Orúkọ Òpópónà Tuntun ní Ìrántí Tọkọtaya Denz Tí Wọ́n Pa.” Lábẹ́ àkọlé yìí, ìwé ìròyìn náà sọ pé, “wọn pa [àwọn òbí mi] ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn nígbà Ìjọba Násì.” Mi ò ronú pé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìlú náà lè ṣe ohun tí wọ́n ṣe yìí rárá àmọ́ ìyípadà náà múnú mi dùn.
Bàbá mi sábà máa ń sọ pé ó yẹ ká máa ronú nípa ọjọ́ iwájú bí ẹni pé Amágẹ́dọ́nì ò ní dé nígbà ayé wa, àmọ́ ká máa hùwà bíi pé ọ̀la ló máa dé, ìmọ̀ràn ṣíṣeyebíye tí mo máa ń gbìyànjú láti fi sílò nìyẹn. Kì í sábà rọrùn láti mú sùúrù téèyàn bá ń retí ohun kan, àgàgà nísinsìnyí tí ọjọ́ ogbó ti sọ mí dẹni tí ò lè jáde nílé mọ́. Síbẹ̀ mi ò ṣiyèméjì rí nípa ìlérí tí Jèhófà ṣe fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. . . . Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀RỌ̀ ÀTÀTÀ LÁTINÚ ÀWỌN LẸ́TÀ TỌ́JỌ́ WỌ́N TI PẸ́
Ní àwọn ọdún 1980, obìnrin kan wá sí ìlú Lörrach láti abúlé kan tí kò jìnnà síbẹ̀. Àkókò yẹn làwọn ará ìlú ń kó àwọn ẹrù tí ò wúlò fún wọn mọ́ jáde síta gbangba káwọn ẹlòmíràn le yẹ̀ ẹ́ wò kí wọ́n sì mú ohun tó bá wù wọ́n níbẹ̀. Obìnrin yìí rí àpótí kékeré kan tí wọ́n kó àwọn ohun èlò ìránṣọ sínú rẹ̀ níbẹ̀, ó sì gbé e lọ sílé. Nígbà tó yá, ó rí àwọn fọ́tò ọmọbìnrin kékeré kan nísàlẹ̀ àpótí náà àtàwọn lẹ́tà tí wọ́n fi bébà tórúkọ àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ wà lára rẹ̀ kọ. Àwọn lẹ́tà náà wú obìnrin náà lórí gan-an ó sì fẹ́ mọ ọmọbìnrin kékeré tí wọ́n di irun rẹ̀ yìí.
Lọ́jọ́ kan ní ọdún 2000, obìnrin náà rí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn tó sọ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn nílùú Lörrach. Àpilẹ̀kọ náà sọ ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láwọn ọdún tí ìjọba Násì fi ṣàkóso, ìtàn ìdílé wa sì wà níbẹ̀. Wọ́n fi àwọn fọ́tò tí mo yà nígbà tí mo ṣì wà ní ọ̀dọ́langba síbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà tí obìnrin náà rí i pé àwọn fọ́tò náà jọ àwọn tó wà lọ́wọ́ òun, ó wá ẹni tó gbé ìròyìn náà jáde kàn, ó sì sọ fún un nípa àwọn lẹ́tà náà, méjìlélógójì ni gbogbo wọn. Gbogbo lẹ́tà ọ̀hún tẹ̀ mí lọ́wọ́ ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn àkókò náà. Àwọn lẹ́tà táwọn òbí mi máa ń kọ́ láti béèrè àlàáfíà mi lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n màmá mi ni gbogbo ìgbà ni wọ́n. Gbogbo ìgbà ni wọ́n ń ṣàníyàn nípa mi. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ pé àwọn lẹ́tà wọ̀nyí ò bà jẹ́, mo tún padà rí wọ́n lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Wọ́n fọ́n ìdílé wa tó jẹ́ aláyọ̀ ká nígbà tí Hitler gbàjọba
[Credit Line]
Hitler: Fọ́tò àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
1. Ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà nílùú Magdeburg
2. Àwọn ọlọ́pàá Gestapo kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti Jim rí ayọ̀ ńláǹlà nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà