Iru Ayọ Wo ni Ó Jẹ́ Lati Jokoo Nidii Tabili Jehofa!
Gẹgẹ bi Ernst Wauer ti sọ ọ
Lonii ó rọrun fun mi ni ifiwera lati lọ si ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, lati kekọọ Bibeli, ati lati waasu ihinrere Ijọba naa. Bi o ti wu ki o ri, iyẹn kii ṣe bi o ti ṣe ri nigba gbogbo nihin in ni Germany. Nigba ti Adolf Hitler jẹ apàṣẹwàá, lati 1933 si 1945, lilọwọ ninu iru awọn igbokegbodo Kristẹni bẹẹ mu fifi ẹmi ara ẹni wewu lọwọ.
ỌDUN naa ṣaaju ki Hitler to gba agbara, nigba ti mo jẹ ẹni ọdun 30, mo kọkọ pade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Dresden. Ni January 1935, mo ya ara mi si mimọ fun Jehofa mo si sọ ifẹ mi lati ṣe iribọmi jade. Iṣẹ wa ni a ti fofin dè tẹlẹ ni 1933, nitori naa a beere lọwọ mi pe: “Njẹ iwọ mọ ohun ti ipinnu rẹ tumọ si? Iwọ nfi idile, ilera, iṣẹ, ominira, ati iwalaaye rẹ paapaa sinu ewu!”
Mo dahun pada pe, “Mo ti ṣiro ohun ti yoo ná mi, mo si mura tan lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun ati lati kú fun un.”
Ani ṣaaju baptism mi paapaa, mo ti bẹrẹ sii waasu lati ile de ile. Ni ẹnu ọna kan, mo pade aṣaaju awọn ọ̀dọ́ SS ti o wọ aṣọ iṣẹ (Hitler’s Blackshirts/Elite Guard), ẹni ti o pariwo pe: “Ṣe iwọ ko mọ pe eyi ni a kà leewọ ni? Mo nlọ pe ọlọpaa!”
“Ó lè ṣe bẹẹ. Mo kan nsọrọ nipa Bibeli ni, ko sì sí ofin lodisi iyẹn,” mo rọra fi pẹlẹ fesi pada. Lati ibẹ mo lọ si ẹnu ọna ile ti o tẹle e ẹni ọwọ oniwa bi ọrẹ kan sì pè mi wọle lọgan. Ko si ohun ti o ṣẹlẹ si mi.
Laipẹ a fi abojuto awujọ ikẹkọọ awọn Ẹlẹrii marun un si meje ti wọn npade lọsọọsẹ si ikawọ mi. A kẹkọọ awọn itẹjade Ilé-ìṣọ́nà ti a ti yọ́ mu wọnu Germany lati awọn orilẹ-ede itosi. Nitori naa, laika ifofinde naa sí, a njokoo deedee nidii “tabili Jehofa” ki a baa le fun wa lokun nipa tẹmi.—1 Kọrinti 10:21, NW.
Lila Awọn Adanwo Kọja
Ni 1936, J. F. Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society, bẹ apejọ kan wo ni Lucerne, Switzerland, o sì kesi awọn arakunrin ti wọn wa ni ipo abojuto iṣakoso Ọlọrun ni Germany lati wà nibẹ. Niwọn bi a ti gba awọn iwe aṣẹ lọ si awọn orile-ede miiran lọwọ awọn arakunrin ti awọn ọlọpa sì nṣọ ọpọlọpọ awọn arakunrin kínníkínní, kiki iwọnba diẹ ni o lè lọ. Arakunrin ti nbojuto iṣẹ naa ni Dresden sọ fun mi lati ṣoju fun oun ni Lucerne.
“Ṣugbọn njẹ emi ko ha kere ju ti mo si jẹ alainiriiri bi?” ni mo beere.
O mú un dá mi loju pe, “Ohun ti ó pọndandan nisinsinyi ni jijẹ oloootọ. Iyẹn ni ohun ti o ṣe pataki ju.”
Ni kété lẹhin pipada dé lati Lucerne, a faṣẹ ọba mu mi a si yà mi nipa kuro lọdọ aya mi, Eva, ati awọn ọmọ wa kekere meji. Ni oju ọna mi si orile-iṣẹ awọn ọlọpaa ni Dresden, mo gbiyanju gidigidi lati ranti iwe mimọ kan lati tọ́ mi sọna. Owe 3:5, 6 wá si mi lọkan: “Fi gbogbo aya rẹ gbẹkẹle Oluwa [“Jehofa,” NW]; ma si ṣe tẹ̀ si imọ araarẹ. Mọ̀ ọ́n ni gbogbo ọna rẹ: oun yoo si maa tọ́ ipa ọna rẹ.” Pipe ẹsẹ iwe yii wa sọkan fun mi lokun fun ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò akọkọ. Lẹhin naa a tì mi mọ yara àhámọ́ híhá gádígádí kan, ati fun igba kukuru mo ni imọlara ikọsilẹ mimuna. Ṣugbọn adura onigbona ọkan si Jehofa fi alaafia kun mi.
Ile-ẹjọ naa da mi lẹjọ ẹwọn oṣu 27. A fi mi sinu àhámọ́ adanikanwa fun ọdun kan ni ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀é ni Bautzen. Nigba kan, oloye aṣofin kan ti o ti fẹhinti lẹnu iṣẹ—ti o nṣoju fun ẹlomiran—ṣí ilẹkun yara àhámọ́ mi o si sọ taanutaanu pe: “Mo mọ pe a ko yọnda fun ọ lati ka ohunkohun, ṣugbọn boya iwọ nilo ohun kan ti ko ni mu ọ ronu.” Nipa bẹẹ o fọgbọn kó awọn iwe-irohin idile ogbologboo diẹ fun mi o si wipe: “Emi yoo gbà wọn lalẹ yii.”
Niti tootọ emi ko nilo ohunkohun lati ‘má mu mi ronu.’ Nigba ti mo wa ninu àhámọ́ adanikanwa, mo pe awọn ọrọ Bibeli wa sọkan lati inu iranti mo si ṣakojọ awọn ọrọ iwaasu mo si nsọ wọn jade ketekete. Mo yẹ awọn iwe-irohin naa wò bi wọn ba ni awọn ọrọ Iwe mimọ eyikeyi ninu—mo si ri melookan! Ọkan jẹ Filipi 1:6, (NW) ti o kà ni apakan pe: “Mo ni igbọkanle pe ẹni ti o ti bẹrẹ iṣẹ daradara ninu yin yoo ṣe e de opin.” Mo dupẹ lọwọ Jehofa fun iṣiri yii.
Lẹhin naa a fi mi ranṣẹ si ibudo oṣiṣẹ kan. Lẹhin naa, ni igba iruwe 1939, nigba ti akoko àhámọ́ mi ti fẹrẹẹ dopin, oluṣabojuto ibudo naa beere boya oju-iwoye mi ti yipada. “Mo ni i lọkan lati wà ni aduroṣinṣin ti igbagbọ mi” ni ifesipada mi. Lẹhin naa o fi tó mi leti pe a o gbé mi lọ si ibudo ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen.
Nibẹ wọn gba aṣọ mi, wọn fi omi wẹ mi, wọn fá gbogbo irun ara mi, wọn si fun mi ni aṣọ ẹwọn. Lẹhin naa a fi omi wẹ mi lẹẹkansi, lakooko yii pẹlu aṣọ ni ara—ọna iṣe kan ti awọn SS pe ni “iribọmi.” Lẹhin eyi a fipa mu mi lati duro lode, ti mo ti rẹ latokedelẹ, titi di aṣalẹ.
Ninu awọn ibudo naa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a fi sabẹ iwa ika akanṣe lati ọwọ awọn SS. Ni ọpọlọpọ igba, a nilati duro lori papa ti awọn ọmọ ogun ti ńyan fun aimọye wakati. Nigba miiran ọkan ninu wa yoo mi ìmí ẹdun pe: “Ki yoo ha dara lati rí ounjẹ kan ti o gbadun niti gidi?” Ẹlomiran yoo dahun pe: “Maṣe gbé ọkan rẹ lé iru awọn nǹkan bẹẹ. Ṣa ti ronu iru ọlá ti o jẹ lati gbeja orukọ Jehofa ati Ijọba rẹ.” Ẹlomiran ẹwẹ yoo tun fikun un pe: “Jehofa yoo fun wa lokun!” Ni ọna yii a fun araawa ẹnikinni keji niṣiiri. Nigba miiran mími ori lọna ọrẹ ti to lati wipe: “Mo fẹ lati jẹ aduroṣinṣin; iwọ pẹlu nfẹ!”
Ounjẹ Tẹmi Ninu Ibudo Naa
Awọn kan mu ipo iwaju ninu fifun awọn ará lounjẹ tẹmi, a sì yàn mi lati ran wọn lọwọ. Bibeli Luther nínípọn ni gbogbo ohun ti a ní. Dajudaju, níní in lọwọ ni a kà leewọ. Nitori naa iṣura yii ni a tọju pamọ, ati ninu ọ̀wọ́ iyara àhámọ́ kọọkan kiki arakunrin ti a yan ni o ní anfaani si i fun igba kukuru. Nigba ti ó kan mi, emi yoo rákòrò wọ abẹ bẹẹdi pẹlu ina tọ́ọ̀ṣì àtìbàpò kan ti emi yoo si ka a fun nǹkan bi iṣẹju 15. Mo há iwe mimọ ti emi yoo le jiroro lẹhin naa pẹlu awọn ará ninu ọ̀wọ́ iyara àhámọ́ wa sori. Nipa bayii, ipinkiri ounjẹ tẹmi ni a ṣeto dé iwọn aye kan.
Gbogbo awọn ara ni a fun nisiiri lati beere ounjẹ tẹmi siwaju sii lọwọ Jehofa ninu adura, oun si gbọ awọn adura ẹbẹ wa. Ni igba otutu 1939/40 arakunrin kan ti a ṣẹṣẹ fi sẹwọn dọgbọn lati yọ́ mu iwọnba awọn itẹjade titun Ilé-ìsọ́nà wọnu ibudo naa ninu ẹsẹ onigi rẹ. Eyi dabi iṣẹ iyanu, niwọn bi a ti yẹ gbogbo awọn eniyan wo fínnífínní.
Awọn iwe-irohin wọnyi, ni a mu wa larọọwọto fun awọn arakunrin ti a yàn fun ọjọ kan nigba kan, fun ete idaabobo. Lẹẹkanri, nigba ti a ńkọ́ ile igbọkọsi kan lọwọ, mo ba mọlẹ sinu iho kan mo si nkawe nigba ti arakunrin kan nṣọna lode. Ni akoko miiran mo tẹ́ Ilé-ìṣọ́nà le ori itan mi lakooko “wakati iranṣọ” (ni awọn irọlẹ a maa njokoo ni bárékè wa ni ṣiṣatunṣe awọn ìbọ̀wọ́ ati awọn ohun eelo miiran), nigba ti awọn arakunrin yoo jokoo ni ẹgbẹ kọọkan gẹgẹ bi oluṣọna. Nigba ti oluṣọ SS kan dé, mo yara tọju Ilé-ìṣọ́nà kiakia. Lati gba mi mu iba ti tumọ si opin iwalaaye mi!
Jehofa ran wa lọwọ ni ọna agbayanu lati pa awọn ironu agbeniro ninu awọn ọrọ ẹkọ naa mọ si iranti. Rirẹ lasan saba maa nmu mi sun wọra ni alẹ. Ṣugbọn ni awọn alẹ lẹhin ti mo ba ka Ilé-ìṣọ́nà, emi yoo tají ni ọpọlọpọ igba ti emi yoo si pe awọn ironu naa pada wa sọkan ni kedere. Awọn arakunrin ti a yan ninu ọ̀wọ́ iyara àhámọ́ miiran ni awọn iriri ti o farajọra. Nipa bayii Jehofa nmu agbara iranti wa muna debi pe a lè pin ounjẹ tẹmi kiri. A ṣe eyi nipa lilọ sọdọ arakunrin kọọkan funraarẹ ti a si ngbe e ró.
Olootọ Titi De Oju Iku
Ni September 15, 1939, ẹka oṣiṣẹ tiwa nilati yan pada lọ si ibudo ni akoko ti o yá ju bi o ti maa nri. Ki ni ó ṣẹlẹ? August Dickmann, ọkan lara awọn ọdọ arakunrin wa, ni a o pa ni gbangba. Awọn Nazi ni igbọkanle pe eyi yoo mu un da ọpọlọpọ awọn Ẹlẹrii loju lati kọ igbagbọ wọn silẹ. Lẹhin pipa naa, gbogbo awọn ẹlẹwọn miiran ni a tuka lọ. Ṣugbọn awa Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a nfooro ẹmi wa siwa ati sẹhin lori ilẹ ti awọn ọmọ-ogun ti nyan naa, a gbá wa nípàá a si fi igi lù wá titi di igba ti a ko le rin mọ. A paṣẹ fun wa lati fọwọ si ipolongo kíkọ̀ igbagbọ wa silẹ; bi ko ba ri bẹẹ, awa pẹlu ni a o yinbọn pa.
Ni ọjọ ti o tẹle e, ko si ẹni ti o tii fọwọsiwee. Nitootọ, ẹlẹwọn titun kan, ti o ti fọwọsiwee nigba ti ó dé ti fa ifọwọsi rẹ pada nisinsinyi. Ó yàn lati kú pẹlu awọn arakunrin rẹ ju ki ó fi ibudo ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ silẹ gẹgẹ bi ọdalẹ. Ni awọn oṣu ti o tẹle e a fiya jẹ wa pẹlu iṣẹ aṣekara, ilosi buburu ti nbaa lọ, ati ifounjẹ duni. Iye ti o ju ọgọrun un ninu awọn arakunrin wa kú lakooko igba otutu mimuna ti 1939/40. Wọn pa iwatitọ wọn mọ si Jehofa ati Ijọba rẹ titi de opin gan an.
Lẹhin naa Jehofa pese itura diẹ. Ọpọlọpọ awọn arakunrin ni a tun yàn siṣẹ ninu ibudo titun ti a ṣẹṣẹ dasilẹ, nibi ti wọn ti rí ounjẹ pupọ gba sii. Siwaju sii, iyọnilẹnu naa lọ silẹ bakan ṣaa. Ni igba iruwe 1940, a gbé mi lọ si ibudo ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Neuengamme.
Awọn Ipese Tẹmi ni Neuengamme
Nigba ti mo dé, a jẹ awujọ nǹkan bi 20 Ẹlẹrii, ti ko ni Bibeli tabi awọn itẹjade miiran. Mo gbadura si Jehofa ki o le ran mi lọwọ lati lo awọn ohun ti mo ti kẹkọọ rẹ ni Sachsenhausen lati fun awọn arakunrin mi ni Neuengamme lokun. Gẹgẹ bi igbesẹ akọkọ, mo pe awọn iwe mimọ wá sọkan mo si yàn wọn gẹgẹ bi awọn ẹṣin ọrọ ojoojumọ. Lẹhin naa awọn ipese ni a ṣe fun ipade ninu eyi ti mo ti le ṣalaye awọn koko lati inu awọn ọrọ-ẹkọ Ilé-ìṣọ́ ti mo ti kà ni Sachsenhausen. Nigba ti awọn arakunrin titun dé, wọn rohin awọn ohun ti wọn ti kọ́ lati inu awọn Ilé-ìṣọ́ lọọlọọ.
Ni 1943 iye awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Neuengamme ti pọ tó 70. O wa di ohun ti wọn fẹ́ jù pe ki awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe iṣẹ lẹhin ode ibudo naa, iru gẹgẹ bi pipalẹmọ lẹhin igbogunti lati ofuurufu. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ, o ṣeeṣe fun wa lati yọ́ mu awọn Bibeli, awọn ẹda Ilé-ìṣọ́nà ati diẹ lara awọn iwe ati iwe pẹlẹbẹ Society wa sinu ibudo naa. A tun ri ẹru dídì nipasẹ ifiweranṣẹ gbà, ti o ni iwe ikẹkọọ afikun ati waini pupa ati akara alaiwu ninu fun Iṣe-iranti ọdọọdun. O han gbangba pe Jehofa fọ́ awọn wọnni ti nṣayẹwo awọn ẹru dídì wọnyẹn loju.
Bi o ti jẹ pe a wà gátagàta laaarin bárékè oriṣiriṣi, a dá awọn awujọ Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́ meje silẹ, ọkọọkan pẹlu oludari ati adele kan. Awọn ẹda Ilé-ìṣọ́nà ni a ṣe lọna aṣiiri ninu ọfiisi ọga ologun ibudo naa, nibi ti mo ti nṣiṣẹ fun igba kukuru. Nitori naa, awujọ ikẹkọọ kọọkan gba ó keretan itẹjade pipe perepere kan fun ikẹkọọ ọsọọsẹ wọn. Ko sì sí ipade kan ti a fagile. Ni afikun, ni owurọ kọọkan lori alẹ ti awọn ologun ti nyan, awọn awujọ naa ngba ẹda kan ti ẹsẹ iwe ojoojumọ, papọ pẹlu alaye ti a mujade lati inu Ilé-ìṣọ́nà.
Nigba kan awọn SS ni ọlidé, nitori naa ó ṣeeṣe fun wa lati ṣe apejọpọ alaabọ ọjọ kan ati lati jiroro bi a o ṣe waasu ninu ibudo naa. A pín ibudo naa si awọn ipinlẹ a sì gbiyanju letoleto lati dé ọdọ awọn ẹlẹwọn pẹlu “ihinrere ijọba yii.” (Matiu 24:14) Niwọn bi awọn ẹlẹwọn ti wá lati oniruuru ilẹ orile-ede, a ṣe awọn káàdì ẹ̀rí elede pupọ ti o ṣalaye iṣẹ wa ati Ijọba naa. A waasu titaratitara gan an debi pe awọn ẹlẹwọn oṣelu ráhùn pe: “Nibikibi ti o ba lọ, gbogbo ohun ti iwọ yoo gbọ ni ọrọ nipa Jehofa!” Irohin iṣẹ-isin papa kan ti igbokegbodo wa tilẹ dé ọfiisi ẹka ni Bern, Switzerland paapaa.
Gbogbo nǹkan lọ deedee titi di igba ti Gestapo ṣe iwadii nipa gbogbo awọn ibudo ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni 1944. Ibudo ikẹrusi wa ni Neuengamme ni a ko rí, ṣugbọn awọn ohun diẹ ni a rí lọdọ Karl Schwarzer ati emi. Fun ọjọ mẹta wọn fi ibeere wadii ọrọ lẹnu wa wọn si lù wa. Nigba ti iriri kikoro naa pari, awa mejeeji ni ara wa bó yánnayànna latokedelẹ. Bi o ti wu ki o ri, pẹlu iranlọwọ Jehofa, a yebọ.
Awọn Ibukun Tẹmi ni Ọpọ Yanturu
A dá mi silẹ nipasẹ awọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun Apawọpọjagun ni May 1945. Ni ọjọ keji ti a dá mi silẹ, mo bẹrẹ sii kẹsẹrin lọ pẹlu awujọ kekere awọn arakunrin ati awọn olufifẹhan. O ti rẹ wa, a jokoo lẹba kanga kan ni abule akọkọ ti a dé ti a sì mu omi. Bi mo ti ni imọlara ifọkanbalẹ, mo lọ lati ile de ile pẹlu Bibeli ni abiya mi. Ọdọ obinrin kan ni imọlara aanu gan an lati mọ pe awa Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wà ninu ibudo ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nitori igbagbọ wa. O sare lọ sinu yara idana rẹ, tí ó sì pada wá pẹlu miliiki tutu ati burẹdi ẹlẹran fun awujọ wa.
Lẹhin naa, pẹlu aṣọ ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ wa ti a ṣì wọ̀ sọrun, a polongo ihin-iṣẹ Ijọba la gbogbo abule yẹn já. Ara abule miiran ké si wa wọle fun ounjẹ ọlọlawọ kan. O pese awọn nǹkan ti a ti ṣalaini fun ọpọlọpọ ọdun fun wa. Iru irisi amu ọfun dá tòró wo ni eyi! Sibẹ, a ko wulẹ yara kó ounjẹ naa mì. A gbadura a si jẹun tọwọtọwọ, ni ọna ọmọluwabi kan. Eyi wu awọn onworan naa lori gan an debi pe nigba ti a bẹrẹ ipade lẹhin naa, wọn fetisilẹ si ọrọ asọye Bibeli. Obinrin kan tẹwọgba ihin-iṣẹ naa o si jẹ arabinrin wa tẹmi lonii.
A tẹ siwaju a si ni iriri itọju Jehofa ni ọna agbayanu. Iru imọlara titayọlọla wo ni ó jẹ lati maa baa lọ ni gbigbadun, nisinsinyi ninu ominira, gbogbo ounjẹ tẹmi ti a tẹ jade nipasẹ eto-ajọ Jehofa ati lati ṣajọpin rẹ pẹlu awọn ẹlomiran! Ni awọn ọdun ti o ti tẹle e, igbẹkẹle wa patapata ninu Jehofa ni a ti san ere fun leralera.
Lati 1945 si 1950, mo ni anfaani ṣiṣiṣẹsin ni Bethel ti Magdeburg ati lẹhin naa, titi di 1955, ni ọfiisi Watch Tower Society ni Berlin. Lẹhin naa, mo ṣiṣẹsin gẹgẹ alaboojuto arinrin-ajo titi di 1963 nigba ti aya mi, Hilde ṣọ pe oun ti loyun. (Eva, aya mi akọkọ ti kú laaarin akoko ifisẹwọn mi, mo si tun igbeyawo ṣe ni 1958.) Ọdọmọbinrin wa di Ẹlẹrii onitara lẹhin naa.
Ki ni nipa ti awọn ọmọ ninu igbeyawo mi akọkọ? Lọna ti o ṣeni laanu, ọmọkunrin mi ko fi ifẹ kankan han ninu otitọ. Ṣugbọn ọmọbinrin mi Gisela fifẹ han, o si lọ si ilé-ẹ̀kọ́ ijihin iṣẹ Ọlọrun Gilead ni 1953. Oun nṣiṣẹsin nisinsinyi, papọ pẹlu ọkọ rẹ, ni ọkan lara awọn Gbọngan Apejọ ni Germany. Pẹlu iranlọwọ Jehofa, mo ti le duro ninu iṣẹ-isin aṣaaju-ọna deedee lati 1963 ati lati sin ni ibiti a ti nilo iranlọwọ, lakọọkọ ni Frankfurt ati lẹhin naa ni Tübingen.
Titi di oni yii mo nbaa lọ lati gbadun gbogbo awọn ipese ti eto-ajọ Jehofa ṣe fun agbo ile igbagbọ rẹ. (1 Timoti 3:15) Ni ode oni, o rọrun gan an lati ri ounjẹ tẹmi, ṣugbọn njẹ iwọ ha mọriri rẹ bi? Mo ni igbọkanle pe ọpọ yanturu awọn ibukun Jehofa wà ni ipamọ fun awọn wọnni ti wọn ni igbẹkẹle ninu rẹ, ti wọn wà ni aduroṣinṣin, ti wọn sì njẹun nidii tabili rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26, 27]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
IBUDO ÌṢẸ́NINÍṢẸ̀Ẹ́ SACHSENHAUSEN
A. Awọn bárékè SS
B. Agbala Ipe-orukọ
C. Ilé àhámọ́
D. Ọgba ẹwọn àdádó
E. Ibi ìmúna orí ati ti aṣọ kuro
F. Ibi ifiya iku jẹni
G. Iyẹwu afẹfẹ asenileeemi