“Lati Ile De Ile”
“ATI ni ojoojumọ ninu tẹmpili ati lati ile de ile, wọn nbaa lọ laijuwọsilẹ ni kikọnilẹkọọ ati kikede ihinrere nipa Kristi naa Jesu.” (Iṣe 5:42, NW) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa saba maa nlo ọrọ ẹsẹ iwe yii ati eyi ti o wà ni Iṣe 20:20 lati fẹri ipilẹ Iwe mimọ han fun iṣẹ iwaasu ile de ile wọn. Bi o ti wu ki o ri, ni Germany, awọn alariiwisi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ti pe ọna ti New World Translation gba tumọ awọn ẹsẹ wọnyi nija, ni jijẹwọ pe o ṣi ede Giriiki ipilẹṣẹ tumọ.
Njẹ iru awọn ọrọ bẹẹ ha fẹsẹmulẹ bi? Bẹẹkọ rara. Idi kan niyii, o kere tan awọn olutumọ Bibeli lede German mẹfa miiran tumọ awọn ẹsẹ wọnyi lọna ti o farajọra. Laaarin wọn ni Zürcher Bibel ti a túnṣe ati “New Testaments” (“Majẹmu Titun”) lati ọwọ Rupert Storr, Franz Sigge, ati Jakob Schäfer (ti a túnṣe lati ọwọ N. Adler). Ọpọlọpọ ẹda itumọ Gẹẹsi fohunṣọkan.
Akẹkọọjinlẹ ara German Hans Bruns dá itumọ rẹ, “lati ile de ile,” ni Iṣe 5:42, lare ni wiwipe: “Gẹgẹ bi ọrọ ẹkọ ipilẹṣẹ naa ti wi, o dabi ẹni pe wọn lọ lati ile de ile.” Bẹẹni, katʼ oiʹkon, ọrọ ipilẹṣẹ ninu ọrọ ẹsẹ iwe yii ni a ko lo ni itumọ ọrọ apejuwe kan (“ni ile”) ṣugbọn ni itumọ ipinkiri kan, ti o tumọ lọna olowuuru si “ni ibamu pẹlu ile.” (katʼ oiʹkous, ti o jẹ ọlọrọ isọdi pupọ, tumọ si “ni ibamu pẹlu awọn ile,” gẹgẹ bi a ti ri i ni Iṣe 20:20.) Awọn akẹkọọjinlẹ miiran, iru bi Heinz Schürmann, fẹri otitọ itumọ ipinkiri awọn ọrọ wọnyi han. Horst Balz ati Gerhard Schneider awọn olutẹ iwe kan ti nṣalaye Majẹmu Titun jade, sọ pe ọrọ yii ni a le tumọ si “ile lẹhin ile.” Ọpọlọpọ awọn iṣẹ itọka lede Gẹẹsi tun ṣalaye ẹsẹ yii lọna ti o farajọra.
Lẹẹkan sii, nigba naa, New World Translation ti koju atako awọn alariiwisi naa. Eyi ti o ṣe pataki ju, o ṣe kedere pe ipilẹ ti o lagbara ti o ba Bibeli mu fun iṣẹ-ojiṣẹ ile de ile wà. (Fiwe Matiu 10:11-14; 24:14.) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni anfaani lati ṣafarawe awọn ẹlẹgbẹ wọn ọgọrun un ọdun kìn-ínní ni ọna yii.