Ìrètí Ló Mú Wa Dúró, Ìfẹ́ Ló ń sún Wa Ṣiṣẹ́
“Àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 13:13.
1. Ìkìlọ̀ wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa pé, bí a ò bá kíyè sára, ìgbàgbọ́ wa lè rì bí ọkọ̀ òkun. Ó sọ̀rọ̀ nípa “dídi ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere mú, èyí tí àwọn kan ti sọ́gọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí wọ́n sì ti ní ìrírí rírì ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn.” (1 Tímótì 1:19) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, igi ni wọ́n fi ń kan ọkọ̀ òkun. Bí igi tí wọ́n lò láti fi kan ọkọ̀ náà ti jẹ́ ojúlówó tó àti bí ẹni tó kàn án ṣe mọṣẹ́ tó ni yóò pinnu bóyá ọkọ̀ òkun náà lè la agbami já tàbí kò lè là á já.
2. Èé ṣe tó fi yẹ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa jẹ́ èyí táa kàn tó dúró dáadáa, kí sì ni èyí ń béèrè lọ́wọ́ wa?
2 Ọkọ̀ òkun yìí táa lè pè ní ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa gbọ́dọ̀ léfòó téńté lójú agbami òkun tí ń ru gùdù, èyí tó dúró fún ìran ènìyàn. (Aísáyà 57:20; Ìṣípayá 17:15) Nítorí náà ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkọ̀ táa kàn tó dúró dáadáa, ọwọ́ wa sì ni èyí wà. Nígbà tí “òkun,” ìyẹn ní ayé àwọn Júù àti ti àwọn Róòmù ìgbàanì fẹ́ di ibi tí kò fara rọ mọ́ fún àwọn Kristẹni ìjímìjí, Júúdà kọ̀wé pé: “Olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, bí ẹ ti ń dúró de àánú Olúwa wa Jésù Kristi pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.” (Júúdà 20, 21) Níwọ̀n bí Júúdà tún ti mẹ́nu kan jíjà fún “ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́,” gbólóhùn náà ‘ìgbàgbọ́ mímọ́ jù lọ’ lè tọ́ka sí àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni lápapọ̀, títí kan ìhìn rere ìgbàlà. (Júúdà 3) Kristi ni ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ yẹn. A nílò ìgbàgbọ́ tó lágbára bí a bá fẹ́ rọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́.
Líla Ìjì “Ìbẹ̀rù Ẹ̀ya Ẹ̀sìn” Já
3. Báwo ni àwọn kan ṣe ń lo “ìbẹ̀rù ẹ̀ya ẹ̀sìn”?
3 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti gbọ́ ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ amúnigbọ̀nrìrì nípa ìpara-ẹni lọ́nà tó gadabú, ìpànìyàn, àti báwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn kéékèèké ṣé ń lo àwọn apániláyà láti dá rògbòdìyàn sílẹ̀. Èyí wá jẹ́ ká lóye ìdí tí ọ̀pọ̀ ènìyàn, títí kan àwọn olórí olóṣèlú tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ọkàn, fi ń ṣàníyàn nípa dídáàbò bo àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn eléwu bẹ́ẹ̀, pàápàá jù lọ àwọn èwe. Kò sí àní-àní pé “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí” ló jẹ́ agbátẹrù àwọn ìwà ọ̀daràn tó burú jáì wọ̀nyí, ó sì ti wá tipa bẹ́ẹ̀ dá ohun tí àwọn kan pè ní ìbẹ̀rù ẹ̀ya ẹ̀sìn sílẹ̀, ó sì wá ń fi èyí ta ko àwọn ènìyàn Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:12) Àwọn kan ti lo èyí láti gbé àtakò dìde sí iṣẹ́ wa. Wọ́n ti gbé àwọn ètò kan kalẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n gbé ètò yìí kalẹ̀ bí ẹni pé wọ́n fẹ́ fi dáàbò bo àwọn èèyàn kúrò lọ́wọ́ “àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn eléwu,” àmọ́, wọ́n wá fi àṣìṣe ka àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn wọ̀nyí, wọ́n sì wá ń fọgbọ́n fẹ̀sùn kàn wá. Èyí ti mú kí iṣẹ́ ilé dé ilé ṣòro ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Yúróòpù, ó sì ti mú kí àwọn kan táa ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ dá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró. Èyí sì ti wá kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn kan lára àwọn arákùnrin wa.
4. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí àtakò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa?
4 Ṣùgbọ́n, dípò tí àtakò yóò fi kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa, ńṣe ló yẹ kó túbọ̀ mú ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i pé ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ là ń ṣe. (Mátíù 5:11, 12) A fẹ̀sùn kan àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú pé wọ́n jẹ́ ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn ọlọ̀tẹ̀, wọ́n sì “ń sọ̀rọ̀ lòdì sí” wọn níbi gbogbo. (Ìṣe 24:5; 28:22) Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì Pétérù túbọ̀ mú un dá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lójú nípa kíkọ̀wé pe: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí iná tí ń jó láàárín yín rú yín lójú, èyí tí ń ṣẹlẹ̀ sí yín fún àdánwò, bí ẹni pé ohun àjèjì ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀ níwọ̀n bí ẹ ti jẹ́ alájọpín nínú àwọn ìjìyà Kristi, kí ẹ lè yọ̀, kí ẹ sì ní ayọ̀ púpọ̀ pẹ̀lú nígbà ìṣípayá ògo rẹ̀.” (1 Pétérù 4:12, 13) Bákan náà, mẹ́ńbà kan nínú ẹgbẹ́ olùṣàkóso ti ọ̀rúndún kìíní kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti mọ̀ ní tòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yìí tí a ti dán wò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ìfaradà ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré, kí ẹ lè pé pérépéré, kí ẹ sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun.” (Jákọ́bù 1:2-4) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀fúùfù líle ṣe ń dán bí ọkọ̀ òkun kan ti lágbára tó wò, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àtakò táa lè fi wé ìjì ń fi kùdìẹ̀-kudiẹ èyíkéyìí tó bá wà nínú ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa hàn.
Ìpọ́njú Ń Mú Ìfaradà Wá
5. Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ìgbàgbọ́ wa yóò dúró gbọn-in nígbà ìpọ́njú?
5 Kìkì ìgbà tí àwọn Kristẹni bá la ìpọ́njú táa lè fi wé ìjì já tán nìkan ló tó lè dá wọn lójú pé wọ́n ní ìfaradà àti pé ìgbàgbọ́ wọn fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in. Ìfaradà wa yóò “ṣe iṣẹ́ rẹ̀ pé pérépéré” nínú òkun ìjì tí ń jà lọ́tùn-ún lósì yìí, kìkì bí a bá ‘pé pérépéré, tí a sì yè kooro ní gbogbo ọ̀nà, láìṣe aláìní ohunkóhun,’ títí kan ìgbàgbọ́ tó lágbára. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Lọ́nà gbogbo, a ń dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run, nípa ìfaradà púpọ̀, nípa àwọn ìpọ́njú, nípa àwọn ọ̀ràn àìní, nípa àwọn ìṣòro.”—2 Kọ́ríńtì 6:4.
6. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa “yọ̀ nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú,” báwo sì ni èyí ṣe ń fún ìrètí wa lókun?
6 Ó yẹ kí a ka ìpọ́njú tí a lè fi wé ẹ̀fúùfù líle tí ń bì lù wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan sí àǹfààní táa ní láti fẹ̀rí hàn pé ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa lágbára, ó sì dúró sán-ún. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí, ìrètí náà kì í sì í ṣamọ̀nà sí ìjákulẹ̀.” (Róòmù 5:3-5) Dídúró gbọn-in nígbà táa bá dojú kọ àdánwò ń jẹ́ kí a rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Èyí, ẹ̀wẹ̀, ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Ìdí Tí Ọkọ̀ Àwọn Kan Fi Ń Rì
7. (a) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ti fi hàn, báwo làwọn kan ṣe nírìírí ọkọ̀ rírì nípa tẹ̀mí? (b) Báwo làwọn kan ṣe yapa kúrò nínú òtítọ́ lónìí?
7 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa níní ìrírí “ọkọ̀ rírì,” àwọn kan tí wọ́n ti “sọ́gọ” ẹ̀rí-ọkàn rere wọn “sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,” tí wọ́n sì ti sọ ìgbàgbọ́ wọn nù ló ní lọ́kàn. (1 Tímótì 1:19) Híméníọ́sì àti Alẹkisáńdà tí wọ́n di apẹ̀yìndà wà lára wọn, àwọn tí wọ́n yapa kúrò nínú òtítọ́, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ burúkú. (1 Tímótì 1:20, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW; 2 Tímótì 2:17, 18) Lónìí, àwọn apẹ̀yìndà, tí wọ́n yapa kúrò nínú òtítọ́, ń sọ̀rọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láìdáa, wọ́n sì wá ń tipa báyìí fojú olóore wọn gúngi, ẹni tó ti ń foúnjẹ tẹ̀mí bọ́ wọn. Àwọn kan fara jọ “ẹrú búburú” náà tó ń sọ nínú ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi ń pẹ́.” (Mátíù 24:44-49; 2 Tímótì 4:14, 15) Wọ́n ò gbà pé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí ti sún mọ́lé, wọ́n sì ń ṣe lámèyítọ́ ẹgbẹ́ ẹrú tó wà lójúfò nípa tẹ̀mí fún mímú kí àwọn ènìyàn Jèhófà ní òye ìjẹ́kánjúkánjú náà. (Aísáyà 1:3) Ó ti ṣeé ṣe fún irú àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ láti “dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan de,” wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣokùnfà jíjẹ́ kí ọkọ̀ wọn nípa tẹ̀mí rì.—2 Tímótì 2:18.
8. Báwo làwọn kan ṣe ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn, tàbí tí wọ́n dáhò sí i lábẹ́?
8 Àwọn Kristẹni mìíràn tó ti ṣe ìyàsímímọ́ ti jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn rì nípa sísọ́gọ ẹ̀rí-ọkàn wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀mí lílépa fàájì àṣerégèé ayé yìí àti ìṣekúṣe rẹ̀ kẹ́ ara wọn bàjẹ́. (2 Pétérù 2:20-22) Síbẹ̀, àwọn mìíràn fọwọ́ ara wọn dáhò sábẹ́ ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn nítorí pé lójú ìwòye tiwọn, kò jọ pé ètò àwọn nǹkan tuntun, tó jẹ́ ibi ààbò, ti sún mọ́lé rárá. Nítorí pé wọn kò lè ṣírò àkókò tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan yóò ṣẹ, tí wọ́n sì mú “ọjọ́ Jèhófà” kúrò lọ́kàn wọn, wọ́n pa ìjọsìn tòótọ́ tì. (2 Pétérù 3:10-13; 1 Pétérù 1:9) Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi padà bá ara wọn nínú odò ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, tí ń ru gùdù, tó dúdú bí aró. (Aísáyà 17:12, 13; 57:20) Àwọn kan tí wọ́n ti dẹ́kun dídarapọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ṣì gbà pé ó jẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́. Àmọ́, ó hàn gbangba pé wọn kò ní sùúrù àti ìfaradà tí a nílò láti dúró de ayé tuntun náà tí Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí. Lójú tiwọn, párádísè náà kò tètè dé.
9. Kí ni àwọn Kristẹni díẹ̀ tó ti ṣe ìyàsímímọ́ ń ṣe, kí ló sì yẹ kí àwọn kókó wọ̀nyí sún wa láti gbé yẹ̀ wò?
9 Ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé, ó dà bíi pé díẹ̀ lára àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ti mọ̀ọ́mọ̀ dín agbára ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wọn kù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkọ̀ náà ṣì léfòó lójú agbami, dípò tí wọn ì bá fi máa fi ìgbàgbọ́ kíkún bá ìrìn-àjò wọn nìṣó, wọn ò jẹ́ kí ọkọ̀ wọn rìn, ńṣe ló ń fà lọ tìì. Nítorí ìrètí dídé “Párádísè láìpẹ́,” àwọn kan kò kọ ohun tí yóò ná wọn láti dé ibẹ̀—wọ́n ń lo ìtara nínú iṣẹ́ ìwàásù, wọn kì í sì í pa ìpàdé jẹ, títí kan àwọn àpéjọ, àti àpéjọpọ̀. Àmọ́, wọ́n ti dín ìtara wọn kù báyìí ní ríronú pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an ju bí àwọn ti fọkàn sí lọ, kí ọwọ́ wọn tó tẹ ohun tí wọ́n ń retí. Èyí hàn gbangba nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù wọn tó ń dín kù sí i, pípa ìpàdé jẹ, àti mímọ̀ọ́mọ̀ máà wá sí àwọn apá kan nínú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ tàbí àpéjọpọ̀. Àwọn mìíràn túbọ̀ ń ya àkókò púpọ̀ sọ́tọ̀ fún eré ìnàjú àti ṣíṣe fàájì. Ó yẹ kí àwọn kókó wọ̀nyí sún wa láti ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó yẹ kó máa sún wa gbé ìgbésí ayé wa ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìtara tí a ní nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sinmi lórí ìrètí dídé “Párádísè láìpẹ́”?
Ìrètí Tí A Fi Wé Ìdákọ̀ró
10, 11. Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ìrètí wa wé, èé sì ti ṣe tí ìfiwéra yìí fi bá a mu wẹ́kú?
10 Pọ́ọ̀lù là á mọ́lẹ̀ pé Jèhófà ṣèlérí láti mú ìbùkún wá nípasẹ̀ Ábúráhámù. Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì náà ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run mú ìbúra kan wọ̀ ọ́, pé, nípasẹ̀ ohun àìlèyípadà méjì [ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìbúra rẹ̀], nínú èyí tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́, kí àwa tí a ti sá sí ibi ìsádi lè ní ìṣírí tí ó lágbára láti gbá ìrètí tí a gbé ka iwájú wa mú. Ìrètí yìí ni àwa ní gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró fún ọkàn, ó dájú, ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in.” (Hébérù 6:17-19; Jẹ́nẹ́sísì 22:16-18) Ìrètí tí a gbé ka iwájú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ni ìyè àìleèkú lókè ọ̀run. Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ní ìrètí kíkọyọyọ ti ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 23:43) Láìsí irú ìrètí bẹ́ẹ̀, a kò lè ní ìgbàgbọ́.
11 Ìdákọ̀ró jẹ́ ohun kan táa ṣe nítorí ààbò ọkọ̀, bí kò bá sí ìdákọ̀ró, ọkọ̀ òkun kò ṣeé so mọ́lẹ̀, òun ni kì í sì í jẹ́ kí ọkọ̀ sú lọ. Kò sí atukọ̀ kan tí yóò dábàá kíkúrò ní èbúté láìsí ìdákọ̀ró. Níwọ̀n bí ọkọ̀ ti ri Pọ́ọ̀lù lọ́pọ̀ ìgbà, ìrírí tí jẹ́ kó mọ̀ pé bí kò bá sí ìdákọ̀ró inú ewu ńlá làwọn atukọ̀ wà. (Ìṣe 27:29, 39, 40; 2 Kọ́ríńtì 11:25) Ní ọ̀rúndún kìíní, ọkọ̀ òkun kì í ní ẹ́ńjìnnì tó lè mú kí ọ̀gákọ̀ fọgbọ́n darí rẹ̀ bó ṣe wù ú. Yàtọ̀ sí àwọn ọkọ̀ ogun tí wọ́n ń fi àjẹ̀ wà, afẹ́fẹ́ gan-an ló ń darí ọkọ̀ òkun. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkọ̀ rẹ̀ fẹ́ forí sọ àpáta, ohun kan ṣoṣo tí ọ̀gákọ̀ kan lè ṣe ni kí ó sọ ìdákọ̀ró rẹ̀ sínú òkun, kó sì wá ní sùúrú títí ìjì náà yóò fi rọlẹ̀, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé ìdákọ̀ró náà kò ní yẹ̀ ní ibi tó fi sọlẹ̀ sí nísàlẹ̀ òkun. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi fi ìrètí Kristẹni kan wé ‘ìdákọ̀ró fún ọkàn, tó dájú, tó sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in.’ (Hébérù 6:19) Nígbà tí a bá dojú kọ àtakò táa lè fi wé ìjì líle tàbí tí a bá dojú kọ àdánwò mìíràn, ìrètí àgbàyanu wa dà bí ìdákọ̀ró tó jẹ́ ká dúró gbọn-in gẹ́gẹ́ bí alààyè ọkàn, kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa má bàa sú lọ sí àgbègbè tí kò jìn, níbi tí ọkọ̀ ti lè fàyà gbálẹ̀, ìyẹn ni àárín àwọn oníyèméjì, tàbí ibi tí àwọn àpáta tó lè fọ́ ọkọ̀ yángá wà, ìyẹn ni àwùjọ àwọn apẹ̀yìndà.—Hébérù 2:1; Júúdà 8-13.
12. Báwo la ṣe lè yẹra fún fífà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà?
12 Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Hébérù tó jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè.” (Hébérù 3:12) Nínú ọ̀rọ̀ Gíríìkì, “lílọ kúrò” ní ṣangiliti túmọ̀ sí “láti ta kété” ìyẹn ni láti di apẹ̀yìndà. Àmọ́, a lè yẹra fún irú ọkọ̀ rírì pátápátá bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ àti ìrètí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ mọ́ Jèhófà, kódà nígbà tí a bá dojú kọ àdánwò táa lè fi wé ìjì tó le jù lọ. (Diutarónómì 4:4; 30:19, 20) Ìgbàgbọ́ wa kò ní dà bí ọkọ̀ òkun tí ẹ̀fúùfù, ìyẹn ni ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà, ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún. (Éfésù 4:13, 14) Níwọ̀n bí a sì ti ní ìrètí gẹ́gẹ́ bí ìdákọ̀ró wa, yóò ṣeé ṣe fún wa láti la ìjì ayé yìí já gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà.
Ìfẹ́ àti Ẹ̀mí Mímọ́ Ló Ń Súnni Ṣiṣẹ́
13, 14. (a) Èé ṣe ti ìdákọ̀ró ìrètí wa nìkan kò fi tó? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ agbára tí ń súnni ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà, èé sì ti ṣe?
13 Kristẹni kan kò ní lè dé inú ètò tuntun tó bá jẹ́ pé ìdí kan ṣoṣo tó fi ń sin Jèhófà ni ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé. Bó ti ń rí sí i pé òun kò jẹ́ kí ìdákọ̀ró ìrètí òun yẹ̀, ìyẹn ni ohun tó mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ dúró dáadáa, ó tún ní láti fi agbára ìfẹ́ tí ń súnni ṣiṣẹ́ kún un, kó tún wá fi èyí kún ìgbàgbọ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ kókó yìí nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 13:13.
14 Ó yẹ kó jẹ́ pé ìfẹ́ àtọkànwá táa ní sí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìfìmoorehàn fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kò láfiwé lórí wa, ló ń sún wa láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sìn ín. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ẹni tí kò bá nífẹ̀ẹ́ kò tíì mọ Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòhánù 4:8, 9, 19) Kí a lè fi ìmoore hàn sí Jèhófà, olórí àníyàn wa kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ká ṣáà ti rí ìgbàlà, bí kò ṣe láti rí bí yóò ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, tí yóò sì dá ipò ọba aláṣẹ òdodo rẹ̀ láre.
15. Báwo ní ìfẹ́ wa fún Jèhófà ṣe kan ọ̀rọ̀ ipò ọba aláṣẹ rẹ̀?
15 Jèhófà fẹ́ kí a sin òun nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ òun, kì í ṣe tìtorí Párádísè nìkan. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Bíbélì náà, Insight on the Scriptures,a sọ pé: “Ohun tí ń mú Jèhófà ṣògo ni òtítọ́ náà pé, ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ àti ìtìlẹ́yìn tí àwọn ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀ fún un jẹ́ tìtorí ìdí pàtàkì náà pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó fẹ́ kìkì àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ nítorí àwọn ànímọ́ dídára tí òun ní àti nítorí pé ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ jẹ́ òdodo, àwọn tí wọ́n fẹ́ràn ipò ọba aláṣẹ tirẹ̀ ju èyíkéyìí mìíràn lọ. (1Kọ 2:9) Wọ́n yàn láti sìn lábẹ́ ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ ju kí wọ́n wà lómìnira ara wọn lọ—èyí jẹ́ nítorí ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa òun alára àti ìfẹ́ rẹ̀, ìdájọ́ òdodo rẹ̀, àti ọgbọ́n rẹ̀, tí wọ́n gbà pé ó ga ré kọjá tiwọn. (Sm 84:10, 11)”—Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 275.
16. Báwo ni ìfẹ́ fún Jésù ṣe jẹ́ agbára tí ń súnni ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa?
16 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ hàn sí Jésù láti fi ìmoore hàn sí ìfẹ́ tó ní sí wa. Pọ́ọ̀lù ronú jinlẹ̀ pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nítorí èyí ni ohun tí àwa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; nítorí bẹ́ẹ̀, gbogbo wọ́n ti kú; ó sì kú fún gbogbo wọn kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn, tí a sì gbé dìde.” (2 Kọ́ríńtì 5:14, 15) Kristi ni ìpìlẹ̀ náà gan-an lórí èyí tí a kọ́ ìgbésí ayé tẹ̀mí wa, ìgbàgbọ́ wa, àti ìrètí wa lé. Ìfẹ́ wa fún Kristi Jésù ń fún ìrètí wa lókun, ó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, pàápàá ní àwọn àkókò tí ìjì líle táa lè fi wé àdánwò bá ń jà.—1 Kọ́ríńtì 3:11; Kólósè 1:23; 2:6, 7.
17. Agbára ńláǹlà wo ni Jèhófà pèsè fún wa, báwo la sì ṣe fi ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ hàn nínú Ìṣe 1:8 àti Éfésù 3:16?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run àti fún Ọmọ rẹ̀ ni olórí agbára tó ń sún wa ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, Jèhófà tún pèsè nǹkan mìíràn tí ń sún wa ṣiṣẹ́, tó ń fún wa lágbára, tó sì ń fún wa lókun láti máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ipá ìṣiṣẹ́ tàbí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ni. Ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “ẹ̀mí” ń tọ́ka sí ọ̀nà lílágbára tí afẹ́fẹ́ gbà ń fẹ́, irú bí ẹ̀fúùfù. Àwọn ọkọ̀ òkun bí irú èyí tí Pọ́ọ̀lù wọ̀ gbára lé agbára tí kò ṣeé fojú rí tó wà nínú ẹ̀fúùfù láti dé ibi tí wọ́n ń lọ. Bákan náà, a nílò ìfẹ́ àti agbára ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run tí a kò lè fojú rí, bí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa yóò bá gbé wa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—Ìṣe 1:8; Éfésù 3:16.
Ẹ Jẹ́ Kí Á Forí Lé Ibi Tí A Ń Lọ!
18. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìdánwò èyíkéyìí tó bá dé bá ìgbàgbọ́ wa lọ́jọ́ iwájú?
18 A ṣì lè dán ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wa wò dé góńgó kí a tó dé inú ètò tuntun àwọn nǹkan. Àmọ́, Jèhófà ti pèsè ìdákọ̀ró kan fún wa ‘tó dájú tó sì dúró gbọn-in’—ìyẹn ni àgbàyanu ìrètí wa. (Hébérù 6:19; Róòmù 15:4, 13) Nígbà tí a bá dojú kọ onírúurú àtakò tàbí àdánwò mìíràn, a lè fara dà á bó bá jẹ́ pé ìrètí táa ní ti mú wa dúró gbọn-in. Lẹ́yìn tí ìjì kan bá lọọlẹ̀, tí òmíràn kò sì tí ì dé, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti mú kí ìrètí wa lágbára, kí a sí fún ìgbàgbọ́ wa lókun.
19. Báwo la ṣe lè mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa máa bá ìrìn àjò rẹ̀ nìṣó, kí ó sì dé èbúté ààbò ayé tuntun Ọlọ́run?
19 Kí Pọ́ọ̀lù tó mẹ́nu kan “ìdákọ̀ró ọkàn,” ó sọ pé: “A fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi akitiyan kan náà hàn [“tara ṣàṣà,” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW] kí ẹ lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìrètí náà títí dé òpin, kí ẹ má bàa di onílọ̀ọ́ra, ṣùgbọ́n kí ẹ jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:11, 12) Pẹ̀lú ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún Ọmọ rẹ̀ tí ń sún wa ṣiṣẹ́ àti ẹ̀mí mímọ́ tí ń fún wa lágbára, ẹ jẹ́ kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa máa bá ìrìn àjò rẹ̀ nìṣó títí a óò fi dé èbúté ààbò ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tí Watch Tower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Ìkìlọ̀ wo ní Pọ́ọ̀lù fún wa lórí ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ wa?
◻ Báwo ni àwọn kan ṣe nírìírí ọkọ̀ rírì nípa tẹ̀mí, báwo sì ni àwọn mìíràn ṣe ń dẹwọ́?
◻ Kí ni àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí a gbọ́dọ̀ fi kún ìgbàgbọ́ wa?
◻ Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dé èbúté ààbò ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
A gbọ́dọ̀ kan ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa kó dúró dáadáa kí ó lè dojú kọ àwọn ìjì ìgbésí ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa lè rì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìrètí jẹ́ ìdákọ̀ró fún ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni