Ǹjẹ́ Ẹnikẹ́ni Tiẹ̀ Bìkítà?
“Omijé àwọn tí a ń ni lára” ń ṣàn bí àgbàrá òjò. Àwọn táa ti fi “ìwà ìninilára” tí kò lóǹkà ṣe lọ́ṣẹ́, tí wọ́n wà káàkiri àgbáyé, ló ń da omijé lójú yìí. Lọ́pọ̀ ìgbà làwọn táa ti fìyà jẹ wọ̀nyí ti rò pé àwọn “kò ní olùtùnú”—pé kò tiẹ̀ sẹ́nikẹ́ni tó bìkítà nípa wọn rárá.—Oníwàásù 4:1.
BÍ OMIJÉ tó ń ṣàn bí àgbàrá òjò yìí sì ti pọ̀ tó, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ìyà tí ń jẹ àwọn ènìyàn bíi tiwọn kò tu irun eléépìnnì lára wọn. Wọ́n ṣe bí ẹni pé àwọn ò mọ̀ pé ìyà ń jẹ àwọn ẹlòmí-ìn, wọ́n fìwà jọ àlùfáà àti ọmọ Léfì inú àkàwé Jésù Kristi tó sọ nípa ọkùnrin kan táwọn jàǹdùkú lù lálùbolẹ̀, tí wọ́n gbowó ọwọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ lápaàpatán lẹ́bàá ọ̀nà. (Lúùkù 10:30-32) Níwọ̀n ìgbà tí nǹkan bá ṣáà ti ń dán fáwọn àtàwọn ẹbí wọn, wọn ò bìkítà mọ́ nípa ohun tó lè máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ẹlòmí-ìn. Ní ṣàkó, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé, “Kí ló kàn mí ńbẹ̀?”
Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ pé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ní ní “ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1, 3) Ẹnì kan tí ń wòye ayé dárò nípa ìwà àìbìkítà tó gbòde kan. Ó wí pé: “Àwọn èèyàn ti fi ìlànà tuntun, ìlànà jíjẹ́ anìkànjọpọ́n, rọ́pò ìgbàgbọ́ àti àṣà àtayébáyé ti àwọn ará Ireland, èyí tó jẹ́ bíbìkítà nípa ẹni àti jíjẹ́ ọ̀làwọ́.” Jákèjádò ayé, ìjàdù bí yóò ṣe dáa fóníkálùkù ni ẹnì kọ̀ọ̀kan ń dù, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó bìkítà mọ́ nípa ìyà tí ń jẹ àwọn ẹlòmíràn.
À Ń Fẹ́ Ẹnì Kan Tó Bìkítà
Kò sí àní-àní pé à ń fẹ́ ẹnì kan tó bìkítà. Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọkùnrin kan tó ń dá gbé ní ilẹ̀ Jámánì, wọ́n “bá a níbi tó jókòó sí níwájú tẹlifíṣọ̀n rẹ̀—ìyẹn lẹ́yìn ọdún márùn-ún tó ti kú nígbà Kérésìmesì.” Kò sẹ́ni tó mọ̀ pé “ọkùnrin tí aya rẹ̀ ti kọ̀ sílẹ̀, tó tún jẹ́ abirùn tó ń dá gbé,” tí ayé ti sú yìí, ti kú, àfìgbà tí owó àpò báǹkì tí wọ́n fi ń san owó ilé rẹ̀ tán pátápátá. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tó bìkítà nípa ọkùnrin yìí rárá.
Bákan náà, ronú nípa àwọn tí wọn kò lólùgbèjà, tí àwọn oníwọra alákòóso, àwọn tágbára ń bẹ lọ́wọ́ wọn, ti fọwọ́ ọlá gbá lójú. Ní àgbègbè kan, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́wàá ènìyàn [200,000] (ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn olùgbé àgbègbè náà) “ni ìtẹnilóríba àti ìyàn lù pa” lẹ́yìn táa ti fi agbára gba ilẹ̀ wọn mọ́ wọn lọ́wọ́. O sì tún lè ronú nípa àwọn ọmọdé táa jẹ́ kí wọ́n fojú rí ìwà ìkà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé gbà gbọ́. Ìròyìn kan sọ pé: “Ní [ilẹ̀ kan] iye àwọn ọmọdé tí wọ́n fojú rí oríṣiríṣi ìwà ìkà burúkú—bí ìpànìyàn, líluni bíi kíkú bíi yíyè, ìfipábánilòpọ̀, èyí táwọn ọ̀dọ́langba mìíràn ń hù, bani lẹ́rù gidigidi.” Ìwọ náà lè wá lóye ìdí tí ẹni tó fojú rí irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ fi lè fi tomijé-tomijé béèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tiẹ̀ bìkítà nípa mi?”
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìròyìn àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ, bílíọ̀nù kan àti mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ènìyàn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lágbàáyé, ló jẹ́ pé owó tí ń wọlé fún wọn lójúmọ́ láti fi gbọ́ bùkátà kò tó dọ́là kan ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú á máa kọminú bóyá ẹnì kankan tiẹ̀ bìkítà nípa wọn. Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn The Irish Times sọ pé, bákan náà ni ọ̀ràn náà rí lọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùwá-ibi-ìsádi, àwọn “tí wọ́n dojú kọ ìpinnu tí kò bára dé, ìyẹn ni pé, ṣé kí wọ́n máa gbé inú àgọ́ jẹ́gẹjẹ̀gẹ nìṣó ni àbí kí wọ́n wà ní orílẹ̀-èdè táwọn ara ibẹ̀ kò fẹ́ràn àlejò àbí kí wọ́n tilẹ̀ gbìyànjú láti padà sí ìlú wọn tí [ogun tàbí ìyapa ẹ̀yà ti tú ká] tàbí tí nǹkan wọ̀nyí ṣì ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.” Ìròyìn kan náà fi àpèjúwe tí ń dótùútù pani yìí kún un, tó sọ pé: “Dijú rẹ ná, ka ení, èjì, ẹ̀ta, ọmọ kékeré kan ti kú. Ìyẹn jẹ́ ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ọmọdé [35,000] tí yóò kú lónìí nítorí àìjẹunrekánú tàbí tí àrùn tó ṣeé wò gbẹ̀mí wọn.” Abájọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń ké nínú wàhálà ẹ̀mí àti ìkorò ọkàn!—Fi wé Jóòbù 7:11.
Ṣé báa ṣe fẹ́ kí gbogbo nǹkan rí nìyí? Ká sọ̀rọ̀ síbi ọ̀rọ̀ wà, ǹjẹ́ ẹnì kan wà tí kì í kàn ṣe pé ó bìkítà nìkan, ṣùgbọ́n, tó tún ní agbára láti fòpin sí ìyà tí ń jẹ àwọn èèyàn, tó sì lè mú gbogbo ìdààmú wọn kúrò pátápátá?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Àwòràn tó wà níwájú àti lẹ́yìn ìwé: Reuters/Nikola Solic/Archive Photos
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
A. Boulat/Sipa Press