ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 10/1 ojú ìwé 16-17
  • Ó Ṣèrànwọ́ Láti Tan Ìmọ́lẹ̀ “Dé Ìkángun Ilẹ̀ Ayé”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ṣèrànwọ́ Láti Tan Ìmọ́lẹ̀ “Dé Ìkángun Ilẹ̀ Ayé”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òṣùṣù Ọwọ̀ ni Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Jèhófà Kí Ẹ Sì Kún fún Ìdùnnú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jèhófà Máa Ń Fa Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Wá Sínú Òtítọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Kí Ló Ń Kó Ẹ Lọ́kàn Sókè?
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 10/1 ojú ìwé 16-17

Ó Ṣèrànwọ́ Láti Tan Ìmọ́lẹ̀ “Dé Ìkángun Ilẹ̀ Ayé”

A LO àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí “dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” Ohun tó yọrí sí ni pe, ọ̀pọ̀ àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun di onígbàgbọ́.”—Ìṣe 13:47, 48; Aísáyà 49:6.

Bákan náà ni ìfẹ́ láti tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí káàkiri ṣe hàn gbangba nínú ìgbésí ayé olùfọkànsìn àti Kristẹni alákitiyan náà, William Lloyd Barry, ẹni tó jẹ́ ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Barry kú ní July 2, 1999, níbi tó ti ń bá àwùjọ sọ̀rọ̀ ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ní Hawaii.

A bí Lloyd Barry ní New Zealand ní December 20, 1916. Ṣáájú ìgbà yẹn làwọn òbí rẹ̀ ti nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí òtítọ́ Bíbélì táwọn ìwé C. T. Russell, ń gbé jáde, èyí tí Watch Tower Bible and Tract Society ń ṣonígbọ̀wọ́ ẹ̀. Nítorí náà, inú agboolé Kristẹni olùfọkànsìn ni Arákùnrin Barry dàgbà sí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ràn eré ìdárayá àti ẹ̀kọ́ ìwé gan-an, débi pé ó gboyè nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, síbẹ̀ Arákùnrin Barry pọkàn rẹ̀ pọ̀ pátápátá sórí àwọn nǹkan tẹ̀mí. Ìdí rèé, tó fi wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní January 1, 1939, tó sì di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ọ́fíìsì Society tó wà ní Ọsirélíà. Lẹ́yìn tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ Society ní 1941, iṣẹ́ ọ́fíìsì ní Arákùnrin Barry gbájú mọ́, nígbà mí-ìn, Society máa ń ní kó báwọn kọ àpilẹ̀kọ tó lè fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níṣìírí. Ó sì tún máa ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìta gbangba.

Ní February 1942, Arákùnrin Barry gbé ìránṣẹ́ alákòókò kíkún níyàwó. Melba, aya rẹ̀ onífẹ̀ẹ́, ti fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, káàkiri ọ̀pọ̀ àgbègbè ayé. Láti lè sìn ní ilẹ̀ òkèèrè, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì nípa lílọ sí kíláàsì kọkànlá ti Watchtower Bible School of Gilead ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ibi táa rán wọn lọ gan-an ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè pè ní “ìkángun ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ni Japan. Lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀ ní November 1949, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní ìlú Kobe, tó ní èbútékọ̀. Nígbà yẹn, ẹni méjìlá péré ló ń wàásù ìhìn rere ní Japan. Arákùnrin Barry kọ́ èdè àti àṣà àwọn ará ìlú rẹ̀ tuntun yìí, ó sì wá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará Japan gan-an, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e ni wọ́n fi sìn pa pọ̀. Ìfẹ́ tó ní fún àwọn “tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” hàn gbangba sí ẹgbẹ́ ará Kristẹni tó ń pọ̀ sí i ní Japan, èyí ló ràn án lọ́wọ́ láti túbọ̀ jáfáfá nínú bíbójútó ẹ̀ka náà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún.

Láàárín ọdún 1975, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Japan ti tó ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000], a gbé Barry àti aya rẹ̀ lọ sí Brooklyn, New York. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ẹni àmì òróró, ńṣe la pe Arákùnrin Barry pé kó wá sìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Róòmù 8:16, 17) Ìrírí tó ti ní nínú ìwé kíkọ wúlò dáadáa nínú iṣẹ́ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ fún un ní Ẹ̀ka Ìkọ̀wé. Ìrírí rẹpẹtẹ tó sì ti ní ní ẹ̀ka ọ́fíìsì mú kó tóótun láti kó ipa tó jọjú gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde lábẹ́ ìdarí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso.

Jálẹ̀ gbogbo ọdún wọ̀nyí, ìfẹ́ tí Arákùnrin Barry ní fún Ìlà Oòrùn ayé àti àwọn èèyàn rẹ̀ kò dín kù rárá. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead àti àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì kò jẹ́ gbàgbé pé, kò sí bó ṣe lè sàsọyé tàbí kó sọ̀rọ̀ tó tí ò ní mẹ́nu kan àwọn ìtàn tó ń múni lọ́kàn yọ̀ nípa àwọn tí wọ́n ti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà ní “ìkángun ilẹ̀ ayé” wá túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí Arákùnrin Barry fìtara sọ ìrírí ara rẹ̀. Díẹ̀ lára wọn wà nínú ìtàn ara rẹ̀ tó jáde nínú Ile-Iṣọ Na September 15, 1960 (Gẹ̀ẹ́sì).

Ó dá wa lójú pé gẹ́gẹ́ bí “ajogún pẹ̀lú Kristi” ìfẹ́ tí Arákùnrin Barry ní fún àwọn “tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” kò ní dín kù, yóò máa pọ̀ sí i ni. Àmọ́ ṣá o, gbogbo àwọn tó mọ̀ ọ́n, tí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tẹ̀mí, tó fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ fún Jèhófà, tó sì ní ìfẹ́ ọlọ́yàyà fáwọn èèyàn Ọlọ́run, ni ikú rẹ̀ yóò dùn. Síbẹ̀, a láyọ̀ pé Arákùnrin Barry di ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú títí tó fi parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 2:10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Lloyd Barry àti John Barr nígbà tí ìwé “Insight on the Scriptures” jáde lọ́dún 1988

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlá ti Gilead, nígbà tí wọ́n pàdé ní Japan lẹ́yìn ogójì ọdún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́