Múra De Ẹgbẹ̀rúndún Tó Ṣe Pàtàkì!
ẸGBẸ̀RÚN Ọdún Ìjọba Kristi yóò mú ìbùkún yàbùgà-yabuga wá fún ìran ènìyàn. Lábẹ́ ìdarí tí Jésù yóò fìfẹ́ ṣe, a ó gbé aráyé kúrò nínú ipò tí ń múni sorí kọ́ tó wà yìí, wọn yóò bọ́ sí ipò ológo pípé. Ronú nípa ohun tí ìyẹn yóò túmọ̀ sí fún ọ. Ìlera tó jí pépé! Tiẹ̀ rò ó wò ná, pé bóo ti ń jí láràárọ̀, lara rẹ̀ ń le ju tàná lọ. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé ló ń wọ̀nà fún gbígbé nínú àkókò aláyọ̀ yẹn. Wọ́n fọkàn sí i, wọ́n sì ń kúnlẹ̀ àdúrà nítorí rẹ̀. Ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì ti jẹ́ kó dá wọn lójú pé àwọn ìbùkún wọ̀nyí lè jẹ́ tiwọn.
Àmọ́, kó tó di pé Jésù Kristi bẹ̀rẹ̀ Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀, ó gbọ́dọ̀ rí i pé gbogbo àwọn ọ̀tá ìjọba rẹ̀ di ẹni àwátì lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà ogun táa pè ní, Amágẹ́dọ́nì, nínú Bíbélì ni yóò ṣe èyí. (Ìṣípayá 16:16) Àwọn ojúlówó Kristẹni tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé kò ní lọ́wọ́ nínú ogun náà o. Ogun Ọlọ́run ni. Kì í sì í ṣe apá ibì kan logun náà yóò ti jà. Bíbélì sọ pé yóò jà dé apá ibi tó jìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo àwọn ọ̀tá ìjọba Kristi la ó pa. Kò síkan nínú wọn tí yóò yè bọ́!—Jeremáyà 25:33.
Ẹ̀yìn èyí ni Jésù yóò wá yíjú sí Sátánì Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. Fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ẹni tó kọ ìwé Ìṣípayá náà ti rí i: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan [Jésù Kristi] tí ń sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá pẹ̀lú kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ àti ẹ̀wọ̀n ńlá ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá dírágónì náà mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí í ṣe Èṣù àti Sátánì, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣípayá 20:1, 2) Lẹ́yìn náà la ó wá pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run pátápátá.—Mátíù 25:41.
“Ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà,” yóò la Amágẹ́dọ́nì já. (Ìṣípayá 7:9) Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń darí àgùntàn rẹ̀ síbi tí omi tó lè ṣe ẹ̀mí lóore wà, Kristi yóò darí àwọn wọ̀nyí sí “àwọn ìsun omi iye,” kó lè ṣe wọ́n láǹfààní. (Ìṣípayá 7:17) Níwọ̀n bí kò ti ṣeé ṣe fún Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ láti dín ìtẹ̀síwájú wọn lọ́wọ́, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a ó ran àwọn wọ̀nyí tó la Amágẹ́dọ́nì já lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun tí ń sún wọn dẹ́ṣẹ̀ títí wọn ó fi dé ìjẹ́pípé níkẹyìn!
Lábẹ́ ìṣàkóso tí Kristi yóò fìfẹ́ ṣe, ìgbésí ayé yóò sunwọ̀n sí i. Nípasẹ̀ Jésù Kristi, Jèhófà Ọlọ́run yóò mú gbogbo ohun tí ń fa ìrora àti ìbànújẹ́ kúrò pátápátá. Òun “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:4) Wòlíì Aísáyà rí ìran náà délẹ̀délẹ̀, nípa sísọ pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 35:5, 6) Àwọn òkú, “ẹni ńlá àti ẹni kékeré,” yóò padà wà láàyè, wọn yóò sì ní ìrètí pé, àwọn ò ní kú mọ́ láéláé!—Ìṣípayá 20:12.
Àní a ti ń kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò la Amágẹ́dọ́nì ja jọ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. Wọ́n ti ń múra sílẹ̀ de Ìjọba Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi. Bó ti lẹ̀ jẹ́ pé, wọn ò mọ ìgbà tí ìjọba náà yóò bẹ̀rẹ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé nígbà tó bá tákòókò lójú Ọlọ́run, yóò bẹ̀rẹ̀. O lè wà lára wọn, àmọ́, ìwọ náà gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀—kì í ṣe pé kóo kó gbogbo dúkìá rẹ tà, kóo wá kó lọ síbì kan o, ṣùgbọ́n ohun tí wàá ṣe ni pé, wàá gba ìmọ̀ pípéye ti Jèhófà Ọlọ́run àti àwọn ète rẹ̀ sínú nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láìsan kọ́bọ̀, tóò sì ni ṣe wàhálà kankan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi tayọ̀tayọ̀ fi hàn ọ́, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè ṣe ìwọ àti ìdílé rẹ̀ láǹfààní. Inú àwọn tó ń ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde yóò dùn láti fún ọ ní ìsọfúnni síwájú sí i.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Ẹgbẹ̀rún Ọdún Náà—Ṣé Ọdún Gidi Ni Àbí Ti Ìṣàpẹẹrẹ?
Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé èdè ìṣàpẹẹrẹ la fi kọ̀ apá tó pọ̀ jù lọ nínú ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì, ìbéèrè kan wáyé. Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi táa mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá ńkọ́? Ṣé ọdún gidi ni àbí ti ìṣàpẹẹrẹ?
Ẹ̀rí gbogbo ló fi hàn pé ẹgbẹ̀rún ọdún gidi la ní lọ́kàn. Rò ó wò ná: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi, nígbà tí a ó ṣèdájọ́ aráyé, ní ọjọ́ kan. (Ìṣe 17:31; Ìṣípayá 20:4) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé ẹgbẹ̀rún ọdún lọ́dọ̀ Jèhófà dà bí ọjọ́ kan (ìyẹn ní wákàtí mẹ́rìnlélógún). (2 Pétérù 3:8) Ìyẹn jẹ́ ká rí i kedere pé “ọjọ́” ìdájọ́ yìí jẹ́ ẹgbẹ̀rún ọdún gidi ní gígùn. Ní àfikún sí i, nínú Ìṣípayá 20:3, 5-7, ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a kà nípa “ẹgbẹ̀rún ọdún náà,” kì í ṣe nípa “ẹgbẹ̀rún ọdún” lásán. Láìsí àní-àní, àkókò kan pàtó lèyí ń sọ.