ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 11/1 ojú ìwé 28-29
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkí Àsíá, Dídìbò àti Sísin Ìlú Ẹni
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Lọ́wọ́ sí Ìṣèlú?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • “Wọn Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣe Ìpinnu Tó Mọ́gbọ́n Dání?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 11/1 ojú ìwé 28-29

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ojú wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo ìdìbò?

Àwọn ìlànà tó ṣe kedere tí ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ojú ìwòye títọ́ lórí ọ̀ràn yìí ní a là lẹ́sẹẹsẹ nínú Bíbélì. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé kò sí ìlànà tó lòdì sí àṣà ìdìbò fúnra rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, kò sí ìdí ti ìgbìmọ̀ olùdarí kan kò fi lè dìbò láti dé orí àwọn ìpinnu tó kan ilé iṣẹ́ wọn. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń dìbò nípa nínawọ́ sókè láti ṣe àwọn ìpinnu tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àkókò ìpàdé àti bí wọn ó ṣe lo owó ìjọ.

Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ìdìbò tó jẹ́ ti ìṣèlú ńkọ́? Ká sọ tòótọ́, ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ń gbé ní àwọn ilẹ̀ kan tó jẹ́ ti òṣèlú ni kì í jáde láti dìbò ní ọjọ́ ìdìbò. Ní ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn kì í yọjúràn sí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn láti dìbò; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sọ̀rọ̀ lòdì sí yíyan àwọn olóṣèlú. Wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ táa yàn sípò nínú irú ìdìbò bẹ́ẹ̀ wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. (Róòmù 13:1-7) Ní ti bóyá àwọn fúnra wọ́n lè dìbò yan ẹnì kan tó gbé àpótí ìbò, ìyẹn kù sọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìpinnu tí ó gbé karí ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí a ti fi Bíbélì kọ́ àti bó ṣe lóye ojúṣe rẹ̀ sí Ọlọ́run àti sí Orílẹ̀-Èdè rẹ̀ tó. (Mátíù 22:21; 1 Pétérù 3:16) Àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń gbé àwọn nǹkan bíi mélòó kan yẹ̀ wò kí wọ́n tó ṣe irú ìpinnu yìí.

Èkíní, Jésù Kristi sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pe: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:14) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìlànà yìí rárá. Nítorí pé wọn “kì í ṣe apá kan ayé,” wọn jẹ́ aláìdásí-tọ̀tún-tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú ayé.—Jòhánù 18:36.

Èkejì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí ara rẹ̀ bí “ikọ̀” tó ń ṣojú Kristi láti bá àwọn ènìyàn tó wà nígbà ayé rẹ̀ sọ̀rọ̀. (Éfésù 6:20; 2 Kọ́ríńtì 5:20) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé Jésù Kristi ni a gbe gorí ìtẹ́ bí Ọba Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run nísinsìnyí, nígbà tó sì jẹ́ pé bí ikọ̀ làwọn náà rí, wọ́n gbọ́dọ̀ kéde èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14; Ìṣípayá 11:15) Ó yẹ kí àwọn ikọ̀ jẹ́ aláìdásí-tọ̀tún-tòsì, kí wọ́n má sì dá sí àwọn àlámọ̀rí tó jẹ́ ti àwọn orílẹ̀-èdè tí a rán wọn sí. Gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé ó di dandan fún àwọn náà láti má ṣe dá sí ọ̀ràn ìṣèlú orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé.

Kókó kẹta láti gbé yẹ̀ wò ni pé àwọn tó lọ́wọ́ nínú dídìbò yan ẹnì kan sípò lè di ẹni tí yóò dáhùn fún àwọn ohun tó bá ṣe. (Fi wé 1 Tímótì 5:22, The New English Bible.) Àwọn Kristẹni ní láti ronú dáradára bóyá wọ́n fẹ́ láti gbé ẹrù yẹn.

Ẹ̀kẹrin, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọrírì ìṣọ̀kan Kristẹni wọn gan-an ni. (Kólósè 3:14) Bí ìsìn bá sì ti ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú, ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni kí àwọn mẹ́ńbà wọn pínyà. Ní fífarawé Jésù Kristi, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹra fún lílọ́wọ́ nínú ìṣèlú, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìṣọ̀kan Kristẹni wọn máa bá a nìṣó.—Mátíù 12:25; Jòhánù 6:15; 18:36, 37.

Ìkarùn-ún tó kẹ́yìn gbogbo rẹ̀ ni pé, bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣe dá sí ọ̀ràn ìṣèlú mú kí wọ́n ní òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ láti bá gbogbo àwọn tó wà ní ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí sọ̀rọ̀ nípa ìhìn iṣẹ́ pàtàkì ti Ìjọba náà.—Hébérù 10:35.

Lójú ìwòye àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí a là lẹ́sẹẹsẹ lókè yìí, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ti dá pinnu láti má ṣe lọ́wọ́ nínú ìdìbò ti ìṣèlú, òfin orílẹ̀-èdè sì ti òmìnira tí wọ́n ní láti ṣe ìpinnu yẹn lẹ́yìn. Bí òfin bá wá sọ pé kí àwọn aráàlú dìbò ńkọ́? Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, ó kù sọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan láti ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu tó sì bá Bíbélì mu nípa bí yóò ṣe yanjú ọ̀ràn náà. Bí ẹnì kan bá pinnu láti lọ síbi tí wọ́n ti ń dìbò, ìpinnu tirẹ̀ nìyẹn. Ohun tó ṣe nínú àtíbàbà ìdìbò wà láàárín òun àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀.

Ile Iṣọ ti November 15, 1950, ojú ewé 445 àti 446, (Gẹ̀ẹ́sì) sọ pé: “Níbi tí Késárì bá ti sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn aráàlú láti dìbò . . . [àwọn Ẹlẹ́rìí] lè lọ síbi tí wọ́n ti ń dìbò kí wọ́n sì wọnú àtíbàbà ìdìbò lọ. Ibí yìí ni wọ́n ti lè tẹ̀ka sórí ìwé ìdìbò tàbí kí wọ́n kọ nǹkan kan sórí rẹ̀, tó fi ipò tí wọ́n dì mú hàn. Ohun tó wu àwọn tí ń dìbò ni wọ́n lè ṣe sórí ìwé ìdìbò náà. Ibí yìí gan-an tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló rí wọn ni àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ ti gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn àṣẹ rẹ̀, tó sì bá ìgbàgbọ́ wọn mu. Kì í ṣe iṣẹ́ tiwa láti sọ ohun tí wọn yóò fi ìwé ìdìbò wọn ṣe.”

Bí ọkọ Kristẹni obìnrin kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ bá ranrí pé obìnrin náà gbọ́dọ̀ fara hàn níbi ìdìbò ńkọ́? Ní ti gidi, ó gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn Kristẹni ṣe ní láti tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ tó wà ní ipò gíga. (Éfésù 5:22; 1 Pétérù 2:13-17) Tó bá ṣègbọràn sí ọkọ rẹ̀, tó sì lọ sí ilé ìdìbò, ìpinnu tirẹ̀ nìyẹn. Kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ ṣe lámèyítọ́ rẹ̀.—Fi wé Róòmù 14:4.

Àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ pé òfin kò sọ pé ó jẹ́ dandan láti dìbò, àmọ́, tí wọ́n máa ń kórìíra àwọn tí kò bá lọ dìbò—bóyá kí wọ́n tilẹ̀ máa wu wọ́n léwu pàápàá ńkọ́? Àbí tí a bá ń fìyà tó burú jáì jẹ àwọn kan nítorí pé wọn kò lọ sí ilé ìdìbò bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin kò kàn án nípá láti dìbò ńkọ́? Ní irú àwọn ipò bí èyí àti àwọn tó fara pẹ́ ẹ, Kristẹni kan ni yóò pinnu fúnra rẹ̀. “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gálátíà 6:5.

Ó wá ṣeé ṣe ká rí àwọn ènìyàn kan tó kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n kíyè si pé àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi àtíbàbà ìdìbò tí àwọn mìíràn kò sì ṣe bẹ́ẹ̀ ní àkókò ìdìbò kan ní orílẹ̀-èdè àwọn. Wọ́n lè sọ pé, ‘ẹnu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò kò.’ Bó ti wù kó rí, ó yẹ kí àwọn èèyàn mọ̀ pé tó bá ti kan ọ̀ràn ẹ̀rí-ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan bí irú èyí, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni yóò ṣe ìpinnu tirẹ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run.—Róòmù 14:12.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣọ́ra láti rí i pé àwọn pa àìdásí-tọ̀tún-tòsì Kristẹni àti òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ àwọn mọ́ lórí ìpinnu èyíkéyìí tí wọ́n bá ṣe lábẹ́ ipò tó yàtọ̀ síra. Nínú gbogbo nǹkan, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run láti fún wọn lókun, àtọgbọ́n, kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wọn lọ́nàkọnà. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi ìdánilójú tí wọ́n ní nínú àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà hàn pé: “Ìwọ ni àpáta gàǹgà mi àti ibi odi agbára mi; àti nítorí orúkọ rẹ, ìwọ yóò ṣamọ̀nà mi, ìwọ yóò sì darí mi.”—Sáàmù 31:3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́