Kí a Má Ṣe Fà Sẹ́yin Sí Ìparun!
“Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun.”—HÉBÉRÙ 10:39.
1. Àwọn ipò wo ló mú kí ojora mú Pétérù?
KÒ SÍ àní-àní pé ojora ti mú àwọn àpọ́sítélì bí wọ́n ti ń gbọ́ tí Ọ̀gá wọn ọ̀wọ́n, Jésù, ń sọ fún wọn pé, a óò tú gbogbo wọn káàkiri, ti wọ́n yóò sì pa òun tì. Kí ló fẹ́ fa irú èyí—ní wákàtí tó nílò wọn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ yìí? Pétérù dúró lórí ìpinnu rẹ̀, ó ní: “Àní bí a bá mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀, síbẹ̀ a kì yóò mú èmi kọsẹ̀.” Ká sòótọ́, ọkùnrin ni Pétérù, ó láyà bíi kìnnìún. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn èèyànkéèyàn da Jésù, tí wọ́n wá fàṣẹ ọba mú un, a mà wá àwọn àpọ́sítélì tì o, wọ́n ti fọ́n ká, títí kan Pétérù alára. Lẹ́yìn èyí, níbi tí wọ́n ti ń fọ̀rọ̀ wá Jésù lẹ́nu wò nínú ilé Àlùfáà Àgbà Káyáfà, ara Pétérù ò balẹ̀ mọ́, bó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ló ń bọ̀ nínú àgbàlá ilé náà. Nígbà tí òtútù òru náà bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù, ó jọ pé Pétérù wá ń bẹ̀rù pé àwọn ará ibí yìí lè pa Jésù tàbí ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fura sí pé ó sún mọ́ ọn. Nígbà táwọn kan tó wà nítòsí sọ pé ọ̀kan lára àwọn tó sún mọ́ Jésù dáadáa ni Pétérù í ṣe, jìnnìjìnnì bò ó. Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sẹ́ Jésù. Pétérù tiẹ̀ lóun ò mọ̀ ọ́n rí rárá!—Máàkù 14:27-31, 66-72.
2. (a) Èé ṣe tí ojora tó mú Pétérù lálẹ́ ọjọ́ táa wá mú Jésù kò sọ ọ́ di ‘ara àwọn tí ń fà sẹ́yìn’? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
2 Àkókò tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá Pétérù jù lọ nínú ìgbésí ayé rẹ̀ nìyí, àkókò kan tó dájú pé ó kábàámọ̀ rẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ yòókù tó lò láyé. Ṣùgbọ́n, ṣé ìwà tí Pétérù hù lálẹ́ ọjọ́ yẹn sọ ọ́ di ojo ẹ̀dá ni? Ǹjẹ́ o sọ ọ́ di ọ̀kan lára “irú àwọn tí” àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ṣàpèjúwe lẹ́yìn náà, nígbà tó kọ̀wé pé: “Wàyí o, àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun”? (Hébérù 10:39) Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ni yóò gbà pé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kò bá Pétérù wí. Èé ṣe? Nítorí pé ẹ̀rù tó ba Pétérù jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ó wulẹ̀ jẹ́ àṣìṣe kékeré nínú ìgbésí ayé tó kún fún ìwà akin àti ìgbàgbọ́ títayọ. Bẹ́ẹ̀ náà ní ọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ nínú wa ṣe rí, àwọn sáà kan wà táa ti lò sẹ́yìn, tó jẹ́ pé táa bá rántí rẹ̀, ó máa ń tì wá lójú, àwọn àkókò tí ojora mú wa lójijì, tí kò sì jẹ́ kí a lè fi ìgboyà dúró fún òtítọ́ bí à bá ṣe fẹ́. (Fi wé Róòmù 7:21-23.) Ẹ jẹ́ ká lọ fọkàn balẹ̀ pé irú àkókò díẹ̀ bẹ́ẹ̀ táa fi ṣàṣìṣe kò sọ wá di irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Síbẹ̀, a ní láti pinnu pé, àgbẹdọ̀, àwa ò ní di irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Èé ṣe? Báwo la sì ṣe lè yẹra fún dídi irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀?
Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Fà Sẹ́yìn sí Ìparun
3. Báwo ni wòlíì Èlíjà àti Jónà ṣe jẹ́ kí ojora mú àwọn?
3 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn,” kì í ṣe àwọn tí ojora ò jẹ́ kí wọ́n ní ìgboyà fúngbà díẹ̀ ló ní lọ́kàn. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pétérù àti àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tó fara pẹ́ ẹ. Nígbà kan, ojora mú Èlíjà pàápàá tó jẹ́ wòlíì onígboyà, tí kì í sì í fọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, nígbà tí Jésíbẹ́lì Ayaba búburú nì sọ pé òun fẹ́ pa á, ni Èlíjà bá yáa bẹ́sẹ̀ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nítorí ẹ̀mí ẹ̀. (1 Àwọn Ọba 19:1-4) Ìbẹ̀rù tó dé bá wòlíì Jónà ló lé kenkà jù. Jèhófà rán an lọ sí Nínéfè, ìlú burúkú yẹn tí gbogbo ayé mọ̀ fún ìwà ipá. Ni Jónà bá wọkọ̀ tó ń lọ sí Táṣíṣì—ìlú tó wà lọ́nà ibòmíì pátápátá, nǹkan tó sì fi jìnnà sí ibi tó yẹ kó lọ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta kìlómítà! (Jónà 1:1-3) Síbẹ̀, a kò lè sọ pé èyíkéyìí nínú àwọn wòlíì wọ̀nyí tàbí àpọ́sítélì Pétérù wà lára irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn. Èé ṣe tí a kò fi lè sọ bẹ́ẹ̀?
4, 5. (a) Báwo ni àyíká ọ̀rọ̀ ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nípa “ìparun” tó sọ nínú Hébérù 10:39? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó wí pé: “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun”?
4 Ṣàkíyèsí gbólóhùn tí Pọ́ọ̀lù lò náà lódindi, ó ní: “Wàyí o, àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun.” Kí ló ní lọ́kàn nípa “ìparun”? Nígbà míì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó lò yẹn máa ń túmọ̀ sí ìparun ayérayé. Ìtumọ̀ yìí sì bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ níbí mu. Pọ́ọ̀lù ṣẹ̀ṣẹ̀ kìlọ̀ tán ni, ó wí pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí kò ṣe ìfojúsọ́nà fún ìdájọ́ akúnfẹ́rù, owú amú-bí-iná sì wà tí yóò jó àwọn tí ń ṣàtakò run.”—Hébérù 10:26, 27.
5 Nítorí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun àti àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó ń kàwé rẹ̀ ti pinnu pé àwọn ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láéláé, àwọn ò sì ní dẹ́kun sísìn ín. Nítorí táwọn bá lọ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ìparun ayérayé ni yóò gbẹ̀yìn àwọn. Júdásì Ísíkáríótù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó fà sẹ́yìn sí ìparun, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá òtítọ́, tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tako ẹ̀mí Jèhófà. (Jòhánù 17:12; 2 Tẹsalóníkà 2:3) Irú àwọn bẹ́ẹ̀ wà lára “àwọn ojo” tí wọ́n gba ìdájọ́ ìparun ayérayé nínú adágún iná ìṣàpẹẹrẹ. (Ìṣípayá 21:8) Rárá o, àwa ò fẹ́ wà lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀!
6. Ọ̀nà wo ni Sátánì Èṣù fẹ́ ká tọ̀?
6 Sátánì Èṣù ń fẹ́ ká fà sẹ́yìn sí ìparun. Ọ̀gá ló jẹ́ nínú “ìwà àrékérekè,” ó mọ̀ pé orí nǹkan bíńtín ni irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí ń sinni lọ sínú ìparun ti máa ń bẹ̀rẹ̀. (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Bó bá lo inúnibíni ní tààràtà, tí ọwọ́ rẹ̀ ò bá tẹ àwọn Kristẹni tòótọ́, ó tún lè lo àwọn ọ̀nà tí wọn ò ní tètè fura sí, kí ìgbàgbọ́ wọn lè yìnrìn. Ohun tó ń fẹ́ ni pé kí àwọn onígboyà, àwọn onítara tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà panu wọn mọ́. Ẹ jẹ́ a wo ọgbọ́n àrékérekè tó lò fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, àwọn tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí.
Bó Ṣe Gbógun Ti Àwọn Kristẹni Kí Wọ́n Lè Fà Sẹ́yìn
7. (a) Kí ni ìtàn ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù? (b) Àwọn ipò tẹ̀mí wo ló yí àwọn tó ń kàwé Pọ́ọ̀lù ká nígbà yẹn lọ́hùn-ún?
7 Ẹ̀rí fi hàn pé nǹkan bí ọdún 61 Sànmánì Tiwa ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà tó kọ sáwọn Hébérù. Ìtàn ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù kún fún rúkèrúdò. Lẹ́yìn ikú Jésù, ni inúnibíni burúkú bẹ́ sílẹ̀, ló bá di pé kí ọ̀pọ̀ Kristẹni máa sá fi ìlú sílẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tó yá, àlàáfíà tún dé, àwọn Kristẹni sì ń pọ̀ sí i. (Ìṣe 8:4; 9:31) Bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ inúnibíni àti ìjìyà dé, nígbà tó yá, wọ́n tún rọlẹ̀. Ó jọ pé nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí àwọn Hébérù, lẹ́ẹ̀kan sí i, àkókò àlàáfíà ni ìjọ tún wà. Síbẹ̀ náà, ìṣòro ń bẹ. Nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan wà tí wọ́n rò pé òpin náà ti ń pẹ́ jù, kí wọ́n sì máa rò pé ó lè máà dé lójú ayé wọn. Àwọn mìíràn sì wà, pàápàá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gba òtítọ́, tó jẹ́ pé wọn kò rí ìdánwò inúnibíni gbígbóná janjan rí, tí wọn kò sì mọ ìjẹ́pàtàkì lílo ìfaradà nígbà tí ìdánwò bá dé. (Hébérù 12:4) Ó dájú pé Sátánì lo àǹfààní ipò yìí láti tàn wọ́n jẹ. “Ìwà àrékérekè” wo ló lò?
8. Ìṣarasíhùwà wo ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù ní sí ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde?
8 Ojú ẹ̀gàn làwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà fi ń wo ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde. Àyíká ọ̀rọ̀ lẹ́tà Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn táwọn aṣáájú ìsìn Júù tí wọ́n jọra wọn lójú bí nǹkan míì àti àwọn ọmọlẹ́yìn wọn ń sọ sáwọn Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa sọ pé: ‘Kì í màá ṣèní, kì í màá ṣàná ni tẹ́ńpìlì ńlá ti wà ní Jerúsálẹ́mù! A láwọn àlùfáà àgbà, àwọn ẹni iyì, ẹni ẹ̀yẹ, tí ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ la sì tún láwọn àlùfáà ọmọ abẹ́. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń rúbọ. A ní Òfin, táa tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì fi lé Mósè lọ́wọ́, táa sì lo àwọn àmì ńláǹlà láti fìdí wọn múlẹ̀ ní Òkè Sínáì. Àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé wọ̀nyí, tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni, tó jẹ́ pé inú ẹ̀sìn àwa Júù ni wọ́n ti ya yìí sì rèé, kò sí ìkankan nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n ní!’ Ǹjẹ́ irú òkò ọ̀rọ̀ báyìí ṣiṣẹ́ tí wọ́n fẹ́ kó ṣe? Ká má wulẹ̀ bo ohun tí kò ṣeé bò, àtakò yìí kó ìdààmú bá àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ Hébérù. Lẹ́tà Pọ́ọ̀lù ràn wọ́n lọ́wọ́ ní àkókò náà gan-an tí wọ́n nílò ìrànwọ́.
Ìdí Tí Wọn Ò Fi Gbọ́dọ̀ Fà Sẹ́yìn sí Ìparun
9. (a) Kókó wo ló wà nínú lẹ́tà táa kọ sí àwọn Hébérù? (b) Lọ́nà wo ni àwọn Kristẹni gbà sìn nínú tẹ́ńpìlì tó dára ju èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ?
9 Ẹ jẹ́ á ṣàgbéyẹ̀wò ìdí méjì tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tó ń gbé ní Jùdíà láti má ṣe fà sẹ́yìn sí ìparun. Èkíní—ipò gíga tí ètò ìsìn Kristẹni wà—èyí fara hàn káàkiri nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù. Jálẹ̀ lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, ó ṣàlàyé kókó yìí. Tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù wulẹ̀ jẹ́ àwòṣe ohun ńlá kan tó ṣeé fọkàn tán, ìyẹn ni tẹ́ńpìlì Jèhófà nípa tẹ̀mí, ilé “tí a kò fi ọwọ́ ṣe.” (Hébérù 9:11) Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn láǹfààní láti sìn nínú ìṣètò tẹ̀mí yẹn, èyí tó wà fún ìjọsìn mímọ́ gaara. Wọ́n sìn lábẹ́ májẹ̀mú tó sàn ju ti ìṣáájú lọ, ìyẹn ni májẹ̀mú tuntun táa ti ṣèlérí látayébáyé, èyí tó ní Alárinà tí ipò rẹ̀ ju ti Mósè lọ, ìyẹn ni Jésù Kristi.—Jeremáyà 31:31-34.
10, 11. (a) Èé ṣe tí ìdílé tí Jésù ti jáde kò sọ ọ́ di ẹni tí kò tóótun láti ṣiṣẹ́ Àlùfáà Àgbà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí? (b) Lọ́nà wo ni Jésù gbà jẹ́ Àlùfáà Àgbà tó ga ju èyí tó ń sìn nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lọ?
10 Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn tún ní Àlùfáà Àgbà tó sàn ju ti ìṣáájú lọ, ìyẹn ni Jésù Kristi. Òun kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Áárónì rárá. Dípò ìyẹn, òun jẹ́ Àlùfáà Àgbà “ní ìbámu pẹ̀lú irú ọ̀nà ti Melikisédékì.” (Sáàmù 110:4) Melikisédékì, tí a kò ní àkọsílẹ̀ kankan nípa ìdílé tó ti wá, jẹ́ ọba Sálẹ́mù ìgbàanì, òun sì tún ni àlùfáà àgbà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù, ipò Melikisédékì bá tirẹ̀ mú wẹ́kú, nítorí ipò àlùfáà tirẹ̀ kò ní í ṣe pẹ̀lú orírun ènìyàn aláìpé kankan bí kò ṣe ohun kan tó tóbi ju ìyẹn lọ—ìyẹn ni ìbúra tí Jèhófà Ọlọ́run alára ṣe. Gẹ́gẹ́ bíi Melikisédékì, kì í ṣe iṣẹ́ Àlùfáà Àgbà nìkan ni Jésù ṣe, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ Ọba, ẹni tí ikú ò lè rí gbé ṣe mọ́.—Hébérù 7:11-21.
11 Síwájú sí i, lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti àlùfáà àgbà inú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, Jésù kò ní láti máa rúbọ lọ́dọọdún. Ìwàláàyè pípée tirẹ̀ fúnra rẹ̀ ló fi ṣèrúbọ, ó sì ṣe é lẹ́ẹ̀kan, kò sì tún ní tún un ṣe mọ́. (Hébérù 7:27) Gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú ní tẹ́ńpìlì láyé ọjọ́hun wulẹ̀ ń ṣàpẹẹrẹ ohun tí Jésù ṣe yìí ni. Ẹbọ pípé rẹ̀ pèsè ìdáríjì tòótọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Ohun tó tún múni lọ́kàn yọ̀ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ tó fi hàn pé Jésù tí kò yí padà ni Àlùfáà Àgbà yìí, ẹni tí àwọn Kristẹni tó wà ní Jerúsálẹ́mù mọ̀ dáadáa. Ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, onínúure, ẹni tó lè ‘bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.’ (Hébérù 4:15; 13:8) Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyẹn ń fojú sọ́nà fún dídi àlùfáà ọmọ abẹ́ fún Kristi! Kí ló máa wá fà á tí wọ́n á fi bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé ó yẹ kí àwọn fà sẹ́yìn sí àwọn ohun “aláìlera àti akúrẹtẹ̀” ti ẹ̀sìn àwọn Júù tí ìbàjẹ́ ti bá?—Gálátíà 4:9.
12, 13. (a) Ìdí kejì wo ni Pọ́ọ̀lù fúnni tí kò fi yẹ ká fà sẹ́yìn? (b) Èé ṣe tí àkọsílẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá fi yẹ kó fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù níṣìírí láti má ṣe fà sẹ́yìn sí ìparun?
12 Kí wọ́n má bàa sọ pé ẹ̀rí tí Pọ́ọ̀lù fún wọn kò tó, ló bá tún fún àwọn Hébérù ní ìdí kejì tí wọn kò fi ní láti fà sẹ́yìn sí ìparun—ìyẹn ni àkọsílẹ̀ tó wà nípa ìfaradà tiwọn fúnra wọn. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́ nínú èyí tí, lẹ́yìn tí a ti là yín lóye, ẹ fara da ìdíje ńláǹlà lábẹ́ àwọn ìjìyà.” Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé, àwọn èèyàn ‘ti gbé wọn síta bí ẹni pé nínú gbọ̀ngàn ìwòran’ kí wọ́n lè kẹ́gàn wọn, kí wọ́n sì pọ́n wọn lójú. Wọ́n ti fìyà pá àwọn mìíràn lórí lọ́gbà ẹ̀wọ̀n; àwọn mìíràn ti bá àwọn tó ń jìyà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kẹ́dùn, wọ́n sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ti fi ìgbàgbọ́ àti ìfaradà tó ṣeé tẹ̀ lé hàn. (Hébérù 10:32-34) Síbẹ̀, èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní rírántí” irú àwọn ìrírí tí ń bani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ kò ní mú wọn rẹ̀wẹ̀sì báyìí?
13 Rárá o, “rírántí àwọn ọjọ́ àtijọ́” yóò rán àwọn Hébérù létí bí Jèhófà ṣe mú wọn la àdánwò já. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún wọn láti borí ọ̀pọ̀ àtakò Sátánì. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà rántí gbogbo iṣẹ́ rere wọn, kò sì jẹ́ gbàgbé wọn. A rán wa létí àwọn ọ̀rọ̀ ìṣítí tí Jésù sọ pé ká máa to ìṣúra wa jọ sí ọ̀run. Kò sí olè tó lè jí àwọn ìṣúra wọ̀nyí níbẹ̀; kò sí òólá tó lè lá a níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ìpẹtà kankan kò lè rí i jẹ níbẹ̀. (Mátíù 6:19-21) Àmọ́ ṣá o, àwọn ìṣúra wọ̀nyí lè run bí Kristẹni kan bá fà sẹ́yìn sí ìparun. Ńṣe ni irú ìwà yẹn yóò mú kí gbogbo ìṣúra tó ti tó jọ sí ọ̀run ṣègbé. Ẹ ò ri pé ìdí tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé kí wọ́n má ṣe gbìyànjú títọ irú ipa ọ̀nà yẹn ṣe pàtàkì gidigidi! Kí ni wọ́n fẹ́ fi gbogbo ọdún tí wọ́n ti fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn ṣòfò fún? Kò sóhun tó lè dà bíi pé kí wọ́n kúkú máa fara dà á.
Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Fà Sẹ́yìn sí Ìparun
14. Àwọn ìpèníjà wo la dojú kọ tó fara jọ èyí tí àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní dojú kọ?
14 Lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú ní ìdí pàtàkì tí wọn ò fi gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ á rántí ìbùkún rẹpẹtẹ táa ní nínú ìjọsìn mímọ́ gaara tí Jèhófà ti gbé lé wa lọ́wọ́. Bíi ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, à ń gbé ní àkókò kan tí àwọn mẹ́ńbà ìsìn tó lókìkí lágbàáyé ń bẹnu àtẹ́ lù wá, tí wọ́n ń yọ ṣùtì ètè sí wa, tí wọ́n ń fi àwọn ilé ìjọsìn ràgàjì-ràgàjì wọn àtàwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé tó jẹ́ ti ẹ̀sìn wọn, ṣe fọ́ńté sí wa. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ní ká lọ fọkàn balẹ̀, ó ní ọ̀nà táa gbà ń jọ́sìn òun ti tẹ́ òun lọ́rùn. Ká sòdodo, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò gbádùn àwọn ìbùkún tí à ń gbádùn lónìí. O lè ṣe kàyéfì pé, ‘Á-àá, kí ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀?’ Ṣe bí ìgbà ayé tiwọn ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ọdún 29 Sànmánì Tiwa mà ni Kristi di Àlùfáà Àgbà. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ fojú rí Ọmọ Ọlọ́run, oníṣẹ́ ìyanu náà. Kódà lẹ́yìn ikú rẹ̀, àwọn iṣẹ́ ìyanu mìíràn tún ṣẹlẹ̀. Àmọ́, gẹ́gẹ́ báa ti sọ tẹ́lẹ̀, irú àwọn ẹ̀bùn bẹ́ẹ̀ dópin.—1 Kọ́ríńtì 13:8.
15. Àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí ń gbé ní àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ wo nímùúṣẹ, kí sì ni ìyẹn túmọ̀ sí fún wa?
15 Ṣùgbọ́n, àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ gbígbòòrò táa sọ nípa tẹ́ńpìlì nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí ogójì sí ìkejìdínláàádọ́taa ń ní ìmúṣẹ lọ́nà tó gba àfiyèsí gidi ni à ń gbé yìí. Nípa báyìí, a ti rí báa ṣe mú ètò ìjọsìn mímọ́ gaara ti Ọlọ́run padà bọ̀ sípò. A ti fọ tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yẹn mọ́ pátápátá, gbogbo onírúurú ìbàjẹ́ ìsìn àti ìbọ̀rìṣà ò sí nínú rẹ̀ mọ́. (Ìsíkíẹ́lì 43:9; Málákì 3:1-5) Ronú nípa àǹfààní tí fífọ̀ tí a fọ̀ ọ́ mọ́ yẹn fún wa.
16. Ìrẹ̀wẹ̀sì wo ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dojú kọ?
16 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọjọ́ iwájú ìjọ Kristẹni táa ṣètò tojú súni. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ńṣe ni yóò dà bíi pé èpò gba inú oko àlìkámà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ gbìn, tó fi jẹ́ pé agbára káká la fi dá àlìkámà mọ̀ yàtọ̀ sí èpò. (Mátíù 13:24-30) Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kìíní, nígbà tó ku àpọ́sítélì Jòhánù nìkan ṣoṣo, arúgbó alárúgbó, tó ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́, ìpẹ̀yìndà ti wá ń ràn bí iná ọyẹ́. (2 Tẹsalóníkà 2:6; 1 Jòhánù 2:18) Kò pẹ́ lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì kú, ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà kan tó yara rẹ̀ sọ́tọ̀ bá wá sí ojútáyé, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fara ni agbo, tí wọ́n sì ń wẹ̀wù gẹ̀rẹ̀jẹ̀-gẹ̀rẹ̀jẹ̀ táa fi lè tètè dá wọn mọ̀ kiri. Ni ìpẹ̀yìndà bá ń tàn bí egbò kíkẹ̀. Ẹ wo bí èyí yóò ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn Kristẹni olóòótọ́ tó! Lójú wọn kòrókòró làwọn ará ibí yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fi ìjọsìn tó ti dómùkẹ̀ bi ètò tuntun táa gbé kalẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ gaara ṣubú. Kò sì tíì ju ọ̀rúndún kan lọ tí Kristi dá ìjọ yìí sílẹ̀ o.
17. Lọ́nà wo ni ìjọ Kristẹni lóde òní gbà wà pẹ́ ju ti aláfijọ wọn tó wà ní ọ̀rúndún kìíní lọ?
17 Wàyí o, ẹ wá wo ìyàtọ̀. Lónìí, ìjọsìn mímọ́ gaara ti wà fún ìgbà pípẹ́ ju àkókò tó fi wà ṣáájú ikú àwọn àpọ́sítélì lọ! Gbàrà láti ìgbà táa ti kọ́kọ́ mú ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn yìí jáde lọ́dún 1879, Jèhófà ti fi ìjọsìn táa fọ̀ mọ́ bù kún wa lọ́nà púpọ̀ sí i. Jèhófà àti Kristi Jésù wọnú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí lọ́dún 1918 nítorí ète àtifọ̀ ọ́ mọ́. (Málákì 3:1-5) Láti ọdún 1919 la ti bẹ̀rẹ̀ sí ní yọ́ ètò tó wà fún jíjọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run mọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Òye wa nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àti ìlànà rẹ̀ túbọ̀ ń ṣe kedere sí i. (Òwe 4:18) Ta ló yẹ kó gba ìyìn nǹkan wọ̀nyí? Kò tọ́ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Jèhófà nìkan, pẹ̀lú Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Orí ìjọ, ló lè dáàbò bo àwọn ènìyàn Rẹ̀, kí wọ́n má bàa bà jẹ́ ní àkókò ìfìbàjẹ́-ṣayọ̀ tí à ń gbé yìí. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní tó fún wa láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn mímọ́ gaara rẹ̀ lónìí. Ẹ sì jẹ́ ká pinnu láìyẹhùn pé, láéláé, àwa ò ní fà sẹ́yìn sí ìparun!
18. Èé ṣe tí a kò fi gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn sí ìparun?
18 Bíi ti àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù wọ̀nyẹn, ìdí kejì wà, táa fi ní láti gbéjà ko ìwà ojo, tó lè mú ká fà sẹ́yìn, ìyẹn ni àkọsílẹ̀ ìfaradà tiwa fúnra wa. Yálà ẹnu àìpẹ́ yìí la ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà ni o tàbí a ti ń sìn ín fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún, a ti ní àkọsílẹ̀ kan pé à ń ṣiṣẹ́ tó yẹ kí Kristẹni máa ṣe. Ọ̀pọ̀ nínú wa lo ti fojú winá inúnibíni, ojú ẹlòmíràn nínú wa ti rí mẹ́wàá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, púpọ̀ nínú wa ti wà níbi táa ti fòfin de iṣẹ́ wa rí, a ti hùwà òǹrorò sáwọn mìíràn, tàbí ká gba dúkìá wọn lọ́wọ́ wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì ti dojú kọ àtakò ìdílé, ọ̀pọ̀ làwọn èèyàn ti kàn lábùkù, tí wọ́n ti fi ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ti dágunlá sí. Gbogbo wa pátá la ti lo ìfaradà, táa sì ń bá iṣẹ́ ìsìn wa tí à ń fòótọ́ ṣe sí Jèhófà nìṣó láìka àwọn ìṣòro àti ìdánwò ìgbésí ayé tó lè dé sí. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ti ní àkọsílẹ̀ jíjẹ́ onífaradà lọ́dọ̀ Jèhófà, kò sì lè gbàgbé àkọsílẹ̀ yìí láé, ilé ìṣúra kan ló jẹ́ ní ọ̀run. Nítorí náà, ó dájú pé àkókò táa wà yìí kì í ṣe àkókò to yẹ ká fà sẹ́yìn sínú ètò ògbólógbòó tó ti dómùkẹ̀, táa ti fi sílẹ̀ sẹ́yìn! Kí ló dé, tí a óò wá sọ gbogbo iṣẹ́ àṣekára wa di asán? Òde òní gan-an ni ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ òótọ́, nítorí “ìgbà díẹ̀ kíún” ló kù kí òpin dé.—Hébérù 10:37.
19. Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e?
19 Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ jẹ́ á pinnu pé “àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun”! Kàkà bẹ́ẹ̀, ká pinnu pé ara “irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́” la wà. (Hébérù 10:39) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bá àpèjúwe yẹn mu, báwo la sì ṣe lè ran àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé e yóò gbé èyí yẹ̀ wò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Ṣé O Rántí?
◻ Kí ló túmọ̀ sí láti fà sẹ́yìn sí ìparun?
◻ Ìṣòro wo làwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sí ń fojú winá rẹ̀?
◻ Àwọn ìdí wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn Hébérù tí kò fi yẹ kí wọ́n fà sẹ́yìn sí ìparun?
◻ Àwọn ìdí wo la ní láti pinnu pé, àgbẹdọ̀, àwa ò ní fà sẹ́yìn sí ìparun?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ojora tó mú Pétérù kò sọ ọ́ di “irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun”