Kí Ni Wọ́n Rí Ní Jésíréélì?
FÚN ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn báyìí ni ibi tí ìlú àtijọ́ nì, Jésíréélì wà, ti dahoro. Láyé ìgbà kan ó lókìkí nínú ìtàn Bíbélì. Àmọ́ báyìí, kò níyì mọ́, ògèlètè yẹ̀pẹ̀ ló wà níbẹ̀, ó ti di òkìtì àlàpà. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn awalẹ̀pìtàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣẹ́kù tó wà ní ìlú Jésíréélì. Kí làwọn òkìtì wọ̀nyí fi hàn nípa àkọsílẹ̀ Bíbélì?
Jésíréélì Inú Bíbélì
Jésíréélì wà ní apá ìlà oòrùn Àfonífojì Jésíréélì, àgbègbè tó jẹ́ ilẹ̀ tó lọ́ràá jù lọ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Ní òdìkejì àfonífojì ọ̀hún gan-an ní ìhà àríwá, ibẹ̀ ni òkè Mórè wà, níbi táwọn ará Mídíánì tẹ́gun sí nígbà tí wọ́n ń gbára dì láti bá Gídíónì Onídàájọ́ àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jà. Sí apá ìlà oòrùn díẹ̀ ni kànga Háródù wà, ní ẹsẹ̀ Òkè Gíbóà. Ibí yìí ni Jèhófà ti dín àwọn ọmọ ogun Gídíónì kù sí ọ̀ọ́dúnrún ọkùnrin láti lè fi hàn pé òun lágbára láti dá àwọn ènìyàn òun nídè láìlo agbo ọmọ ogun tó lágbára gan-an. (Onídàájọ́ 7:1-25; Sekaráyà 4:6) Lẹ́bàá Òkè Gíbóà ni àwọn Filísínì ti ṣẹ́gun Sọ́ọ̀lù, ọba Ísírẹ́lì, nínú ogun kan tó múni gbọ̀n rìrì, ìyẹn nígbà tí wọ́n pa Jónátánì àti àwọn méjì mìíràn tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù, tí Sọ́ọ̀lù alára sì para rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 31:1-5.
Onírúurú ọ̀nà tó gba àfiyèsí ni Bíbélì gbà sọ̀rọ̀ nípa ìlú àtijọ́ yìí tí a ń pè ní Jésíréélì. Ó sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣi agbára lò àti ìwà apẹ̀yìndà tí àwọn alákòóso Ísírẹ́lì hù, ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa ìṣòtítọ́ àti ìtara àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Samáríà gan-an ni olú ìlú, Jésíréélì ni Áhábù Ọba, ẹni tó ṣàkóso ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti àríwá Ísírẹ́lì ní àádọ́ta ọdún tó kẹ́yìn ọ̀rúndún kẹwàá ṣááju Sànmánì Tiwa, kọ́ ààfin rẹ̀ sí. (1 Àwọn Ọba 21:1) Jésíréélì náà ni aya àjèjì tí Áhábù fẹ́, ìyẹn Jésíbẹ́lì, ti fikú halẹ̀ mọ́ Èlíjà, wòlíì Jèhófà. Inú bí obìnrin yìí nítorí pé Èlíjà ò bẹ̀rù rárá láti pa àwọn wòlíì Báálì, lẹ́yìn tó parí ìdánwò tí wọ́n fi mọ Ọlọ́run tòótọ́ lórí Òkè Kámélì.—1 Àwọn Ọba 18:36–19:2.
Lẹ́yìn èyí, ìwà ọ̀daràn wáyé ní Jésíréélì. Wọ́n pa Nábótì ará Jésíréélì. Ọgbà àjàrà Nábótì wọ Áhábù Ọba lójú. Nígbà tí ọba sọ pé ilẹ̀ náà wu òun, Nábótì fi ẹ̀mí ìdúróṣinṣin fèsì pé: “Kò ṣeé ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi, ní ojú ìwòye Jèhófà, pé kí n fi ohun ìní àjogúnbá àwọn baba ńlá mi fún ọ.” Èsì tó fi hàn pé ọkùnrin yìí mọ ohun tó ń ṣe bí Áhábù nínú gidigidi. Nígbà tí Ayaba Jésíbẹ́lì rì i pé inú ọba ò dùn, ló bá gbé ìgbẹ́jọ́ awúrúju kalẹ̀, ni wọ́n bá fẹ̀sùn kan Nábótì pé ó sọ̀rọ̀ òdì. Bí wọ́n ṣe dá Nábótì aláìṣẹ̀ lẹ́bi nìyẹn, wọ́n dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò nípa sísọ ọ́ lókùúta pa, tí ọba sì gba ọgbà àjàrà rẹ̀.—1 Àwọn Ọba 21:1-16.
Nítorí ìwà burúkú yìí, Èlíjà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ajá ni yóò jẹ Jésíbẹ́lì ní abá ilẹ̀ Jésíréélì.” Wòlíì náà tún sọ síwájú sí i pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ ti Áhábù tí ó bá kú ní ìlú ńlá, ni àwọn ajá yóò jẹ . . . Láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí Áhábù, ẹni tí ó ta ara rẹ̀ láti ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, ẹni tí Jésíbẹ́lì aya rẹ̀ ń kì láyà.” Ṣùgbọ́n, nítorí Áhábù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí Èlíjà kéde ìdájọ́ Jèhófà, Jèhófà kéde pé, ìjìyà yìí kò ní ṣẹlẹ̀ lójú ayé Áhábù. (1 Àwọn Ọba 21:23-29) Àkọsílẹ̀ Bíbélì ń bá a lọ ní sísọ pé ní àwọn ọjọ́ wòlíì tó dé lẹ́yìn Èlíjà, ìyẹn Èlíṣà, a yan Jéhù gẹ́gẹ́ bí ọba Ísírẹ́lì. Bí Jéhù ti ń gẹṣin wọ Jésíréélì, ló bá pàṣẹ pé kí wọ́n taarí Jésíbẹ́lì láti ojú fèrèsé ààfin rẹ̀, kí la máa rí, làwọn ẹṣin bá fi pátákò wọn tẹ̀ ẹ́ ní àtẹ̀rẹ́. Nígbà tó ṣe, la wá rí i pé àwọn ajá jòkújòkú ti jẹ ẹ́ ku kìkì apopo orí, ẹsẹ̀, àti àtẹ́lẹwọ́. (2 Àwọn Ọba 9:30-37) Àkọsílẹ̀ Bíbélì tó tún ní í ṣe pẹ̀lú Jésíréélì jẹ́ lẹ́yìn táa pa àádọ́rin àwọn ọmọ Áhábù. Jéhù to orí wọn jọ gègèrè sọ́nà méjì ní ẹnubodè ìlú Jésíréélì, lẹ́yìn èyí ló wá pa àwọn aṣáájú àti àlùfáà yòókù tí wọ́n ti lọ́wọ́ sí ìjọba apẹ̀yìndà tí Áhábù gbé kalẹ̀.—2 Àwọn Ọba 10:6-11.
Kí Làwọn Awalẹ̀pìtàn Rí?
Ní ọdún 1990, iṣẹ́ àpawọ́pọ̀ṣe láti walẹ̀ Jésíréélì bẹ̀rẹ̀. Àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó lọ́wọ́ nínú rẹ̀ ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn ti Yunifásítì Tel Aviv (tí David Ussishkin ṣojú fún) àti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìwalẹ̀pìtàn ti Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní Jerúsálẹ́mù (tí John Woodhead ṣojú fún). Ní ọdún 1990 sí 1996, sáà méje (tí sáà kan jẹ́ ọ̀sẹ̀ mẹ́fà) ni àwọn òṣìṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn tí wọ́n tó ọgọ́rin sí ọgọ́rùn-ún fi ń ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ yìí.
Ọ̀nà ìwalẹ̀pìtàn tóde òní ni pé ká yẹ ohun táa bá rí lórí ilẹ̀ kan wò gẹ́gẹ́ bó ti rí gan-an, láìtọ́ka sí àwọn èrò tàbí àbá èrò orí tó ti wà tẹ́lẹ̀. Nítorí náà, lọ́dọ̀ àwọn awalẹ̀pìtàn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ilẹ̀ Bíbélì, wọn ò gbà pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nìkan labẹ́ gé. Wọ́n gbọ́dọ̀ gbé gbogbo ìsọfúnni àti ẹ̀rí mìíràn tó ṣeé fojú rí yẹ̀ wò dáadáa. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí John Woodhead ti sọ, yàtọ̀ sí àwọn orí díẹ̀ nínú Bíbélì, kò tún sí ẹ̀rí àkọsílẹ̀ ìgbàanì kankan nípa Jésíréélì. Nítorí náà, àkọsílẹ̀ Bíbélì àti déètì rẹ̀ yẹ kó wà lára ohun tí a ó yẹ̀ wò. Kí ni àwọn awalẹ̀pìtàn rí?
Bí wọ́n ti ń wú ògiri àti ohun àfamọ̀ṣe jáde, ó wá ṣe kedere láti ìbẹ̀rẹ̀ pé, àwọn àwókù náà ti wà láti Sànmánì Irin Rírọ, èyí wá fi wọ́n sí àkókò kan náà pẹ̀lú àkókò Jésíréélì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ti ń bá iṣẹ́ wíwalẹ̀ náà lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ìyanu ló ṣẹlẹ̀. Àkọ́kọ́ ni títóbi ilẹ̀ náà àti ti àwọn ògiri rẹ̀ ràgàjì-ràgàjì. Àwọn awalẹ̀pìtàn rò pé àwọn yóò rí ibì kan tó ní ògiri táa lè fi wé ti Samáríà ìgbàanì, olú ìlú ìjọba Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n, bí wíwalẹ̀ náà ti ń bá a lọ, ó wá ṣe kedere pé, Jésíréélì tóbi ju ìyẹn lọ dáadáa. Ògiri rẹ̀ gùn tó ọ̀ọ́dúnrun mítà sí àádọ́jọ mítà, àgbègbè náà sì fẹ̀ tó ìlọ́po mẹ́ta ìlú èyíkéyìí táa rí ní Ísírẹ́lì ní àkókò yẹn. Kòtò ńlá kan tí inú rẹ̀ gbẹ táútáú ló yí i ká, ó wá fi mítà mọ́kànlá jìn lọ sísàlẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri náà. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ussishkin ti sọ, a ò rí irú kòtò ńlá yìí rí ṣáájú ìgbà táa kọ Bíbélì. Ó wí pé: “A ò rí ohunkóhun tó jọ èyí ní Ísírẹ́lì títí di ìgbà àwọn Ajagun Ẹ̀sìn.”
Ohun mìíràn tó tún ṣàjèjì ni pé, kò sí àwọn ilé ńláńlá nígboro ìlú náà. Ọ̀pọ̀ iyẹ̀pẹ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú táa kó wá sínú ìlú náà nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé ń lọ lọ́wọ́ la ti lò láti ṣe ibi táa ti lè dúró sọ̀rọ̀—ìyẹn ni pèpéle tó ga sókè—tó ní àkámọ́. Ìwé náà, Second Preliminary Report, èyí tó dá lórí ilẹ̀ tí wọ́n wà ní Tel Jezreel sọ pé, pèpéle tó lókìkí yìí lè jẹ́ ẹ̀rí pé Jésíréélì kì í kàn ṣe ààfin lásán. Ó wí pé: “A óò fẹ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn gbà gbọ́ pé, ó ṣeé ṣe kí Jésíréélì ti jẹ́ ibùdó àwọn ológun fún àwọn ọmọ ogun ti ọba Ísírẹ́lì nígbà ayé àwọn Omride [Ómírì àti àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀] . . . ibi tí wọ́n kó àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹṣin sí, tí wọ́n sì ti ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tí Woodhead wo sàkun pèpéle táa mọ̀ sókè yìí, àti àkámọ́ náà gan-an, ó méfò pé ó ṣeé ṣe kí ibí yìí ti jẹ́ ibi gbàgede táa ti ń fi ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹlẹ́ṣin tó tóbi jù lọ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé ní àkókò náà ṣe ṣekárími.
Àwọn àwókù ẹnubodè ìlú náà tún jẹ́ ohun mìíràn tó tún fa àwọn awalẹ̀pìtàn lọ́kàn mọ́ra. Ó kéré tán, wọ́n rí ẹnu ọ̀nà ẹnubodè oníyẹ̀wù mẹ́rin níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí àwọn kan ti wá ń kó àwọn òkúta tó wà níbẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, a ò tíì lè dórí ìparí èrò lórí ohun táa rí. Èrò Woodhead ni pé, àwọn àwókù náà ń tọ́ka sí ẹnubodè oníyàrà mẹ́fà tó tóbi tó èyí táa rí ní Mẹ́gídò, Hásórì, àti Gésérì.a
Àwọn àwárí ìwalẹ̀pìtàn fi ohun yíyanilẹ́nu kan hàn pé ìgbà díẹ̀ ni ìlú náà fi wà, ilú tó jẹ́ pé ibi tó dára jù lọ ló wà ní ti iṣẹ́ ogun àti ní ti ilẹ̀. Woodhead tẹnu mọ́ ọn pé gẹ́gẹ́ bí ìlú olódi ńlá, Jésíréélì jẹ́ ibi tó wà fún ìgbà díẹ̀—ó wà fún ẹ̀wádún díẹ̀ péré. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀pọ̀ àwọn ìlú mìíràn ní Ísírẹ́lì táa mẹ́nu kàn nínú Bíbélì, irú bí Mẹ́gídò, Hásórì àti Samáríà òlú ìlú, tí wọ́n tún kọ́ léraléra, tí wọ́n fẹ̀ lójú sí i, tí wọ́n sì gbé inú rẹ̀ ní àwọn àkókò tó yàtọ̀ síra. Èé ṣe táwọn èèyàn fi yáa pa ilẹ̀ ẹlẹ́tù lójú yìí tì? Woodhead lérò pé Áhábù àti agbo ilé rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dojú ọrọ̀ ajé ilẹ̀ náà dé pátápátá nítorí ìná àpà tí wọ́n ń ná owó orílẹ̀-èdè náà. Èyí hàn gbangba nínú bí Jésíréélì ti tóbi tó àti bó ti lágbára tó. Ó jọ pé ìjọba tuntun lábẹ́ ìdarí Jéhù kò fẹ́ kí ohunkóhun nípa Áhábù máa wá sí ìrántí òun, ó sì wá torí bẹ́ẹ̀ pa ìlú náà tì.
Gbogbo ẹ̀rí táa wú jáde ló fi hàn pé ibi tí Jésíréélì wà ló jẹ́ àárín gbùngbùn Ísírẹ́lì ní Sànmánì Irin Rírọ. Ìtóbi rẹ̀ àti odi rẹ̀ bá àpèjúwe tó wà nínú Bíbélì mu, èyí tó sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààfin olókìkí fún Áhábù àti Jésíbẹ́lì. Àwọn àmì tó fi hàn pé a gbé inú rẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ bá àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìlú náà mu: Ó tètè di olókìkí nígbà ìjọba Áhábù, nígbà tí Jèhófà sì pàṣẹ bẹ́ẹ̀, a dójú tì í pátápátá nígbà tí Jéhù “tẹ̀ síwájú láti ṣá gbogbo ẹni tí ó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésíréélì balẹ̀, àti gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀ àti àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, títí òun kò fi jẹ́ kí ó ṣẹ́ ku olùlàájá kankan fún un.”—2 Àwọn Ọba 10:11.
Ìṣirò Àkókò Tí Jésíréélì Fi Wà
John Woodhead sọ pé, “ó ṣòro nínú ìwalẹ̀pìtàn láti rí ohun kan pàtó tí a ó fi mọ̀ pé ìgbà báyìí ni ohun báyìí ṣẹlẹ̀.” Nítorí náà bí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe ń ṣàyẹ̀wò àbájáde ìwalẹ̀pìtàn wọn tó gba ọdún méje, wọ́n ń fi ohun tí wọ́n ṣàwárí yìí wéra pẹ̀lú àwọn ibòmíràn tí wọ́n ti ń walẹ̀. Èyí ti yọrí sí títún nǹkan gbé yẹ̀ wò àti iyàn jíjà. Èé ṣe? Nítorí láti ìgbà tí awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì nì Yigael Yadin ti wú nǹkan jáde ní Mẹ́gídò ní àwọn ọdún 1960 àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn awalẹ̀pìtàn ti gbà pé ó ti rí àwọn odi àti ẹnubodè tó ti wà láti ìgbà Sólómọ́nì Ọba. Wàyí o, àwọn odi, ohun àfamọ̀ṣe, àti ẹnubodè táa rí ní Jésíréélì ń mú kí àwọn kan máa kọminú sí ìparí èrò yìí.
Fún àpẹẹrẹ, àwọn ohun àfamọ̀ṣe táa rí ní Jésíréélì bá èyí táa rí ní Mẹ́gídò mu, èyí tí Yadin sọ pé ó ti wà láti ìgbà ìṣàkóso Sólómọ́nì. Ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ẹnubodè náà àti bí ilẹ̀ méjèèjì ti fẹ̀ tó jọra, tàbí ká sọ pé wọ́n rí bákan náà. Woodhead sọ pé: “Gbogbo ẹ̀rí fi hàn pé àkókò Sólómọ́nì ni Jésíréélì ti wà tàbí kí wọ́n sún déètì náà síwájú sí ìgbà ayé Áhábù nítorí ohun tí wọ́n rí ní àwọn ilẹ̀ mìíràn [Mẹ́gídò àti Hásórì].” Níwọ́n ìgbà tó ṣe kedere pé Bíbélì so ibi tí Jésíréélì wà mọ́ àkókò Áhábù, ó kà á sí ohun tó túbọ̀ bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àwọn àwókù wọ̀nyí fi hàn pé àkókò ìṣàkóso Áhábù ni ìlú yìí ti wà. David Ussishkin gbà pẹ̀lú èrò yìí nípa sísọ pé: “Bíbélì sọ pé Sólómọ́nì ló kọ́ Mẹ́gídò—kò sọ pé òun ló kọ́ àwọn ẹnubodè wọ̀nyẹn ní pàtó.”
Ǹjẹ́ A Lè Mọ Ìtàn Jésíréélì?
Ǹjẹ́ àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí wọ̀nyí àti awuyewuye tó ń lọ lọ́wọ́ kò mú kí a máa kọminú nípa àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Jésíréélì tàbí Sólómọ́nì báyìí? Ká sòótọ́, awuyewuye àwọn awalẹ̀pìtàn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àkọsílẹ̀ Bíbélì. Ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn máa ń gbé àyẹ̀wò ìtàn wọn kà yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ. Ó máa ń tọpinpin onírúurú ìbéèrè, ó sì máa ń tẹnu mọ́ ohun tó yàtọ̀. Ẹnì kan lè fi akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti awalẹ̀pìtàn wé àwọn arìnrìn àjò tó ń rìnrìn àjò lójú ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí kò bára mu. Ìkan ń wakọ̀ tirẹ̀ nínú ìgboro, èkejì ń rìn ní ọ̀nà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Ibi tí wọ́n ń wò àti àníyàn wọn yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà dípò kí ìrònú ìkan ta ko ti ìkejì, ńṣe ni wọ́n máa ń ranra wọn lọ́wọ́. Gbígbé èrò àwọn arìnrìn àjò méjèèjì yẹ̀ wò lè yọrí sí òye jíjinlẹ̀ tó fani mọ́ra.
Bíbélì ní àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìgbàanì àti àwọn ènìyàn ìgbà náà; àwọn awalẹ̀pìtàn ń gbìyànjú láti rí ìsọfúnni nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn ènìyàn náà nípa ṣíṣàyẹ̀wò ohunkóhun tí wọ́n bá tún lè rí wú jáde nípa wọn. Ṣùgbọ́n, nígbà míì, àwọn àwókù wọ̀nyí kì í jẹ́ odindi, onírúurú àlàyé làwọn èèyàn sì lè ṣe nípa wọn. Nípa èyí, nínú ìwé rẹ̀, Archaeology of the Land of the Bible—10,000−586 B.C.E., Amihai Mazar sọ pé: “Lọ́nà púpọ̀ iṣẹ́ ìwalẹ̀pìtàn . . . jẹ́ iṣẹ́ ọnà, ó sì tún jẹ́ pípa ẹ̀kọ́ pọ̀ mọ́ òye iṣẹ́. Kò sí ìlànà lílekoko kan tó lè mú un dáni lójú pé ẹnì kan yóò kẹ́sẹ járí, jíjẹ́ ẹni tó ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún àti ẹni tó lè fi ọpọlọ rẹ̀ gbé nǹkan kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀gá iṣẹ́ náà bá ti sọ jẹ́ ohun tó pọndandan. Bí ìwà, ẹ̀bùn, àti ọpọlọ awalẹ̀pìtàn kan ti ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ̀ rẹ̀ àti ohun èlò tó ní lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú.”
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti jẹ́rìí sí i pé ààfin pàtàkì kan àti ibùdó àwọn ológun ti wà ní Jésíréélì rí, ibùdó kan tó yani lẹ́nu pé ìgbà kúkúrú ló fi wà, ìyẹn ní àkókò tí ìtàn fi hàn pé ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìṣàkóso Áhábù—gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ń kọni lóminú la ti béèrè, èyí táwọn awalẹ̀pìtàn lè máa wádìí rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún tó ń bọ̀. Síbẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni Bíbélì, ń bá a lọ láti máa sọ̀rọ̀ ketekete, ó ń sọ ìtàn fún wa lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí àwalẹ̀pìtàn kò lè gbà gbé e kalẹ̀ láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Àṣírí-Ohun-Ìjìnlẹ̀ Àwọn Ibodè” nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1988.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ohun táwọn awalẹ̀pìtàn wú jáde ní Jésíréélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Òrìṣà àwọn ará Kénáánì táa rí ní Jésíréélì