Ìkórìíra Gbòde Kan
“Àwọn èèyàn ò lè mọ ìwà ẹni tí wọ́n bá kórìíra.”—JAMES RUSSELL LOWELL, ALÁRÒKỌ ÀTI AṢOJÚ ORÍLẸ̀-ÈDÈ.
Ó DÀ bí ẹni pé ìkórìíra yí wa ká lóde òní. Àwọn orúkọ àgbègbè bíi East Timor, Kosovo, Liberia, Littleton, àti Sarajevo—títí kan ẹgbẹ́ alátakò ìjọba Násì, àwọn afáríkodoro, àti àwọn tó gbà gbọ́ nínú kí funfun jẹ gàba lé dúdú lórí—ti di ohun tí ń gbé àwòrán burúkú tí kì í lọ bọ̀rọ̀ wá sọ́kàn wa títí kan ti àwọn àgbègbè tí wọ́n ti sun deérú, àwọn sàréè ẹlẹ́ni púpọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́, àti àwọn òkú.
Ìrètí táa ní nípa ọjọ́ ọ̀la kan tí kò ti ní sí ìkórìíra, ìforígbárí, àti ìwà ipá ti forí ṣánpọ́n. Danielle Mitterand, aya ààrẹ ilẹ̀ Faransé tẹ́lẹ̀, rántí ìgbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó ní: “Àwọn ènìyàn lérò pé àwọn ó máa rin fàlàlà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà táwọn lè fọkàn tán; pé ìbágbé àwọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn yóò wọ̀; wọ́n lérò pé àwọn óò ní ìlera, tí àwọn óò máa gbé ìgbésí ayé alálàáfíà àti iyì nínú ayé kan tó dúró sán-ún tó sì lẹ́mìí ọ̀làwọ́ tó ń bójú tó wọn.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn èrò wọ̀nyẹn? Obìnrin náà kédàárò pé: “Àádọ́ta ọdún lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo ibi tí a fojú sí, ọ̀nà ò gbabẹ̀ mọ́.”
Kò sí bí a ṣe lè gbójú fo ìkórìíra tó wà báyìí dá. Ó túbọ̀ ń tàn kálẹ̀ ni, ó sì túbọ̀ ń gogò sí i ṣáá ni. Ààbò ẹnì kọ̀ọ̀kan tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kò kà sí nǹkan kan tẹ́lẹ̀ ti di ohun tí wọ́n pàdánù, nítorí ìwà ìkà tí ìkórìíra ń fà, ìyẹn ìwà ìkà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan ń burú ju èyí tó ṣáájú rẹ̀ lọ. Ká tiẹ̀ sọ pé a bọ́ lọ́wọ́ ìkórìíra nínú ilé wa tàbí lórílẹ̀-èdè wa, ó tún ń dúró dè wá láwọn ibòmíràn. Ó ṣeé ṣe kí á máa rí ẹ̀rí rẹ̀ lójoojúmọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú ìròyìn àti àwọn ìkéde ọ̀rọ̀ tó ń lọ. Àwọn kan tiẹ̀ ti wọnú ọ̀nà táa ń gbà fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí kọ̀ǹpútà, èyí táa mọ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì pàápàá. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
Bí ọ̀ràn nípa ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti ká àwọn èèyàn lára ní ọ̀rúndún tó kọjá ti pọ̀ jù, àní a ò rírú ẹ̀ rí. Joseph S. Nye Kékeré, tó jẹ́ olùdarí Ibùdó fún Àwọn Àlámọ̀rí Gbogbo Orílẹ̀-Èdè, sọ pé: “Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni túbọ̀ ń peléke sí i láwọn ibi tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé, kò dín kù rárá. Dípò kí gbogbo ayé jẹ́ ọ̀kan, ṣe ló pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ tí wọ́n sì ń fura sí ara wọn. Ìyẹn gan-an ló wá ń jẹ́ kí ìforígbárí túbọ̀ máa pọ̀ sí i.”
Ìkórìíra mìíràn tún wà tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ ju ìyẹn lọ, tó jẹ́ pé àárín orílẹ̀-èdè kan náà tàbí àárín àdúgbò kan náà pàápàá ló ti ń jà ràn-ìn. Nígbà tí àwọn afáríkodoro márùn-ún pa baba arúgbó ẹlẹ́sìn Sikh kan ní Kánádà, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí “wá jẹ́ ká mọ ohun táwọn kan ń sọ, pé àwọn ìwà ọ̀daràn tí ìkórìíra ń fà tún ti bẹ̀rẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kan táa sábà máa ń yìn fún rírí tí ó rí ara gba ẹ̀yà mìíràn mọ́ra tẹ́lẹ̀.” Ní Jámánì, lẹ́yìn tí ìkórìíra ti dín kù léraléra ní àwọn ọdún tó ti kọjá, àwọn aláṣerégèé tí wọ́n ń dojú ìjà kọ àwọn ẹ̀yà mìíràn tún jẹ́ kó lọ sókè ní ìpín mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ní 1997. Manfred Kanther, tó jẹ́ Mínísítà Ọ̀ràn Abẹ́lé sọ pé: “Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́ gbáà ni.”
Ní àríwá Albania, ìròyìn kan fi hàn pé àwọn ọmọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ẹlẹ́wọ̀n nínú ilé ara wọn nítorí ìbẹ̀rù pé àwọn tó jẹ́ ọ̀tá ìdílé wọn lè yìnbọn pa àwọ́n. Aáwọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, “tó ti ba ìgbésí ayé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdílé jẹ́” làwọn ọmọ wọ̀nyí ń jìyà rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ (FBI) sọ, “ẹ̀tanú kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló ṣokùnfà èyí tí ó ju ìdajì nínú ẹgbẹ̀rún méje, ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti márùndínlọ́gọ́ta [7,755] ìkórìíra oníwà ipá tí wọ́n ròyìn fún Ẹ̀ka Iṣẹ́ náà pé àwọn ènìyàn hù ní ọdún 1998” ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn nǹkan bíi mélòó kan tó fa ìyókù ìkórìíra oníwà ipá náà ni ẹ̀tanú ìsìn, ti ẹ̀yà tàbí ti orílẹ̀-èdè tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ti wá, àti àwọn àìtóótun kan.
Ní àfikún sí i, àwọn àkọlé tí a ń rí nínú àwọn ìwé ìròyìn lójoojúmọ́ ń tọ́ka sí ẹ̀mí àìfẹ́ rí àjèjì sójú, tó sì jẹ́ pé àwọn olùwá-ibi-ìsádi ló máa ń forí fá ìyẹn jù lọ, ìyẹn àwọn tí iye wọn ti pọ̀ kọjá mílíọ̀nù mọ́kànlélógún báyìí. Ó ṣeni láàánú pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó ń fi ìkórìíra hàn sí àwọn àjèjì ni àwọn ọ̀dọ́, tí àwọn òṣèlú tí kò ní láárí àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń wá ẹni tí wọ́n máa yí ọ̀ràn lé lórí ń ki láyà. Àwọn àmì mìíràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta nípa ọ̀ràn kan náà yìí ni èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àìní ìgbẹ́kẹ̀lé, àìráragba-nǹkan-sí, àti níní èrò kan pàtó nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n yàtọ̀.
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó fa ìkórìíra tó gbòde kan yìí? Kí la sì lè ṣe láti mú ìkórìíra kúrò pátápátá? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀yìn, lókè: FỌ́TÒ UN 186705/J. Isaac
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Daud/Sipa Press