ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 12/15 ojú ìwé 30
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣíṣiṣẹ́ Nínú “Pápá” Ṣáájú Ìkórè
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Ẹ Jẹ́ Ká Fi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Wé Ara Wọn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • “Àwọn Àkókò Ìmúpadàbọ̀sípò” Ti Kù sí Dẹ̀dẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 12/15 ojú ìwé 30

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ǹjẹ́ o mọrírì kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

• Kí ló ṣe pàtàkì báa bá fẹ́ yanjú aáwọ̀ táa ní pẹ̀lú ẹnì kan?

Ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń ní èrò òdì àti ìṣarasíhùwà tí kò dára. Lẹ́yìn náà a gbọ́dọ̀ gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò dáadáa ká lè mọ̀ bóyá àwa gan-an la fa aáwọ̀ náà dípò ẹni yẹn.—8/15, ojú ìwé 23.

• Ìgbà wo ni “àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò ohun gbogbo,” táa mẹ́nu kàn nínú Ìṣe 3:21 yóò jẹ́?

Ìmúpadàbọ̀sípò náà yóò wá ní ipele méjì. Ipele àkọ́kọ́ tó jẹ́ ìmúpadàbọ̀sípò sínú párádísè tẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919. Ìmúpadàbọ̀sípò mìíràn yóò tún wáyé nígbà tí ilẹ́ ayé wa bá di Párádísè kan tí a lè fojú rí.—9/1, ojú ìwé 17, 18.

• Báwo ni eèrà kò ṣe ní olùdarí, gẹ́gẹ́ báa ti kíyè sí i nínú Òwe 6:6-8, síbẹ̀ tó sì ń pèsè àpẹẹrẹ rere fún wa?

Nínú agbo eèrà kan, ọbabìnrin wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n ó kàn jẹ́ ọbabìnrin kìkì nítorí pé ó ń yé ẹyin, àti pé òun ni ìyá agbo náà ni. Àwọn eèrà jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, bó sì ṣe yẹ kí àwa náà jẹ́ nìyẹn, ká gbìyànjú láti mú kí iṣẹ́ wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i, kódà bi wọn ò tiẹ̀ ṣọ́ wa pàápàá.—9/15, ojú ìwé 26.

• Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Húlídà, gẹ́gẹ́ báa ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú 2 Àwọn Ọba 22:20 pé Jòsáyà yóò kú “ní àlàáfíà,” rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ńṣe ló gbọgbẹ́ lójú ogun tó fi kú?

Bẹ́ẹ̀ ni, ó kú ní àlàáfíà ní ti pé ó kú kí àjálù náà tó ṣẹlẹ̀ ní 609 sí 607 ṣááju Sànmánì Tiwa tóó wáyé, nígbà tí àwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì pa á run.—9/15, ojú ìwé 30.

• Báwo ló ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀ àpọ́nlé ni Sólómọ́nì ń sọ nígbà tó ṣàpèjúwe aya kan gẹ́gẹ́ bí “egbin dídára lẹ́wà àti ewúrẹ́ olóòfà ẹwà ti orí òkè ńlá”? (Òwe 5:18, 19)

Abo ewúrẹ́ ẹgàn, tàbí ewúrẹ́ orí òkè ńlá, ní ìwà jẹ́jẹ́ àti ìṣesí ẹlẹ́wà. Síbẹ̀, ó lè fara da ìyà, kó sì bímọ sí àwọn ibi olókùúta, láwọn ibi tí kò ṣeé dé tí oúnjẹ ti lè ṣòro láti rí.— 10/1, ojú ìwé 30, 31.

• Àwọn wo ni Henry Grew àti George Storrs?

Àwọn ọkùnrin méjì wọ̀nyí gbé ayé ní àwọn ọdún 1800, wọ́n sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onílàákàyè. Grew kẹ́kọ̀ọ́ pé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan kò bá Ìwé Mímọ́ mu, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn, àti ti iná ọ̀run àpáàdì. Storrs fòye mọ̀ pé àwọn kan yóò gbádùn ìwàláàyè tí kò lópin lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn méjèèjì jẹ́ aṣáájú fún Charles Taze Russell, ẹni tó bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde ní 1879.—10/15, ojú ìwé 26 sí 30.

• Ojú wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wo àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tó ní lílo ẹ̀jẹ̀ ara ẹni nínú?

Nítorí tí wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn karí Bíbélì, wọn kì í tọ́jú ẹ̀jẹ̀ ara wọn pa mọ́, kí wọ́n sì wá gbà á bí ìfàjẹ̀sínilára níkẹyìn. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló ń fúnra rẹ̀ pinnu ọ̀nà tó fẹ́ kí wọ́n gbà lo ẹ̀jẹ̀ òun lásìkò iṣẹ́ abẹ, àyẹ̀wò ìṣègùn, tàbí ìtọ́jú lọ́ọ́lọ́ọ́ kan. Ó gbọ́dọ̀ gbé ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀jẹ̀ yẹ̀ wò, kó sì rántí pé òun tí ya ara òun sí mímọ́ pátápátá fún Ọlọ́run.—10/15, ojú ìwé 30, 31.

• Kí ni ohun pàtàkì tí ìwádìí kan táa ṣe níbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílò kárí ayé?

A nílò ohun tó lé ni ẹgbẹ̀rún mọ́kànlá [11,000] Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, níbi tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Ọrẹ látọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni tó wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè là ń ná láti ṣèrànwọ́ fún kíkọ́ àwọn ibi ìpàdé tó bójú mu.—11/1, ojú ìwé 30.

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ inú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ táa lò nínú Bíbélì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn?

Ọ̀kan ni lei·tour·giʹa, tí a túmọ̀ sí “iṣẹ́ ìsìn fún gbogbo ènìyàn.” Òmíràn ni la·treiʹa, tí a túmọ̀ sí “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.” (Hébérù 10:11; Lúùkù 2:36, 37)—11/15, ojú ìwé 11, 12.

• Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè kọ́ látinú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Ádámù àti Éfà?

Ó jẹ́ ká mọ̀ pé ìwà arìndìn lásánlàsàn ló jẹ́ láti máa dọ́gbọ́n wá òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run.—11/15, ojú ìwé 24 sí 27.

• Ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ wo ló fi hàn pé Ọlọ́run ń fi agbára fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀?

Dáfídì, Hábákúkù, àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pèsè àwọn ẹ̀rí ti ara wọn tó fi kókó náà hàn pé Jèhófà Ọlọ́run fún wọn ní agbára. (Sáàmù 60:12; Hábákúkù 3:19; Fílípì 4:13) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run múra tán láti fún wa lókun, ó sì lè ṣe bẹ́ẹ̀.—12/1, ojú ìwé 10, 11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́