Àjíǹde Jésù Wà Lábẹ́ Àyẹ̀wò Fínnífínní
“Kí n kúkú sojú abẹ níkòó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dá wa lójú gbangba pé Jésù gbé ayé rí . . . , kò fi bẹ́ẹ̀ dá wa lójú pé Ọlọ́run gbé E dìde kúrò nínú òkú.” Olórí Ìjọ Áńgílíkà, ìyẹn Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti Canterbury, ló sọ bẹ́ẹ̀.
KRISTẸNI àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò ṣe irú iyèméjì bẹ́ẹ̀ rárá. Ní orí kẹẹ̀ẹ́dógún lẹ́tà onímìísí tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nílùú Kọ́ríńtì ìgbàanì, ó kọ̀wé pé: “Nítorí mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.”—1 Kọ́ríńtì 15:3, 4.
Ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde Jésù Kristi ló sún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn rere náà jákèjádò gbogbo àgbègbè ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù—àní “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kólósè 1:23) Dájúdájú, àjíǹde Jésù ni òpómúléró ẹ̀sìn Kristẹni.
Àmọ́ o, láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá làwọn kan ti ń ṣiyèméjì, tí wọ́n sì ń kọminú sí àjíǹde Jésù. Lójú àwọn Júù lápapọ̀, ọ̀rọ̀ òdì gbáà lọ̀rọ̀ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń sọ pé ọkùnrin tí wọ́n kàn mọ́gi yẹn ni Mèsáyà. Ọ̀rọ̀ àjíǹde ò sì tà rárá létí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Gíríìkì, torí pé àìleèkú ọkàn ni wọ́n gbà gbọ́.—Ìṣe 17:32-34.
Àwọn Oníyèmejì Òde Òní
Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni ti tẹ àwọn ìwé àti àpilẹ̀kọ kan jáde tó ń sọ pé ìtàn àròsọ lásán ni àjíǹde Jésù jẹ́, wọ́n sì ti dá àríyànjiyàn tó gbóná sílẹ̀ lórí kókó yìí. Onírúurú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wọ̀nyí tó sọ pé àwọn ń wá “òótọ́ nípa Jésù inú ìtàn” kiri, sọ pé àwọn ti rí i wàyí pé ìtàn àròsọ pọ́ńbélé làwọn ìròyìn inú Ìwé Ìhìn Rere tó sọ̀rọ̀ nípa sàréè tó ṣófo àti àwọn ìfarahàn Jésù lẹ́yìn àjíǹde. Wọ́n ní ó ti kú tipẹ́ káwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ tó wá gbé ìtàn wọ̀nyí jókòó, láti lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn pé ó ní agbára àtọ̀runwá.
Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbọ́ èrò ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Jámánì náà, Gerd Lüdemann, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nípa Májẹ̀mú Tuntun, ẹni tó ṣe ìwé náà, What Really Happened to Jesus—A Historical Approach to the Resurrection. Ó sọ pé “ọ̀rọ̀ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ rárá” lọ̀rọ̀ àjíǹde Jésù, ó ní kò yẹ kí ẹnikẹ́ni tó bá ní “ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ayé yìí” ṣú já a.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Lüdemann sọ pé ìran lásán ni ohun tí àpọ́sítélì Pétérù rí, tó pè ní Jésù tó ti jíǹde. Ó ní ìdí tí Pétérù sì fi ríran yìí kò ju pé ó ní ẹ̀dùn ọkàn ńláǹlà àti pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ń nà án ní pàṣán nítorí sísẹ́ tó sẹ́ Jésù. Ní ti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] àwọn onígbàgbọ́ tí Bíbélì sọ pé Jésù fara hàn lẹ́ẹ̀kan náà, Lüdemann sọ pé “múyèmúyè ló mú gbogbo wọn.” (1 Kọ́ríńtì 15:5, 6) Ká má fọ̀rọ̀ gùn, ojú tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ fi ń wo àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Jésù tí a jí dìde kò yàtọ̀ sáwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣẹlẹ̀ lójú àlá, tó wá ta àwọn ọmọ ẹ̀yìn jí nípa tẹ̀mí, tó sì fi kún ìtara wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.
Lóòótọ́, a mọ̀ pé ṣàṣà làwọn tó ráyè fífa ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde Jésù kan gbogbo wa. Èé ṣe? Nítorí pé, bó bá ṣe pé kò jíǹde ni, á jẹ́ pé orí èké la gbé ẹ̀sìn Kristẹni kà. Àmọ́, bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni Jésù jíǹde, á jẹ́ pé orí òtítọ́ la gbé ẹ̀sìn Kristẹni kà. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, á jẹ́ pé kì í ṣe kìkì pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tí Kristi sọ nìkan ni, àní àwọn ìlérí rẹ̀ pẹ̀lú kò ní ṣaláìṣẹ. Síwájú sí i, bí àjíǹde bá wà lóòótọ́, á jẹ́ pé ikú kì í ṣe ajagunmólú, bí kò ṣe ọ̀tá táa lè borí.—1 Kọ́ríńtì 15:55.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Látinú ìwé Self-Pronouncing Edition of the Holy Bible, tó ní ẹ̀dà King James àti ẹ̀dà Revised nínú