ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w14 11/15 ojú ìwé 3-7
  • Àjíǹde Jésù—Àǹfààní Wo Ló Ṣe Wá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àjíǹde Jésù—Àǹfààní Wo Ló Ṣe Wá?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ ÀJÍǸDE JÉSÙ FI ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀
  • JÈHÓFÀ FI HÀN PÉ ÒUN NÍ AGBÁRA LÓRÍ IKÚ
  • ÌDÍ TÁ A FI GBÀ PÉ ỌLỌ́RUN JÍ JÉSÙ DÌDE
  • ÀǸFÀÀNÍ TÍ ÀJÍǸDE JÉSÙ ṢE WÁ
  • Àjíǹde Dájú!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Ṣé Òótọ́ Ni Pé Jésù Jíǹde?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • “Mo Ní Ìrètí Sọ́dọ̀ Ọlọ́run”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ìrètí Àjíǹde Lágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
w14 11/15 ojú ìwé 3-7

Àjíǹde Jésù​—Àǹfààní Wo Ló Ṣe Wá?

“A ti gbé e dìde.”​—MÁT. 28:6.

ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?

  • Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe yàtọ̀ sí àwọn àjíǹde tó wáyé ṣáájú tirẹ̀?

  • Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Ọlọ́run jí Jésù dìde àti pé ó wà láàyè lónìí?

  • Àǹfààní wo ni àjíǹde Jésù ṣe ẹ́?

1, 2. (a) Kí ni àwọn aṣáájú ìsìn kan fẹ́ mọ̀, báwo sì ni Pétérù ṣe dá wọn lóhùn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Kí ló fún Pétérù ní ìgboyà láti sọ̀rọ̀ nígbà tó wà níwájú wọn?

KÒ TÍÌ pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Jésù kú, wọ́n mú àpọ́sítélì Pétérù wá sáàárín àwùjọ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ àkòtagìrì àti òǹrorò. Àwọn aṣáájú ìsìn Júù táwọn èèyàn ń wárí fún ni wọ́n, àwọn ló sì ṣe okùnfà ikú Jésù. Ní báyìí, wọ́n ní kí Pétérù sọ tẹnu ẹ̀. Àwọn aṣáájú ìsìn náà fẹ́ mọ agbára tí Pétérù lò tàbí orúkọ ẹni tó fi ṣe ìwòsàn ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní arọ. Àpọ́sítélì náà fìgboyà dá wọn lóhùn pé: “Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì, ẹni tí ẹ̀yin kàn mọ́gi ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run gbé dìde kúrò nínú òkú, nípasẹ̀ ẹni yìí ni ọkùnrin yìí fi dúró níhìn-ín pẹ̀lú ara dídá níwájú yín.”—Ìṣe 4:5-10.

2 Ṣáájú ìgbà yẹn, ìbẹ̀rù ti mú kí Pétérù sẹ́ Jésù nígbà mẹ́ta. (Máàkù 14:66-72) Ní báyìí tó wà níwájú àwọn aṣáájú ìsìn yẹn, kí ló fún un ní ìgboyà? Ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ ló mú kí Pétérù nígboyà àmọ́, mímọ̀ tó mọ̀ pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde tún ràn án lọ́wọ́. Kí ló mú kó dá àpọ́sítélì náà lójú tó bẹ́ẹ̀ pé Jésù wà láàyè? Kí ló sì mú kó dá àwa náà lójú?

3, 4. (a) Àwọn àjíǹde wo ló wáyé kí wọ́n tó bí àwọn àpọ́sítélì Jésù? (b) Àwọn wo ni Jésù jí dìde?

3 Kì í ṣe ohun tuntun lójú àwọn àpọ́sítélì Jésù pé àwọn òkú lè jíǹde torí pé àwọn àjíǹde kan ti wáyé kí wọ́n tó bí wọn. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run fún wòlíì Èlíjà àti Èlíṣà lágbára láti ṣe irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀. (1 Ọba 17:17-24; 2 Ọba 4:32-37) Wọ́n sì tún mọ̀ pé ọkùnrin kan jíǹde nígbà tí wọ́n ju òkú rẹ̀ sínú ibojì Èlíṣà tí ara rẹ̀ sì kan egungun wòlíì náà. (2 Ọba 13:20, 21) Àwọn Kristẹni ìgbàanì gba àwọn àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ yìí gbọ́ bí àwa náà ṣe gbà gbọ́ pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

4 Kò sí àní-àní pé ó máa ń wọ̀ wá lọ́kàn gan-an tá a bá kà nípa àwọn tí Jésù jí dìde. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó jí ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí opó kan bí dìde, ó jọ obìnrin náà lójú gan-an. (Lúùkù 7:11-15) Ìgbà kan tún wà tí Jésù jí ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìlá kan dìde. Ẹ wo bí inú àwọn òbí tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yìí ṣe dùn tó tí ẹnu sì yà wọ́n nígbà tí Jésù jí ọmọ wọn dìde! (Lúùkù 8:49-56) Ẹ sì wo bí inú àwọn tó rí Lásárù á ṣe dùn tó nígbà tó ń jáde bọ̀ látinú ibojì tí ara rẹ̀ sì dá ṣáṣá!—Jòh. 11:38-44.

ÌDÍ TÍ ÀJÍǸDE JÉSÙ FI ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀

5. Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe yàtọ̀ sí àwọn àjíǹde tó wáyé ṣáájú tirẹ̀?

5 Àwọn àpọ́sítélì mọ̀ pé àjíǹde Jésù yàtọ̀ sí àwọn àjíǹde tó wáyé ṣáájú tirẹ̀. A jí àwọn èèyàn yẹn dìde nígbà yẹn ní ara ìyára, wọ́n sì tún kú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Àmọ́, a jí Jésù dìde ní ara ti ẹ̀mí tí kò lè díbàjẹ́. (Ka Ìṣe 13:34.) Pétérù sọ pé Jésù jẹ́ ẹni tí “a fi ikú pa nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.” Síwájú sí i, “ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, nítorí tí ó bá ọ̀nà rẹ̀ lọ sí ọ̀run; a sì fi àwọn áńgẹ́lì àti àwọn aláṣẹ àti àwọn agbára sábẹ́ rẹ̀.” (1 Pét. 3:18-22) Ohun àgbàyanu ni àwọn àjíǹde tó wáyé ṣáájú àjíǹde Jésù jẹ́, iṣẹ́ ìyanu sì ni wọ́n, àmọ́ àjíǹde Jésù jẹ́ iṣẹ́ ìyanu tó ju gbogbo wọn lọ.

6. Ipa wo ni àjíǹde Jésù ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

6 Àjíǹde Jésù ní ipa tó jinlẹ̀ lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Kì í ṣe òkú mọ́ bí àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe gbà pé ó jẹ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ pé ó ti jíǹde, ó sì ti di ẹ̀mí alágbára tí èèyàn kankan ò lè pa lára. Àjíǹde Jésù fi hàn pé Ọmọ Ọlọ́run ni. Mímọ̀ tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ kí wọ́n banú jẹ́ mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń yọ̀ gidigidi. Síwájú sí i, wọn ò bẹ̀rù mọ́, wọ́n di onígboyà. Ipa pàtàkì ni ọ̀rọ̀ àjíǹde Jésù kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ àti nínú ìhìn rere tí wọ́n fìgboyà wàásù rẹ̀ níbi gbogbo.

7. Kí ni Jésù ń ṣe lónìí, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

7 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ dáadáa pé Jésù kì í ṣe ẹni ńlá nìkan, àmọ́ ó tún wà láàyè lónìí, ó sì ń darí iṣẹ́ kan tó kan gbogbo èèyàn tó wà láyé. Torí pé Jésù Kristi ni Ọba tó ń ṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run, ó máa tó fọ ayé yìí mọ́, yóò sì sọ ayé di Párádísè tí àwọn èèyàn á máa gbé inú rẹ̀ títí láé. (Lúùkù 23:43) Gbogbo èyí ò ní ṣeé ṣe bí Jésù ò bá jíǹde. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìdí wo ló wà tá a fi gbà pé Ọlọ́run jí Jésù dìde? Àǹfààní wo sì ni àjíǹde rẹ̀ ṣe wá?

JÈHÓFÀ FI HÀN PÉ ÒUN NÍ AGBÁRA LÓRÍ IKÚ

8, 9. (a) Kí nìdí tí àwọn aṣáájú ìsìn Júù fi sọ pé kí wọ́n sé sàréè Jésù mọ́? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn obìnrin wá sí ibojì Jésù?

8 Lẹ́yìn tí wọn pa Jésù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí lọ sọ́dọ̀ Pílátù wọ́n sì sọ fún un pé: “Ọ̀gá, àwa ti rántí pé afàwọ̀rajà yẹn sọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, a óò gbé mi dìde.’ Nítorí náà, pàṣẹ kí a sé sàréè náà mọ́ títí di ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa wá, kí wọ́n jí i gbé, kí wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé, ‘A ti gbé e dìde kúrò nínú òkú!’ Ìfàwọ̀rajà ìkẹyìn yìí yóò sì burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.” Pílátù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ní ẹ̀ṣọ́. Ẹ lọ sé e mọ́ dé àyè ibi tí ẹ bá lè ṣe é dé.” Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn.—Mát. 27:62-66.

9 Ibojì kan tí wọ́n gbẹ́ sínú àpáta ni wọ́n gbé òkú Jésù sí, wọ́n wá gbé òkúta ńlá kan dí ẹnu ihò náà. Inú ibojì yẹn làwọn aṣáájú ìsìn Júù fẹ́ kí Jésù máa wà títí gbére, kó sì jẹrà síbẹ̀. Àmọ́, ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn yàtọ̀ pátápátá sí tiwọn. Nígbà tí Màríà Magidalénì àti Màríà kejì dé ibojì náà ní ọjọ́ kẹta, wọ́n rí i ti òkúta náà ti yí kúrò lẹ́nu ibojì, wọ́n sì rí áńgẹ́lì kan tó jókòó lórí òkúta náà. Áńgẹ́lì náà sọ fún àwọn obìnrin náà pé kí wọ́n yọjú wo inú ibojì náà, wọ́n á sì rí i pé ó ti ṣófo. Áńgẹ́lì náà sọ fún wọn pé: “Kò sí níhìn-ín, nítorí a ti gbé e dìde.” (Mát. 28:1-6) Ẹ ò rí nǹkan, Jésù ti jíǹde!

10. Ẹ̀rí wo ni Pọ́ọ̀lù mú wa pé Jésù ti jíǹde?

10 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn náà mú kó ṣe kedere pé Jésù ti jíǹde. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń ṣe àkópọ̀ àwọn ẹ̀rí náà sínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó ní: “Nítorí mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé ó fara han Kéfà, lẹ́yìn náà, àwọn méjìlá náà. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, púpọ̀ jù lọ nínú àwọn tí wọ́n ṣì wà títí di ìsinsìnyí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn nínú ikú. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fara han Jákọ́bù, lẹ́yìn náà, gbogbo àpọ́sítélì; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn gbogbo rẹ̀, ó fara han èmi pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a bí ní kògbókògbó.”—1 Kọ́r. 15:3-8.

ÌDÍ TÁ A FI GBÀ PÉ ỌLỌ́RUN JÍ JÉSÙ DÌDE

11. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù jíǹde “gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí”?

11 Ìdí àkọ́kọ́ tá a fi gbà pé Ọlọ́run jí Jésù dìde ni pé àjíǹde rẹ̀ wáyé “gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ó máa jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì sọ pé Ọlọ́run kò ní fi olórí “ẹni ìdúróṣinṣin” rẹ̀ sílẹ̀ nínú Ṣìọ́ọ̀lù tàbí sàréè. (Ka Sáàmù 16:10.) Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣẹ sí Jésù lára, ó ní: “[Dáfídì] rí i tẹ́lẹ̀, ó sì sọ nípa àjíǹde Kristi, pé a kò ṣá a tì sínú Hédíìsì, bẹ́ẹ̀ ni ẹran ara rẹ̀ kò rí ìdíbàjẹ́.”—Ìṣe 2:23-27, 31.

12. Àwọn wo ló rí Jésù lẹ́yìn tí Ọlọ́run jí i dìde?

12 Ìdí kejì tá a fi gbà pé Ọlọ́run jí Jésù dìde ni pé àwọn èèyàn púpọ̀ ló jẹ́rìí sí i. Jálẹ̀ ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ọgbà tí ibojì náà wà àti lójú ọ̀nà tó lọ sí Ẹ́máọ́sì àti níbòmíràn. (Lúùkù 24:13-15) Láwọn ìgbà yẹn, ó bá àwọn èèyàn kan sọ̀rọ̀, títí kan Pétérù àtàwọn èèyàn ní àwùjọ-àwùjọ. Kódà, Jésù tí Ọlọ́run jí dìde náà tún fara han àwọn èèyàn tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] lọ! Ẹ̀rí àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ kò ṣeé kó dà nù.

13. Báwo ni ìtara àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe fi hàn pé ó dá wọn lójú pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde?

13 Ìdí kẹta tá a fi gbà pé Ọlọ́run jí Jésù dìde ni ìtara tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi polongo àjíǹde rẹ̀. Torí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi ìtara jẹ́rìí nípa àjíǹde Kristi, wọ́n dojú kọ inúnibíni, ìjìyà àti ikú. Bí Ọlọ́run ò bá jí Jésù dìde, àní tó bá jẹ́ pé ẹ̀tàn ni, kí nìdí tí Pétérù fi máa fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu torí kó lè polongo àjíǹde Kristi fún àwọn aṣáájú ìsìn tí wọ́n kórìíra Jésù tí wọ́n sì gbìmọ̀ pa á? Ìdí ni pé ó dá Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù lójú pé Jésù ti jíǹde, ó sì ń darí iṣẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe. Síwájú sí i, àjíǹde Jésù mú kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé àwọn náà máa jíǹde. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí Sítéfánù sọ bó ṣe ń kú lọ jẹ́ ká mọ̀ pé ó dá a lójú pé àjíǹde òkú máa wà.—Ìṣe 7:55-60.

14. Kí nìdí tó o fi gbà pé Jésù wà láàyè?

14 Ìdí kẹrin tá a fi gbà pé Ọlọ́run jí Jésù dìde ni pé a rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ti di Ọba tó ń ṣàkóso báyìí àti pé òun ni Orí ìjọ Kristẹni. Ìdí rèé tí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ fi ń gbèrú. Ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀ bí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run ti jí Jésù dìde? Ká sòótọ́, ó ṣeé ṣe ká má tiẹ̀ gbọ́ nípa Jésù rárá bí kì í bá ṣe pé Ọlọ́run jí i dìde ni. Àmọ́, ó dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Jésù jíǹde àti pé ní báyìí, ó ń ṣamọ̀nà wa ó sì ń darí wa bá a ṣe ń polongo ìhìn rere níbi gbogbo.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ ÀJÍǸDE JÉSÙ ṢE WÁ

15. Kí nìdí tí àjíǹde Jésù fi mú ká máa fìgboyà wàásù?

15 Àjíǹde Kristi mú ká máa fìgboyà wàásù. Ó ti tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì [2,000] báyìí tí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ti ń lo onírúurú ohun ìjà láti dá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà dúró, wọ́n ti lo ìpẹ̀yìndà, ìfiṣẹ̀sín, àwọn jàǹdùkú, ìwà ipá, ifòfindè, ìdálóró àti ìṣekúpani. Síbẹ̀, kò sí ‘ohun ìjà yòówù tí wọ́n ṣe sí wa’ tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn dúró. (Aísá. 54:17) A ò bẹ̀rù àwọn ìránṣẹ́ Sátánì. Jésù wà pẹ̀lú wa, ó sì ń tì wá lẹ́yìn bó ṣe ṣèlérí pé òun máa ṣe. (Mát. 28:20) Kò sídìí tó fi yẹ ká bẹ̀rù, torí pé bó ti wù kí àwọn ọ̀tá wa gbógun tó, wọn ò ní lè pa wá lẹ́nu mọ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àjíǹde Jésù mú ká máa fìgboyà wàásù(Wo ìpínrọ̀ 15)

16, 17. (a) Báwo ni àjíǹde ṣe fìdí ohun tí Jésù kọ́ni múlẹ̀? (b) Gẹ́gẹ́ bí Jòhánù 11:25 ti sọ, agbára wo ni Ọlọ́run fún Jésù?

16 Àjíǹde Jésù fìdí gbogbo ohun tó kọ́ni múlẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé bí Kristi kò bá jíǹde a jẹ́ pé asán ni ìgbàgbọ́ àwa Kristẹni àti iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì sọ pé: “Bí Kristi kò bá jíǹde, . . . a jẹ́ pé àwọn Kristẹni jẹ́ òpè èèyàn tá à ń káàánú fún, tí wọ́n tún wá kó sọ́wọ́ baba ńlá ẹlẹ̀tàn.” Bí Jésù ò bá jíǹde, ńṣe nìyẹn á mú kí àkọsílẹ̀ inú ìwé Ìhìn Rere di ìtàn ìbànújẹ́ nípa ọkùnrin ọlọgbọ́n kan tó ń ṣe rere, tí àwọn ọ̀tá rẹ̀ wá ṣekú pa á lẹ́yìn náà. Àmọ́ Kristi jíǹde, ìyẹn sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni gbogbo ohun tó kọ́ni, títí kan ohun tó sọ nípa ọjọ́ iwájú.—Ka 1 Kọ́ríńtì 15:14, 15, 20.

17 Jésù sọ pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.” (Jòh. 11:25) Ọ̀rọ̀ tó kàmàmà yìí máa ṣẹ láìkùnà. Kì í ṣe àwọn tó máa jíǹde sí ìyè tẹ̀mí lọ́run nìkan ni Jèhófà fún Jésù lágbára láti jí dìde, àmọ́ yóò tún jí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn dìde, ìyẹn àwọn tí wọ́n nírètí láti gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Ẹbọ Jésù tó ń ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ àti àjíǹde rẹ̀ ló mú kó dájú pé ikú kò ní sí mọ́. Ǹjẹ́ ohun tá a mọ̀ yìí kò fún wa lókun láti máa fara da àdánwò èyíkéyìí, ká sì dojú kọ ikú láìbẹ̀rù?

18. Kí ni àjíǹde Jésù mú kó dáni lójú?

18 Àjíǹde Jésù mú kó dá wa lójú pé àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà la máa fi ṣèdájọ́ àwọn olùgbé ayé. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwùjọ àwọn ọkùnrin àti obìnrin sọ̀rọ̀ ní ìlú Áténì ìgbàanì, ó ní: “[Ọlọ́run] ti dá ọjọ́ kan nínú èyí tí ó pète láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé tí a ń gbé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí ó ti yàn sípò, ó sì ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:31) Ó dájú pé Jésù ni Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn, ó sì dá wa lójú pé kò ní ṣègbè, ìfẹ́ ni yóò sì máa fi ṣèdájọ́.—Ka Aísáyà 11:2-4.

19. Kí ni gbígbà tá a gbà pé Kristi jíǹde mú ká ṣe?

19 Gbígbà tá a gbà pé Jésù jíǹde mú ká máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Bí kì í bá ṣe ti ikú ìrúbọ tí Jésù kú àti àjíǹde rẹ̀ ni, a kì bá tí bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Bí Ọlọ́run kò bá jí Jésù dìde ni, ó ṣeé ṣe kí àwa náà máa sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí a sì máa mu, nítorí ọ̀la ni àwa yóò kú.” (1 Kọ́r. 15:32) Àmọ́, a kò lépa adùn ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, a mọyì ìrètí àjíǹde tá a ní, ó sì yé wa dáadáa pé ó yẹ ká máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà nínú ohun gbogbo.

20. Báwo ni àjíǹde Jésù ṣe fi hàn pé òótọ́ ni Ọlọ́run tóbi lọ́ba?

20 Àjíǹde Kristi tó ṣẹlẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà tóbi lọ́ba, àti pé “òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Héb. 11:6) Ẹ wo bí agbára àti ọgbọ́n tí Jèhófà lò ṣe pọ̀ tó bó ṣe jí Jésù dìde sí ìyè àìleèkú ní ọ̀run! Síwájú sí i, Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun lágbára láti mú gbogbo ìlérí òun ṣẹ. Lára àwọn ìlérí náà ni àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run pé “irú-ọmọ” pàtàkì kan máa kó ipa pàtàkì nínú yíyanjú ọ̀ràn ẹni tó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tó lè ṣẹ, ó pọn dandan pé kí Jésù kú kí Ọlọ́run sì jí i dìde.—Jẹ́n. 3:15.

21. Àǹfààní wo ni ìrètí àjíǹde ṣe ẹ́?

21 Ǹjẹ́ o kì í dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó mú ká ní ìrètí pé àjíǹde máa wà? Ìwé Mímọ́ mú kó dá wa lójú pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Ìrètí àgbàyanu yẹn la sọ fún àpọ́sítélì Jòhánù adúróṣinṣin. A tún sọ fún un pé: “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.” Ọ̀dọ̀ ta ni Jòhánù ti rí ìṣípayá tó ní ìmísí yìí gbà? Ọ̀dọ̀ Jésù Kristi tó ti jíǹde ló ti rí i gbà.—Ìṣí. 1:1; 21:3-5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́