“Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ń Bá A Lọ Ní Gbígbilẹ̀”
“Ó ń fi àsọjáde rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé; ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré.”—SÁÀMÙ 147:15.
1, 2. Iṣẹ́ wo ni Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́, kí ló sì wé mọ́ ọn?
Ọ̀KAN lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó tayọ jù lọ nínú Bíbélì ni èyí tó wà nínú Ìṣe 1:8. Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jésù gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ bàǹtàbanta lèyí máa jẹ́!
2 Láti pòkìkí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run káàkiri ayé ti ní láti jẹ́ iṣẹ́ kan tó fakíki fún ìwọ̀nba kéréje àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó fiṣẹ́ lé lọ́wọ́ nígbà yẹn. Gbé ohun tó wé mọ́ ọn yẹ̀ wò. Wọ́n ní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Jíjẹ́rìí nípa Jésù tún béèrè pé kí wọ́n máa fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí wọ́n sì máa ṣàlàyé ipa tó kó nínú ète Jèhófà. Síwájú sí i, iṣẹ́ náà ní sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn nínú, kí wọ́n sì máa batisí wọn. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe èyí jákèjádò ayé!—Mátíù 28:19, 20.
3. Kí ni Jésù mú dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú, ọwọ́ wo ni wọ́n sì fi mú iṣẹ́ táa gbé lé wọn lọ́wọ́?
3 Àmọ́, Jésù mú un dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé ẹ̀mí mímọ́ yóò wà pẹ̀lú wọn bí wọ́n ṣe ń bá iṣẹ́ tó gbé lé wọn lọ́wọ́ náà nìṣó. Abájọ tó fi jẹ́ pé pẹ̀lú bí iṣẹ́ náà ṣe pọ̀ tó àti bí àwọn alátakò ṣe ń sa gbogbo ipá wọn láti pa wọ́n lẹ́nu mọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ìjímìjí ṣe ohun tó darí wọn láti ṣe pẹ̀lú àṣeyọrí. Òótọ́ pọ́ńbélé tí ẹnikẹ́ni kò lè já ní koro lọ̀rọ̀ yìí.
4. Báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe fara hàn nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn?
4 Iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tí a ń ṣe jákèjádò ayé jẹ́ àfihàn ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwọn tí kò mọ̀ ọ́n. Ó ń fún wọn láǹfààní láti sún mọ́ Jèhófà, kí wọ́n sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Ìṣe 26:18) Iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni tún fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fún àwọn tó ń kéde ìhìn náà hàn, níwọ̀n bó ti fún wọn láǹfààní láti fi ìfọkànsìn wọn sí Jèhófà àti ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn hàn. (Mátíù 22:37-39) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọyì iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni débi pé ó pè é ní “ìṣúra.”—2 Kọ́ríńtì 4:7.
5. (a) Ibo la ti lè rí ìtàn tó ṣeé gbára lé jù lọ nípa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ìbísí wo la sì ṣàpèjúwe níbẹ̀? (b) Èé ṣe tí ìwé Ìṣe fi nítumọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní?
5 Ìtàn tó ṣeé gbára lé jù lọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe ni èyí táa rí nínú ìwé Ìṣe onímìísí náà, tí Lúùkù ọmọ ẹ̀yìn kọ. Ó jẹ́ àkọsílẹ̀ nípa ìbísí tó ṣeni ní kàyéfì, tó sì yá kánmọ́kánmọ́. Ìtẹ̀síwájú yìí nínú ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rán wa létí Sáàmù 147:15, tó sọ pé: “[Jèhófà] ń fi àsọjáde rẹ̀ ránṣẹ́ sí ilẹ̀ ayé; ìyára kánkán ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi ń sáré.” Ìtàn àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, tí ẹ̀mí mímọ́ fún lágbára, jẹ́ èyí tó ń mórí ẹni yá, tó sì nítumọ̀ tó ṣe kókó fún wa lónìí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọlẹ́yìn bákan náà, ó kàn jẹ́ pé a ń ṣe é lọ́nà tó túbọ̀ gbòòrò ni. Àwa náà ń dojú kọ àwọn ìṣòro tó bá ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mu. Báa ṣe ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe bù kún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, tó sì fún wọn lágbára ni ìgbàgbọ́ táa ní pé ó ń tì wá lẹ́yìn túbọ̀ ń lágbára sí i.
Ìbísí Nínú Iye Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn
6. Kí ni gbólóhùn tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbísí tó fara hàn nígbà mẹ́ta nínu ìwé Ìṣe, kí ló sì tọ́ka sí?
6 Ọ̀nà kan táa lè gbà ṣàyẹ̀wò ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ inú Ìṣe 1:8 ni pé ká gbé gbólóhùn náà “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀” yẹ̀ wò. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré ni gbólóhùn yìí, pẹ̀lú ìyàtọ̀ díẹ̀díẹ̀, wáyé nínú Bíbélì, inú ìwé Ìṣe sì ni gbogbo rẹ̀ wà. (Ìṣe 6:7; 12:24; 19:20) “Ọ̀rọ̀ Jèhófà,” tàbí “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” nínú àyọkà wọ̀nyí ń tọ́ka sí ìhìn rere náà—ìyẹn ni ìhìn òtítọ́ àtọ̀runwá tí ń múni lára yá gágá, ìhìn kan tó wà láàyè, tó lágbára tó ń yí ìgbésí ayé àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á padà.—Hébérù 4:12.
7. Kí ni ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé mọ́ nínú Ìṣe 6:7, kí ló sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
7 Ibi táa ti kọ́kọ́ tọ́ka sí ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ìṣe 6:7. Ibẹ̀ la ti kà á pé: “Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.” Níhìn-ín, ìbísí wé mọ́ pípọ̀ tí iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i. Ṣáájú àkókò yẹn, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, a tú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run dà sórí àwọn bí ọgọ́fà ọmọ ẹ̀yìn tó kóra jọ sí yàrá òkè kan. Àpọ́sítélì Pétérù wá sọ àsọyé amóríyá kan, àwọn bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] lára àwọn tó gbọ́ sì di onígbàgbọ́ ní ọjọ́ yẹn gan-an. Àfàìmọ̀ ni ẹsẹ̀ gìrìgìrì ò fi ní gbòde o, bí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ṣe ń wọ́ tìrítìrí lọ sódò tàbí sí àwọn odò tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti àgbègbè rẹ̀ láti ṣe batisí ní orúkọ Jésù, ọkùnrin tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ kàn mọ́gi bí arúfin ní nǹkan bí àádọ́ta ọjọ́ ṣáájú àkókò yẹn!—Ìṣe 2:41.
8. Báwo ni iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe pọ̀ sí i ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa?
8 Ṣùgbọ́n, a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹẹ́ bọ̀ lápò nígbà yẹn ni o. Gbogbo ìsapá àwọn aṣáájú ìsìn Júù láti dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró ló já sí pàbó. Gẹ́gẹ́ bí ìjákulẹ̀ fún àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn, “Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ [àwọn ọmọ ẹ̀yìn] lójoojúmọ́.” (Ìṣe 2:47) Láìpẹ́, “iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” Lẹ́yìn ìyẹn, “ṣe ni a ń fi àwọn onígbàgbọ́ nínú Olúwa kún wọn ṣáá, ògìdìgbó lọ́kùnrin àti lóbìnrin.” (Ìṣe 4:4; 5:14) Nígbà tó yá, a kà á pé: “Ní tòótọ́, nígbà náà, ìjọ jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú sáà àlàáfíà, a ń gbé e ró; bí ó sì ti ń rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́, ó ń di púpọ̀ sí i ṣáá.” (Ìṣe 9:31) Ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan bí ọdún 58 Sànmánì Tiwa, a kà nípa “ọ̀pọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún onígbàgbọ́.” (Ìṣe 21:20) Ní àkókò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí onígbàgbọ́ ló tún wà.
9. Báwo lo ṣe máa ṣàpèjúwe àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀?
9 Ìyínilọ́kànpadà ló fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìbísí yìí. Ẹ̀sìn náà jẹ́ tuntun lóòótọ́—àmọ́ ó gbéṣẹ́. Dípò kí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ tó kàn ń jókòó dẹngbẹrẹ lásán, ńṣe ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà yọ̀ǹda ara wọn pátápátá fún Jèhófà àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn tó ti fojú winá inúnibíni líle koko ni wọ́n ti sábà ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (Ìṣe 16:23, 26-33) Àwọn tó di Kristẹni ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ronú jinlẹ̀ dáadáa, tí wọ́n sì ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. (Róòmù 12:1) Wọ́n mọ ọ̀nà Ọlọ́run dunjú; òtítọ́ sì wà nínú èrò inú àti ọkàn-àyà wọn. (Hébérù 8:10, 11) Wọ́n múra tán láti kú nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́.—Ìṣe 7:51-60.
10. Ẹrù iṣẹ́ wo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tẹ́wọ́ gbà, ìbáradọ́gba wo la sì rí lónìí?
10 Àwọn tó tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Kristẹni mọ ojúṣe wọn láti mú òtítọ́ náà tọ àwọn ẹlòmíràn lọ. Èyí ló wá jẹ́ kí ìbísí náà túbọ̀ pọ̀ sí i. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ pé: “Bíbáni sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn náà kò mọ sọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ onítara gan-an, tàbí sọ́dọ̀ kìkì àwọn ajíhìnrere táa yàn sípò nìkan. Iṣẹ́ ìjíhìnrere jẹ́ iṣẹ́ àti ojúṣe gbogbo àwọn mẹ́ńbà Ìjọ. . . . Bí àwọn Kristẹni ṣe máa ń yọ sí àwọn èèyàn tọ̀yàyà-tọ̀yàyà ló mú kí ẹ̀sìn Kristẹni gbèrú láti ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Ó tún kọ̀wé síwájú sí i pé: “Iṣẹ́ ìjíhìnrere ló wà ní góńgó ẹ̀mí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀.” Bí ọ̀ràn àwọn tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni ṣe rí gẹ́lẹ́ lóde òní nìyẹn.
Ìbísí Nínú Iye Ìpínlẹ̀
11. Irú ìbísí wo la ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìṣe 12:24, báwo lèyí sì ṣe ṣẹlẹ̀?
11 Ibi kejì tí wọ́n tún ti tọ́ka sí ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni èyí tó wà nínú Ìṣe 12:24, tó kà pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀ àti ní títànkálẹ̀.” Pípọ̀ tí iye ìpínlẹ̀ ń pọ̀ sí i ni gbólóhùn yìí tọ́ka sí níhìn-ín. Láìka gbogbo àtakò tí ìjọba gbé dìde sí, iṣẹ́ náà ń tẹ̀ síwájú. A kọ́kọ́ tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn ní Jerúsálẹ́mù, àtibẹ̀ ni ọ̀rọ̀ náà ti ń tàn kálẹ̀ lẹ́yẹ-ò-sọkà. Inúnibíni tí wọ́n gbé dìde sí wọn ní Jerúsálẹ́mù fọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn káàkiri Jùdíà àti Samáríà. Kí ni àbájáde rẹ̀? “Àwọn tí a tú ká la ilẹ̀ náà já, wọ́n ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 8:1, 4) A darí Fílípì láti jẹ́rìí fún ọkùnrin kan, tó mú ìhìn náà lọ sí Etiópíà lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀. (Ìṣe 8:26-28, 38, 39) Kíá ni òtítọ́ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní Lídà, ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì àti Jópà. (Ìṣe 9:35, 42) Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà lójú òkun àti lórí ilẹ̀, láti dá àwọn ìjọ sílẹ̀ jákèjádò ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbègbè Mẹditaréníà. Àpọ́sítélì Pétérù lọ sí Bábílónì. (1 Pétérù 5:13) Láàárín ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn tí a tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí wọn ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ìhìn rere náà ni a ti “wàásù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé apá ibi tí wọ́n mọ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn ló ń tọ́ka sí.—Kólósè 1:23.
12. Báwo ni àwọn alátakò ìsìn Kristẹni ṣe jẹ́rìí sí ìbísí nínú iye ìpínlẹ̀ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dé?
12 Kódà àwọn tó jẹ́ alátakò ẹ̀sìn Kristẹni pàápàá gbà pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ta gbòǹgbò jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Fún àpẹẹrẹ, Ìṣe 17:6 ròyìn pé ní Tẹsalóníkà, ìyẹn àríwá Gíríìsì, àwọn alátakò figbe ta pé: “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí wọ́n ti sojú ilẹ̀ ayé tí a ń gbé dé ti dé síhìn-ín pẹ̀lú.” Síwájú sí i, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kejì, Pliny Kékeré kọ̀wé nípa ẹ̀sìn Kristẹni láti ẹkùn ilẹ̀ Bítíníà sí Trajan, Olú Ọba Róòmù. Ó ṣàròyé pé: “[Ẹ̀sìn yìí] kò fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ sáàárín kìkì àwọn ìlú ńlá, àmọ́ ó ti kó èèràn ran àwọn abúlé àtàwọn eréko.”
13. Ọ̀nà wo ni ìbísí nínú iye ìpínlẹ̀ gbà ń fi ìfẹ́ Ọlọ́run fún ìran ènìyàn hàn?
13 Ìbísí nínú iye ìpínlẹ̀ yìí jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní fún ìran ènìyàn tó ṣeé rà padà. Nígbà tí Pétérù rí i tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé Kọ̀nílíù, Kèfèrí nì, ó sọ pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìhìn rere jẹ́ ìhìn fún gbogbo ènìyàn, ìbísí nínú iye ìpínlẹ̀ tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tàn dé sì ń fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo láǹfààní láti fi ìmọrírì wọn hàn fún ìfẹ́ Ọlọ́run. Ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti tàn dé apá ibi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé.
Ìbísí Tó Borí
14. Irú ìbísí wo la ṣàpèjúwe nínú Ìṣe 19:20, ohun wo sì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run borí?
14 Ibi kẹta táa ti mẹ́nu kan ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Ìṣe 19:20, tó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.” Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì táa tú sí “bíborí” ń mú èrò “sísa agbára” wá síni lọ́kàn. Àwọn ẹsẹ tí ó ṣáájú ṣàlàyé bí ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù ṣe di onígbàgbọ́, àti bí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó fi idán pípa ṣíṣẹ ṣe ṣe dáná sun àwọn ìwé wọn níwájú gbogbo ènìyàn. Bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe borí àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn èké nìyẹn. Ìhìn rere náà tún borí àwọn ìdènà mìíràn, bí inúnibíni. Kò sí ohun tó lè dá a dúró. A tún rí i bí èyí ṣe bá ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ mu ní àkókò tiwa.
15. (a) Kí ni ẹnì kan tó jẹ́ òpìtàn Bíbélì sọ nípa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀? (b) Ta ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi ògo àṣeyọrí wọn fún?
15 Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ìtara polongo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹnì kan tó jẹ́ òpìtàn Bíbélì sọ nípa wọn pé: “Nígbà táwọn èèyàn bá nífẹ̀ẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Olúwa wọn, ọ̀nà tí wọ́n máa gbé e gbà kì í ṣòro fún wọn rárá. Ní ti gidi, ohun tó sún àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin wọ̀nyí ṣe é gan-an ló wú wa lórí ju àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe é.” Síbẹ̀, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wọ̀nyẹn mọ̀ pé àṣeyọrí tí wọ́n ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà kò sinmi lórí ìsapá tàwọn nìkan ṣoṣo. Wọ́n ní àṣẹ àtọ̀runwá láti máa bá iṣẹ́ wọn nìṣó, wọ́n sì ní ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá láti ṣe iṣẹ́ náà láṣeparí. Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbísí tẹ̀mí ti ń wá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ èyí nínú lẹ́tà tó kọ sí ìjọ tó wà ní Kọ́ríńtì. Ó kọ̀wé pé: “Èmi gbìn, Àpólò bomi rin, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ń mú kí ó máa dàgbà. Nítorí àwa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 3:6, 9.
Ẹ̀mí Mímọ́ Wà Lẹ́nu Iṣẹ́
16. Kí ló fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lágbára láti fi àìṣojo wàásù?
16 Rántí pé Jésù mú un dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé ẹ̀mí mímọ́ yóò kó ipa kan nínú ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti pé ẹ̀mí mímọ́ yóò fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn lágbára nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Ìṣe 1:8) Báwo nìyẹn ṣe ṣẹlẹ̀? Kò pẹ́ lẹ́yìn táa tú ẹ̀mí dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì, tí wọ́n fi pe Pétérù àti Jòhánù pé kí wọ́n wá sọ tẹnu wọn níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn àwọn Júù, ìyẹn ni ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà, ilé ẹjọ́ tí àwọn onídàájọ́ rẹ̀ dájọ́ ikú fún Jésù Kristi. Ṣé jìnnìjìnnì máa bá àwọn àpọ́sítélì níwájú irú ìgbìmọ̀ aládàá ńlá, tí wọ́n jẹ́ abatẹnijẹ́ yẹn ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Ẹ̀mí mímọ́ fún Pétérù àti Jòhánù ní agbára láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà tó ga débi pé ẹnu ya àwọn alátakò wọn, tí wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí rí i kedere nípa wọn pé wọ́n ti máa ń wà pẹ̀lú Jésù.” (Ìṣe 4:8, 13) Ẹ̀mí mímọ́ tún mú kó ṣeé ṣe fún Sítéfánù láti fìgboyà wàásù fún Sànhẹ́dírìn. (Ìṣe 6:12; 7:55, 56) Ṣáájú àkókò yẹn, ẹ̀mí mímọ́ ti mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi àìṣojo wàásù. Lúùkù ròyìn pé: “Nígbà tí wọ́n sì ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ tán, ibi tí wọ́n kóra jọpọ̀ sí mì; gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan sì kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì ń fi àìṣojo sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”—Ìṣe 4:31.
17. Ní àwọn ọ̀nà mìíràn wo ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn?
17 Jèhófà àti Jésù tí ó jí dìde ń darí iṣẹ́ ìwàásù náà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tó lágbára. (Jòhánù 14:28; 15:26) Nígbà táa tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí Kọ̀nílíù, àtàwọn ará ilé rẹ̀, àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, àpọ́sítélì Pétérù rí i pé àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ pàápàá tóótun láti ṣe batisí ní orúkọ Jésù Kristi. (Ìṣe 10:24, 44-48) Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ kó ipa pàtàkì nínú yíyan Bánábà àti Sọ́ọ̀lù (àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù) fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó sì tún darí wọn láti mọ ibi tó yẹ kí wọ́n lọ àti ibi tí kò yẹ kí wọ́n lọ. (Ìṣe 13:2, 4; 16:6, 7) Ó darí ìpinnu tí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ṣe ní Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 15:23, 28, 29) Ẹ̀mí mímọ́ tún darí yíyan àwọn alábòójútó sípò nínú ìjọ Kristẹni.—Ìṣe 20:28.
18. Báwo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe fi ìfẹ́ hàn?
18 Ní àfikún sí i, ẹ̀mí mímọ́ tún hàn lára àwọn Kristẹni náà alára, ó ń jẹ́ kí wọ́n ní àwọn ànímọ̀ Ọlọ́run bí ìfẹ́. (Gálátíà 5:22, 23) Ìfẹ́ sún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti ṣàjọpín àwọn nǹkan láàárín ara wọn. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, wọ́n ṣètò dídáwó jọ sójú kan, kí wọ́n lè pèsè fún àìní àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé: “Kò sí ọ̀kan láàárín wọn tí ó wà nínú àìní; nítorí gbogbo àwọn tí ó ní pápá tàbí ilé a tà wọ́n, wọn a sì mú iye owó àwọn ohun tí wọ́n tà wá, wọn a sì fi wọ́n lélẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ àwọn àpọ́sítélì. Ẹ̀wẹ̀, wọn a pín nǹkan fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí.” (Ìṣe 4:34, 35) Kì í ṣe kìkì àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn nìkan ni wọ́n ń fi ìfẹ́ yìí hàn sí, àmọ́ wọ́n tún ń fi hàn sí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ nípa sísọ ìhìn rere náà fún wọn àti nípa fífi inú rere hàn sí wọn láwọn ọ̀nà mìíràn. (Ìṣe 28:8, 9) Jésù sọ pé ìfẹ́ ìfara ẹni rúbọ ni a ó fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀. (Jòhánù 13:34, 35) Dájúdájú, ànímọ́ pàtàkì tí ìfẹ́ jẹ́ ló fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ Ọlọ́run, tó sì mú kí ìbísí wà ní ọ̀rúndún kìíní bó ṣe wà lóde òní.—Mátíù 5:14, 16.
19. (a) Ọ̀nà mẹ́ta wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà gbà ní ìbísí ní ọ̀rúndún kìíní? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?
19 Lápapọ̀, gbólóhùn náà, “ẹ̀mí mímọ́” fara hàn nígbà mọ́kànlélógójì nínú ìwé Ìṣe. Ó ṣe kedere pé agbára àti ìdarí ẹ̀mí mímọ́ ló jẹ́ kí àwọn Kristẹni ní ìbísí ní ọ̀rúndún kìíní. Iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn pọ̀ sí i, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn dé àwọn àgbègbè tó pọ̀, ó sì borí àwọn ìsìn àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó wà nígbà yẹn. Irú ìbísí tó wà ní ọ̀rúndún kìíní ti fara hàn nínú iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e, a ó ṣàyẹ̀wò bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń bí sí i lọ́nà kíkàmàmà ní àkókò tiwa yìí.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe pọ̀ sí i ní iye?
• Lọ́nà wo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà tàn dé ọ̀pọ̀ ilẹ̀?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe borí ní ọ̀rúndún kìíní?
• Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ kó nínú ìbísí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Fílípì wàásù fún ará Etiópíà, ó mú kí ìhìn rere náà tàn dé ilẹ̀ mìíràn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ẹ̀mí mímọ́ darí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní Jerúsálẹ́mù
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
Apá ọ̀tún lókè pátápátá: Àwòrán ìlú ńlá Jerúsálẹ́mù ní àkókò Tẹ́ńpìlì Kejì–ó wà ní àgbègbè Hòtẹ́ẹ̀lì Holyland, Jerúsálẹ́mù