ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 7/1 ojú ìwé 30
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 6, 2001

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpàdé Ọdọọdún October 6, 2001
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 6, 2001
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 7, 2000
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 7, 2000
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìpàdé Ọdọọdún October 4, 1997
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 7/1 ojú ìwé 30

Ìpàdé Ọdọọdún October 6, 2001

ÌPÀDÉ ỌDỌỌDÚN ti àwọn mẹ́ńbà Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania yóò wáyé ní October 6, 2001, ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní 2932 Kennedy Boulevard, Jersey City, New Jersey. A ó ṣe ìpàdé àṣeṣáájú ti àwọn mẹ́ńbà nìkan ní aago mẹ́sàn-án kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láàárọ̀ [9:15 a.m.], ìpàdé ti gbogbo gbòò yóò tẹ̀ lé e ní aago mẹ́wàá òwúrọ̀.

Kí àwọn mẹ́ńbà àjọ náà jọ̀wọ́ fi ìyípadà èyíkéyìí nínú àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ wọn nínú ọdún tó kọjá tó Ọ́fíìsì Akọ̀wé létí nísinsìnyí, kí àwọn lẹ́tà ìfitónilétí tí a ń lò déédéé àti ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni bàa lè dé ọ̀dọ̀ wọn ní oṣù July.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ tètè dá àwọn ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni, tí a ó fi ránṣẹ́ sí àwọn mẹ́ńbà pẹ̀lú ìfitónilétí nípa ìpàdé ọdọọdún náà padà, kí ó bàa lè dé Ọ́fíìsì Akọ̀wé Society, ó pẹ́ tán ní August 1. Kí mẹ́ńbà kọ̀ọ̀kan tètè kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni tirẹ̀ ní kíá mọ́sá, kí ó sì dá a padà, kí ó sọ bóyá òun fúnra òun yóò wà níbi ìpàdé náà tàbí pé òun kò ní sí níbẹ̀. Kí ìsọfúnni tí a kọ sórí ìwé àṣẹ ìṣojúfúnni kọ̀ọ̀kan ṣe pàtó lórí kókó yìí, nítorí pé ìwé yìí ni a ó fi mọ iye èèyàn tó ń bọ̀.

A retí pé gbogbo ìpàdé náà, títí kan ìpàdé nípa bí iṣẹ́ ṣe ń lọ sí, àti àwọn ìròyìn tí a óò gbọ́, yóò parí ní aago kan ọ̀sán tàbí kó kọjá díẹ̀. Kò ní sí ìpàdé mìíràn ní ọ̀sán. Nítorí ìwọ̀nba àyè tó wà, àwọn tó bá ní tíkẹ́ẹ̀tì lọ́wọ́ nìkan ni yóò wọlé. Kò ní sí ètò kankan fún lílo tẹlifóònù láti so ìpàdé ọdọọdún náà pọ̀ mọ́ àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ mìíràn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́