ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 7/15 ojú ìwé 21-23
  • Ṣé Lóòótọ́ Ni Ò Ń Rára Gba Nǹkan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Lóòótọ́ Ni Ò Ń Rára Gba Nǹkan?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Jèhófà Ń Dárí Gbogbo Ìṣìnà Rẹ Jì Ọ́’
  • Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Ṣe Pàtàkì
  • Ẹ Máa Fi Sùúrù Fara Dà Á fún Ara Yín
  • “Pẹ̀lú Inú Tútù àti Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀”
  • Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Máa Bọ̀wọ̀ fún Èrò Àwọn Míì
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Ń Mú Nǹkan Mọ́ra Tó?
    Jí!—2001
  • Àmúmọ́ra
    Jí!—2015
  • Jíjẹ́ Aláìrinkinkin, Síbẹ̀ Tí Ó Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Àtọ̀runwá
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 7/15 ojú ìwé 21-23

Ṣé Lóòótọ́ Ni Ò Ń Rára Gba Nǹkan?

ǸJẸ́ ìwà ìbàjẹ́ tí ẹnì kan hù ti mú ọ bínú kọjá ààlà rí? Ǹjẹ́ o tètè máa ń gbégbèésẹ̀ nígbà tí àwọn ohun tí ń sọni dìbàjẹ́ bá ń wá ọ̀nà láti kó wọ àárín àwọn tí ẹ jọ jẹ́ kòríkòsùn?

Ìgbà mìíràn máa ń wà tó jẹ́ pé ìgbésẹ̀ kíá láìgbagbẹ̀rẹ́ la nílò láti paná ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó fẹ́ máa tàn kálẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ìwà àìtọ́ tó bùáyà fẹ́ sọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dìbàjẹ́ ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣááju Sànmánì Tiwa, Fíníhásì, ọmọ ọmọ Áárónì gbé ìgbésẹ̀ akíkanjú láti mú ohun búburú kúrò. Jèhófà Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ohun tó ṣe yẹn, ó sọ pé: “Fíníhásì . . . ti yí ìrunú mi padà kúrò lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa bí òun kò ṣe fàyè gba bíbá mi díje rárá láàárín wọn.”—Númérì 25:1-11.

Fíníhásì gbé ìgbésẹ̀ tó bá a mu wẹ́kú láti dá ìwà ìbàjẹ́ tó ń tàn kálẹ̀ dúró. Àmọ́ kéèyàn wá fa ìbínú yọ rẹpẹtẹ nítorí kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ẹlòmíràn ńkọ́? Táa bá lọ tutọ́ sókè táa fojú gbà á tàbí táa ṣe ohun kan láìnídìí, a ó di ẹni tí kì í ṣe pé ó ń fi gbogbo ara gbèjà òdodo bí kò ṣe ẹni tí kò wulẹ̀ rára gba nǹkan—ìyẹn ni ẹni tí kì í gba ti àìpé àwọn ẹlòmíràn rò. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ọ̀fìn yìí?

‘Jèhófà Ń Dárí Gbogbo Ìṣìnà Rẹ Jì Ọ́’

Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run owú (onítara); Ọlọ́run tí kò fàyè gba ìbánidíje.” (Ẹ́kísódù 20:5, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Nítorí tí ó jẹ́ Ẹlẹ́dàá, ó ní ẹ̀tọ́ láti béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe lọ́wọ́ wa. (Ìṣípayá 4:11) Síbẹ̀, Jèhófà ń fara da àìlera ẹ̀dá ènìyàn. Dáfídì onísáàmù kọrin nípa rẹ̀ pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo . . . Òun kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.” Dájúdájú, bí a bá ronú pìwà dà, Ọlọ́run ‘ń dárí gbogbo ìṣìnà wa jì wá.’—Sáàmù 103:3, 8-10.

Nítorí pé Jèhófà mọ̀ pé ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ làwa èèyàn, kì í ‘fìgbà gbogbo wá àléébù’ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. (Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Àní, ó ti pète pé òun yóò mú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé kúrò. Títí tí ìyẹn yóò fi ṣẹ ní kíkún, dípò tí Ọlọ́run ì bá fi máa mú “ohun tí ó yẹ wá” wá sórí wa, ńṣe ló ń fi inú rere dárí jì wá lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. Kò sí èyíkéyìí nínú wa tí ì bá tóótun láti là á já, ká ní Jèhófà kò fi àánú hàn nígbà tó yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 130:3) A mà dúpẹ́ o, pé Baba wa ọ̀run, tó lẹ́tọ̀ọ́ láti béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe, jẹ́ Ọlọ́run tí ń rára gba nǹkan!

Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Ṣe Pàtàkì

Níwọ̀n bí Olúwa Ọba Aláṣẹ ọ̀run òun ayé ti ní àmúmọ́ra ní ti bó ṣe ń bá àwa aláìpé ẹ̀dá ènìyàn lò, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀? Ìráragba-nǹkan la lè túmọ̀ sí “fífàyè gba èrò àti ìṣe àwọn ẹlòmíràn.” Ǹjẹ́ àwa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ní irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀—ìyẹn ni láti sinmẹ̀dọ̀, ká sì mú sùúrù nígbà táwọn ẹlòmíràn bá sọ àwọn nǹkan tàbí tí wọ́n bá ṣe àwọn nǹkan tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo àmọ́ tó dà bí ẹni pé kò bọ́ sí i lójú tiwa?

Àmọ́ ṣa o, a gbọ́dọ̀ yẹra fún gbígba ìgbàkugbà. Fún àpẹẹrẹ, wàhálà ńlá ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn aláṣẹ inú ìsìn bá ń fàyè gba àwọn àlùfáà oníwàkiwà tí wọ́n máa ń fi gbogbo ìgbà bá àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn ọmọdébìnrin ṣèṣekúṣe. Oníròyìn kan ní Ireland sọ pé: “Nítorí pé àwọn aláṣẹ inú ṣọ́ọ̀ṣì ń wo ohun táwọn àlùfáà ń ṣe sí àwọn ọmọdé wọ̀nyẹn bí ìgbà tí ẹ̀ṣẹ̀ bá kàn lé èèyàn bá, wọ́n wulẹ̀ ń gbé àlùfáà tó dẹ́ṣẹ̀ náà [lọ síbòmíràn ni].”

Ǹjẹ́ wíwulẹ̀ gbé irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti ibì kan lọ síbòmíràn jẹ́ àpẹẹrẹ ìráragba-nǹkan lọ́nà yíyẹ? Rárá o! Ó dà bíi ká sọ pé ẹgbẹ́ àwọn oníṣègùn kan yọ̀ǹda fún oníṣègùn iṣẹ́ abẹ kan tí kò ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́ láti máa báṣẹ́ lọ, tí wọ́n wulẹ̀ ń gbé e láti ilé ìwòsàn kan lọ sí òmíràn, bó tiẹ̀ ń pa àwọn aláìsàn tàbí tó ń sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara. Ẹ̀mí kí àṣírí ọmọ ẹgbẹ́ máà tú lè jẹ́ kéèyàn fi àṣìṣe ka irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí “ìráragba-nǹkan.” Ṣùgbọ́n àwọn tí ẹ̀mí wọ́n ti ṣòfò tàbí tí wọ́n kàgbákò nítorí àìka nǹkan sí, tàbí ìwà arúfin pàápàá tó hù ńkọ́?

Ewu tún wà nínú kéèyàn má fi bẹ́ẹ̀ rára gba nǹkan. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, àwọn Júù kan táa mọ̀ sí àwọn Onítara Ìsìn fi àṣìṣe gbìyànjú láti lo àpẹẹrẹ Fíníhásì nígbà tí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n máa gbà dá ìgbòkègbodò tiwọn láre. Àṣejù tí àwọn Onítara Ìsìn máa ń ṣe ni pé “wọ́n á kó sáàárín àwọn èrò ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀ àti àwọn àṣeyẹ mìíràn, wọ́n á sì máa gún àwọn tí wọ́n bá kà sí ọ̀tá lọ́bẹ lójijì.”

Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a kò ní ṣe bíi ti àwọn Onítara Ìsìn yẹn láé, ìyẹn ni pé a ò ní dojú ìjà kọ àwọn tí wọ́n ṣe ohun tí kò tẹ́ wa lọ́rùn. Àmọ́, ṣe àìráragba-nǹkan dé àyè kan ń sún wa láti lo ọ̀nà mìíràn láti fìtínà àwọn tí wọ́n ń ṣe ohun tí kò dùn mọ́ wa nínú—bóyá bíi ká máa yọ èébú lára wọn? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ là ń rára gba nǹkan, a kò ní jẹ́ kí nǹkan kan sún wa dédìí sísọ irú àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé bẹ́ẹ̀.

Àwọn Farisí ọ̀rúndún kìíní tún jẹ́ ẹgbẹ́ mìíràn tí kì í rára gba nǹkan. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń dá àwọn mìíràn lẹ́bi, wọ́n kì í sì í ro ti àìpé ẹ̀dá. Àwọn Farisí agbéraga náà máa ń fojú yẹpẹrẹ wo àwọn gbáàtúù, wọ́n máa ń pè wọ́n ní “ẹni ègún.” (Jòhánù 7:49) Abájọ tí Jésù ṣe fi irú àwọn olódodo àṣelékè bẹ́ẹ̀ bú, tó sọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá efinrin àti ewéko dílì àti ewéko kúmínì, ṣùgbọ́n ẹ ṣàìka àwọn ọ̀ràn wíwúwo jù lọ nínú Òfin sí, èyíinì ni, ìdájọ́ òdodo àti àánú àti ìṣòtítọ́. Àwọn ohun wọ̀nyí pọndandan ní ṣíṣe, síbẹ̀ àwọn ohun yòókù ni kí ẹ má ṣàìkà sí.”—Mátíù 23:23.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí kò túmọ̀ sí pé ó fojú di ìjẹ́pàtàkì pípa Òfin Mósè mọ́. Ó kàn ń fi hàn pé apá “wíwúwo,” tàbí èyí tó ṣe pàtàkì jù nínú Òfin náà ń béèrè pé kí wọ́n fi òye àti àánú mú un lò. Ẹ ò rí bí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe yàtọ̀ pátápátá sí àwọn Farisí àtàwọn Onítara Ìsìn tí wọn kì í rára gba nǹkan!

Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi kì í fàyè gba ìwà ibi. Láìpẹ́, ‘ẹ̀san yóò wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.’ (2 Tẹsalóníkà 1:6-10) Àmọ́ ṣá o, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ní ìtara fún òdodo, kò fìgbà kan kùnà láti fi sùúrù, àánú, àti aájò tí Baba rẹ̀ ọ̀run ní fún àwọn tó fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, hàn. (Aísáyà 42:1-3; Mátíù 11:28-30; 12:18-21) Àpẹẹrẹ àtàtà mà ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa yìí o!

Ẹ Máa Fi Sùúrù Fara Dà Á fún Ara Yín

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè ní ìtara tó ga fún ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ ẹ jẹ́ kí a máa fi ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sílò pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.” (Kólósè 3:13; Mátíù 6:14, 15) Ìráragba-nǹkan ń béèrè pé ká máa fara da kùdìẹ̀-kudiẹ àti àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn nínú ayé aláìpé yìí. Ó yẹ kí ohun táa ń retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn mọ níwọ̀n.—Fílípì 4:5.

Jíjẹ́ ẹni tó ń rára gba nǹkan kò fi ọ̀nà kankan túmọ̀ sí pé ká fara mọ́ ìwà àìtọ́ tàbí ká di ojú wa sí ohun tí kò tọ̀nà. Àwọn apá ibì kan nínú èrò àti ìṣe onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni lè máà bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà mú láwọn ọ̀nà kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú yíyà bàrá bẹ́ẹ̀ lè máà tíì burú débi tí Ọlọ́run fi lè kọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, ó lè jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé àwọn àtúnṣe kan yẹ ní ṣíṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 4:6, 7) Ẹ ò rí i bó ṣe fìfẹ́ hàn tó nígbà tí àwọn tó tóótun nípa tẹ̀mí bá gbìyànjú láti tọ́ àwọn tó ṣe àṣìṣe bẹ́ẹ̀ sọ́nà nínú ẹ̀mí ìwà tútù! (Gálátíà 6:1) Àmọ́, ká tó lè ṣàṣeyọrí nínú ìsapá yìí, ó pọndandan láti ṣe é nítorí pé a ń ṣàníyàn nípa wọn, dípò tí a ó fi ṣe é pẹ̀lú ẹ̀mí lámèyítọ́.

“Pẹ̀lú Inú Tútù àti Ọ̀wọ̀ Jíjinlẹ̀”

Ọ̀rọ̀ nípa fífi sùúrù bá àwọn tí ẹ̀sìn wọ́n yàtọ̀ sí tiwa lò ńkọ́? “Ẹ̀kọ́ fún Gbogbo Ènìyàn” tí wọ́n lẹ̀ mọ́ gbogbo Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba tí wọ́n dá sílẹ̀ ní Ireland ní 1831, kà pé: “Jésù Kristi kò ní in lọ́kàn pé ìsìn òun yóò di èyí tí a ń fagbára mú àwọn èèyàn ṣe. . . . Bíbá àwọn aládùúgbò wa jà, kí a sì máa bú wọn, kọ́ ni ọ̀nà táa máa gbà yí wọn lérò padà pé àwa la tọ̀nà, àwọn sì kùnà. Ohun tó ṣeé ṣe kírú ìwà bẹ́ẹ̀ fi yé wọn ni pé a ò lẹ́mìí Kristẹni.”

Jésù kọ́ni, ó sì hùwà lọ́nà tó mú káwọn èèyàn sún mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ló sì yẹ kí àwa náà ṣe. (Máàkù 6:34; Lúùkù 4:22, 32; 1 Pétérù 2:21) Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ òye àrà ọ̀tọ̀ tí Ọlọ́run fún un, ó lè rí ọkàn. Nítorí náà, nígbà tó bá pọndandan, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti pe ìfibú gbígbóná janjan wá sórí àwọn ọ̀tá Jèhófà. (Mátíù 23:13-33) Ṣíṣe èyí kò túmọ̀ sí pé kò rára gba nǹkan.

Àwa ò lágbára láti rí ọkàn bíi ti Jésù. Nítorí náà, ó yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pétérù pé: “Ẹ sọ Kristi di mímọ́ gẹ́gẹ́ bí Olúwa nínú ọkàn-àyà yín, kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pétérù 3:15) Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, a gbọ́dọ̀ gbèjà ohun tí a gbà gbọ́, nítorí pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbé e kà lọ́nà tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe èyí lọ́nà tó fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn ẹlòmíràn àti fún ohun tí wọ́n fi tọkàntọkàn gbà gbọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.

Nínú Ìwàásù olókìkí tí Jésù ṣe lórí Òkè, ó sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fi sùúrù fara dà á fún ara wa, kí a sì máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí a ń wàásù ìhìn rere náà fún. Nípa ṣíṣàì jẹ́ kí ìtara táa ní fún òdodo ru bò wá lójú tí a ò fi gbà gbé ẹ̀mí ìráragba-nǹkan lọ́nà tó bá Bíbélì mu, a óò múnú Jèhófà dùn, a ó sì jẹ́ ẹni tí ń rára gba nǹkan lóòótọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Yẹra fún ẹ̀mí àìráragba-nǹkan tí àwọn Farisí ní

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jésù fi ẹ̀mí ìráragba-nǹkan tí Baba rẹ̀ ní hàn. Ìwọ ńkọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́