ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w01 8/1 ojú ìwé 18
  • Ọlọ́run Ti Nu Omijé Rẹ̀ Nù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ti Nu Omijé Rẹ̀ Nù
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohunkóhun Pa Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run Lára Bó O Bá Ń Tọ́jú Ìbátan Rẹ Tó Ń Ṣàìsàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Wọ́n Mọyì Àwọn Lẹ́tà Tó Kọ
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Jèhófà Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Borí Onírúurú Ìṣòro
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ojútùú sí Àwọn Àròyé Tó Máa Ń Wáyé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
w01 8/1 ojú ìwé 18

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Ọlọ́run Ti Nu Omijé Rẹ̀ Nù

ÀWỌN tí ń mú ìgbésí ayé wọn bá òfin àti ìlànà Jèhófà mu ni à ń bù kún gidigidi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í sábàá rọrùn láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ ní ṣíṣe, ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí wà lárọ̀ọ́wọ́tó. (Sáàmù 84:11) Ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí láti apá Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà fi èyí hàn.

Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan láti ilẹ̀ Faransé wà ní àkókò ìsinmi, ó bá Kima tó ni ilé ìtajà kan sọ̀rọ̀ nípa ète tí Jèhófà ní fún ilẹ̀ ayé. Ó tún fún Kim ní ẹ̀dà kan ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Bí Kim ti ń wo ìwé náà gààràgà, ó rí ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” (Ìṣípayá 21:4) Kim sọ pé: “Ẹsẹ yìí wọ̀ mí lára gan-an ni. Ta ló lè rí mi bí mo ṣe máa ń rẹ́rìn-ín, tí mo sì máa ń báwọn èèyàn ṣeré nílé ìtajà látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀, tó máa mọ̀ pé bí mo bá ti délé lálẹ́, ẹkún ni mo máa ń sun títí oorun á fi gbé mi lọ?” Nígbà tó ń sọ ohun tó ń kó ìbànújẹ́ bá òun, ó ní: “Mo ti ń bá ọkùnrin kan gbé fún ọdún méjìdínlógún, inú mi ò sì dùn rárá nítorí pé ó kọ̀ láti gbé mi níyàwó. Mo fẹ́ fòpin sí irú ọ̀nà ìgbésí ayé tí mò ń gbé yìí, ṣùgbọ́n mi ò lẹ́mìí àtiṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ó ti pẹ́ táa ti jọ ń bọ̀.”

Ìgbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, Kim gbà pé kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Linh wá máa bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kim sọ pé: “Mo ń hára gàgà láti fi ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì sílò. Fún àpẹẹrẹ, mo jáwọ́ nínú jíjọ́sìn àwọn baba ńlá mi ìgbàanì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí fa àtakò látọ̀dọ̀ ìdílé mi. Yàtọ̀ síyẹn, mo tún gbìyànjú láti rí i pé a ń gbé pa pọ̀ lọ́nà tó bá òfin mu, ṣùgbọ́n ẹnì kejì mi kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Láàárín àkókò ìṣòro yìí, Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé yẹn ń fi àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì ránṣẹ́ sí mi, Linh náà sì ń fún mi níṣìírí gan-an. Sùúrù àti ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ àwọn arábìnrin wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láti forí tì í títí dìgbà tí mo fi wá mọ irú ẹni tí ẹnì kejì mi jẹ́ gan-an. Mo wá rí i pé ó ti ní ‘ìyàwó’ márùn-ún tẹ́lẹ̀, ó sì ti bí ọmọ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n! Èyí ló wá fún mi nígboyà láti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

“Ṣíṣí kúrò nínú ilé ńlá tí mo ti ń gbádùn lọ sínú ibùgbé kékeré kan kò rọrùn rárá. Kì í ṣèyẹn nìkan, ẹni tí mò ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kò fi mí lọ́rùn sílẹ̀, ó ní kí n padà wá sọ́dọ̀ òun, ó tiẹ̀ halẹ̀ pé òun á da ásíìdì sí mi lára bí mo bá kọ̀ láti padà. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣe ohun tí ó tọ́.” Kim ń tẹ̀ síwájú, níkẹyìn, ó ṣe batisí ní April 1998. Láfikún sí i, méjì lára àwọn arábìnrin rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́langba bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Kim sọ pé: “Mo máa ń rò pé ìgbésí ayé aláìnírètí ni màá máa gbé títí lọ. Àmọ́, mo láyọ̀ gan-an lónìí, mi ò sunkún ní alaalẹ́ mọ́. Jèhófà ti nu omijé nù kúrò ní ojú mi.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ náà padà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́