ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 2/1 ojú ìwé 13
  • Àwọn Ajẹ́rìíkú Òde Òní Jẹ́rìí Nílẹ̀ Sweden

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ajẹ́rìíkú Òde Òní Jẹ́rìí Nílẹ̀ Sweden
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì Ṣé Ó Ṣì Tún Lè Ṣẹlẹ̀?
    Jí!—2001
  • Kí Nìdí Tí Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Fi Ṣẹlẹ̀? Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Kò Ṣe Fòpin Sí I?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Bí Wọ́n Ṣe Pa Ọ̀pọ̀ Èèyàn Nípakúpa Títí Kan Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ẹ̀rí Ìgbàgbọ́ Wọn
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 2/1 ojú ìwé 13

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Ajẹ́rìíkú Òde Òní Jẹ́rìí Nílẹ̀ Sweden

Ọ̀RỌ̀ tí èdè Gíríìkì lò fún “ẹlẹ́rìí” ni martyr. Ó túmọ̀ sí “ẹni tó ń jẹ́rìí nípasẹ̀ ikú rẹ̀.” Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ló jẹ́rìí nípa Jèhófà, tí wọ́n sì kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn.

Bákan náà ni àwọn ẹmẹ̀wà Hitler ṣe pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ní ọ̀rúndún ogún, nítorí pé wọn ò dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Àwọn ajẹ́rìíkú òde òní wọ̀nyí náà jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nílẹ̀ Sweden lẹ́nu àìpẹ́ yìí nìyẹn.

Gẹ́gẹ́ bí ara ayẹyẹ àjọ̀dún àádọ́ta ọdún tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ìjọba ilẹ̀ Sweden tún ṣètò ẹ̀kọ́ kan ní orílẹ̀-èdè náà, èyí tó dá lórí ọ̀rọ̀ nípa Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà. Wọ́n pe ètò náà ní Ìtàn Mánigbàgbé. Wọ́n ké sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti kópa nínú ètò náà, kí wọ́n sì sọ ohun tójú wọ́n rí.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà nípa ṣíṣe ìfihàn-sójútáyé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Àwọn Òjìyà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Náà Tí A Ti Gbàgbé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Strängnäs. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó la Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà já wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti sọ ìrírí wọn fún àwọn olùṣèbẹ̀wò tó lé ní ẹgbàárin lé irínwó [8,400] tó wá síbẹ̀ ní ọjọ́ àkọ́kọ́! Nígbà tó fi máa di òpin ọdún 1999, ìfihàn-sójútáyé náà ti wáyé ní ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí àtàwọn ibi ìkówèésí tó lé ní ọgọ́rùn-ún jákèjádò ilẹ̀ Sweden, àwọn èèyàn bí ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin [150,000] sì ti wò ó. Àwọn aláṣẹ ìjọba bíi mélòó kan wà lára àwọn olùṣèbẹ̀wò náà, wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ohun tí wọ́n rí.

Kò sí ètò kankan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Sweden tí wọ́n tíì gbé sójútáyé tó bẹ́ẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí gbogbo èèyàn tẹ́wọ́ gbà tó bẹ́ẹ̀ rí. Ọ̀pọ̀ olùṣèbẹ̀wò ló ń béèrè pé: “Kí ló dé tí ẹ ò ti sọ ìrírí tẹ́ ẹ ní nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà fún wa ṣáájú àkókò yìí?”

Lẹ́yìn tí ìfihàn-sójútáyé náà wáyé lágbègbè kan, ìjọ kan tó wà níbẹ̀ ròyìn ìbísí ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé! Ẹlẹ́rìí kan sọ fún ẹnì kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níbi kan náà pé kó wá wo àfihàn náà. Tayọ̀tayọ̀ ni ẹni tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ọ̀hún fi tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan sì jọ wá síbẹ̀. Lẹ́yìn náà, ọ̀rẹ́ náà sọ pé ó ṣòro fún òun láti lóye bí àwọn èèyàn ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ tó lágbára tó bẹ́ẹ̀, tí wọ́n á fi gbà láti kú ju kí wọ́n fọwọ́ sí ìwé tí yóò mú kí wọ́n kọ ìgbàgbọ́ wọn sílẹ̀. Èyí yọrí sí ìjíròrò síwájú sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Gẹ́gẹ́ bíi tàwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ọ̀rúndún kìíní, àwọn olóòótọ́ ajẹ́rìíkú ọ̀rúndún ogún wọ̀nyí ti fi àìṣojo jẹ́rìí pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, ẹni tí ìgbàgbọ́ àti ìdúróṣinṣin wa tí kò lè yẹ̀ tọ́ sí.—Ìṣípayá 4:11.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Ẹni tó wà lẹ́wọ̀n: Państwowe Muzeum Oświęcim-Brzezinka, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda the USHMM Photo Archives

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́