Àwọn Ìlànà Tí O Yàn
ṢÉ ẸNI tó ń tẹ̀ lé ìlànà ni ọ́? Àbí ńṣe lo ka ìlànà ìwà híhù sí ohun tí kò bágbà mu mọ́? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé kálukú ló ní àwọn ìlànà tó ń tẹ̀ lé, ìyẹn àwọn nǹkan tẹ́nì kan gbà pé ó ṣe pàtàkì. A lè túmọ̀ ìlànà sí ohun tá a fi ń díwọ̀n ìgbésẹ̀ títọ́. Ìlànà máa ń nípa lórí àwọn ìpinnu wa, ó sì máa ń pinnu ọ̀nà ìgbésí ayé wa. A lè lo ìlànà gẹ́gẹ́ bí atọ́ka.
Fún àpẹẹrẹ, Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti pa Òfin Pàtàkì náà mọ́, èyí tó wà nínú Mátíù 7:12, tó kà pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Confucius ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà li àti jen, èyí tó dá lórí àwọn ànímọ́ bí inú rere, ìwà ìrẹ̀lẹ̀, ọ̀wọ̀, àti ìdúróṣinṣin. Kódà àwọn tí kì í ṣe ẹ̀sìn kankan pàápàá ní àwọn ohun tí wọ́n kà sí pàtàkì tàbí àwọn ìlànà tó ń pinnu ìwà wọn.
Irú Ìlànà Wo Ló Yẹ Ká Yàn?
Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká mọ̀ pé ìlànà lè jẹ́ rere tàbí búburú. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó ń da àwọn èèyàn tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i láàmú láti ohun tó lé lọ́dún mẹ́wàá síbí ni ohun tá a mọ̀ sí ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lè ṣàìlóye gbólóhùn náà, tàbí kí wọ́n rò pé kò kan àwọn, ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá ló máa ń gba àwọn èèyàn lọ́kàn nígbà tí wọ́n bá ti kọ ìlànà ìwà híhù tó ga sílẹ̀. Bó ti wù kó rí, ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá jẹ́ ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan, tó sábà máa ń bá ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì rìn. Ọ̀gá àgbà kan nílé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan ní ilẹ̀ China sọ pé: “Ìlànà méjì péré la ní. Ọ̀kan ni ríra ohun tó wù wá. Ìkejì ni kíkó owó jọ.”
Ńṣe ni ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá máa ń fani mọ́ra bí agbára òòfà tó wà lára irin tútù ti máa ń ṣe. Báwo sì ni agbára òòfà ṣe máa ń nípa lórí atọ́ka kan? Nígbà tí irin tútù àti atọ́ka bá fẹ̀gbẹ́ kan ara wọn, abẹ́rẹ́ atọ́ka náà yóò kọrí síbòmíràn. Bákan náà ni ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá lè sọ atọ́ka ìwà rere, tàbí ìwà ọmọlúwàbí dìdàkudà nípa jíjẹ́ kí gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe wà ní ipò kejì, kí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn onítọ̀hún sì wà ní ipò kìíní.
Ǹjẹ́ kò ní yà ọ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá kì í ṣe ohun tuntun? Àtinú ọgbà Édẹ́nì ni ẹ̀mí yìí ti bẹ̀rẹ̀, nígbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́ pa ìlànà ìwà híhù tí Ẹlẹ́dàá wa gbé kalẹ̀ tì. Ìyẹn ló mú kí ìlànà ìwà rere wọn dojú rú. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, ẹ̀mí kan náà yẹn ló ń yọ àwọn èèyàn lẹ́nu, èyí tá a wá mọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí sí “ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:6-8, 12.
Gbígbilẹ̀ tí ẹ̀mí yẹn ń gbilẹ̀ la wá rí kedere láàárín àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tí í ṣe “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn.” Abájọ tó fi gba ìsapá láti yẹra fún ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá.—2 Tímótì 3:1-5.
Bóyá o rí i pé ìwọ náà fara mọ́ ohun tí ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Olaf sọ, ẹni tó kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè kan nílẹ̀ Yúróòpù pé: “Jíjẹ́ oníwà mímọ́ kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, àgàgà fún àwa ọ̀dọ́. Ẹ jọ̀wọ́ kí ẹ máa rán wa létí pé ó pọn dandan láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.”
Olaf ní ojú ìwòye tó mọ́gbọ́n dání. Àwọn ìlànà Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìlànà ìwà híhù tó ga, yálà ọmọdé ni wá tàbí àgbà. Wọ́n sì tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti sá fún ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá, yálà a pè é bẹ́ẹ̀ tàbí a ò pè é bẹ́ẹ̀. Bí o bá fẹ́ túbọ̀ mọ̀ nípa bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́, jọ̀wọ́ fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn kì í ká lára lóde òní