ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 12/1 ojú ìwé 8
  • Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan​—Ṣé Gbogbo Èèyàn Rere Ló Máa Lọ sí Ọ̀run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Lórí Tábìlì Wo Ni Ìwọ Ti Ń Jẹun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ta Ló Dá Ẹ̀sìn Yín Sílẹ̀?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • A Bí Ìjọba Ọlọ́run ní Ọ̀run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 12/1 ojú ìwé 8

Lórí Tábìlì Ọ̀gákọ̀

ÀWỌN èèyàn tó gbayì tó gbáfẹ́, oúnjẹ aládùn, àti ìjíròrò tó lárinrin máa ń mú kí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan lórí tábìlì ọ̀gákọ̀ nínú ọkọ̀ òkun gbádùn mọ́ni gan-an. Àmọ́ ìjíròrò kan lórí tábìlì Ọ̀gákọ̀ Robert G. Smith, tó ń bá ilé iṣẹ́ ọkọ̀ ojú omi White Star Line ṣiṣẹ́, tànmọ́lẹ̀ sórí àsè tẹ̀mí kan.—Aísáyà 25:6.

Ní 1894, nígbà tí Robert wà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélógún, ó wa ọkọ òkun Kinclune of Dundee láti rin ìrìn àjò ojú òkun tó kọ́kọ́ rìn káàkiri ayé. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá ń darí àwọn ọkọ̀ òkun ti White Star, bíi Cedric, Cevic, àti Runic.a Nígbà tí Robert wà nínú ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ òkun wọ̀nyí, tó ń gba Àtìláńtíìkì ní New York kọjá lọ sí Liverpool, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ó gba Charles Taze Russell lálejò lórí tábìlì tí ọ̀gákọ̀ tí máa ń jẹun. Ìjíròrò tí Robert ní pẹ̀lú Russell ló tanná ran ìfẹ́ tí Robert ní nínú ìhìn Bíbélì, kó lè túbọ̀ mọ̀ sí i, ó fi tayọ̀tayọ̀ gba àwọn ẹ̀dà bíi mélòó kan ìwé Studies in the Scriptures lọ́wọ́ Russell.

Russell wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sí Robert, bí ìfẹ́ tí Robert ní sí ìhìn Bíbélì ṣe pọ̀ sí i nìyẹn. Robert sọ nípa ìmọ̀ tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ní fún ìyàwó rẹ̀. Kò pẹ́ rárá tí àwọn méjèèjì fi di ògbóṣáṣá Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Nígbà tó yá, Robert láǹfààní láti máa sọ àsọyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ̀rọ̀ lórí “Ìkunra Gílíádì” ní Brisbane, Ọsirélíà, ó sì fi bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ní ìhìn kan tó jẹ́ “ẹ̀rọ̀ fún gbogbo wàhálà ayé” hàn. Ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ láti fi “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] han àwọn èèyàn ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, wọ́n sì máa ń fi rẹ́kọ́ọ̀dù ọ̀rọ̀ tí Russell fi ṣàlàyé àwọn àwòrán náà sínú ẹ̀rọ agbóhùnjáde káwọn èèyàn lè máa gbọ́ ọ bí àwòrán ti ń jáde.

Robert fi ogún òtítọ́ Ìjọba náà tó rí gbà lé àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Lónìí, tó ti ní ìrandíran karùn-ún lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn méjìdínlógún tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ ló ń kópa nínú sísọ ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn, wọ́n sì ń dúpẹ́ fún oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n fún un jẹ lórí tábìlì ọ̀gákọ̀.

Àwọn ìwé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ jáde àti iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe ni wọ́n fi ń ran àwọn èèyàn jákèjádò ayé lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìhìn Bíbélì tó ru Ọ̀gákọ̀ Smith lọ́kàn sókè gan-an. Ìwọ náà lè wádìí ohun tó dùn mọ́ni tó bẹ́ẹ̀ lórí tábìlì ọ̀gákọ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọkọ̀ òkun kan tó fara jọ ìyẹn, tó ń jẹ́ Titanic, ni Ọ̀gákọ̀ E. J. Smith (wọn kì í ṣe mọ̀lẹ́bí o) ń wà nígbà tó rin ìrìn àjò oníjàábá tó kọ́kọ́ rìn lórí òkun.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Robert G. Smith

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Charles T. Russell

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́