ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 1/1 ojú ìwé 3
  • ‘Áà Ọlọ́run, O Ṣe Jẹ́ Kéyìí Ṣẹlẹ̀?’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Áà Ọlọ́run, O Ṣe Jẹ́ Kéyìí Ṣẹlẹ̀?’
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ló Máa Ń Dìde Nígbà Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • A Fara Da Ìpọ́njú, Jèhófà sì Bù Kún Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2019
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 1/1 ojú ìwé 3

‘Áà Ọlọ́run, O Ṣe Jẹ́ Kéyìí Ṣẹlẹ̀?’

RICARDO ṣì máa ń rántí bó ṣe jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ Maria, aya rẹ̀, nínú iyàrá táwọn èèyàn ti máa ń dúró de dókítà.a Kò sí ìkankan nínú àwọn méjèèjì tó láyà láti ka àbájáde ohun tí dókítà rí nígbà tó yẹ ara Maria wò kẹ́yìn. Ricardo wá já àpò ìwé náà, àwọn méjèèjì sì sáré wo èdè ìṣègùn tí wọ́n fi kọ àbájáde ọ̀hún. Kíá ni wọ́n rí ọ̀rọ̀ náà, “àrùn jẹjẹrẹ,” àwọn méjèèjì wá bẹ̀rẹ̀ sí sunkún nítorí pé wọ́n mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí.

Ricardo rántí pé: “Dókítà náà ṣèèyàn gan-an, àmọ́ òun náà mọ bí ipò náà ṣe lágbára tó, nítorí pé ńṣe ló ṣáà ń sọ fún wa pé ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run.”

Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú onítànṣán ni dókítà Maria ti rí i pé kò lè ṣàkóso ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún mọ́. Àwọn àyẹ̀wò mìíràn tí wọ́n ṣe fi hàn pé àrùn jẹjẹrẹ náà ti dé ọpọlọ rẹ̀. Lẹ́yìn tó gbàtọ́jú fún ọ̀sẹ̀ kan péré, wọ́n dá ìtọ́jú onítànṣán náà dúró. Maria wá dákú lọ gbári, ó sì kú ní oṣù méjì lẹ́yìn náà. Ricardo ṣàlàyé pé: “Inú mi dùn pé ìrora rẹ̀ ti dópin, àmọ́ àárò rẹ̀ sọ mi gan-an débi pé ó wá ń ṣe èmi náà bíi pé kí n kú. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń fẹkún béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: ‘O ṣe jẹ́ kéyìí ṣẹlẹ̀?’”

Ọ̀pọ̀ Ìbéèrè Ló Máa Ń Dìde Nígbà Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

Bíi ti Ricardo, àìmọye èèyàn jákèjádò ayé ló di dandan fún láti kojú ohun tó ń jẹ́ ìpọ́njú ní ti gidi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ pé àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ ló máa ń fojú winá rẹ̀. Ronú nípa ìbànújẹ́ tí ń mọ́kàn pami, èyí tí ìforígbárí àwọn ológun lọ́tùn-ún lósì ti fà fún ọmọ aráyé. Tàbí kó o ronú lórí ìbànújẹ́ tó ti bá àwọn tí wọ́n fipá bá lò pọ̀, àwọn ọmọdé tí wọ́n hùwà àìdáa sí, àwọn tí wọ́n hùwà ipá sí nínú ilé àtàwọn tọ́mọ aráyé tí hu onírúurú ìwà ibi mìíràn sí. Jálẹ̀ ìtàn, ó dà bíi pé ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìkà tí tọkùnrin tobìnrin máa ń fẹ́ hù sí ọmọnìkejì wọn kò lópin. (Oníwàásù 4:1-3) Làásìgbò tó máa ń bá àwọn tí àjálù bá tàbí àwọn tó ní ìmí ẹ̀dùn, àwọn tó ní àrùn ọpọlọ, àti àwọn tí àìsàn ń ṣe, náà tún wà níbẹ̀. Abájọ tí ọ̀pọ̀ fi máa ń béèrè pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú ìyà bẹ́ẹ̀?”

Ìyà kì í ṣe ọ̀rẹ́ ara rárá, kódà fáwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ pàápàá. Ìwọ náà lè máa ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára gbogbo fi ní láti fàyè gba ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé. Rírí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn tó sì jẹ́ òtítọ́ sí ìbéèrè tó rúni lójú yìí ṣe pàtàkì fún ìfọ̀kànbalẹ̀ wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Bíbélì pèsè irú ìdáhùn bẹ́ẹ̀. Jọ̀wọ́ gbé ohun tó sọ yẹ̀ wò bó ṣe wà nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ wọn padà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Dókítà náà ṣáà ń sọ fún wa pé ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́