ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 7/1 ojú ìwé 8
  • Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ ‘Ọ̀nà Ìfẹ́ Títayọ Ré Kọjá’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìfẹ́ (Agape)—Ohun Tí Kò jẹ́ Àti Ohun Tí Ó Jẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”
    Ẹ Máa Ṣọ́nà!
  • “Òun Ló Kọ́kọ́ Nífẹ̀ẹ́ Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 7/1 ojú ìwé 8

Irú Ìfẹ́ Tó Ga Jù Lọ

Ọ̀RỌ̀ Gíríìkì náà a·gaʹpe la túmọ̀ sí “ìfẹ́” ní ibi tó pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tàbí Májẹ̀mú Tuntun.

Nígbà tí ìwé Insight on the Scripturesa tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ń ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn, ó sọ pé: “[A·gaʹpe] kì í ṣe ìfẹ́ tó ń ru boni lójú, tó dá lórí ìfàsí ọkàn lásánlàsàn, gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn èèyàn sábà máa ń rò. Àmọ́ ó jẹ́ ìfẹ́ tá a fi ìwà rere pilẹ̀ rẹ̀ tó dá lórí mímọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó wuni tó jẹ́ ọ̀ràn nípa ìlànà, ojúṣe ẹni, àti ohun tó bójú mu, tó máa ń fi gbogbo ọkàn wá ire àwọn ẹlòmíràn níbàámu pẹ̀lú ohun tó tọ́. A·gaʹpe (jẹ́ ìfẹ́) tó borí bíbániṣọ̀tá, kò ní jẹ́ kí ohun tí ẹlòmíràn ṣe múni pa ìlànà rere tì láé kò sì ní jẹ́ kéèyàn fi búburú san búburú.”

A·gaʹpe tún lè ní ìmọ̀lára tó jinlẹ̀ nínú. Àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan [a·gaʹpe] fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pétérù 4:8) Látàrí èyí, a lè sọ pé a·gaʹpe ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn kì í ṣe pẹ̀lú èrò inú nìkan. O ò ṣe gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi mélòó kan yẹ̀ wò, èyí tó fi bí irú ìfẹ́ tó ga lọ́lá yìí ṣe lágbára tó hàn tó sì tún jẹ́ ká mọ ibi tó nasẹ̀ dé? Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nísàlẹ̀ yìí lè ṣèrànwọ́: Mátíù 5:43-47; Jòhánù 15:12, 13; Róòmù 13:8-10; Éfésù 5:2, 25, 28; 1 Jòhánù 3:15-18; 4:16-21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́