ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 2/1 ojú ìwé 4-7
  • Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Ohun Tó O Nílò Nípa Tẹ̀mí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Ohun Tó O Nílò Nípa Tẹ̀mí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsìn Tòótọ́ Ń Gbé Ipò Tẹ̀mí Lárugẹ
  • Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé fún Ìlera Tẹ̀mí
  • Ṣé Ó Tó Ohun Téèyàn Ń Sapá Fún?
  • O Lè Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run
    Jí!—2010
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Sún Mọ́ Ọlọ́run? Ṣé Mo Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run Bí Mi Ò Bá Ṣe Ẹ̀sìn Kankan?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Onírúurú Èrò Nípa Béèyàn Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Sapá Láti Túbọ̀ Di Ẹni Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 2/1 ojú ìwé 4-7

Bí Ọwọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Ohun Tó O Nílò Nípa Tẹ̀mí

ÌWÉ ìròyìn U.S.News & World Report sọ pé: “Àwọn ìwé tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún táwọn èèyàn kọ ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lórí ipa tí ipò tẹ̀mí èèyàn ń kó lórí iṣẹ́ téèyàn ń ṣe ti kún gbogbo ilé ìtàwé báyìí. Ọ̀kan lára àwọn ìwé wọ̀nyí ni èyí tí wọ́n pè ní Jesus CEO, tó dá lórí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti òmíràn tí wọ́n pè ní The Tao of Leadership, èyí tí wọ́n kọ láti gbani nímọ̀ràn nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ aṣáájú tó dára jù lọ.” Èyí wulẹ̀ fi hàn pé àwọn tó wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù ti ń wá ìtọ́sọ́nà nípa tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé wọn gan-an báyìí. Nígbà tí ìwé Training & Development tó jẹ́ ìwé àtìgbàdégbà lórí ètò ìṣòwò ń sọ̀rọ̀ nípa èyí, ó ní: “Nígbà tí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti nípa lórí gbogbo ìgbésí ayé wa, ohun tá a ń wá kiri nísinsìnyí ni ìtumọ̀ tó jinlẹ̀, ohun tá a fẹ́ fi ìgbésí ayé wa ṣe àti bá a ó ṣe ní ìtẹ́lọ́rùn.”

Ibo la ti wá lè rí ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tó tẹ́ni lọ́rùn? Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ìsìn tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ làwọn èèyàn máa ń wò pé ó lè ran àwọn lọ́wọ́ láti rí “ìtumọ̀ tó jinlẹ̀” àti “ohun tá a fẹ́” nínú ìgbésí ayé. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ti kẹ̀yìn sáwọn ìsìn tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀ yẹn lóde òní. Ìwé Training & Development sọ pé ìwádìí kan tá a ṣe lọ́dọ̀ àádọ́rùn-ún olùdarí àtàwọn ọ̀gá apàṣẹwàá tí wọ́n wà nípò gíga fi hàn pé “àwọn èèyàn ti ń fìyàtọ̀ sáàárín ìsìn àti ipò tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí gan-an báyìí.” Àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò nínú ìwádìí náà wo ìsìn gẹ́gẹ́ bí “ohun tí kò rára gba nǹkan sí tó sì ń fa ìpínyà,” nígbà tí wọ́n sì ń wo ipò tẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí “ohun tó wà níbi gbogbo tó sì kóni mọ́ra.”

Bákan náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó wà láwọn ibi táwọn èèyàn kò ti fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀ràn ẹ̀sìn sí, bí Ọsirélíà, New Zealand, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti Yúróòpù, ṣe rí ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìsìn àti ipò tẹ̀mí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Ruth Webber, tó kọ̀wé sínú ìwé ìròyìn Youth Studies Australia, sọ pé: “Àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀dọ́ ló gba Ọlọ́run gbọ́, tàbí kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn agbára kan tó ju ti ẹ̀dá lọ àmọ́, wọn ò ka ṣọ́ọ̀ṣì sí ohun tó ṣe pàtàkì tàbí ohun tó lè ran àwọn lọ́wọ́ láti fi irú ẹni táwọn jẹ́ nípa tẹ̀mí hàn.”

Ìsìn Tòótọ́ Ń Gbé Ipò Tẹ̀mí Lárugẹ

Kò yani lẹ́nu pé àwọn èèyàn ń ṣiyèméjì nípa ìsìn. Ọ̀pọ̀ ètò ìsìn ni ìwà jìbìtì tàwọn èèyàn ń hù nínú ọ̀ràn òṣèlú ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọ́n ń hù ìwà àgàbàgebè, tí ọwọ́ wọn si kún fún ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tó ti kú nínú àìlóǹkà àwọn ogun ìsìn. Ó ṣeni láàánú pé sísá tàwọn èèyàn ń sá fún àwọn ètò ìsìn tó kún fún àgàbàgebè àti ẹ̀tàn tí wá mú kí àwọn kan fi àṣìṣe kọ Bíbélì pàápàá sílẹ̀, nítorí wọ́n rò pé òun ló fàyè gba irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀.

Ní ti tòótọ́, Bíbélì dẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè àti ẹ̀mí ta-ni-yóò-mú-mi. Jésù sọ fún àwọn olórí ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè! nítorí pé ẹ jọ àwọn sàréè tí a kùn lẹ́fun, tí wọ́n fara hàn lóde bí ẹlẹ́wà ní tòótọ́ ṣùgbọ́n ní inú, wọ́n kún fún egungun òkú ènìyàn àti gbogbo onírúurú ohun àìmọ́. Ní ọ̀nà yẹn, ẹ̀yin pẹ̀lú, ní tòótọ́, fara hàn lóde bí olódodo sí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n ní inú, ẹ kún fún àgàbàgebè àti ìwà-àìlófin.”—Mátíù 23:27, 28.

Ìyẹn nìkan kọ́ o, Bíbélì tún gba àwọn Kristẹni níyànjú láti jẹ́ ẹni tí kò dá sí tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú. Dípò kó sọ pé káwọn onígbàgbọ́ máa pa onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, ohun tó sọ ni pé, wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti kú fún ẹnì kejì wọn. (Jòhánù 15:12, 13; 18:36; 1 Jòhánù 3:10-12) Dípò kí ìsìn tòótọ́ tá a gbé karí Bíbélì jẹ́ “ohun tí kò rára gba nǹkan sí tó sì ń fa ìpínyà,” ńṣe ló “wà ní ibi gbogbo tó sì ń kóni mọ́ra.” Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Bíbélì Jẹ́ Amọ̀nà Tó Ṣeé Gbára Lé fún Ìlera Tẹ̀mí

Bíbélì sọ fún wa pé a dá àwọn èèyàn ní àwòrán Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Bí èyí kò tiẹ̀ túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn jọ Ọlọ́run ní ìrísí wọn, ohun tó túmọ̀ sí ni pé àwọn èèyàn lágbára láti gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ, títí kan lílóye àwọn nǹkan tẹ̀mí, tàbí ipò tẹ̀mí.

Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò pèsè ọ̀nà tí ọwọ́ wa yóò fi tẹ ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí, yóò sì tún fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó dára tá a ó fi mọ ìyàtọ̀ láàárín ohun tó lè ṣe wá láǹfààní àti èyí tó lè pa wá lára nípa tẹ̀mí. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dá agbára ìdènà àrùn kan tó lágbára sínú ara wa, èyí tó ń gbógun ti àwọn àrùn tó sì ń jẹ́ kí ara wa le, bẹ́ẹ̀ náà ló tún fún wa ní ẹ̀rí ọkàn, tàbí ohùn kan tó ń dún nínú lọ́hùn-ún, tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dára ká sì yẹra fún àwọn àṣà tó lè pa wá lára nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. (Róòmù 2:14, 15) Gẹ́gẹ́ bá a ṣe mọ̀, tá a bá fẹ́ kí agbára ìdènà àrùn wa ṣiṣẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ fi oúnjẹ aṣaralóore bọ́ ọ. Bákan náà, kí ẹ̀rí ọkàn wa tó lè ṣiṣẹ́ dáadáa, a gbọ́dọ̀ fi oúnjẹ tẹ̀mí tó dára bọ́ ọ.

Ká bàa lè dá irú oúnjẹ tí yóò sọ wá di ẹni tó lera nípa tẹ̀mí mọ̀ ni Jésù ṣe sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Àwọn ọ̀rọ̀ tó jáde látẹnu Jèhófà wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.” (2 Tímótì 3:16) Ó wá kú sí ọwọ́ wa láti sa gbogbo ipá wa ká lè jẹ oúnjẹ tẹ̀mí ní àjẹyó. Bá a bá ṣe mọ Bíbélì tó àti bá a ṣe ń gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà rẹ̀ sílò tó nínú ìgbésí ayé wa, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe máa jàǹfààní nínú rẹ̀ nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara tó.—Aísáyà 48:17, 18.

Ṣé Ó Tó Ohun Téèyàn Ń Sapá Fún?

Lóòótọ́, ó máa ń gba àkókò láti mú kí ìlera wa nípa tẹ̀mí sunwọ̀n sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì; ó sì dà bíi pé ọwọ́ àwọn èèyàn ti wá ń dí gan-an báyìí. Àmọ́ èrè ibẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Kíyè sí ohun tí àwọn amọṣẹ́dunjú tí ọwọ́ wọn máa ń dí gan-an sọ nípa ìdí tí wíwá àyè láti bójú tó ire tẹ̀mí ẹni fi ṣe pàtàkì gan-an lójú tiwọn.

Marina, tó jẹ́ dókítà, sọ pé: “Mi ò fìgbà kan ronú nípa ipò tí mo wà nípa tẹ̀mí rí títí dìgbà tí mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn tí mò sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ẹlòmíràn káàánú nítorí ìrora wọn. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé mo ní láti mọ ohun tí mo nílò nípa tẹ̀mí kí n sì wá nǹkan ṣe nípa rẹ̀ tí mo bá fẹ́ ní ìtẹ́lọ́rùn àti ìbàlẹ̀ ọkàn, níwọ̀n bí hílàhílo ayé àti bíbójútó ohun tó ń da àwọn ẹlòmíràn láàmú ti lè kó jìnnìjìnnì bá ẹni tó bá ń ṣe irú iṣẹ́ tí mò ń ṣe yìí.

“Mo ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Ẹ̀kọ́ yìí sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣe mi àti èrò inú mi lọ́nà tó máa mú kí nǹkan sunwọ̀n sí i, kí n sì tún jẹ́ kí ọ̀nà tí mò ń gbà ronú túbọ̀ dára sí i, kí ìgbésí ayé mi lè nítumọ̀. Ọkàn mi ti balẹ̀ gan-an nídìí iṣẹ́ mi báyìí. Àmọ́ ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì ló túbọ̀ fi mí lọ́kàn balẹ̀, tó ràn mí lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun tó máa ń dà mí láàmú, èyí ló bá mi dín pákáǹleke kù, tó sì jẹ́ kí n túbọ̀ máa fi sùúrù àti ìyọ́nú bá àwọn ẹlòmíràn lò. Fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò tún ti ṣàǹfààní fún ìgbéyàwó mi. Ní pàtàkì jù lọ, mo ti wá mọ Jèhófà, mo sì ti rí díẹ̀ lára ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gbà ń ṣiṣẹ́, èyí tó jẹ́ kí ìgbésí ayé mi túbọ̀ nítumọ̀ gan-an.”

Nicholas, tó ń ṣe iṣẹ́ yíya àwòrán ilé, sọ pé: “Mi ò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tẹ̀mí rárá kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó jẹ mí lọ́kàn jù lọ nínú ìgbésí ayé mi ni bí mo ṣe máa kẹ́sẹ járí nínú iṣẹ́ tí mo yàn láàyò. Ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì ti wá jẹ́ kí n mọ̀ pé iṣẹ́ ẹni nìkan kọ́ ló ṣe pàtàkì jù lọ ní ìgbésí ayé àti pé ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà ni yóò fúnni láyọ̀ tòótọ́ tí kò lópin.

“Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi ń múnú mi dùn gan-an, àmọ́ Bíbélì ló kọ́ mi pé ó ṣe pàtàkì láti gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí kí n má bàa walé ayé máyà. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ti mú kó ṣeé ṣe fún èmi àti ìyàwó mi láti yẹra fún pákáǹleke tí gbígbé ìgbésí ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì máa ń kó báni. Àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn tí wọ́n ní èrò kan náà bíi tiwa nípa tẹ̀mí ti jẹ́ ká ní àwọn ojúlówó ọ̀rẹ́ báyìí.”

Vincent, tó jẹ́ agbẹjọ́rò, sọ pé: “Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó dáa lè fúnni láyọ̀ dé ààyè kan. Àmọ́, mo ti wá rí i pé kì í ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹni nìkan ló máa ń fúnni láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Kó tó di pé mo mọ̀ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni lórí kókó náà, mo rántí pé ohun tí mo kàn mọ̀ nípa ìgbésí ayé kó fi bẹ́ẹ̀ nítumọ̀—kò ju pé ká bí èèyàn, kó dàgbà, kó gbéyàwó, kó wá iṣẹ́ tó máa ṣe láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, kó kọ́ wọn láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìgbésí ayé kan náà yẹn, níkẹyìn kó darúgbó kó sì kú.

“Ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ìdáhùn tó tẹ́ mi lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè mi nípa ìdí tá a fi wà nílé ayé. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mo ṣe ti ràn mí lọ́wọ́ láti wá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan àti láti ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún un. Èyí sì ti fún mi láǹfààní láti ní èrò tó dára nípa tẹ̀mí bí mo ṣe ń tiraka láti gbé ìgbésí ayé mi ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí mo mọ̀ pé ó wù ú. Ní báyìí, inú èmi àti aya mi ń dùn pé à ń lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó nítumọ̀ jù lọ.”

Ìwọ náà lè mọ ìdí tá a fi wà nílé ayé kí ìgbésí ayé rẹ sì nítumọ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́. Bíi ti Marina, Nicholas, àti Vincent, ìwọ náà lè ní ayọ̀ tó ń wá látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti àwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé lápapọ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe fún ìwọ gan-an alára. Kì í ṣe pé inú rẹ yóò dùn pé ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ ohun tó o nílò nípa tẹ̀mí nísinsìnyí nìkan, àmọ́ wàá tún máa yọ̀ pé ó ní ìrètí gbígbádùn ìgbésí ayé tí kò lópin nínú ìlera pípé, ìyẹn sì jẹ́ ìrètí tó wà fún kìkì àwọn tí ‘ohun tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.’—Mátíù 5:3.

Àdúrà jẹ́ ọ̀nà kan tá a fi lè di ẹni tẹ̀mí. Jésù lo àkókò láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá a ṣe ń gbàdúrà, ó kọ́ wọn ní ohun tá a mọ̀ sí Àdúrà Olúwa. Kí ni àdúrà yẹn túmọ̀ sí fún ọ lónìí? Báwo lo ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀? Wàá rí ìdáhùn nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó kàn.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Marina

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Nicholas

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Vincent

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́