Ipò Rẹ Nípa Tẹ̀mí àti Ìlera Rẹ
Ó ṢEÉ ṣe kó jẹ́ pé èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ lo fi máa ń bójú tó ìlera rẹ. Ó lè jẹ́ pé ojoojúmọ́ lo máa ń fi nǹkan bíi wákàtí mẹ́jọ sùn, o sì máa ń fi wákàtí bíi mélòó kan dáná oúnjẹ tí wàá sì jẹun, tó o sì ń fi wákàtí mẹ́jọ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣiṣẹ́ tí wàá fi gbọ́ bùkátà ara rẹ. Tí ara rẹ kò bá yá, ó ṣeé ṣe kó ná ẹ lówó àti àkókò kó o tó lè rí dókítà tàbí láti se àgbo tó o máa fi tọ́jú ara rẹ. O máa ń bójú tó ilé rẹ kó lè wà ní mímọ́ tónítóní, ò máa ń wẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kó o máa ṣe eré ìmárale déédéé, ò ń ṣe gbogbo èyí kí ara rẹ lè dá ṣáṣá.
Àmọ́ ṣá o, bíbójútó àwọn ohun tó o nílò nípa tara nìkan kọ́ ló máa jẹ́ kí ara rẹ yá gágá. Ohun kan tún wà tó ṣe pàtàkì gan-an fún ìlera rẹ. Àwọn tó ń ṣe ìwádìí lórí ọ̀ràn ìṣègùn ti sọ pé ńṣe ni ìlera ara rẹ àti ìlera tẹ̀mí rẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ìyẹn ni pé ipò rẹ nípa tẹ̀mí ń nípa lórí ìlera rẹ.
Wọ́n Wọnú Ara Wọn Gan-an
Ọ̀jọ̀gbọ́n Hedley G. Peach tó wà ní Yunifásítì Melbourne, ti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ pé: “Ìwádìí tó ṣeé gbára le jù lọ lórí kókó náà fi hàn pé ipò tẹ̀mí tó túbọ̀ sunwọ̀n sí i ló ń jẹ́ kí ara èèyàn túbọ̀ yá gágá.” Nígbà ti ìwé àtìgbàdégbà The Medical Journal of Australia ń sọ̀rọ̀ nípa ìwádìí tí wọ́n ṣe yìí, ó ní: “Jíjẹ́ ẹni tí kò fi ọ̀ràn ẹ̀sìn ṣeré tún máa ń mú kí . . . ìwọ̀n ìfúnpá èèyàn lọọlẹ̀, kì í jẹ́ kí ọ̀rá pọ̀ jù nínú ara, ó sì lè dín ewu níní àrùn jẹjẹrẹ inú ìfun kù.”
Bákan náà, ìwádìí kan tí Yunifásítì California ti Berkeley, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣe, nígbà tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wá àwọn egbèjìlélọ́gbọ̀n àti àádọ́jọ dín márùn-ún [6,545] èèyàn lẹ́nu wò ní ọdún 2002 fi hàn pé, “àwọn èèyàn tó máa ń lọ sí ilé ìjọsìn lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀ máa ń pẹ́ láyé ju àwọn tí kì í lọ déédéé tàbí àwọn tí kì í tiẹ̀ lọ rárá.” Doug Oman, tó kọ́kọ́ kọ̀wé nípa ìwádìí náà, tó tún jẹ́ olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Berkeley Tó Wà fún Ìlera Ará Ìlú ní Yunifásítì California, sọ pé: “Kódà, ẹ̀yìn tá a gbé àwọn ọ̀ràn bí àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìlera ara, títí kan sìgá mímú àti eré ìmárale yẹ̀ wò la rí ìyàtọ̀ tá a ń wí yìí.”
Nígbà tí ìwé àtìgbàdégbà The Medical Journal of Australia ń tọ́ka sí àwọn àǹfààní mìíràn tó wà fún àwọn tó bìkítà nípa ohun tẹ̀mí, ó ní: “Ìwádìí àwọn ará Ọsirélíà ti fi hàn pé ìgbéyàwó àwọn tí ọ̀ràn ìsìn jẹ lọ́kàn kì í sábà tú ká, wọ́n kì í mu ọtí àmupara, wọn kì í lo oògùn olóró, wọn kì í sábà pa ara wọn, ìrònú pípa ara ẹni kì í tiẹ̀ tètè wá sí wọn lọ́kàn, wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í soríkọ́, wọn kì í sì í mọ ti ara wọn nìkan.” Láfikún sí i, ìwé ìròyìn BMJ (tá a mọ̀ sí British Medical Journal tẹ́lẹ̀) ròyìn pé: “Ó dà bíi pé ìbànújẹ́ àwọn èèyàn tí ìgbàgbọ́ wọn lágbára máa ń tètè pòórá, ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n máa ń ní lẹ́yìn ikú èèyàn wọn sì máa ń tètè fò lọ pátápátá ju ti àwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́.”
Onírúurú èrò làwọn èèyàn ní nípa ohun tí ojúlówó ipò tẹ̀mí jẹ́. Síbẹ̀, ipò rẹ nípa tẹ̀mí ní ipa pàtàkì lórí ìlera rẹ àti ọpọlọ rẹ. Ẹ̀rí yìí bá ohun tí Jésù Kristi sọ mu, ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Níwọ̀n bí ìlera àti ayọ̀ rẹ ti sinmi lórí ipò tó o wà nípa tẹ̀mí, ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti béèrè pé: ‘Ibo ni mo ti lè rí ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí tó ṣeé gbára lé? Kí sì ni jíjẹ́ ẹni tẹ̀mí wé mọ́?’
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Photo Credits: Ojú ìwé 18: Mao Tse-tung àti Golda Meir: Hulton/Archive láti ọwọ́ Getty Images; Francis Ferdinand: Látinú ìwé The War of the Nations; Hirohito, Lindbergh, & Einstein: U.S. National Archives photo; Stalin: Fọ́tò U.S. Army; Roosevelt: Franklin D. Roosevelt Library; Churchill: The Trustees of the Imperial War Museum (MH 26392)