Jèhófà Ń pèsè Àwọn Ohun Tá a Nílò Lójoojúmọ́
“Ẹ sì jáwọ́ nínú àníyàn àìdánilójú; nítorí . . . Baba yín mọ̀ pé ẹ nílò nǹkan wọ̀nyí.”—Lúùkù 12:29, 30.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè fún àwọn ohun tó dá?
ǸJẸ́ o tíì rí ológoṣẹ́ tàbí àwọn ẹyẹ mìíràn níbi tí wọ́n ti ń ṣa ilẹ̀ jẹ lórí àkìtàn? Ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe kàyéfì pé kí ni ẹyẹ yìí ń rí ṣà jẹ níbẹ̀. Nínú Ìwàásù Jésù lórí Òkè, ó fi hàn pé a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń pèsè fún àwọn ẹyẹ. Ó sọ pé: “Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” (Mátíù 6:26) Ọ̀nà àrà ni Jèhófà gbà ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo àwọn ohun tó dá.—Sáàmù 104:14, 21; 147:9.
2, 3. Ẹ̀kọ́ nípa tẹ̀mí wo la lè rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe kọ́ wa láti máa gbàdúrà nípa oúnjẹ òòjọ́ wa?
2 Ó dára, kí nìdí tí Jésù fi sọ pé: “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní” nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó gbà? (Mátíù 6:11) Ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa tẹ̀mí la lè rí kọ́ nínú ohun tó béèrè fún yìí. Lákọ̀ọ́kọ́, ó rán wa létí pé Jèhófà ni Olùpèsè Tó Ga Jù Lọ. (Sáàmù 145:15, 16 ) Ènìyàn lè gbìn kí wọ́n sì roko, ṣùgbọ́n Ọlọ́run nìkan ló lè mú kó dàgbà nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́ríńtì 3:7) Gbogbo ohun tí à ń jẹ àti ohun tí à ń mu jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Ìṣe 14:17) Àdúrà tí a ń gbà pé kó fún wa ní àwọn ohun tá a nílò lójoojúmọ́ fi hàn án pé a kì í ṣe abara-moore-jẹ. Àmọ́ ṣá, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ká má ṣiṣẹ́ tá a bá lágbára láti ṣe é o.—Éfésù 4:28; 2 Tẹsalóníkà 3:10.
3 Ìkejì, bíbéèrè tí a ń béèrè fún “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní” fi hàn pé kò yẹ̀ ká máa ṣàníyàn àṣejù nípa ọjọ́ iwájú. Jésù sọ síwájú sí i pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín. Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” (Mátíù 6:31-34) Àdúrà tá a gbà pé kó fún wa ní “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní” fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún gbígbé ìgbésí ayé oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa “fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”—1 Tímótì 6:6-8.
Oúnjẹ Tẹ̀mí Lójoojúmọ́
4. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo nínú ìgbésí ayé Jésù àti ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí?
4 Àdúrà tí à ń gbà nípa oúnjẹ òòjọ́ yẹ kó tún máa rán wa létí àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò lójoojúmọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi á ti máa pa Jésù gan-an, lẹ́yìn tó ti gba ààwẹ̀ fún àkókò gígún, ó kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí Sátánì dán an wò pé kó sọ òkúta di àkàrà, ó sọ pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’” (Mátíù 4:4) Níhìn, Jésù fa ọ̀rọ̀ wòlíì Mósè yọ, ẹni tó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “[Jèhófà] rẹ̀ ọ́ sílẹ̀, ó sì jẹ́ kí ebi pa ọ́, ó sì fi mánà bọ́ ọ, èyí tí ìwọ kò mọ̀, tí àwọn baba rẹ kò sì mọ̀; kí a lè mú ọ mọ̀ pé ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” (Diutarónómì 8:3) Ọ̀nà tí Jèhófà gbà pèsè mánà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ kí wọ́n rí oúnjẹ nípa tara, ó sì tún kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa tẹ̀mí. Ẹ̀kọ́ kan nípa tẹ̀mí ni pé “olúkúlùkù yóò sì kó iye tirẹ̀ ti òòjọ́ fún òòjọ́.” Bí wọ́n bá kó ju ohun tí wọ́n nílò fún ọjọ́ yẹn, èyí tó ṣẹ́ kù yóò máa rùn yóò sì yọ kòkòrò mùkúlú. (Ẹ́kísódù 16:4, 20) Àmọ́, èyí kì í ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹfà nígbà tí wọ́n bá kó ìlọ́po méjì ohun tí wọ́n máa ń kó lójúmọ́, kí wọ́n bàa lè rí ohun tí wọ́n á jẹ ní ọjọ́ Sábáàtì. (Ẹ́kísódù 16:5, 23, 24) Nítorí náà, mánà yẹn tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onígbọràn àti pé, ìgbésí ayé wọn kò sinmi lórí oúnjẹ nìkan, ṣùgbọ́n lórí “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”
5. Báwo ni Jèhófà ṣe ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa lójoojúmọ́?
5 Bákan náà, àwa náà ní láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ pèsè lójoojúmọ́. Nítorí èyí ni Jésù fi yan ẹrú “olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu’ fún agbo ilé ìgbàgbọ́. (Mátíù 24:45) Kì í ṣe pé ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ yìí ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu nípasẹ̀ àwọn ìwé tí a lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ǹ rọ̀ wá láti máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3) Bíi ti Jésù, àwa náà lè rí ohun tó máa gbé wa ró nípa tẹ̀mí nípa gbígbìyànjú láti kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́ kí á sì máa ṣe é lójoojúmọ́.—Jòhánù 4:34.
Ìdáríjì Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀
6. Irú àwọn gbèsè wo la fẹ́ tọrọ ìdáríjì fún, kí sì ni ohun tó lè mú kí Jèhófà pa wọ́n rẹ́?
6 Ohun tó kan nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà ni pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mátíù 6:12) Kì í ṣe gbèsè owó ni Jésù ń sọ níbí yìí o. Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa ni Jésù ní lọ́kàn. Nínú àkọsílẹ̀ Lúùkù nípa àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà, ó sọ pé: “Dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa fúnra wa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè.” (Lúùkù 11:4) Nítorí náà, bá a bá dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé à jẹ Jèhófà ní gbèsè. Àmọ́, Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ ti ṣe tán láti ‘pa ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́’ tàbí kó mú ẹ̀ṣẹ̀ yẹn kúrò kìkì bí a bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ‘tí a sì yí padà’ tá a wá bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi.—Ìṣe 3:19; 10:43; 1 Tímótì 2:5, 6.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa lójoojúmọ́?
7 Bá a bá tún gba ibòmíràn wò ó, à ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tá a bá kùnà láti dójú ìlà àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, gbogbo wa là ń ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, nínú ìṣe, àti nínú ìrònú wa tàbí nígbà tá a bá kùnà láti ṣe ohun tó yẹ ká ṣe. (Oníwàásù 7:20; Róòmù 3:23; Jákọ́bù 3:2; 4:17) Nítorí náà, bóyá a mọ ìgbà ti a dẹ́ṣẹ̀ lóòjọ́ tàbí a kò mọ̀ ọ́n, ó yẹ ká máa bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nínú àdúrà wa ojoojúmọ́.—Sáàmù 19:12; 40:12.
8. Kí ló yẹ kí àdúrà tá a gbà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ mú kí á ṣe, àǹfààní wo ni yóò sì ṣe wá?
8 Ó yẹ ká fi òótọ́ inú ṣàyẹ̀wò ara wa, ká ronú pìwà dà, ká sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ tá a ní nínú agbára tí ẹ̀jẹ̀ Kristi tí wọ́n ta sílẹ̀ ní láti rà wá padà, nígbà náà, a óò wá gbàdúrà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. (1 Jòhánù 1:7-9) Láti fi hàn pé àdúrà tá a gbà dénú wa, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun tó fi hàn pé a fẹ́ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lóòótọ́, ìyẹn “iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 26:20) Nígbà náà, a wá lè ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà ti ṣe tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. (Sáàmù 86:5; 103:8-14) Ohun tó máa jẹ́ àbájáde rẹ̀ ni ìbàlẹ̀ ọkàn tí kò láfiwé, ìyẹn “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” tí yóò “ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:7) Ṣùgbọ́n àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù gbà túbọ̀ kọ́ wá ní ohun tá a lè ṣe láti rí ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà.
Bá A Bá Fẹ́ Ìdáríjì, A Gbọ́dọ̀ Dárí Jini
9, 10. (a) Kókó wo ni Jésù fi kún àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà, kí sì ni kókó yìí ń tẹnu mọ́? (b) Báwo ni Jésù ṣe túbọ̀ ṣàpèjúwe ìdí tá a fi ní láti máa dárí jini?
9 Ohun tó gbàfiyèsí ni pé, kìkì àdúrà tá a gbà pé “dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa,” nìkan ni apá tí Jésù sọ̀rọ̀ lé lórí nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà. Lẹ́yìn tó parí àdúrà rẹ̀ tán, ó fi kún un pé: “Nítorí bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.” (Mátíù 6:14, 15) Nítorí náà, Jésù mú un ṣe kedere pé kí Jèhófà tó lè dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ ṣe tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn.—Máàkù 11:25.
10 Nígbà kan, Jésù ṣàpèjúwe kan tó fi hàn bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa dárí ji àwọn èèyàn bá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá. Ó sọ ìtàn ọba kan tí àánú sún láti fagi lé gbèsè ńlá tí ẹrú kan jẹ̀ ẹ́. Nígbà tó yá, ọba náà fi ìyà ńlá jẹ ọkùnrin yìí nítorí pé ó kọ̀ láti fagi lé gbèsè kékeré tí ẹ̀rú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ ẹ́. Jésù parí àpèjúwe rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ọ̀nà kan náà ni Baba mi ọ̀run yóò gbà bá yín lò pẹ̀lú bí olúkúlùkù yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ láti inú ọkàn-àyà yín wá.” (Mátíù 18:23-35) Ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀ ṣe kedere pé: Gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà ń dárí rẹ̀ jì wá tóbi fíìfíì ju ẹ̀ṣẹ̀ èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni lè ṣẹ̀ wá lọ. Àti pé, ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń dárí jì wá. Bọ́rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ́ ká lè dárí ji àwọn èèyàn, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá.
11. Bí a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá, ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún wa wo ló yẹ ká tẹ̀ lé, ìyọrísí dáradára wo sì ni ìyẹn lè ní?
11 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:32) Àlàáfíà yóò jọba láàárín àwa tá a jẹ Kristẹni bí a bá ń dárí ji ara wa lẹ́nì kìíní-kejì. Pọ́ọ̀lù tún gbà wá níyànjú síwájú sí i pé: “Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ. Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:12-14) Gbogbo èyí ló wà nínú àdúrà tí Jésù kọ́ wa pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.”
Ààbò Nígbà Tá A Bá Wà Nínú Ìdẹwò
12, 13. (a) Kí ni ìtumọ̀ ohun mìíràn tí Jésù bẹ̀bẹ̀ fún kó tó sọ èyí tó kẹ́yìn nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó gbà? (b) Ta ni Adẹniwò tó burú jù lọ, kí sì ni àdúrà náà pé kí á má ṣe wá sínú ìdẹwò túmọ̀ sí?
12 Ohun mìíràn tí Jésù bẹ̀bẹ̀ fún kó tó sọ èyí tó kẹ́yìn nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó gbà náà ni pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò.” (Mátíù 6:13) Ṣé ohun tí Jésù ń sọ ni pé ká bẹ Jèhófà pé kó máà dán wa wò? Kò lè rí bẹ́ẹ̀, nítorí Ọlọ́run mí sí Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti kọ̀wé pé: “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà lábẹ́ àdánwò, kí ó má ṣe sọ pé: ‘Ọlọ́run ni ó ń dán mi wò.’ Nítorí a kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Síwájú sí i, onísáàmù kọ̀wé pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Jèhófà kì í ṣọ́ gbogbo àṣìṣe tá a bá ṣe, ó sì dájú pé kì í dẹ wá wò ká bàa lè ṣàṣìṣe. Ó dára, kí wá ni apá yìí nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà túmọ̀ sí?
13 Sátánì Èṣù ló máa ń dẹ wá wò, tó máa ń mú ká kọsẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìwà àrékérekè rẹ̀, àní òun ló máa ń wù láti ṣe wá léṣe. (Éfésù 6:11) Òun ni Adẹniwò tó burú jù lọ. (1 Tẹsalóníkà 3:5) Nígbà tá a bá gbàdúrà pé kí á má ṣe wá sínú ìdẹwò, ńṣe la ń bẹ Jèhófà pé kó máà jẹ́ ká juwọ́ sílẹ̀ nígbà tá a bá wà lábẹ́ àdánwò. Ńṣe là ń bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ kí “Sátánì má bàa fi ọgbọ́n àyínìke borí wa,” ká wá tipa bẹ́ẹ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ìdẹwò. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Àdúrà wa ni pé kí á wà ní “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ,” ká sì máa rí ààbò tẹ̀mí tí Jèhófà ń fún àwọn tó bọ̀wọ̀ fún ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe.—Sáàmù 91:1-3.
14. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò ní kọ̀ wá sílẹ̀ bá a bá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Rẹ̀ nígbà tá a bá wà nínú ìdẹwò?
14 Ó yẹ kó dá wa lójú pé, bó bá jẹ́ ohun tó ń wù wá lọ́kàn lóòótọ́ nìyẹn, tá a sì fi sínú àdúrà, tó sì tún hàn nínú àwọn ohun tá a ń ṣe, ó dájú pé Jèhófà kò ní kọ̀ wá sílẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú un dá wa lójú pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
“Dá Wa Nídè Kúrò Lọ́wọ́ Ẹni Burúkú Náà”
15. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì nísinsìnyí ju ti ìgbàkígbà rí lọ láti máa gbàdúrà kí á lè bọ́ lọ́wọ́ ẹni burúkú náà?
15 Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì táwọn èèyàn fọkàn tán jù lọ, ọ̀rọ̀ tí Jésù fi parí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó gbà náà ni: “Dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”a (Mátíù 6:13) Ààbò kúrò lọ́wọ́ Èṣù tiẹ̀ wá ṣe pàtàkì gan-an nísinsìnyí tá a ti wà ní àkókò òpin. Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń gbógun ti àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró, ìyẹn “àwọn ẹni tí ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù,” ó ṣì ń gbógun ti àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú. (Ìṣípayá 7:9; 12:9, 17) Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ. Ṣùgbọ́n ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.” (1 Pétérù 5:8, 9) Sátánì á fẹ́ láti dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró, nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé—bóyá ètò ìsìn, ètò ìṣòwò tàbí ti ìṣèlú—ó ń gbìyànjú láti ṣẹ̀rù bà wá. Àmọ́, bí a bá dúró ṣinṣin, Jèhófà yóò gbà wá. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.
16. Ipasẹ̀ àwọn wo ni Jèhófà ń gbà ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó bá wà lábẹ́ ìdẹwò lọ́wọ́?
16 Jèhófà gba ìdẹwò tó dé bá Ọmọ rẹ̀ láyè. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Jésù ti kọ ojú ìjà sí Èṣù, tó fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ààbò, Jèhófà rán àwọn áńgẹ́lì láti fún un lókun. (Mátíù 4:1-11) Bákan náà, Jèhófà ń lo àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ bá a bá fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà tá a sì fi Ọlọ́run ṣe ààbò wa. (Sáàmù 34:7; 91:9-11) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.”—2 Pétérù 2:9.
Ìdáǹdè Pátápátá Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé
17. Báwo ni Jésù ṣe to àwọn nǹkan bó ṣe yẹ nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà?
17 Jésù to àwọn nǹkan bó ṣe yẹ nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà. Sísọ orúkọ ńlá àti orúkọ mímọ́ Jèhófà di mímọ́ ló yẹ kó gbà wá lọ́kàn. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ìjọba Mèsáyà ni irinṣẹ́ tá ó fi ṣe èyí, nígbà náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ìjọba náà tètè dé láti wá pa gbogbo ìjọba èèyàn aláìpé wọ̀nyí run, kó sì rí i dájú pé ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe níhìn lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí ń ṣe lọ́run. Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé tá a ní sinmi lórí sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, káwọn èèyàn jákèjádò ayé sí mọ̀ nípa ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ tó jẹ́ ti òdodo. Lẹ́yìn tá a bá ti gbàdúrà fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì gan-an yìí, à wá lè gbàdúrà fún àwọn ohun tá a nílò lóòjọ́, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ìdẹwò àti àwọn ètekéte ẹni burúkú náà, Sátánì Èṣù.
18, 19. Báwo ni àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù gbà ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, tó sì tún jẹ́ kí ìrètí wa ‘fìdí múlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin’?
18 Ìdáǹdè wa pátápátá kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà àti kúrò lọ́wọ́ ètò àwọn nǹkan rẹ̀ tó ti dómùkẹ̀ yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé báyìí. Sátánì mọ̀ dáadáa pé ìwọ̀nba “àkókò kúkúrú” ló kù fún òun láti fi “ìbínú ńlá” hàn sórí ayé yìí, pàápàá jù lọ sórí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Ìṣípayá 12:12, 17) Nínú àmì “ìparí ètò àwọn nǹkan” tó ní oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ nínú, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń múni jí gìrì, èyí tí díẹ̀ nínú wọn ṣì wà lọ́jọ́ iwájú. (Mátíù 24:3, 29-31) Bá a ṣe ń rí ìmúṣẹ àwọn nǹkan wọ̀nyí, ńṣe ni ìrètí tá a ní pé a ó dá wa nídè túbọ̀ lágbára sí i. Jésù sọ pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀, ẹ gbé ara yín nà ró ṣánṣán, kí ẹ sì gbé orí yín sókè, nítorí pé ìdáǹdè yín ń sún mọ́lé.”—Lúùkù 21:25-28.
19 Àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tó ṣe ṣókí tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yìí fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé nípa àwọn ohun tá a lè fi sínú àdúrà wa bí òpin tí ń sún mọ́lé. Ǹjẹ́, kí á ní ìdánilójú pé títí dé òpin, Jèhófà yóò máa bá a lọ láti pèsè àwọn ohun tá a nílò nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Wíwàlójúfò wa nínú àdúrà yóò jẹ́ ká lè “di ìgbọ́kànlé tí a ní ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mú ṣinṣin ní fífìdímúlẹ̀ gbọn-in títí dé òpin.”—Hébérù 3:14; 1 Pétérù 4:7.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun táwọn Bíbélì kan tó ti pẹ́ irú bíi Bíbélì Mímọ́, fi parí àdúrà Olúwa ni gbígbé ògo fún Ọlọ́run, tó kà pé: “Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.” Ìwé The Jerome Biblical Commentary sọ pé: “ Kò sí gbígbé ògo fún Ọlọ́run nínú [ẹ̀dà àfọwọ́kọ] tá a fọkàn tán jù lọ.”
Àtúnyẹ̀wò
• Kí ló túmọ̀ sí láti gbàdúrà nípa “oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní”?
• Ṣàlàyé àdúrà náà tó sọ pé “dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.”
• Kí ló túmọ̀ sí nígbà tá a bá sọ pé kí Jèhófà má fà wá sínú ìdẹwò?
• Kí nìdí tá a fí ní láti gbàdúrà pé kí Jèhófà “dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà”?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A ní láti dárí ji àwọn ẹlòmíràn bí a bá fẹ́ kí wọ́n dárí ji àwa náà
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]
Lydekker