Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àdúrà Olúwa
ÀDÚRÀ Olúwa, tí Jésù kọ́ni nínú Ìwàásù Lórí Òkè, wà nínú Bíbélì ní Mátíù orí kẹfà, ẹsẹ kẹsàn-án sí ìkẹtàlá. Ṣáájú kí Jésù tó gba àdúrà yìí, ó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé a óò gbọ́ tiwọn nítorí lílò tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ púpọ̀.”—Mátíù 6:7.
Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé Jésù kò ní in lọ́kàn pé ká máa ka Àdúrà Olúwa ní àkàtúnkà bí wọ́n ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ gan-an. Lóòótọ́, ó tún àdúrà yìí gbà lẹ́yìn náà fún àǹfààní àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mìíràn. (Lúùkù 11:2-4) Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà náà yàtọ̀ síra tá a bá wo àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Mátíù àti ti Lúùkù. Láfikún sí i, nínú àwọn àdúrà mìíràn tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbà lẹ́yìn ìgbà náà, wọn ò tún àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà sọ.
Kí wá nìdí tí Àdúrà Olúwa fi wà nínú Bíbélì? Ìdí ni pé nípasẹ̀ àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yìí ni Jésù kọ́ wa ní ọ̀nà tá a fi lè gbàdúrà kí Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà á. Nínú àdúrà yìí, a tún rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìdí téèyàn fi wà láyé. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò kókó kọ̀ọ̀kan inú Àdúrà Olúwa.
Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run nípa pípè é ní “Baba wa.” Bí ọkàn ọmọ kékeré kan ti máa ń fà mọ́ òbí tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sì lóye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ làwa náà lè gbàdúrà sí Baba wa ọ̀run kí ọkàn wa sì balẹ̀ pé yóò gbọ́ wa. Dáfídì Ọba kọ ọ́ lórin pé: “Ìwọ Olùgbọ́ àdúrà, àní ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara gbogbo yóò wá.”—Sáàmù 65:2.
Jésù ní ká máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Àmọ́ kí ni orúkọ Ọlọ́run? Bíbélì dáhùn pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Ǹjẹ́ o ti rí orúkọ yẹn kà rí nínú Bíbélì?
Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìgbà ẹgbẹ̀rún méje lọ tí orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, fara hàn nínú àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn atúmọ̀ èdè kan yọ orúkọ yìí kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Ó tọ̀nà nígbà náà pé ká gbàdúrà pé kí Ẹlẹ́dàá sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Ìsíkíẹ́lì 36:23) Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe ohun tí àdúrà yìí sọ ni pé ká máa lo orúkọ náà Jèhófà nígbà tá a bá ń gbàdúrà sí Ọlọ́run.
Inú ìsìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Patricia dàgbà, ó sì mọ Àdúrà Oluwa bí ẹní mowó. Báwo ló ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi orúkọ Ọlọ́run hàn án nínú Bíbélì? Kò lè mú un mọ́ra, ó sọ pé: “Ó ṣòro fún mi láti gbà pé ó wà níbẹ̀ lóòótọ́! Mo mú Bíbélì tèmi náà mo sì wò ó, bẹ́ẹ̀ ni mo rí i níbẹ̀. Lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí yìí ṣí Mátíù 6:9, 10 hàn mí ó sì ṣàlàyé pé Àdúrà Olúwa sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Ọlọ́run. Inú mi dùn gan-an, mo sì ní kí obìnrin náà wá máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Kí Ìfẹ́ Ọlọ́run Di Ṣíṣe Lórí Ilẹ̀ Ayé
“Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Báwo ni kókó inú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ Jésù yìí yóò ṣe nímùúṣẹ? Ọ̀pọ̀ èèyàn ka ọ̀run sí ibi àlàáfíà àti ibi ìfọ̀kànbalẹ̀. Ìwé mímọ́ pe ọ̀run ní “ibùjókòó [Jèhófà] gíga fíofío ti ìjẹ́mímọ́ àti ẹwà.” (Aísáyà 63:15) Abájọ tá a fi ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé “gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run”! Àmọ́, ǹjẹ́ èyí yóò ṣẹlẹ̀?
Dáníẹ́lì tó jẹ́ wòlíì Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Dáníẹ́lì 2:44) Láìpẹ́, Ìjọba ọ̀run yìí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti mú kí àlàáfíà jọba ní gbogbo ayé nípásẹ̀ ìṣàkóso òdodo.—2 Pétérù 3:13.
Àdúrà tá à ń gbà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọ̀rọ̀ tó fi ìgbàgbọ́ hàn, ìrètí wa yìí kò sì ní já sófo. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’” Lẹ́yìn náà Jòhánù fi kún un pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: . . . ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́’”—Ìṣípayá 21:3-5.
Gbígbàdúrà fún Àwọn Ohun Tá A Nílò Nípa Tara
Látinú ohun tí Jésù sọ nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà, ó jẹ́ ká rí i pé ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ wá lọ́kàn jù lọ tá a bá ń gbàdúrà làwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀. Àmọ́ o, ohun tí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà mẹ́nu kàn tẹ̀ lé e ni bíbéèrè àwọn nǹkan tara téèyàn nílò lọ́wọ́ Jèhófà.
Àkọ́kọ́ lára àwọn nǹkan náà ni: “Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní.” (Mátíù 6:11) Ọrọ̀ kọ́ ni Jésù ní ká tọrọ lọ́dọ̀ Ọlọ́run. “Oúnjẹ wa fún òòjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí òòjọ́ ń béèrè” ló rọ̀ wá pé ká gbàdúrà fún. (Lúùkù 11:3) Bá a ṣe rí i nínú Àdúrà Olúwa, a lè gbàdúrà ká sì ní ìgbàgbọ́ pé Ọlọ́run yóò pèsè àwọn ohun tá a nílò lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan fún wa bá a bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tá a sì ń ṣègbọràn sí i.
Tá a bá wá ń ṣàníyàn tí kò yẹ nítorí àtijẹ àtimu, èyí lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìnáání àwọn nǹkan tẹ̀mí a ò sì ní ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Àmọ́ tá a bá fi ìjọsìn Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa, àá ní ìfọ̀kànbalẹ̀ pé inú Ọlọ́run yóò dùn láti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa fún àwọn ohun tara tá a nílò, irú bí oúnjẹ àti aṣọ. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:26-33) Wíwá òdodo Ọlọ́run kò rọrùn, níwọ̀n bí gbogbo wa ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tá a sì ń fẹ́ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Àdúrà Olúwa tún mẹ́nu kan kókó yìí.
Gbígbàdúrà fún Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀
“Dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa.” (Mátíù 6:12) Nínú àkọsílẹ̀ tí Lúùkù kọ nípa Àdúrà Olúwa, “ẹ̀ṣẹ̀” ló pe àwọn “gbèsè” wọ̀nyí. (Lúùkù 11:4) Ṣé lóòótọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run yóò dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, ó ronú pìwà dà ó sì fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà pé: “Ẹni rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini; inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́ sì pọ̀ yanturu.” (Sáàmù 86:5) Ẹ ò rí i pé gbólóhùn yìí ń tuni nínú gan-an! Baba wa ọ̀run “ṣe tán láti dárí” ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì ké pè é. Bó ṣe dájú pé a lè dárí gbèsè tẹ́nì kan jẹ jì í pátápátá, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá pátápátá.
Àmọ́ ṣá o, Jésù sọ ohun kan tó lè mú kí èyí ṣeé ṣe: Ohun náà ni pé kí Ọlọ́run tó lè dárí jì wá, àwa náà gbọ́dọ̀ dárí ji àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 6:14, 15) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Jóòbù mẹ́ta hùwà tí kò tọ́ sí i, síbẹ̀ ó dárí jì wọ́n, kódà ó tún gbàdúrà fún wọn. (Jóòbù 42:10) Bá a bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a óò múnú Ọlọ́run dùn yóò sì ṣeé ṣe fún wa láti jàǹfààní àánú rẹ̀.
Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti múra tán láti tẹ́tí sí àwọn ẹ̀bẹ̀ wa, ó yẹ kí èyí sún wa láti máa wá ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. A sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé. (Mátíù 26:41) Lórí kókó yìí, Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti fi hàn nínú ẹ̀bẹ̀ pàtàkì tó fi kádìí àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ náà.
Gbígbàdúrà fún Ìrànwọ́ Láti Lè Máa Gbé Ìgbé Ayé Òdodo
“Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Kì í ṣe pé Jèhófà máa ń fini sílẹ̀ láti dá kojú ìdẹwò bẹ́ẹ̀ ni kì í súnni dẹ́ṣẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Ọlọ́run máa ń fàyè sílẹ̀ ká rí ìdẹwò, àmọ́ ó lè gbà wá lọ́wọ́ Adẹniwò tó burú jù lọ náà, ìyẹn “ẹni burúkú náà” tá a mọ̀ sí Sátánì Èṣù.
Àpọ́sítélì Pétérù gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.” (1 Pétérù 5:8) Àní, Sátánì dẹ Jésù Kristi tó jẹ́ ẹni pípé pàápàá wò! Kí ni ète Èṣù? Ó fẹ́ láti fa Jésù kúrò nínú ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run. (Mátíù 4:1-11) Bó o bá fẹ́ sin Ọlọ́run, Sátánì yóò máa wá ọ̀nà tí yóò fi mú ìwọ náà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́!
Èṣù lè lo ayé tó ń darí yìí láti dẹ wá wò ká lè lọ́wọ́ sáwọn ohun tí Ọlọ́run kà léèwọ̀. (1 Jòhánù 5:19) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì ká máa gbàdúrà sí Ọlọ́run déédéé pé kó ràn wá lọ́wọ́, àgàgà tí ìdẹwò kan bá ń wá léraléra. Tá a bá sì jọ́sìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bó ṣe là á sílẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, yóò gbà wá nípa ríràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún Èṣù. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
Ìgbàgbọ́ Nínú Ọlọ́run Ṣe Kókó
Mímọ̀ pé ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa jẹ Baba wa ọ̀run lógún ń múnú ẹni dùn gan-an ni! Kódà ó tún jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi, kọ́ wa bí a ó ṣe máa gbàdúrà. Ó dájú pé èyí mú ká fẹ́ láti múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn. Báwo la ṣe lè ṣe é?
Bíbélì sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Báwo la ṣe lè ní irú ìgbàgbọ́ yìí? Bíbélì dáhùn pé: “Ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.” (Róòmù 10:17) Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń dùn láti bá gbogbo àwọn tó fẹ́ láti sin Ọlọ́run pẹ̀lú ojúlówó ìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ.
A nírètí pé ìjíròrò Àdúrà Olúwa yìí ti mú kí òye rẹ nípa ìtumọ̀ àdúrà náà túbọ̀ jinlẹ̀ sí i. Tó o bá gba ìmọ̀ síwájú sí i nípa Jèhófà àti èrè tí yóò san fún “àwọn tí ń fi taratara wá a,” ìgbàgbọ́ rẹ nínú Ọlọ́run á túbọ̀ lágbára sí i. À ń rọ̀ ọ́ pé kó o túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run àti nípa àwọn ohun tó fẹ́ ṣe kó o lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Baba rẹ ọ̀run títí láé.—Jòhánù 17:3.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
“Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú. Fún wa lónìí oúnjẹ wa fún ọjọ́ òní; kí o sì dárí àwọn gbèsè wa jì wá, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti dárí ji àwọn ajigbèsè wa. Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.”—Mátíù 6:9-13
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jèhófà máa ń pèsè nǹkan táwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nílò fún wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọlọ́run tún ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa juwọ́ sílẹ̀ fún Èṣù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bíi Jóòbù, táwa náà bá ń darí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, a ó jàǹfààní àánú Ọlọ́run