Ṣé Ìsìn Ló Fa Ìṣòro Aráyé?
“TÍ ÌSÌN ò bá fa gbọ́nmisi-omi-ò-to, á sọ ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn di aláìṣiṣẹ́mọ́ tàbí kó máa tan àwọn èèyàn jẹ́. . . . [Ó] ń sọ àwọn èèyàn di aláìgbatẹnirò, onígbàgbọ́ nínú ohun àsán, oníkòórìíra àti ẹni tó máa ń bẹ̀rù.” Ẹni kan to jẹ́ míṣọ́nnárì tẹ́lẹ̀ rí nínú ìjọ Mẹ́tọ́díìsì, tó sọ ọ̀rọ̀ ìṣáájú yẹn tún fi kún un pé: “Òótọ́ ni àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyẹn. Bí ìsìn rere ṣe wà ni ìsìn burúkú wà.”—Látinú ìwé Start Your Own Religion.
Àwọn kan lè máa sọ pé ‘àríwísí yẹn ò tọ̀nà rárá.’ Àmọ́ ta ló lè sẹ́ pé àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ látẹ̀yìnwá kì í ṣòótọ́? Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ìsìn sí “sísìn àti jíjọ́sìn Ọlọ́run tàbí agbára kan tó jú ti ẹ̀dá lọ.” Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìwà ìbàjẹ́ ni ìsìn ti hù. Ńṣe ló yẹ́ kí ìsìn máa là wá lóye, kó sì jẹ́ ìṣírí fún wa. Dípò ìyẹn, ẹ̀mí ìjà, ẹ̀tanú àti ìkórìíra ló sábà máa ń gbìn sáwọn èèyàn lọ́kàn. Kí nìdí tí ìsìn fi ń fa irú ìṣòro yìí?
“Áńgẹ́lì Ìmọ́lẹ̀” Tó Ń Ṣini Lọ́nà
Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú Bíbélì, ìdáhùn ìbéèrè yẹn rọrùn. Sátánì Èṣù ń ṣe bí “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀,” ó sì ti ṣi ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́nà láti máa tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tirẹ̀ dípò ti Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 11:14) Àpọ́sítélì Jòhánù fi hàn pé ipa tí Sátánì ní lórí àwọn èèyàn pọ̀ débi pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Jòhánù mọ̀ pé Sátánì ń “ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.”—Ìṣípayá 12:9.
Kí wá ni èyí ti yọrí sí? Sátánì ń gbé ètò ìsìn lárugẹ tó fi dà bíi pé ó jẹ́ mímọ́. “‘Ìsìn’ ojú ayé ni wọ́n ń ṣe,” èso búburú tí wọ́n ń mú jáde ló fi bí wọ́n ṣe rí gan-an hàn. (2 Tímótì 3:5, ìtumọ̀ ti J. B. Phillips; Mátíù 7:15-20) Dípò tí ìsìn á fi tán ìṣòro aráyé, ńṣe ló ń dá kún un.
Má kàn yára gbà pé ọ̀rọ̀ yìí ò jóòótọ́ tàbí pé kò bọ́gbọ́n mu. Ohun kan tí kò yẹ ká gbàgbé ni pé àwọn tí wọ́n bá ń tàn jẹ kì í mọ̀ pé ẹ̀tàn ni. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ èyí hàn nígbà tó kọ̀wé pé: “Àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 10:20) Ìyàlẹ́nu ló máa jẹ́ fáwọn èèyàn wọ̀nyẹn láti mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù làwọn ń jọ́sìn. Wọ́n rò pé àwọn ń jọ́sìn ọlọ́run rere kan tàbí irú àwọn ọlọ́run kan. Òótọ́ ibẹ̀ sì ni pé “àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run,” tó ń ti Sátánì lẹ́yìn láti ṣi aráyé lọ́nà, ti tàn wọ́n jẹ.—Éfésù 6:12.
Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí Sátánì ṣe ń rí ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni tàn jẹ tó sì ń ṣì wọ́n lọ́nà, ìyẹn àwọn tí kò kọbi ara sí ìkìlọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù fúnni nípa agbára àwọn ẹ̀mí èṣù.—1 Kọ́ríńtì 10:12.
Ọ̀dọ́ Ọlọ́run Ni Jésù Ti Gba Ẹ̀kọ́ Tó Fi Ń Kọ́ni
Jésù Kristi sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Òótọ́ ni, ọ̀dọ́ Ọlọ́run Olódùmarè ló ti gba ẹ̀kọ́ tó fi ń kọ́ni. Ìdí rèé tí ẹ̀kọ́ Jésù fi ní ipa lílágbára àti ipa rere lórí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ̀kọ́ rẹ̀ kò ‘sọ ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn di aláìṣiṣẹ́mọ́ bẹ́ẹ̀ ní kì í ṣe ẹ̀tàn.’ Dípò ìyẹn, ńṣe làwọn ẹ̀kọ́ Jésù máa ń gba àwọn èèyàn lọ́wọ́ àwọn àṣìṣe ìsìn àti ọgbọ́n orí tí ó wá látinú ayé tí ìtànjẹ Èṣù mú kó wà “nínú òkùnkùn ní ti èrò orí.”—Éfésù 4:18; Mátíù 15:14; Jòhánù 8:31, 32.
Sísọ tí àwọn kan ń sọ pé àwọn ní ìtara ìsìn kọ́ la fi máa mọ̀ pé wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ìgbàgbọ́ tí ó gbé àwọn ànímọ́ dídára ti ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yọ la fi ń mọ̀ wọ́n. (Gálátíà 5:22, 23; Jákọ́bù 1:22; 2:26) Ọ̀kan tó ta yọ lára àwọn ànímọ́ yìí, tá a sì fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀, ni ìfẹ́.—Jòhánù 13:34, 35.
Àmọ́, kíyè sí kókó pàtàkì yìí: Jésù ò retí pé ìjọ Kristẹni yóò máa bá a lọ bó ṣe kọ́kọ́ wà ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, bẹ́ẹ̀ làwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ò retí pé yóò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Wọ́n mọ̀ pé àwọn apẹ̀yìndà yóò dìde àti pé ìsìn tòótọ́ yóò fara sin fún àkókò kan.
Ìsìn Tòótọ́ Fara Sin fún Àkókò Kan
Nínú àkàwé kan tí Jésù ṣe nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé ìsìn tòótọ́ yóò fara sin fún àkókò kan. Ka ìtàn náà fúnra rẹ nínú Mátíù 13:24-30, 36-43. Jésù gbin àlìkámà, ìyẹn “irúgbìn àtàtà,” sínú ilẹ̀. Irúgbìn náà dúró fún àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ó kìlọ̀ pé tó bá yá “ọ̀tà kan,” ìyẹn Sátánì Èṣù, yóò gbin “àwọn èpò,” sínú oko àlìkámà náà. “Àwọn èpò” náà sì dúró fún àwọn tó pe ara wọn ní ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi ṣùgbọ́n tí wọn kò fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀.
Kété lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì Jésù kú tán làwọn kan tí wọ́n jẹ́ “èpò” dìde, wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èèyàn tó gbòdì dípò “ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Jeremáyà 8:8, 9; Ìṣe 20:29, 30) Àbájáde èyí sì ni pé ayédèrú ìsìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n kúnnú rẹ̀ ni àwọn tí Bíbélì pè ní “aláìlófin,” ìyẹn ẹgbẹ́ àlùfáà oníwà ìbàjẹ́ tí “gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo” ti wọ̀ lẹ́wù. (2 Tẹsalóníkà 2:6-10) Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ipò yìí yóò yí padà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan.” A óò kó àwọn Kristẹni tí wọ́n dà bí àlìkámà jọ ní ìṣọ̀kan, a ó sì pa “àwọn èpò” run lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Àwọn ayédèrú ìsìn Kristẹni yìí kan náà ló fa “ojú dúdú fún àìmọye ọdún” àti òkùnkùn tẹ̀mí tó bo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì mọ́lẹ̀ biribiri ní ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e. Nítorí àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé èyí àti gbogbo àwọn ìwàkíwà àti ìwà ìkà tí wọ́n ń hù lórúkọ ìsìn látìgbà náà wá yóò ṣẹlẹ̀, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní tìtorí [àwọn tó pera wọn ní Kristẹni] wọ̀nyí, ọ̀nà òtítọ́ yóò sì di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú.”—2 Pétérù 2:1, 2.
“Ẹ̀kọ́ Ìgbàgbọ́ Tó Dá Lórí Ìbínú àti Ìkórìíra”
Dájúdájú, kì í ṣe àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nìkan ló ń bá ìsìn lórúkọ jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìtàn àwọn “alágídí onítara ìsìn” tí wọ́n jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Obìnrin kan tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tẹ́lẹ̀ rí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Karen Armstrong, sọ pé inú “àwọn ìsìn kàǹkàkàǹkà” ni wọ́n ti jáde. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Armstrong, ọ̀nà kan tá a lè fi dán ìsìn kan wò láti mọ̀ bóyá ó dáa ni pé, ká wò ó bóyá ó ń gbin “ẹ̀mí ìyọ́nú” sí àwọn èèyàn lọ́kàn. Kí ni ìtàn ẹ̀sìn àwọn agbawèrèmẹ́sìn fi hàn lórí ọ̀ràn yìí? Obìnrin náà kọ̀wé pé, “tí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ àwọn agbawèrèmẹ́sìn, yálà tàwọn ẹlẹ́sìn Júù, Kristẹni tàbí ti Mùsùlùmí, bá di èyí tó dá lórí ìbínú àti ìkórìíra, á jẹ́ pé wọn kò yege ìdánwò náà nìyẹn.” (Ìwé The Battle for God—Fundamentalism in Judaism, Christianity and Islam) Àmọ́, ṣé “ẹ̀sìn àwọn agbawèrèmẹ́sìn” nìkan ni kò yege ìdánwò yìí, tí wọ́n sì ń fi “ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ tó dá lórí ìbínú àti ìkórìíra” kọ́ni? Ìtàn fi han pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀ràn rí.
Sátánì gbé ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé kalẹ̀, ohun tí a sì fi ń dá ilẹ̀ ọba náà mọ̀ ni ìbínú, ìkórìíra àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ò dáwọ́ dúró. Bíbélì pé ilẹ̀ ọba yìí ni “Bábílónì Ńlá, ìyá . . . àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé,” ó sì fi í hàn bí aṣẹ́wó tó ń gun ètò ìṣèlú oníwà ẹhànnà bí ẹní gẹṣin. Ó yẹ fún àfiyèsí pé yóò jíyìn fún “ẹ̀jẹ̀ . . . gbogbo àwọn tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 17:4-6; 18:24.
Kì Í Ṣe Gbogbo Èèyàn Ló Rí Tàn Jẹ?
Ìtàn fi hàn pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló rí tàn jẹ. Melvyn Bragg sọ pé láwọn àkókò táráyé wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí pàápàá, “ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe rere, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà ìkà lọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó yí wọn ká ń hù.” Àwọn Kristẹni tòótọ́ kò yé “jọ́sìn [Ọlọ́run] ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:21-24) Wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára ètò ìsìn àgbáyé, tó ti sọ ara rẹ̀ di aṣẹ́wó tó jẹ́ “alátìlẹyìn àwọn ológun.” Wọ́n kọ̀ láti dá sí àjọṣe tó wà láàárín Ìsìn àti Ìjọba, èyí tí ìtàn fi hàn pé “Sátánì ló pa wọ́n pọ̀, kì í ṣe Jésù ti Násárétì.”—Ìwé Two Thousand Years—The Second Millennium: From Medieval Christendom to Global Christianity.
Lónìí, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ní ipa tó dára lórí àwọn èèyàn. Kí ìsìn èké má bàa kó àbàwọ́n kankan bá wọn, wọ́n gbé gbogbo ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìṣe wọn ka Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ìyẹn Bíbélì. (2 Tímótì 3:16, 17) Bíi tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn náà ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù láti má ṣe jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 15:17-19; 17:14-16) Bí àpẹẹrẹ, nígbà ìjọba Násì ní ilẹ̀ Jámánì, wọ́n kọ̀ láti fi ìlànà Kristẹni báni dọ́rẹ̀ẹ́ nítorí èyí wọn kò tẹ́wọ́ gbà wọn gẹ́gẹ́ ìlànà ìjọba Násì ti wí. Hitler kórìíra wọn nítorí èyí. Ìwé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà . . . tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ka gbígbé ohun ìjà ogun léèwọ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun tàbí kí wọ́n torí bọ ọ̀ràn èyíkéyìí tó jẹ mọ́ ti ìjọba Násì. Kí àwọn ẹ̀ṣọ́ tá à ń pé ní SS lè gbẹ̀san, wọ́n fi gbogbo ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí àtìmọ́lé. Nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà [ní ilẹ̀ Jámánì] ni wọ́n pa nínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.”—Germany—1918 sí 1945.
Òótọ́ ni pé àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ onígboyà nínú onírúurú ìsìn pàápàá jìyà nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́, ńṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ jìyà pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwùjọ onísìn tó wà níṣọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn rọ̀ mọ́ ìlànà pàtàkì inú Ìwé Mímọ́ tó ní: “Ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29; Máàkù 12:17.
Ohun Tó Fa Ìṣòro Náà Gan-an
A ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé ìsìn ló fa gbogbo ìṣòro aráyé. Ìsìn èké ló fà á. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run ti ní in lọ́kàn láti mú gbogbo ìsìn èké kúrò láìpẹ́. (Ìṣípayá 17:16, 17; 18:21) Àṣẹ tó pa fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo àti òdodo ni: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, [ìyẹn Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé], ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́ jọpọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti mú àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.” (Ìṣípayá 18:4, 5) Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Ọlọ́run kò dùn sí ẹ̀sìn tó ń ‘fa gbọ́nmisi-omi-ò-to, tó ń sọ ẹ̀rí ọkàn àwọn èèyàn di aláìṣiṣẹ́mọ́, tó ń tan àwọn èèyàn jẹ, tó ń mú káwọn èèyàn di aláìgbatẹnirò, onígbàgbọ́ nínú ohun àsán, oníkòórìíra àti ẹni tó máa ń bẹ̀rù’!
Ní báyìí ná, Ọlọ́run ń kó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ jọ sínú ìsìn mímọ́ gaara. Èyí ni ìsìn tó rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà àti ẹ̀kọ́ Ẹlẹ́dàá, onífẹ̀ẹ́, tó jẹ́ aláìṣègbè àti oníyọ̀ọ́nú. (Míkà 4:1, 2; Sefanáyà 3:8, 9; Mátíù 13:30) Ìwọ náà lè wà lára wọn. Tó o bá ń fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa bó o ṣe lè dá ìsìn mímọ́ gaara mọ̀, máà lọ́tìkọ̀ láti kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde tàbí kó o sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn èèyàn láti ibi gbogbo ń láyọ̀ nínú ìsìn mímọ́ gaara