Ìtùnú fún Àwọn Tó Wà Nínú Ìpọ́njú
NÍGBÀ táwọn ọkùnrin àtobìnrin olóòótọ́ ayé àtijọ́ bá wà nínú ìpọ́njú, wọ́n máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn sí Ọlọ́run fún ìtọ́sọ́nà. Àmọ́ wọ́n tún máa ń lo ìdánúṣe láti ṣe àwọn ohun tó máa mú kí ìpọ́njú ọ̀hún dín kù, bíi lílo ọgbọ́n láti yẹra fún àwọn aninilára. Bí àpẹẹrẹ, gbígbé tí Dáfídì gbára lé Jèhófà àti akitiyan tóun fúnra rẹ̀ ṣe ló ràn án lọ́wọ́ láti fara da àwọn ìṣòro tó ní. Àwa náà ńkọ́ lónìí?
Nígbà tó o bá wà nínú ìpọ́njú, ìwọ́ náà lè lo ìdánúṣe láti yanjú ìṣòro rẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí o kò bá níṣẹ́ lọ́wọ́, ṣé o ò ní sapá gidigidi láti wáṣẹ́ tó dáa tí wàá lè máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ àti ìdílé rẹ? (1 Tímótì 5:8) Tàbí àìsàn kan ló ń yọ ọ́ lẹ́nu, ṣé o ò ní lọ wá ìtọ́jú tó péye lọ́dọ̀ oníṣègùn? Kódà, Jésù pàápàá tí Ọlọ́run fún lágbára tó lè fi wo onírúuru àìsàn sàn, sọ pé ‘àwọn tí ń ṣòjòjò nílò oníṣègùn.’ (Mátíù 9:12) Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣòro rẹ lè má yanjú tán lẹ́ẹ̀kan; ó lè gba pé kó o ṣì máa fara dà á títí dé ìwọ̀n àyè kan.
Tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run nípa ọ̀ràn náà ńkọ́? Bí àpẹẹrẹ, gbígbáralé Ọlọ́run àti gbígbàdúrà sí i nígbà tá à ń wáṣẹ́ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìdẹwò èyíkéyìí tá ò fi ní tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí kò bá ìlànà Bíbélì mu. A ó sì tún yẹra fún ẹ̀mí ìwọra tàbí ìfẹ́ owó kó má bàa mú wa “ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni o, tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó kan iṣẹ́, ìdílé tàbí ìlera, a lè tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú Dáfídì pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.
Àdúrà àtọkànwá yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìrònú wa já gaara, kí ìpọ́njú wa má bàa mú ọkàn wa pòrúurùu. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni kọ̀wé pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Ọ̀nà wo ní àdúrà àtọkànwá lè gbà tù wá nínú? “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Àlàáfíà Ọlọ́run “ta gbogbo ìrònú yọ.” Nítorí náà, yóò mú ká lè mẹ́sẹ̀ dúró tí àwọn nǹkan tó ń ko ìdààmú bá wa bá pọ̀ jù. Yóò ‘ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa,’ èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe máa kù gììrì ṣe nǹkan tàbí ká máa hùwà àìlọ́gbọ́n tó lè dá kún ìpọ́njú wa.
Àdúrà lè nípa lórí ohun tó máa jẹ́ àbájáde ọ̀ràn kan. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n ní Róòmù, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún òun. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ní kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀? Ó kọ̀wé sí wọn pé: “Mo gbà yín níyànjú pàápàá jù lọ láti ṣe èyí, kí a lè tètè mú mi padà bọ̀ sípò sọ́dọ̀ yín.” (Hébérù 13:19) Lédè mìíràn, Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé dídáhùn tí Jèhófà bá dáhùn àdúrà tí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ń gbà láìsinmi lè nípa lórí ìgbà tí wọ́n máa dá òun sílẹ̀.—Fílémónì 22.
Ǹjẹ́ àdúrà lè yí ohun tó máa jẹ́ àbájáde ìpọ́njú wa padà? Ó kúkú lè yí i padà. Síbẹ̀, ó yẹ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run lè máà dáhùn àdúrà wa lọ́nà tá a fẹ́ kó gbà dáhùn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà nítorí ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ rẹ̀, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro àìlera. Àmọ́, dípò tí Ọlọ́run á fi mú ìpọ́njú náà kúrò, ó sọ fún Pọ́ọ̀lù pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.”—2 Kọ́ríńtì 12:7-9.
Èyí fi hàn pé ìpọ́njú wa lè máà kúrò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n, èyí a fún wa láǹfààní láti fi hàn pé lóòótọ́ la gbára lé Baba wa ọ̀run. (Jákọ́bù 1:2-4) Kí ó dá wa lójú pé bí Jèhófà Ọlọ́run ò bá tiẹ̀ mú ìpọ́njú náà kúrò, ó lè “ṣe ọ̀nà àbájáde kí [á] lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ó yẹ fún àfiyèsí pé Bíbélì pe Jèhófà ní “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, . . . tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Ọlọ́run lè fún wa ní ohun tá a nílò láti fara dà á, iye àìnípẹ̀kun tá à ń retí sì tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Bíbélì tí i ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèlérí pé Jèhófà “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Lójú tìrẹ, ǹjẹ́ ayé kan tí ìpọ́njú ò ti ní sí jọ ohun tí kò lè ṣeé ṣe? Ó lè rí bẹ́ẹ̀ lójú rẹ tó bá jẹ́ pé ńṣe lò ń tinú ìpọ́njú kan bọ́ sínú òmíràn. Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run ṣèlérí pé a óò bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àti àjálù, ó sì dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣẹ.—Aísáyà 55:10, 11.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Látinú ìbànújẹ́ sínú ìtura