Jèhófà Máa Ń gba Àwọn Tó Wà Nínú Ìpọ́njú Sílẹ̀
“Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo, ṣùgbọ́n Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.”—SÁÀMÙ 34:19.
1, 2. Ìṣòro wo ni arábìnrin olóòótọ́ kan ní, báwo la sì ṣe mọ̀ pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin yìí lè ṣẹlẹ̀ sí wa?
Ó TI lé lógún ọdún tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Keikoa ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákòókò kan, ó ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn ni pé ó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó sì mọyì iṣẹ́ ìsìn yìí gan-an ni. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a nítorí pé ó ti ro ara ẹ̀ pin àti nítorí ó rò pé wọ́n ti pa òun tì. Ó sọ pé: “Ẹkún ni mò ń sun ṣáá.” Kí Keiko lè mú èrò òdì yìí kúrò lọ́kàn, ó túbọ̀ tẹra mọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì. Àmọ́, ó ní: “Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, ìṣòro ọ̀hún ò yanjú. Kódà, ìrẹ̀wẹ̀sì náà wá pọ̀ débi pé ayé sú mi.”
2 Ǹjẹ́ ohun tó ṣe arábìnrin yẹn ti ṣe ìwọ náà rí? Níwọ̀n bó o ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó máa múnú rẹ dùn, nítorí pé ìfọkànsìn Ọlọ́run “ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí àti ti èyí tí ń bọ̀.” (1 Tímótì 4:8) Ó ṣe tán, inú Párádísè tẹ̀mí lo wà nísinsìnyí! Àmọ́, ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé o ti bọ́ nínú ìṣòro ni? Rárá o! Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ni ìyọnu àjálù olódodo.” (Sáàmù 34:19) Èyí ò yani lẹ́nu nítorí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” Sátánì Èṣù. (1 Jòhánù 5:19) Gbogbo wa pátá ni ìṣàkóso Sátánì sì ń ni lára lọ́nà kan tàbí òmíràn.—Éfésù 6:12.
Àwọn Ohun Tí Ìpọ́njú Máa Ń Fà
3. Mẹ́nu kan àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan nínú Bíbélì tí wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà.
3 Tí ìpọ́njú tàbí ẹ̀dùn ọkàn bá pàpọ̀jù, ó lè jẹ́ kí ayé súni. (Òwe 15:15) Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù, ọkùnrin adúróṣinṣin náà. Inú ìpọ́njú ńláǹlà ló ti sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Jóòbù wá dẹni tí ò láyọ̀ mọ́. Nígbà tó tiẹ̀ wá dójú ẹ̀, ó rò pé ńṣe ni Jèhófà ti pa òun tì. (Jóòbù 29:1-5) Àmọ́, Jóòbù nìkan kọ́ ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó bára ẹ̀ nínú ìpọ́njú tó lékenkà. Bíbélì sọ fún wa pé Hánà ní “ìkorò ọkàn” nítorí àìrọ́mọbí. (1 Sámúẹ́lì 1:9-11) Rèbékà náà tí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ̀ kó ẹ̀dùn ọkàn bá sọ pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí.” (Jẹ́nẹ́sísì 27:46) Nígbà tí Dáfídì ń ronú nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ni mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́.” (Sáàmù 38:6) Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ wọ̀nyí fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó gbé ayé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé ní ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà.
4. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé àwọn Kristẹni kan lóde òní wà lára “àwọn ọkàn tí ó soríkọ́”?
4 Àwọn Kristẹni ńkọ́? Àwọn náà máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ fáwọn ará Tẹsalóníkà pé kí wọ́n “máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.”(1 Tẹsalóníkà 5:14) Ìwé kan sọ pé a lè lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” fún àwọn “tí àníyàn ìgbésí ayé wọ̀ lọ́rùn fúngbà díẹ̀.” Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí fi hàn pé àwọn kan lára àwọn ẹni àmì òróró tó wà ní ìjọ Tẹsalóníkà sorí kọ́. Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ ṣe rí fáwọn Kristẹni kan lónìí. Àmọ́ kí ló ń mú kí wọ́n sorí kọ́? Ẹ jẹ́ ká gbé ohun mẹ́ta tó sábà máa ń fà á yẹ̀ wò.
Ẹ̀dá Ẹlẹ́ṣẹ̀ Tá A Jẹ́ Lè Fa Ìsoríkọ́
5, 6. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ló wà nínú Róòmù 7:22-25?
5 Ó máa ń dun àwọn Kristẹni tòótọ́ pé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, wọn ò dà bí àwọn oníwàkiwà èèyàn tí wọ́n ti “ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere.” (Éfésù 4:19 ) Nígbà míì, àwọn Kristẹni wọ̀nyí lè ní irú èrò tí Pọ́ọ̀lù ní, ẹni tó kọ̀wé pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ èyí tán, ó ní: “Èmi abòṣì ènìyàn!”—Róòmù 7:22-24.
6 Ǹjẹ́ ohun tó ṣe Pọ́ọ̀lù yìí ti ṣe ọ́ rí? Kò sóhun tó burú tó o bá ń ronú nípa jíjẹ́ tó o jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí èyí lè jẹ́ kó o túbọ̀ mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ kì í ṣe nǹkan kékeré, kó o sì túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ pé o ò ní gba ìwàkiwà láyè. Àmọ́ kì í ṣe pé kó o kúkú wá máa banú jẹ́ ní gbogbo ìgbà nítorí àwọn àṣìṣe rẹ o. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ tó bà á nínú jẹ́ tá a fà yọ lẹ́ẹ̀kan, ó ní: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Bẹ́ẹ̀ ni, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé ẹ̀jẹ̀ Jésù táwọn èèyàn ta sílẹ̀ lè ra òun padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tóun ti jogún.—Róòmù 5:18.
7. Kí ni kò ní jẹ́ kí ẹnì kan máa soríkọ́ nítorí jíjẹ́ tó jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀?
7 Tí ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ tó o jẹ́ bá ń mú kó o soríkọ́, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù lè tù ọ́ nínú. Ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Tó o bá ní ẹ̀dùn ọkàn nítorí jíjẹ́ tó o jẹ́ ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, máa rántí pé àwọn ẹni pípé kọ́ ni Jésù kú fún bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23.
8, 9. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi?
8 Àmọ́, ká sọ pé nígbà kan rí, o dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan. Ó dájú pé wàá ti gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, bóyá lọ́pọ̀ ìgbà pàápàá. Wàá ti lọ bá àwọn alàgbà ìjọ kí wọ́n lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Jákọ́bù 5:14, 15) Wàá sì ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn, ìdí nìyẹn tó o ṣì fi jẹ́ akéde ìjọ. Tàbí kẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti fìgbà kan rí kúrò nínú ètò Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tó yá o ronú pìwà dà, o sì dẹni tó tún ń ṣe dáadáa nínú ìjọ. Èyí ó wù ó jẹ́ nínú méjèèjì, o lè máa ronú nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó o ti dá nígbà kan rí yìí, èyí sì lè máa kó ìdààmú ọkàn bá ọ. Tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, rántí pé Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn “lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:7) Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run ò fẹ́ kó o ro ara rẹ pin, pé o ò wúlò mọ́. Ohun tí Sátánì ń fẹ́ nìyẹn, torí ó mọ̀ pé irú èrò bẹ́ẹ̀ lè ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́. (2 Kọ́ríńtì 2:7, 10, 11) Ọlọ́run máa pa Èṣù run nítorí ìparun tọ́ sí i, àmọ́ Èṣù á fẹ́ kó o máa rò pé ńṣe ni ìwọ náà máa pa run. (Ìṣípayá 20:10) Má ṣe jẹ́ kí Sátánì fi èyí ba ìgbàgbọ́ rẹ jẹ́ o. (Éfésù 6:11) Dípò ìyẹn, ńṣe ni kó o “mú ìdúró [rẹ] lòdì sí i,” gẹ́gẹ́ bó o ṣe ń dènà rẹ̀ láwọn ọ̀nà míì.—1 Pétérù 5:9.
9 Ìṣípayá 12:10 pe Sátánì ní “olùfisùn àwọn arákùnrin wa,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. Ó ń “fẹ̀sùn kàn wọ́n tọ̀sán-tòru” níwájú Ọlọ́run. Tó o bá ronú lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, wàá rí i pé inú Sátánì, ẹni tí ń fẹ̀sùn èké kanni, yóò dùn tó o bá ń ka ẹ̀sùn sí ara rẹ lọ́rùn tàbí tó ò ń dá ara rẹ lẹ́bi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ò dá ọ lẹ́bi. (1 Jòhánù 3:19-22) Ǹjẹ́ ó yẹ kí àṣìṣe rẹ máa dà ọ́ láàmú débi tí wàá fi sọ pé o fẹ́ ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run? Má gba Sátánì láyè láti ba àjọṣe rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Má ṣe jẹ́ kó mú ọ gbàgbé pé Jèhófà jẹ́ ‘aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ẹni tó ń lọ́ra láti bínú, tó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.’—Ẹ́kísódù 34:6.
Ìrẹ̀wẹ̀sì Lè Bá Wa Tá Ò Bá Lè Ṣe Tó Bá A Ṣe Fẹ́
10. Àwọn nǹkan wo ló lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa?
10 Àwọn Kristẹni kan ti rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé wọn ò lágbára láti ṣe bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Ṣé bí ọ̀rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn? Ó lè jẹ́ àìsàn líle, ọjọ́ ogbó, tàbí àwọn nǹkan míì ni ò jẹ́ kó o lè máa lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù bíi ti tẹ́lẹ̀. Lóòótọ́, Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká ra àkókò padà láti fi ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. (Éfésù 5:15, 16) Ṣùgbọ́n, táwọn nǹkan kan bá wà lóòótọ́ tí ò jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe fẹ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, tí èyí sì ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ ńkọ́?
11. Báwo ni ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù tó wà nínú Gálátíà 6:4 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
11 Bíbélì rọ̀ wá pé ká má ṣe jẹ́ onílọ̀ọ́ra, àmọ́ ká “jẹ́ aláfarawé àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí náà.” (Hébérù 6:12) Ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà ṣe èyí ni pé ká gbé àpẹẹrẹ rere irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ká sì gbìyànjú láti ní irú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní. Àmọ́ ṣá o, kò ní ṣe wá lóore kankan tá a bá lọ ń fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì lọ́nà tí kò bójú mu, tá a sì ń ronú pé ohun tá à ń ṣe kò tó. Torí náà, á dára ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún wa pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 6:4.
12. Kí nìdí tó fi yẹ kí iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà máa múnú wa dùn?
12 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó yẹ kó máa múnú àwa Kristẹni dùn, àní bí àìlera kò bá tiẹ̀ jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 6:10) Ipò nǹkan tó kọjá agbára rẹ lè má jẹ́ kó o lè ṣe tó bó o ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, o ṣì lè túbọ̀ kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù láwọn ọ̀nà mìíràn, irú bíi fífi tẹlifóònù tàbí lẹ́tà wàásù. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà Ọlọ́run yóò bù kún ọ bó o ṣe ń fi tọkàntọkàn sìn ín àti nítorí ìfẹ́ tó o ní sí i àti sáwọn èèyàn.—Mátíù 22:36-40.
“Àwọn Àkókò Lílekoko” Yìí Lè Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Wa
13, 14. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni “àwọn àkókò lílekoko” yìí lè gbà kó ìpọ́njú báni? (b) Kí ló fi hàn pé kò sí ìfẹ́ láàárín ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní?
13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń fojú sọ́nà láti gbádùn ìwàláàyè nínú ayé tuntun òdodo Ọlọ́run, síbẹ̀ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la ṣì ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Àwọn nǹkan tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni tó ń ṣẹlẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé a ò ní pẹ́ bọ́, èyí sì jẹ́ ìtùnú fún wa. Àmọ́ ṣá, àwọn ìṣòro wọ̀nyí kan àwa náà. Bí àpẹẹrẹ, báwo ni ìṣòro wọ̀nyí ṣe lè kàn ọ́ tó ò bá níṣẹ́ lọ́wọ́? O lè wáṣẹ́ títí kó o máà rí, bí ọjọ́ sì ṣe ń gorí ọjọ́, o lè máa ronú pé bóyá ni Jèhófà rí ìyà tó ń jẹ ọ́ tàbí pé bóyá ló gbọ́ àdúrà rẹ. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe làwọn kan ń ṣe kèéta rẹ tàbí kí wọ́n máa hùwà àìdáa sí ọ. Kódà, àwọn àkọlé ìwé ìròyìn lè kó ìdààmú ọkàn bá ọ bíi ti Lọ́ọ̀tì tí ìwà àìníjàánu àwọn èèyàn tó yí i ká “kó wàhálà-ọkàn . . . gidigidi” bá.—2 Pétérù 2:7.
14 Ohun kan tún wà tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí tá ò lè gbójú fò. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn yóò jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:3) Kò sí ìfẹ́ nínú ọ̀pọ̀ ìdílé. Ìwé Family Violence sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé kò wọ́pọ̀ kẹ́nì kan wá láti ìta láti wá gbẹ̀mí èèyàn, láti wá báni jà, láti wá ṣe ohun tó máa kó ẹ̀dùn ọkàn báni tàbí láti wá báni ṣèṣekúṣe bíi kẹ́ni kan ṣe é fáwọn tí wọ́n jọ wà nínú ìdílé kan náà. Inú ìdílé tó yẹ kó jẹ́ ibi táwọn èèyàn yóò ti rẹ́ni tó máa fi ìfẹ́ bá wọn lò, tó sì yẹ kó jẹ́ ibi ààbò ló wá di ibi eléwu jù lọ báyìí fáwọn àgbàlagbà àtàwọn ọmọdé kan.” Nígbà táwọn tó gbé nírú ilé tí ìwàkiwà kúnnú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá dàgbà, àníyàn lè gbà wọ́n lọ́kàn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ro ara wọn pin. Tó bá jẹ́ pé irú nǹkan báyìí lò ń fojú winá rẹ̀ ńkọ́?
15. Kí ló mú kí ìfẹ́ Jèhófà ju ti òbí èyíkéyìí lọ?
15 Onísáàmù náà Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Ohun ìtùnú gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ju èyí tí òbí èyíkéyìí lè ní sí ọmọ rẹ̀ lọ! Òótọ́ ni pé yóò dùn ọ́ gan-an táwọn òbí rẹ bá kọ̀ ẹ́ sílẹ̀, tàbí tí wọ́n bá ṣàìdáa sí ọ tàbí tí wọ́n pa ọ́ tì, àmọ́ jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà ṣì bìkítà fún ọ. (Róòmù 8:38, 39) Rántí pé àwọn tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ló máa ń fà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. (Jòhánù 3:16; 6:44) Láìka ohun táwọn èèyàn lè máa fojú ẹ rí, mọ̀ dájú pé Bàbá rẹ ọ̀run nífẹ̀ẹ́ rẹ!
Àwọn Ohun Tá A Lè Ṣe Láti Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì
16, 17. Tẹ́nì kan bá rẹ̀wẹ̀sì, kí lonítọ̀hún lè ṣe kó bàa lè lókun nípa tẹ̀mí?
16 Àwọn ohun kan wà tó o lè ṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì ò fi ní bò ọ́ mọ́lẹ̀. Lára wọn ni pé kó o máa kópa nínú gbogbo ìgbòkègbodò àwa Kristẹni déédéé. Máa ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì ọ̀hún bá fẹ́ pàpọ̀jù. Onísáàmù kan kọ ọ́ lórin pé: “Nígbà tí mo wí pé: ‘Ṣe ni ẹsẹ̀ mi yóò máa rìn tàgétàgé,’ Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró. Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sáàmù 94:18, 19) Tó o bá tún ń ka Bíbélì déédéé, wàá rí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tó ń tuni nínú tó sì ń gbéni ró.
17 Àdúrà gbígbà tún ṣe pàtàkì. Bó ò bá tiẹ̀ lè sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára rẹ gan-an, Jèhófà mọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn rẹ. (Róòmù 8:26, 27) Onísáàmù kan sọ ọ̀rọ̀ kan tó fọkàn ẹni balẹ̀, ó ní: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.”—Sáàmù 55:22.
18. Kí làwọn ohun tẹ́ni tó bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn lè ṣe?
18 Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn tó lékenkà ti mú káwọn kan ro ara wọn pin.b Tó o bá wà nírú ipò yẹn, gbìyànjú láti máa ronú nípa ayé tuntun Ọlọ́run níbi tí “kò [ti ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Àmọ́ ṣá o, tí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn rẹ bá ń ṣe lemọ́lemọ́, á dáa kó o lọ rí dókítà. (Mátíù 9:12) Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o tọ́jú ara rẹ dáadáa. Máa jẹ oúnjẹ tó ń ṣara lóore, kó o sì máa ṣe eré ìmárale. Rí i dájú pé ò ń fún ara rẹ ní ìsinmi tó tó. Má ṣe máa wo tẹlifíṣọ̀n títí di ọ̀gànjọ́ òru, má sì máa ṣe eré ìmárale tó máa tán ọ lókun pátápátá. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tínú Ọlọ́run dùn sí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì tó àkókò tí Jèhófà máa “nu omijé gbogbo nù kúrò,” síbẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara dà á.—Ìṣípayá 21:4; 1 Kọ́ríńtì 10:13 .
Bí A Ṣe Lè Wà “Lábẹ́ Ọwọ́ Agbára Ńlá Ọlọ́run”
19. Kí ni Jèhófà ṣèlérí fáwọn tó wà nínú ìpọ́njú?
19 Bíbélì fi dá wa lójú pé bí àjálù olódodo tilẹ̀ pọ̀, “Jèhófà ń dá a nídè nínú gbogbo wọn.” (Sáàmù 34:19) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń ṣe èyí? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbàdúrà sí Ọlọ́run léraléra pé kó mú ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ òun kúrò, Jèhófà sọ fún un pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” (2 Kọ́ríńtì 12:7-9) Kí ni Jèhófà ń ṣèlérí fún Pọ́ọ̀lù níbí yìí, kí ló sì ṣèlérí fún ìwọ náà? Ìwòsàn ojú ẹsẹ̀ kọ́ ni Ọlọ́run ṣèlérí bí kò ṣe agbára láti lè fara dà á.
20. Láìka àdánwò tá a lè ní sí, kí ni 1 Pétérù 5:6, 7 fi dá wa lójú?
20 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run, kí ó lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.” (1 Pétérù 5:6, 7) Nítorí pé Jèhófà bìkítà fún ọ, kì yóò pa ọ́ tì láé. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láìka àdánwò tó o lè ní sí. Má gbàgbé pé àwọn Kristẹni olóòótọ́ wà “lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run.” Bá a ṣe ń sin Jèhófà, yóò máa fún wa lókun láti fara dà á. Tá a bá sì jẹ́ olóòótọ́ sí i, kò sóhun tó máa lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ lọ́nàkọnà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ká bàa lè ní ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tó ṣèlérí, ká sì lè rí ọjọ́ náà tí yóò mú ìpọ́njú àwọn èèyàn kúrò títí láé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
b Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ju ìrẹ̀wẹ̀sì lásán lọ. Irú ìrẹ̀wẹ̀sì yìí máa ń le gan-an, ó sì máa ń pẹ́ kó tó lọ lára èèyàn. Àlàyé síwájú sí i lórí ọ̀rọ̀ yìí wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà October 15, 1988, ojú ìwé 25 sí 29; November 15, 1988, ojú ìwé 21 sí 24; àti Ilé Ìṣọ́ September 1, 1996, ojú ìwé 30 sí 31.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà náà fi ń rí ìpọ́njú?
• Kí làwọn nǹkan tó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn Ọlọ́run?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ohun tó ń mú ká ṣàníyàn?
• Báwo la ṣe lè wà “lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run”?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Bí àwọn èèyàn Jèhófà tiẹ̀ ń rí ìpọ́njú, ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń fún wọn láyọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Fífi tẹlifóònù wàásù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà